ÌJỌ ÀPỌ́SÍTÉLÌ KRISTI Ẹ̀KỌ́ ỌJỌ́ ÌSINMI FUN August 12, 2018 :ISỌRI KÍNNÍ: IFẸ ENIYAN SI ỌLỌ́RUN.

--> Note :- Are you born again? You are never going to win the battle against the devil if you are not born again. I plead with you to give your life to Jesus today because the longer you stay in sin and remain unsaved, the more hardened your nature becomes against the purpose and the way God wants you to be for His purpose. To give your life to Jesus now, say this prayer: “Father, I come to You in the name of Jesus. I know that I am a sinner and I cannot save myself but Jesus died for me and shed His blood that I might be saved. Today, I accept Jesus as my Lord and Saviour. Jesus, I ask You to come into my heart, be my Lord, wash me with Your blood and make me whole. I believe with my heart and confess with my mouth that Jesus is my Lord. Thank You for saving me. In Jesus' name I pray. Amen.” I congratulate you and welcome you to the family of God if you have sincerely said that prayer. Now you are fit to discover, know and walk in your destiny. Call our helpline on +2348037252124, Join Our Daily Whatsapp Devotionals Group : +2347033046607 for Daily Devotionals, crucial discipleship and counselling.s"
ÌJỌ ÀPỌ́SÍTÉLÌ KRISTI  Ẹ̀KỌ́ ỌJỌ́ ÌSINMI FUN August 12, 2018 :ISỌRI KÍNNÍ: IFẸ ENIYAN SI ỌLỌ́RUN.



ÌJỌ ÀPỌ́SÍTÉLÌ KRISTI
Ẹ̀KỌ́ ỌJỌ́ ÌSINMI.
ISỌRI KÍNNÍ: IFẸ ENIYAN SI ỌLỌ́RUN.
August 12, 2018

Ẹ̀KỌ́ KEJÌ
AFIWE ÌJÌNLẸ̀ LAARIN BÁLÁÁMÙ ÀTI FÍNÍHÁSÌ.

IPA KEJÌ.
12 August, 2018: | II. FÍNÍHÁSÌ FẸ́ IWA MÍMỌ́ ỌLỌ́RUN (Númérì 25:1-13) (Ọjọ́ Àwọn Ọdọ Lagbaye).
Ọlọ́run maa n ní àwọn ti n jẹri Rẹ ni gbogbo ìran. Àlùfáà Fíníhásì jẹ ọkan lara wọn ni ìran rẹ bi àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ti n lọ nínú aginjù si ilẹ Kénáánì, lẹyin ìjáde wọn, ti wọn si sunmọ ilẹ̀ ìlérí. Ifẹ tootọ si Ọlọ́run ni yoo mu ọ fi ori la ewu fun Un.


