ÌJỌ ÀPỌ́SÍTÉLÌ KRISTI, Ẹ̀KỌ́ ILÉ-Ẹ̀KỌ́ ỌJỌ́ ÌSINMI September 2, 2018 : Ẹ̀KỌ́ KẸRIN - FIFẸ ỌLỌ́RUN NÍ ÀWỌN ASIKO TI O LEWU

--> Note :- Are you born again? You are never going to win the battle against the devil if you are not born again. I plead with you to give your life to Jesus today because the longer you stay in sin and remain unsaved, the more hardened your nature becomes against the purpose and the way God wants you to be for His purpose. To give your life to Jesus now, say this prayer: “Father, I come to You in the name of Jesus. I know that I am a sinner and I cannot save myself but Jesus died for me and shed His blood that I might be saved. Today, I accept Jesus as my Lord and Saviour. Jesus, I ask You to come into my heart, be my Lord, wash me with Your blood and make me whole. I believe with my heart and confess with my mouth that Jesus is my Lord. Thank You for saving me. In Jesus' name I pray. Amen.” I congratulate you and welcome you to the family of God if you have sincerely said that prayer. Now you are fit to discover, know and walk in your destiny. Call our helpline on +2348037252124, Join Our Daily Whatsapp Devotionals Group : +2347033046607 for Daily Devotionals, crucial discipleship and counselling.s"
ÌJỌ ÀPỌ́SÍTÉLÌ KRISTI, Ẹ̀KỌ́ ILÉ-Ẹ̀KỌ́ ỌJỌ́ ÌSINMI  September 2, 2018 : Ẹ̀KỌ́ KẸRIN - FIFẸ ỌLỌ́RUN NÍ ÀWỌN ASIKO TI O LEWU



ÌJỌ ÀPỌ́SÍTÉLÌ KRISTI
Ẹ̀KỌ́ ILÉ-Ẹ̀KỌ́ ỌJỌ́ ÌSINMI
September 2, 2018.

Ẹ̀KỌ́ KẸRIN
FIFẸ ỌLỌ́RUN NÍ ÀWỌN ASIKO TI O LEWU

Jobu ri wàhálà nlá, síbẹ̀ o yàn lati fẹ Oluwa titi de òpin. Igbẹyin ologo rẹ pè wá nija lati fẹ́ràn Jesu, bi ipenija aye tilẹ wa.


AKỌSÓRÍ

Sa wo o, awa a maa ka awọn ti o farada iya si ẹni ibukun, ẹyin ti gbọ ti suuru Jobu, ẹyin si ri igbẹyin ti Oluwa se, pe Oluwa kun fun ìyọnu O sì ni aanu (Jákọ́bù 5:11)

ÀLÀYÉ KÚKÚRÚ

A gbọ́dọ̀ ni ìfaradà bẹẹni a sì gbọdọ ni sùúrù bi i Jobu. Ohun tí a n reti ni pe a gbọdọ ni ìfaradà bii Jobu ni akoko ijiya ati idanwo. Ni akoko Idanwo Jobu rii pe Ọlọ́run kun fun ọpọlọpọ aanu bí ó-tilẹ̀-jẹpe o jiya gidigidi ti o si padanu gbogbo ohun ini rẹ, ẹran ọ̀sìn, àwọn òṣìṣẹ́ ni àjálù nla, o pàdánù gbogbo ọmọ rẹ nínú ijanba. Ni àfikún si gbogbo nnkan wọ̀nyii, ìyàwó rẹ bínú sii nítorí pe o kọ lati ṣẹ Ọlọ́run fun mimu ìparun ba ayé wọn. Jobu kò jẹ ki idanwo ki o bori oun. Ko sẹ igbagbọ rẹ nínú Ọlọ́run. Bí ó-tilẹ̀-jẹ́ pé ko mọ ohun ti o n ṣẹlẹ̀ si oun, o kọ lati lodi si Ọlọ́run.

Nítorí naa awọn onigbagbọ gbọ́dọ̀ farada ìpọ́njú, ipelẹjọ́ àti idanwo nípa gbígbé ojú wọn si ara Olúwa. A gbọdọ jẹ lóòótọ́ nínú inúnibíni ki àwọn ti wọn n bọ lẹ́yìn wa baa le pe wa ni olóòótọ́ ki wọn o si jeere irúlọ́kàn soke nítorí igbagbọ wa pe ohun gbogbo yoo wa si opin. Ifarada Jobu lati inu àdánù kan si ikejì fun akoko kan, síbẹ̀ o jẹ olóòótọ́ nipa gbígbẹkẹle Ọlọ́run pe yoo pa oun mọ. Ìrètí àwọn olododo ni pe, a o gba wọn ninu inúnibíni aye yii.

