ÌJỌ ÀPỌ́SÍTÉLÌ KRISTI. Ẹ̀KỌ́ ILÉ Ẹ̀KỌ́ ỌJỌ́ ÌSINMI FUN April 7, 2019 : AKORI - Eto Ayeraye Olorun Fun Eniyan.

ÌJỌ ÀPỌ́SÍTÉLÌ KRISTI.  Ẹ̀KỌ́ ILÉ Ẹ̀KỌ́ ỌJỌ́ ÌSINMI FUN April 7, 2019 : AKORI - Eto Ayeraye Olorun Fun Eniyan.Click to read previous CAC Sunday School Manuals in Yoruba here

ÌJỌ ÀPỌ́SÍTÉLÌ KRISTI.
Ẹ̀KỌ́ ILÉ Ẹ̀KỌ́ ỌJỌ́ ÌSINMI.
Eto Ayeraye Olorun Fun Eniyan.
April 7, 2019.

II.    ÒPIN YÓÒ DÉ (Mateu 13:27-43)
Òpin nnkan ṣàn ju ìbẹ̀rẹ̀ rẹ, lọ (Oniw. 7:8). Òpin n sọ̀rọ̀ nípa igunlẹ, ìparí pátápátá nnkan. Lẹ́yìn òpin náà, ko si nnkankan mọ. Síbẹ̀, bi nnkan ti pari ṣe koko, yoo si sọ boya nnkan naa jẹ àṣeyọrí tàbí bẹẹ kọ. O dara láti maa ronú nípa òpin.


A.   DÍDÀGBÀ PAPỌ ISINSIN YII (ẹsẹ 27-30)
      "Ẹ jẹ ki àwọn méjèèjì kí o dàgbà pọ titi di ìgbà ìkórè: ni akoko ìkórè, èmi o sì wí fún olùkórè pé, Ẹ tete kọ ko èpò jọ, ki ẹ di wọn ni iti láti fi ina sún wọn, ṣùgbọ́n ẹ ko àlìkámà sinu aba mi" (ẹsẹ 30)
i.   ẹsẹ 27,28: Nibi yii, a ri àdàlù irúgbìn rere àti búburú (àlìkámà àti èpò) àti bi o ṣe ṣòro tó láti da wọn mọ yàtọ̀. Wọn béèrè lọ́wọ́ ọga, boya kí wọn fà àwọn èpò naa tu.
ii.   Ẹsẹ 29: Ọga naa, nínú ọgbọ́n Rẹ da àwọn ọmọ ọdọ naa dúró láti máṣe tu àwọn èpò naa kúrò, o si wí pé wọn ní láti wa nibẹ fún ìgbà díẹ̀. Jesu wí pe wọn ko lè yanjú wọn nípa fífà wọn tu kúrò.
iii.  Àwọn ẹni ibi / ènìyàn ika ni a ko le ya sọtọ tàbí ti jáde kúrò nínú ìjọ látàrí líle wọn lọ kúrò nínú ìjọ pátápátá, fún asiko yii, wọn yoo si maa gbe pẹlu awọn oníwà-bí-Ọlọ́run. Kin ni ìdí rẹ?
iv.  Onisuuru ni Ọlọ́run, ko fẹ ki ẹnikẹ́ni ṣègbé / Esek. 18:23, 32; 2 Pet. 3:9. Niti Ọlọ́run gbogbo ẹlẹ́sẹ̀ ni o lágbára láti yipada di òní ẹni mímọ. Ṣùgbọ́n sa, ko túmọ̀ sí pe a ki yoo safihan ẹsẹ, pẹ̀lú tí ẹ̀kọ́ òtítọ́. A ko si gbọdọ fi ààyè gba àwọn to n safihan onírúurú ìwà aitọ láti di ipo aṣáájú mú nínú ìjọ.
v.   Ko si ipa ẹ̀dá ènìyàn kan tí ó le mú àwọn ìṣìnà wọnyii kúrò; wọn ní láti dàgbà pọ. Àwọn ọmọ ẹni ibi wá ní gbogbo ìjọ tí wọn ń sọ̀rọ̀ tí wọn sì ń hùwà òde-ara gẹ́gẹ́ bí Kristẹni, ṣùgbọ́n tí wọn kò ti i jọ̀wọ́ ara wọn fún Jesu Kristi Olúwa nítòótọ́ (2 Tim. 3:5). Wọn dúró fún ẹ̀kọ́ ẹ̀mí èṣù nínú ìjọ.
vi.  Àwọn ẹni rere àti ẹni ibi ni lati dàgbà pọ nínú ìjọ titi di ìgbà ìkórè, ṣùgbọ́n dídúró rẹ láti jẹ ọmọ ijọba (Ọlọ́run) àti agbára láti koju ẹ̀kọ́ odi / ìwà búburú dúró lè orí ibasepọ rẹ pẹlu Jesu Kristi Olúwa.
vii.  Ọlọrun tí pinnu pé kí irúgbìn búburú àti rere maa dàgbà pọ nínú oko kan naa (aye). O le fa èpò naa tú, ṣùgbọ́n O pinnu láti jẹ ki wọn wa bẹẹ, titi di ìgbà tí O ṣètò fun ìpínyà. Àwọn ọmọ Ọlọ́run gbọdọ béèrè fun Oore-ọ̀fẹ́ láti jẹ olotitọ, ẹni tí a ko le si nidii, àti ẹni tí o dúróṣinṣin síbẹ̀ titi de òpin.

