ÌJỌ ÀPỌ́SÍTÉLÌ KRISTI Ẹ̀KỌ́ ỌJỌ́ ÌSINMI August 26, 2018 : Ẹ̀KỌ́ KẸTA. - IFẸ JÒSÁYÀ FÚN ỌLỌ́RUN

--> Note :- Are you born again? You are never going to win the battle against the devil if you are not born again. I plead with you to give your life to Jesus today because the longer you stay in sin and remain unsaved, the more hardened your nature becomes against the purpose and the way God wants you to be for His purpose. To give your life to Jesus now, say this prayer: “Father, I come to You in the name of Jesus. I know that I am a sinner and I cannot save myself but Jesus died for me and shed His blood that I might be saved. Today, I accept Jesus as my Lord and Saviour. Jesus, I ask You to come into my heart, be my Lord, wash me with Your blood and make me whole. I believe with my heart and confess with my mouth that Jesus is my Lord. Thank You for saving me. In Jesus' name I pray. Amen.” I congratulate you and welcome you to the family of God if you have sincerely said that prayer. Now you are fit to discover, know and walk in your destiny. Call our helpline on +2348037252124, Join Our Daily Whatsapp Devotionals Group : +2347033046607 for Daily Devotionals, crucial discipleship and counselling.s"
ÌJỌ ÀPỌ́SÍTÉLÌ KRISTI  Ẹ̀KỌ́ ỌJỌ́ ÌSINMI  August 26, 2018 : Ẹ̀KỌ́ KẸTA. - IFẸ JÒSÁYÀ FÚN ỌLỌ́RUN



ÌJỌ ÀPỌ́SÍTÉLÌ KRISTI
Ẹ̀KỌ́ ỌJỌ́ ÌSINMI
August 26, 2018.

Ẹ̀KỌ́ KẸTA.
IFẸ JÒSÁYÀ FÚN ỌLỌ́RUN

ÌPÍN KEJÌ.

26 August, 2018 | O DARI ÀWỌN YOKU LATI ṢE BẸẸ GẸ́GẸ́


Nigba ti igbe ayé adari kan ba ru awọn ọmọlẹ́yìn rẹ soke lati se ohun ti o n se; yoo ni ipa pupọ. Ṣùgbọ́n ti o ba jẹ lati se ohun ti mo sọ, kii se ohun ti mo ṣe; wàhálà wa nigba naa. Jòsáyà ṣe ohun ti o fẹ ki awọn eniyan naa ṣe wọn si se e. A gbọ́dọ̀ setan lati se ohun kan naa, koda bii Pọ́ọ̀lù (I Kor. 11; 1; 2 Tim. 3:10.

A.    O SATUNRI ỌRỌ NAA (22:3-20)

O si ṣe, nígbà tí ọba gbọ́ ọrọ inú ìwé ofin naa, o si fa aṣọ rẹ ya (ẹsẹ 11).
i.    Ẹsẹ 3-7: Ni ọmọ-ọdún mẹrin-dín-lọgbọn (ẹsẹ 3). Oluwa ti Josaya lẹyin, O si gbee dide lati bẹ̀rẹ̀ isẹ àtúnṣe tẹmpili naa ti àwọn aṣáájú rẹ Mánásè àti Ámónì ti o jẹ eniyan búburú pati ti wọn si lo ni ilokulo. Ara rẹ jẹ tẹmpili Ọlọ́run (I Kor. 6:19-20). Njẹ o ko ro wipe onilo awọn àtúnṣe kan nípa tẹmi (2 Kor. 13:5)?.
ii.    Ẹsẹ 8-10: Itara Josaya fún Ọlọ́run àti àwọn nǹkan Rẹ ni o sokunfa awari ohun iranti ti o yanilẹ́nu ninu tẹmpili naa (wo 2 Kor. 34:14-16). Bi a ba ti ni itara Ọlọ́run to ti a si sunmọ Ọn to, naa ni a o maa ri gba to lọwọ Rẹ.
iii.   O han gbangba ninu tẹmpili naa pe ẹda ofin naa ku ẹyọ kan ṣoṣo; eyi ti o jẹ pe iru ipese ati oore-ọ̀fẹ́ Ọlọ́run ní o pa a mọ. Bákan naa, o seese kí wọn mọ pe iru iwe bẹẹ wa ti ninu tẹmpili naa ri ṣùgbọ́n ki wọn ro pe o ti sọnù. O jẹ ohun ti ko se e gbọ́ pe Iwe Ọlọ́run sọnu ninu Tẹmpili! Sisatunri ọrọ Ọlọ́run lonii (nipasẹ ijọsin adase, ẹ̀kọ́ bibeli ati ẹ̀kọ́ ilé ẹ̀kọ́ ọjọ ìsinmi) jẹ́ ohun tí a nilo.
iv.   Ẹsẹ 11-13: Bi o ti gbọ ohun ti wọn ka ninu Iwe naa, Josaya safihan ìrònúpìwàdà ńlá. Igbesẹ ìgbọràn rẹ wà láti inú ọkàn ti o tẹríba tí ó fẹ́ràn Ọlọ́run. O tete gbé igbesẹ fun iwadii.
v.   Ọba naa pe wolii Hulda. Yoo yanilẹnu eredi ti o fi beere ìmọ̀ràn lọwọ obinrin! Jeremáyà àti Sefanáyà naa jẹ akẹgbẹ rẹ (Jer. 1:1-3,22:11,18). Kin ni idi ti ko fi pe wọn? Eyi safihan irẹlẹ ọba naa ati ipo Hulda nipa tẹmi. Ẹnikẹ́ni ti o ba yọnda ara rẹ fun ko nii dẹni apati.
vi.   Ìṣoji àti abẹwo Ọlọ́run yoo bẹ̀rẹ̀ pẹlu awọn eniyan ti o fẹ́ràn Rẹ. Bawo ni a ṣe le gbàdúrà fun Ìṣoji? Báwo ni a ṣe le ri ìran pe yoo sẹlẹ? O gbọdọ re kọjá ọrọ sisọ lẹ́nu lásán!
vii.   Àtunri àti isamulo ọrọ naa mu Ìṣoji àti ìmúṣẹ ayanmọ waye. Lo ṣàwárí ọrọ naa.