Aposteli Jacobu sọ̀rọ̀ láti inú imisi pe gbogbo àwọn ti wọn ba farada inúnibíni ti wọn si yan lati fẹ Ọlọ́run ni àwọn àkókò elewu; ni aye ati ọrun ka si alábùkún fun, alábùkún nítorí pe oore-ọ̀fẹ́ Ọlọ́run ati aanu Rẹ ni a o fí han si wọn laye yii àti ni ayérayé. Wọn le maa jiya bayii, ṣùgbọ́n níkẹyìn wọn yoo rẹrìn.

ÀṢÀRÒ FÚN ÌFỌKÀNSÌN

1.   Bi o ti wu ki nnkan o le to ifẹ fun Ọlọ́run kii dinku; ni tootọ ti olódodo ba n jìyà, fun ogo Ọlọ́run ni.
2.   Ọlọ́run setan láti mu wa la idanwo kọjá, nípa bibukun wa pẹlu ìwàláàyè Rẹ, ìyọnu àti àánú. Ki a tẹjúmọ Ọlọ́run fun itusilẹ pátápátá, ki a si jẹ olóòótọ́.

ẸSẸ BÍBÉLÌ FUN ÌPÍNLẸ̀ Ẹ̀KỌ́ : I Pétérù 2:18-20; 3:17

ILÉPA ÀTI ERONGBA

ILÉPA:   lati safihan bi Ọlọ́run ṣe n fun àwọn ènìyàn Rẹ ti wọn ba duro fun Un ni akoko idanwo ni itusilẹ pátápátá.

ÀWỌN ERONGBA:   Ni opin ẹ̀kọ́ yii, a n reti pe ki àwọn akẹ́kọ̀ọ́ gbọdọ lee:
i.   ṣàlàyé awọn ẹkọ ti o nitumọ lati inu idanwo Jobu.
ii.   safihan pàtàkì jíjẹ lóòótọ́ àti olódodo níwájú Ọlọ́run.
iii.  ṣàlàyé pe bio-ti-wu ki ipenija aye o le to, a ko gbọ́dọ̀ fi òrìṣà rọ́pò Ọlọ́run wa.
iv.   sọ pe Ọlọ́run kan ṣoṣo ni o n bẹ, Ẹniti o ni àgbàrá tí kii sakii láti gba awọn olódodo la àti tu wọn silẹ.

IFAARA
ORÍSUN Ẹ̀KỌ́:  JOBU 1:2; 2 A. ỌBA 5:1 SIWAJU SII.
A dupẹ lọwọ Ọlọ́run ti o mu wa la ẹ̀kọ́ kẹta ja. IFẸ JÒSÁYÀ FÚN ỌLỌ́RUN, níbi ti a ti kọ wa nipa ọkùnrin ti o se ohun ti o yatọ ni akoko tìrẹ gẹ́gẹ́bí ọba Juda. Eso àsọtẹ́lẹ̀, Jòsáyà fẹ́ràn Ọlọ́run bẹẹni o sì sìn Ọlọ́run débi pe o wo àwọn ibi gíga òrìṣà ti àwọn bàbà rẹ gbe kalẹ lulẹ. A tun kọ nípa bi o se mu àwọn miran wa sinu iwa mimọ, o ṣàwárí ọrọ naa. Bẹẹni o si mu awọn eniyan rẹ wa sinu isin tòótọ́ si Yahweh. O duro grgegbe, bi o tilẹ̀-jẹ́pé aiwa-bi-Olorun asiko (ìran) rẹ kan. Ìrètí wa ni pe a ko ni ya kuro ninu awọn ẹkọ wọ̀nyí.

Ọṣẹ yii ati ọ̀sẹ̀ ti o n bọ nípa ọrẹ-ọ̀fẹ́ Ọlọ́run, ni a o fi wo ẹ̀kọ́ kẹrin ti àkọlé rẹ jẹ́ FIFẸ ỌLỌ́RUN NI ÀSÌKÒ TÍ O LEWU. Ẹ̀kọ́ yii yoo ṣàlàyé ìtàn ifẹ Jobu, ìpọ́njú ati imubọslipo rẹ. A o wo ọkùnrin ọlọ́rọ̀ tí o jẹ ẹni ìdúróṣinṣin tí ó si bẹru Ọlọ́run, a dan an wo pẹlu ìpọ́njú, bẹẹni o si pàdánù ohun gbogbo tí o ní, ṣùgbọ́n ko pàdánù Ọlọ́run. Jobu gba pe ko si ohun ti yoo mu ki oun ṣẹ si Ọlọ́run, ìmọ̀ràn àwọn ọrẹ rẹ ko le mú ṣẹ si Ọlọ́run. Níkẹyìn, a mu un padà bọsipo ni ọna ìlọ́po meji.