B.    ÌKÓRÈ NÁÀ NÍ ÌKẸYÌN (ÒPIN) (ẹsẹ 39-43)
Ọmọ ènìyàn yoo ran àwọn áńgẹ́lì rẹ̀, wọn o sì ko gbogbo ohun tí ó mu-ni-kọ̀sẹ̀ ni ijọba rẹ kúrò, àti àwọn tí o n dẹ́ṣẹ̀ (ẹsẹ 41).
i.   Ẹsẹ 39-43: Ayé yii ni opin dájúdájú, gẹgẹ bí ọrọ Ọlọ́run. Oluwa wá n gbaradi láti padà wá gba agbára àti ògo ni opin ayé yii. Ní ìgbà ìkórè gbogbo ènìyàn a kórè ohun tí ó gbin.
ii.  Ẹsẹ 39 síwájú: Àwọn olùkórè ni àwọn áńgẹ́lì (àwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run) àwọn ni Olúwa yoo rán lọ láti kórè ayé.
iii.  Ẹsẹ 40-42: Àwọn èpò (àwọn ọmọ ẹni búburú ni; àwọn ẹni tí a ko rapada) a o ko wọn jáde papọ, a o si ju wọn sínú iná ìdájọ́ àti iná ọrùn àpáàdì. Bio tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn ẹni rere àti ẹni búburú wá papọ nínú ayé yii laida wọn mọ yàtọ̀, nígbà ìkórè, a o pin wọn niya.
iv.  A o di wọn ní ìtì. Àwọn tí wọn darapọ mọ ẹsẹ àti àgàbàgebè yoo wa ninu ìtìjú àti ibanujẹ, nínú iná níbi tí ẹkùn òun ìparun keke wa, níbi tí irora tí a kì ṣipẹ fún ati níbi tí ìrunú Ọlọ́run ti ko ṣe e tù lójú wa. Ara, kiyesara, ìkórè ayé dájú (Mat. 13:39; Ifi. 14:16).
v.   Ẹsẹ 43: Ọrun ni 'aba' naa. Gbogbo àlìkámà Ọlọ́run (àwọn ọmọ ijọba Rẹ) wọn yoo kóra jọpọ nínú aba Ọlọ́run nibi ti ààbò ayérayé wa. Àwọn tí wọn tan gẹ́gẹ́ bi imọlẹ nínú ayé yii ki Ọlọ́run lè di ayinlogo yoo maa ran bí òórùn nínú ayé to ń bọ̀ kí a bá lè yín wọn logo. Ẹ ha tí ṣe tí ìwọ yoo padanu èyí?
vi.  Ìgbà naa yoo de, ni èyí ti gbogbo àwọn wooli tí ń wọna fun, nígbà tí gbogbo ayé yoo maa tán bí òdòdó, àwọn ọkùnrin yoo lu idà wọn bi itulẹ àti ọkọ wọn láti fi kọ, kí yoo si sí ogún mọ káàkiri orí ilẹ̀ ayé.
vii.  Olùkórè naa maa n ṣe àsayan, ko si le ṣe àṣìṣe. A ko ni ṣe àṣìṣe láti gbé irúgbìn búburú fun irúgbìn rere. Ó wọ́pọ̀ níbi pe ki ọ̀daràn o gba ominira, ìyẹn kò le ṣẹlẹ̀ lábẹ́ ìdájọ́ Ọlọ́run, torí ko si ẹni ti yoo gba ọna àlùmọ̀kọ́rọ́yí wọlé. Ohun tí o bá gbìn ni ìwọ yoo ká.