B.    O MU ÌJỌSÌN TOOTỌ BỌ SIPO (23:1-25).

Ọba si pàṣẹ fún gbogbo ènìyàn wí pé, pa ìrékọjá mọ fún Oluwa Ọlọ́run yín, bi a ti kọ ọ ninu iwe májẹ̀mú yii (ẹsẹ 21).
i.   Ẹsẹ 1-3: Ninu mímú ìjọsìn tòótọ́ Bọsipo, nítorí wọn yoo ni imọ juu lọ, wọn yoo si wulo ninu Ìṣoji naa.
ii.   Ẹsẹ 2: O ko gbogbo ènìyàn jọ, laiwo ipo wọn, o si FÚNRARẸ ka (waasu) Ọrọ Ọlọ́run si wọn. Òtítọ́ àti ìdúró-ṣinṣin ọkàn ati erongba Josiah ti o han kedere ru àwọn ènìyàn naa soke, o si tun pe wọn nija.
iii.  Ẹsẹ 3: Josiah kọ́kọ́ da majẹmu niwaju Olúwa, lẹ́yìn naa gbogbo àwọn ènìyàn naa se bẹẹ gẹgẹ. Bi o ba fẹ́ràn Ọlọ́run ni tòótọ́, o yẹ ki àwọn ẹlòmíràn ti o wa ni àyíká rẹ rii ki wọn si gba ipenija lati tẹle ọ.
iv.  Ẹsẹ 4-25: Àtúnṣe májẹ̀mú pẹ̀lú Rẹ ni o tẹle kika ofin Ọlọ́run ní gbangba (ẹsẹ 1-3). Lẹ́yìn naa ni iwẹnimọ ibi gbangba waye, mimu ibọrisa kuro ni ilẹ̀ naa (ẹsẹ 4:14). Iwẹnumọ naa rekoja Juda (ẹsẹ 15-20). Àjọ ìrékọjá ti wọn ti pati di mímu bọ sipo (ẹsẹ 24-25). Ìjọsìn ti o tọ fìdímúlẹ̀ ninu ohun gbogbo.
v.   Lati ni iriri, kí a sì gbádùn Ọlọ́run, a gbọ́dọ̀ gbógun ti, ki a si se gbogbo ogun ti o fẹẹ bori ifẹ wa fun Ọlọ́run àti láti ba A rin.
vi.   Nígbà naa, a o le jọsin nitootọ ninu Ẹ̀mí ati òtítọ́.

ÀWỌN Ẹ̀KỌ́ TÍ A RI KỌ

1.   Fifẹ lati mọ, ni oye lati ba Ọlọ́run rin nípasẹ̀ ọrọ Rẹ ni ọna kansoso ti o dara lati safihan ifẹ wa fun Un.
2.    Ìyípadà gbọ́dọ̀ jẹ ẹri afojuri ti kii se arọpo fun ọkàn ti o yipada.