Ipin kejì sọ̀rọ̀ nípa ìránṣẹ́bìnrin iyawo Náámánì àti ìfẹ́ rẹ̀ fún Ọlọ́run ní oko ẹrù. Ipo ti o wa ko mu ki o gbàgbé Ọlọ́run Ísírẹ́lì bẹẹni ko si di oju rẹ si ìpọ́njú ọga rẹ, ṣùgbọ́n o ni ìgbẹ́kẹ̀lé ninu Ọlọ́run rẹ fun itusilẹ. Ifẹ ọmọbìnrin naa fun Ọlọ́run tan de ọdọ ọga rẹ, ó sì mú ògo kiakia àti ayérayé ba Ọlọ́run.

A gbàdúrà ki oore-ọ̀fẹ́ láti fẹ Ọlọ́run, ni asiko ti o lewu ki o ba le wa bi a ti n lọ nínú ẹ̀kọ́ ọ̀sẹ̀ méjì yìí ni orúkọ Jésù. Àmín.

IFAARA SI ÌPÍN KỌ̀Ọ̀KAN :
A pín ẹ̀kọ́ yii si ìpín méjì I ati II pẹlu atunpin si A ati B.

ÌPÍN KÍNNÍ: JOBU RỌ MỌ ỌLỌ́RUN

Ipín yii jẹ ki a mọ pe nígbà ti Jobu n la ìpọ́njú nla kọjá, o fi ara rẹ han gẹgẹ bi olóótọ́ ati olódodo ènìyàn. O fi han kedere pe oun fẹ́ràn Ọlọ́run, Jobu ko pada sẹ́yìn ko gba ki idanwo gba ipo Ọlọ́run ninu aye oun ko kọ igbagbọ rẹ ninu Ọlọ́run silẹ. Nítorí ìgbàgbọ́ Jobu nínú Ọlọ́run, Ọlọ́run sì mú ki o laa ja. Ìwàláàyè Ọlọ́run wa pẹ̀lú Jobu ni gbogbo ọjọ aye rẹ. O gbadun aanu Ọlọ́run Jobu ni gbogbo ọjọ aye rẹ. Ìwàláàyè Ọlọ́run gba Jobu pẹlu ìwàláàyè Rẹ kúrò nínú idanwo ayé, bẹẹni O sì fun Jobu ni igbe àṣẹgùn ti a fojuri. Nítorí pe Jobu jẹ olóótọ́ nínú ìpọ́njú.

ÌPÍN KEJÌ: ÌRÁNṢẸ́-BÌNRIN ÌYÀWÓ NÁÁMÁNÌ

Ipin yii sọ̀rọ̀ lori ìránṣẹ́bìnrin aya Náámánì, ọmọbìnrin Hébérù ẹniti o fi Ọlọ́run Yahweh han iya rẹ (ọga). Ìránṣẹ́bìnrin Náámánì o jẹ ọmọ Ísírẹ́lì ti wọn mu wa lati ilu ati ile rẹ wa. Bíó-tilẹ̀-jẹ́pé oun jẹ ẹrù, o fẹ́ràn Yahweh, Ọlọ́run àwọn obi rẹ. Wọn fun ọmọ yii ni ẹkọ rere ni ilu ìbílẹ̀ rẹ o si mu ifẹ ti o ni si Ọlọ́run tọ ọga rẹ lọ. Igbagbọ ọmọbìnrin kékeré yii wa ọna àbáyọ si arun ẹtẹ Náámánì. Ìgbàgbọ́ rẹ yọrísí ìyípadà Náámánì.

KOKO Ẹ̀KỌ́

I.    JOBU RỌMỌ ỌLỌ́RUN RẸ
      A.   A DAN AN WO, PẸLU BI O TI JẸ ẸNI ÌDÚRÓṢINṢIN
      B.   O GBẸKẸLE IFẸ ỌLỌ́RUN NINU GBOGBO RẸ

II.    ÌRÁNṢẸ́-BÌNRIN ÌYÀWÓ NÁÁMÁNÌ
       A.   O FẸ́ RAN ỌLỌ́RUN NÍ IPO ẸRÚ TI O WA
       B.   O FI IFẸ ỌLỌ́RUN HAN SI NÁÁMÁNÌ.