ÀWỌN Ẹ̀KỌ́ TÍ A RÍ KỌ
1.   Pe a n gbé láyé kan naa pẹ̀lú àwọn ènìyàn búburú kò gbọ́dọ̀ mú ọ tẹle ọpọ ènìyàn lọ sínú ìwà aìwà-bí-Ọlọ́run. Pẹ̀lú suuru; farada ìrora ìyára-ẹni sọtọ f'Ọlọ́run rẹ. Oluwa wá n bọ wa lati mú wa lọ ile laipẹ.
2.   Nibo ni o dúró le? Ṣé irúgbìn Ọlọ́run ń dàgbà nínú ọkàn rẹ gẹ́gẹ́ bí ọmọ ìjọba? Ìdáhùn tòótọ́ rẹ sì àwọn ìbéèrè wọnyii ni yoo sọ bóyá ó maa gbádùn ìkórè rere tàbí ìkórè ìbínú. Ronú kí o sì ṣíṣẹ lórí èyí.

ÀWỌN ÌBÉÈRÈ
1.   Nínú Òwe Àlìkámà àti Èpò, dárúkọ kí o sì ṣàlàyé àwọn olukopa pàtàkì mẹta.
2.  Ṣàlàyé ise dáadáa (ìrònú jinlẹ) tí irúgbìn naa ati èpò bí wọn tí ń dàgbà pọ ṣáájú ìgbà ìkórè.

ÀWỌN ÌDÁHÙN TÍ A DÁBÀÁ FÚN ÀWỌN ÌBÉÈRÈ :
ÌDÁHÙN SI ÌBÉÈRÈ KÍNNÍ:
Awọn olukopa Pataki ninu òwe àlìkámà àti èpò:
i.    Olufurugbin rere naa Èyí ni Jesu Kristi Ẹni tí a ń pè ní ọmọ Ènìyàn.
ii.   Ọ̀tá naa: Ọ̀tá tí o wa lati fun àwọn irúgbìn búburú sínú irúgbìn rere ní sátánì. Oun ni olufurugbin búburú naa. A rí isẹ rẹ nínú ìwé Genesisi, bí ó ti mú àìsàn ẹṣẹ wọlé sí ara ènìyàn. Sátánì kò tii dẹkùn fífún irúgbìn búburú sínú ayé àwọn ènìyàn, ìgbéyàwó, ìṣẹ́-ìránṣẹ́ abbl. Irúgbìn iyapa, àìgbọràn èké abbl rẹ han gbangba nínú ayé àwọn ènìyàn. Àwọn kristẹni gbọ́dọ̀ sọra.
iii.  Oko Naa: Oko náà ni ayé, níbi tí a gbìn irúgbìn méjèèjì sì. Nípa ọgbọ́n Ọlọ́run, àwọn irúgbìn méjèèjì naa yoo maa dàgbà pọ, titi di ìgbà ìkórè ikẹyin. Jesu lè mú àwọn onigbagbọ kúrò láyé yii nígbà tí O ṣi wa laye, ṣùgbọ́n O pinnu láti ma ṣe bẹ́ẹ̀. Wọn ní láti maa dàgbà pọ titi di ọjọ ìkórè ikẹyin. Ìkórè ikẹyin níbi yii ń sọ pé ìkórè kii wáyé nígbà gbogbo; àwọn ènìyàn n kú lojoojumọ láti lọ ba Ẹlẹda wọn. Ọna ìkórè kan nìyẹn. Síbẹ̀, a ti ya ọjọ́ kan sọtọ, nígbà tí a o kórè ayé ni kíkún.
iv.  Àwọn èpò ni àwọn irúgbìn búburú, àwọn ọmọ èṣù (satani)
v.   Àwọn àlìkámà ni àwọn irúgbìn rere; àwọn ọmọ ijọba Ọlọ́run.