ÀWỌN ÌBÉÈRÈ

1.    Iru iṣẹlẹ ìrántí ti o yanilẹnu wo ni o ṣẹlẹ̀ nígbà ti wọn n se Iwẹnumọ tẹmpili?
2.    Bawo ni ifẹ Josaya fun Ọlọ́run (ninu ise) ṣe ru gbogbo àwọn eniyan naa soke láti mu ìjọsìn tòótọ́ bọsipo ni ilẹ̀ naa?

ÀWỌN ÌDÁHÙN TI A DÁBÀÁ FÚN ÀWỌN ÌBÉÈRÈ

ÌDÁHÙN SI ÌBÉÈRÈ KÍNNÍ

i.    Hilkiah àlùfáà ni o ṣàwárí ìwé òfin Olúwa (2 Kron. 34:14).

ÌDÁHÙN SI ÌBÉÈRÈ KEJÌ

i.     Bí o ti gba iwe naa nigba ti wọn sawari rẹ, Josiah faaye silẹ ki a ka a fun wọn; ọrọ naa ṣàtúnṣe aye rẹ.
ii.    Lẹ́yìn naa, o ko àwọn ènìyàn naa jọ, o bẹ̀rẹ̀ pẹlu awọn olori awọn eniyan naa.
iii.   Oun fúnrarẹ ka ọrọ Ọlọ́run fun àwọn ènìyàn naa.
iv.   Ifẹ Josiah fun Ọlọ́run ni a ri ninu òtítọ́ àti ododo ọkan rẹ.
v.    O ba Ọlọ́run da májẹ̀mú ni gbangba níwájú àwọn ènìyàn naa, lati maa ba Ọlọ́run rin, lati pa àwọn àṣẹ Rẹ mọ (2 A. Ọba 23:3) àwọn ènìyàn si fi tinútinú ṣe e bakan naa.
vi.  Wọn ko gbogbo àwọn ohun ibọrisa kuro ninu tẹmpili naa, wọn si se iwẹnumọ ìta gbangba.
vii.  Ase àjò ìrékọjá tí wọn tí pa ti di mímú bọsipo, wọn si mu ìwà-búburú kuro.
viii. Ifẹ Josiah fun Ọlọ́run waye ni ọna afojuri, wọn rii, àwọn ènìyàn naa si tẹ́wọ́gba a.

ÀMÚLÒ FÚN ÌGBÉ AYÉ ẸNI :

"O fẹrẹ jẹ pe gbogbo ènìyàn ti o ti fi kun àṣeyọrí ìran ènìyàn nípa isẹ ayé rẹ... ni o ti gbe ọpọ ìgbé-ayé rẹ le awọn ẹkọ Bibeli " Theodore Roosevelt.

Eniyan ti o fi ohun ti o dara julọ dun ara rẹ laye tí dun ara rẹ ni ohun yii (oye Bibeli) " Woodrow Wilson.

Asayan ọrọ méjèèjì oke yii n sọ bi ọrọ ti ní ipa to, àti ipa ti o le ni lori ẹnikẹ́ni tí o ba fi òtítọ́ ati ododo samulo òtítọ́ ti o n fun ni.

Ọ̀rọ̀ naa le ṣíṣẹ fun ìwọ naa. O lè sọ ọ di ẹni-nla ati ẹnì ìmúṣẹ laye. Fẹ Ọrọ naa, ka Ọrọ naa, gba Ọrọ naa gbọ.

Click Here To Read Previous C.A.C Sunday School Lessons 

IGUNLẸ :

Ninu ẹ̀kọ́ yii, a ti ri bi Josiah ti di ọba ni ìmúṣẹ àsọtẹ́lẹ̀; ati awọn isẹ nla ti o se nípasẹ̀ lílo Ọrọ Ọlọ́run gege bi ohun elo. A gbàdúrà pe ẹ̀kọ́ yii yoo mu wa se ìpinnu lati bẹ̀rẹ̀ ibasẹpọ ọtun pẹlu Ọrọ Ọlọ́run ki a ba le mu àwọn ayanmọ ti Ọlọ́run fifun wa sẹ ni orúkọ Jésù. Ọlọ́run yoo bukun fun ọ.
ÌJỌ ÀPỌ́SÍTÉLÌ KRISTI Ẹ̀KỌ́ ỌJỌ́ ÌSINMI August 26, 2018 : Ẹ̀KỌ́ KẸTA. - IFẸ JÒSÁYÀ FÚN ỌLỌ́RUN ÌJỌ ÀPỌ́SÍTÉLÌ KRISTI  Ẹ̀KỌ́ ỌJỌ́ ÌSINMI  August 26, 2018 : Ẹ̀KỌ́ KẸTA. - IFẸ JÒSÁYÀ FÚN ỌLỌ́RUN Reviewed by Muyiwa Abodunrin (Muyilight) on August 26, 2018 Rating: 5

No comments:

Powered by Blogger.