ITUPALẸ Ẹ̀KỌ́

September 2, 2018. | I.  JOBU RỌMỌ ỌLỌ́RUN RẸ (Job 1:1-2:10; 16:1 síwájú sii)
Àwọn onigbagbọ ni lati farada ìpọ́njú idanwo Nípa gbigboju wọn sara Ọlọ́run. A gbọ́dọ̀ ni suuru ìpọ́njú. Bii Jobu ninu idanwo nítorí Ọlọ́run wa kun fun aanu.

A.   A DAN AN WO PẸLU BI O TI JẸ ẸNI ÌDÚRÓṢINṢIN (1:1-2:8).
Njẹ na ọwọ rẹ nisinsin yii, ki o si fi tọ ohun gbogbo ti o ni, bi ki yoo si bọ́hùn ni oju Rẹ (1:11).
i.    Ẹsẹ 1-3: Jobu jẹ ẹni ìdúró-ṣinṣin, eyi ni pe o fi irẹlẹ fẹ́ràn Ọlọ́run, bẹẹni o sì gbọ́ràn si Ọlọ́run lẹ́nu de ìkòríta ti Ọlọrun fi n fi ọwọ rẹ sọ aya (ẹsẹ 8). Abájọ ti Ọlọrun fi da ibukun nla Rẹ lu u (ẹsẹ 2,3; wo Owe 10:22). Bawo ni Ọlọ́run ṣe ri ọ si?
ii.   Ẹsẹ 4,5: Ifẹ Jobu si Ọlọ́run ran àwọn ọmọ rẹ ti wọn kórajọpọ pẹlu ara wọn nínú ìfẹ́, ní ilé olúkúlùkù wọn nígbà tí ó ba ti kan wọn (ẹsẹ 4). A dupẹ lọ́wọ́ baba wọn fun sisakoso wọn pẹlu ìjọsìn (ẹsẹ 5).
iii.  Ẹsẹ 6-12: Síbẹ̀, satani ọ̀tá wa (I Pet. 5:8) ṣe akọlù sii, Ọlọ́run si fi aaye gba satani lati dan ifẹ ati ìfọkàntan Jobu wi Ọlọ́run wo. Ọlọ́run maa n faaye gba awọn iriri atun iwa mọ wọ̀nyí lati dan iwọn wa ninu Rẹ wo, ki O si le fi ọwọ rẹ sọyà nipa wa (wo ẹsẹ 8; I Kor. 10:13).
iv.   1:13-2:8: Wo iwuwo àdánwò ti Ọlọrun mu ki o ba ẹni ìdúróṣinṣin yii, o pàdánù dukia ati àwọn ọmọ (1:13-19) ati ìlera (2:1-8). Lotitọ asiko idanwo ti o de gongo ti o mu ki o fi ọjọ ibi rẹ re (3:1 siwaju) bẹẹni o si fẹ lati ku (6:8-10). Bẹẹni ọrọ ẹ̀gàn awọn ọrẹ rẹ tun pá kun isoro naa.
v.   Satani ṣe ohun gbogbo ti o mọ lati sọ Jobu di alailagbara, aláìlera, iporuuru ọkan, ki o si rẹ̀wẹ̀sì lati ya Jobu kúrò nínú ìfẹ́ Yahwe rẹ (wo Rom. 8:35).