ÌDÁHÙN SI ÌBÉÈRÈ KEJÌ.
i.    O jẹ ọrọ ti o le (lágbára) láti maa jẹ ki awọn irúgbìn naa o dàgbà nígbà kan náà. Síbẹ̀, Ọlọ́run ni agbara lati mú àwọn irúgbìn réré dúró kí ó sì pa wọn mọ kúrò nínú idibajẹ.
ii.   Láìsí aniani, kò sì agbẹ tí yóò fẹ́ kí koríko (èpò) o dúró nínú oko láti dàgbà pẹ̀lú àwọn irúgbìn tí o fẹ. Idi ni yìí tí wọn fi máa ń ṣan (ro) oko ṣáájú ìkórè.
iii.  Koríko máa n saaba gba àwọn èròjà tí o wà fún mimu àwọn irúgbìn rere dàgbà daradara.
iv.  Lọpọ ìgbà, wọn maa n fà aidagba daradara tàbí kí wọn pá àwọn irúgbìn daradara naa.
v.   Síbẹ̀, Ọlọ́run ti pinnu láti mu ki àwọn ọmọ Rẹ àti àwọn ọmọ búburú naa o maa gbe pọ titi di ìgbà ìkórè ìkẹyìn. Njẹ ìyẹn sọ wí pe (túmọ̀ si pe) o buru? Rara.
vi.  Ìwàláàyè àwọn ọmọ Rẹ yoo ka ẹsẹ sì awọn ọmọ ẹni búburú lọrun, ki wọn le dojúkọ idajọ wọn láìsí awawi.
vii.  Àwọn ọmọ ẹni búburú yoo dúró gẹ́gẹ́ bí àdánwò láti mọ jíjẹ ojúlówó àti iduroore àwọn ọmọ Ọlọ́run. Wọn o gba ìyìn lẹ́yìn-ó-rẹyìn fun jijẹ olóòótọ́ sí isẹ wọn, gẹgẹ bí ọmọ ímọ́lẹ̀.