B.    O GBẸKẸLE IFẸ ỌLỌ́RUN NÍNÚ GBOGBO RẸ (1:20-22; 2:9,10; 16:1).
Siwaju nínú gbogbo eyi Jobu ko ṣẹ, bẹẹni ko si fi were pe Ọlọrun lèjọ (1:22).
i.   1:20,21: Jobu jẹ aláìlera ati ẹlẹ́ran ara, o sọfọ awọn ohun ti o pàdánù rẹ, bi o ti ṣẹlẹ̀ kíákíá ati lojiji (1:15-19). Síbẹ̀ o sin Ọlọrun. Irufẹ ifẹ ti ko se e ja wo ni eyi fun Ọlọ́run titobi (O.D.115:3)!
ii.   Ẹsẹ 22: Jobu hu iwa ti o tọ si Ọlọrun. O ṣetán lati gba ohun gbogbo ti Ọlọ́run ni fun un pẹlu ayọ̀ (wo Efe. 5:20; I Tesal. 5:18). O ni ìgbẹ́kẹ̀lé nínú títóbi ifẹ Ọlọ́run ati àṣẹ Rẹ lori ohun gbogbo ti o ti fun un. Jobu yege ninu idanwo naa, eyi ti o túmọ̀si pé a le fẹ Ọlọ́run nítorí ẹniti O jẹ láìsí jẹ nítorí ohun ti O fun wa.
iii.   O gbẹkẹle Ọlọ́run onifẹ pe ko ni ṣe ohun ti o dara julọ fun oun (wo Rom. 8:28). Gbogbo awọn ti wọn ba n ro Ọlọ́run lẹjọ yoo maa yọrí rẹ si rírí ìbínú Ọlọ́run (Num. 14:2-12).
iv.   2:9,10: Jobu fẹran Ọlọ́run nitòótọ́, si Jobu ko si ohun ti o fẹ bu Ọlọ́run fun. Ko fi aidunnu rẹ han boya nínú ọrọ tabi ni ise. Oun ko sẹ si baba ti o ni ifẹ rẹ. Ko gba ìmọ̀ràn iyawo rẹ lati bu Ọlọ́run. Ifẹ si Ọlọ́run ju ohun gbogbo lọ (wo Gen. 39:9).
v.  16:1 siwaju: si àwọn ọrẹ Jobu, ìpọ́njú rẹ jẹ nípa ẹsẹ. Boya èyí ni o mu ki ijiya rẹ pọ̀, ṣùgbọ́n dípò kí ó maa káánú ara rẹ tàbí sọ ìsọkusọ si Ọlọ́run, o da ọ̀rọ̀ wọn sọnù.

ÀWỌN Ẹ̀KỌ́ TÍ A RÍ KỌ
1.    A gbọ́dọ̀ maa reti idanwo iwa gẹgẹ bi ìdánilójú ifẹ wa si Ọlọ́run.
2.    Awọn eniyan yoo maa wa ni àyíká rẹ ni gbogbo igba ti wọn yoo fẹ lati mu ọ kọlu Ọlọ́run olufẹ. Mase gba lati kọlu Ọlọ́run!

IṢẸ ṢÍṢE
Jobu ko fi igba kankan ṣiyèméjì lori ifẹ Ọlọ́run. Salaye.

Click to read previous CAC Sunday School Manuals HERE

ÌDÁHÙN TÍ A DÁBÀÁ FÚN IṢẸ́ ṢIṢẸ́

i.   Jobu jẹ ẹni iduro ṣinṣin, o fẹran Ọlọ́run, o si gbọ́ràn si I lẹ́nu.
ii.  Ifẹ Jobu si Ọlọrun ran awọn ọmọ rẹ, ti wọn n kórajọ ti wọn ba ara wọn ṣe ohun gbogbo papọ nínú ìfẹ́ ni ile olúkúlùkù wọn.
iii.  Ọlọ́run gba satani laaye láti dan Jobu wo, ṣùgbọ́n Jobu jẹ olóótọ́ sì Ọlọ́run.
iv.  Ní àkókò idanwo, Jobu ko sọ igbagbọ rẹ ati ifẹ tí o ní sí Ọlọ́run nu.
v.   Jobu huwa ti o tọ si Ọlọ́run o ṣetán lati gba ohun gbogbo ti Ọlọrun ni fun un pẹlu ayọ̀.
vi.  Jobu gbagbọ pe Ọlọrun alààyè kò ní pa oun lara nítorí ohunkóhun.
vii. Jobu ko ṣiyèméjì ninu Ọlọ́run, o gbe ìmọ̀ràn ìyàwó rẹ lati sẹ Ọlọ́run ju si ẹgbẹ́ kan.
viii. Jobu tẹ oju rẹ mọ Ọlọ́run.
ix.   Jobu farada wàhálà kan si èkejì fun saa kan bẹẹni o sì jẹ olòótọ́ ni gbígbẹkẹle Ọlọ́run lati dáàbò bo o.
ÌJỌ ÀPỌ́SÍTÉLÌ KRISTI, Ẹ̀KỌ́ ILÉ-Ẹ̀KỌ́ ỌJỌ́ ÌSINMI September 2, 2018 : Ẹ̀KỌ́ KẸRIN - FIFẸ ỌLỌ́RUN NÍ ÀWỌN ASIKO TI O LEWU ÌJỌ ÀPỌ́SÍTÉLÌ KRISTI, Ẹ̀KỌ́ ILÉ-Ẹ̀KỌ́ ỌJỌ́ ÌSINMI  September 2, 2018 : Ẹ̀KỌ́ KẸRIN - FIFẸ ỌLỌ́RUN NÍ ÀWỌN ASIKO TI O LEWU Reviewed by Muyiwa Abodunrin (Muyilight) on September 02, 2018 Rating: 5

No comments:

Powered by Blogger.