ÀMÚLÒ FÚN IGBE AYÉ ẸNI :
Awọn ọrẹ méjì kan wa ni igba kan, tí ìṣòro ayé dojúkọ gidigidi. Fun ọdún mẹrin lẹyin tí wọn jáde ní ilé-ìwé Fasiti, wọn kò rí isẹ. Ọkàn lára àwọn méjì naa pinnu láti wa ọna àbáyọ. O pinnu láti darapọ mọ àwọn ẹgbẹ́ ọlọ́ṣà tí wọn tí wọn tun n kopa ninu jijinigbe àti onírúurú oogun owó ṣíṣe/ìṣẹ́so. Ó ṣe lodi sì ọrọ ìyànjú ọrẹ rẹ. Lẹ́yìn ọdún meji, àwọn mejeeji ṣe kongẹ ara wọn. Eyi tó n huwakiwa, tí ó ti wa ninu ọlá gbìyànjú láti yí ọkàn ọrẹ rẹ padà láti darapọ mọ ìgbé-ayé búburú naa, o gbìyànjú láti yi i lọ́kàn padà láti pa ìjìyà tì, bí o ti n da ìjọba lẹbi lórí airisẹ wọn. Dipo kí o gba, ọrẹ olododo naa gbìyànjú láti ba a sọ̀rọ̀ pe ki o fi ìwà naa silẹ, niwọn bi Ọlọ́run ti jẹ olóore-ọ̀fẹ́ àti aláàánú síbẹ̀ láti gba a la. Ko gbọ rara. O ti rin jìnnà nínú ọna búburú rẹ. Lẹyin ọdún kan, ọrẹ ti o ti wọlé sí ibi iṣẹ́ rẹ, o gbọ orúkọ ọrẹ rẹ àtijọ nínú ìròyìn pe wọn tí mu un, ni ibi tí o ti n ṣíṣẹ ibi, o si ti fẹ́rẹ̀ẹ́ ku. Àwọn ọmọ ènìyàn búburú lè dabi ẹni n rọwọ mu bayii, ṣùgbọ́n ìyẹn kò le pẹ. Àpẹ ko to jẹun kii jẹ ibajẹ.

IGUNLẸ
Láti ìbẹ̀rẹ̀ ni a ti n jẹ gbádùn oore-ọ̀fẹ́ Ọlọ́run àti ìwàláàyè Rẹ ti ko lẹgbẹ nínú ẹ̀kọ́ tí o jẹ ìyanu, ti o n yí ayé padà tí o sì n mu igbagbọ dàgbà yii. Ọlọ́run ti fi idi ti o fi gba àwọn onigbagbọ àti àwọn ọmọ ènìyàn búburú láàyè láti maa gbe pọ bayii (fun ìgbà díẹ̀) nínú ayé yii hàn wa. A ti kọ wa pe laipẹ jọjọ ìpínyà (ìyàtọ̀) yoo de. Àwọn ènìyàn búburú yoo wa ni ibi ti wọn tọ si, awa ọmọ ímọ́lẹ̀ yoo si wa pẹ̀lú Baba Ímọ́lẹ̀. Ko si ohunkóhun tí o gbọdọ mú kí àwọn ọmọ o gba láti faramọ iwa àti ìṣe òkùnkùn. Ọlọ́run yoo ro ọ lágbára. Eyi ni ipari ẹ̀kọ́ yii. Jẹ ọmọ Ọlọ́run síbẹ̀.

ÀṢÀRÒ LÁTI INÚ BÍBÉLÌ FÚN ỌSẸ IKEJI
Mon.    April 1:    Owe Àlìkámà àti Epo (Mat. 13:24-30)
Tue.      "     2:     Irúgbìn Rere Naa: Tí Ọlọ́run Fun (Mat. 13:27)
Wed.     "     3:     Oko Ní Ayé (Mat. 13:28)
Thur.    "     4:     Irúgbìn Rere Naa: Àwọn Ọmọ Ijọba Ọ̀run (Mat. 13:38)
Fri.       "     5:      Èpò: Ni Àwọn Ọmọ Èṣù (Mat. 13:38)
Sat.      "     6:      Ọ̀tá Àti Ìkórè Tí A Ṣápejuwe (Mat. 13:38-39).
ÌJỌ ÀPỌ́SÍTÉLÌ KRISTI. Ẹ̀KỌ́ ILÉ Ẹ̀KỌ́ ỌJỌ́ ÌSINMI FUN April 7, 2019 : AKORI - Eto Ayeraye Olorun Fun Eniyan. ÌJỌ ÀPỌ́SÍTÉLÌ KRISTI.  Ẹ̀KỌ́ ILÉ Ẹ̀KỌ́ ỌJỌ́ ÌSINMI FUN April 7, 2019 : AKORI - Eto Ayeraye Olorun Fun Eniyan. Reviewed by Muyiwa Abodunrin (Muyilight) on April 07, 2019 Rating: 5

No comments:

Powered by Blogger.