A.   IFẸ TOOTỌ NI O RU U SOKE
      Nigba ti Fíníhásì, ọmọ Eleasari, ọmọ Aaroni alufaa rii, o dide laarin ìjọ, o si mu ọkọ kan ni ọwọ rẹ (ẹsẹ 7).
i.   25:1-3: Asako ati awọn Ọ lọrun líle eniyan ti subu sinu idanwo ti ise isẹ ọwọ Báláámù. O han kedere pe wọn ko nifẹ Ọlọ́run fun ẹni ti o jẹ. Wọn kan n tẹle E ni nítorí ohun tí wọn yoo ri gba lọwọ Rẹ. Abájọ ti o fi rọrùn fun wọn láti ṣe Panṣágà àti Ibọrisa pẹlu awọn ọta Ọlọ́run, ifẹ rẹ sì Ọlọ́run ko ṣeé fi pamọ. (Jhn. 15:14).
ii.   Ẹsẹ 3-5: Eyi maa n ru ìbínú Ọlọ́run soke, ti o si n mu ìparun wa si ori àwọn ènìyàn Rẹ.
iii.  Ẹsẹ 6: Ohun ìríra tí o tún ga julọ ni bi Simri (ẹsẹ 4) ṣe mu Kosibi ara Mídíánì wọlé níwájú Mose àti àwọn ènìyàn ti wọn n sọkún fun ẹsẹ wọn àti egun ti n tẹle e.
iv.  Gẹ́gẹ́ bi àwọn alariwisi kan ṣe sọ, wọn ni boya Kosibi jẹ abọrẹ obìnrin orisa, o si ṣe e ṣe ki wọn o maa ṣe iṣẹ́ panṣágà níwájú gbogbo ìjọ Ọlọ́run lẹ́nu ọna agọ.
v.   Ẹsẹ 7,8: Lotitọ ko si ẹnikẹ́ni ti o n gbe ìtara mímọ Ọlọ́run pẹlu iwa àìmọ ti yoo si rọ ọ lọrun pẹlu ìgboyà aiwa-bi-Olorun. Niwọn igba ti wọn si wa ninu ogun mímọ, ẹ lẹsẹ naa ni wọn ní lati pa ki ìbínú Ọlọ́run ba a le dawọ dúró.
vi.  Ẹsẹ 7-9: Ko si ẹnikẹ́ni ti o ni ìtara ati igboya lati se eyi, ayafi alufaa Fíníhásì, ọmọ Eleaseri (Eks. 6:25). Ifẹ rẹ fun Ọlọ́run àti ìwà mímọ ni o ru u soke lati se ohun ti o yẹ ti o si fi òpin si ìyọnu tabi ajakalẹ arun naa (wo ẹsẹ 10,11).
vii.  Irú ìfẹ́ tí o ru Fíníhásì si oke jẹ ifẹ tootọ si Ọlọ́run. Ìfẹ́ ti o lágbára láti rí ere nínú ṣíṣe ohun ti o wu Ọlọ́run, ti a ri gẹ́gẹ́ bí ohun tí o ru ifẹ Ìjìnlẹ̀ soke nínú ẹni. O jẹ ohun ti o jẹ Fíníhásì run ti o fi gbe igbesẹ láti gun ara Ísírẹ́lì tí o ṣe àṣìṣe pa ni ọjọ ti a n wi yii. Bawo ni ifẹ rẹ si Ọlọ́run ṣe le ti ọ (ru ọ soke) si.

B.   OLUWA SAN ERE RẸ FÚN (Ẹsẹ 12-13)
Nitori naa wi pe, 'kiyesii, emi fi Majẹmu àlàáfíà mi fun un. Yoo si jẹ tìrẹ àti irú ọmọ rẹ lẹ́yìn rẹ ani májẹ̀mú isẹ àlùfáà tiri ayé; nítorí ti o ṣe ìtara fun Ọlọ́run rẹ, o si setutu fun àwọn ọmọ Ísírẹ́lì (ẹsẹ 12-13).
i.   Ẹsẹ 10,11: Ọlọ́run ki i fi oju fo ifẹ atọ́kanwa bi eyi fun oun ni asiko ewu da. O fi eyi han ni gbangba bẹẹni O si gbori yin fun ìtara Fíníhásì fun oun Ọrọ Hébérù ti a n pe ni ìtara ni a le túmọ̀ si owú.
ii.   Ẹsẹ 12: Nítorí pe Fíníhásì ko fẹ ki aga àwọn ọmọ Ísírẹ́lì dibajẹ pẹlu iwa àìmọ ti o ni ise pẹlu isin baali; Ọlọ́run bu ọ̀la fún un pẹlu májẹ̀mú àlàáfíà Rẹ. Àlàáfíà ayérayé wa fun gbogbo ẹni ti o ba yan lati mase fi ifẹ wọn fun Ọlọ́run pamọ bi o ti wu ki se to (Mk. 8:38).
iii.  Ẹsẹ 13: Ọlọ́run san an fun pẹlu májẹ̀mú àlàáfíà títí láéláé. Oni. 20:27-28 jẹri si pe a sure fun Fíníhásì lati maa tẹsiwaju nínú isẹ àlùfáà.
iv.  Síbẹ̀, ìtara mímọ rẹ ti ifẹ rẹ si Ọlọ́run ran lọwọ ni a kaa si ododo fun un si gbagbọ ìran titi lae (O.D. 106:31).
v.  Ifẹ Fíníhásì ati iwa mimọ rẹ fun Yahweh pee pupọpupọ, oun ko dabi Báláámù ti o yan lati ran àwọn ọta Ọlọ́run lọwọ láti kọjú si i ṣùgbọ́n o parí rẹ si ìparun.
vi.  Ẹnikẹ́ni tí ó bá fi igbona ọkàn fẹ Ọlọ́run yoo gba ere eyi. Ọlọ́run ki ìṣe arẹnìjẹ. Mase sìwọ lati ni ifẹ Rẹ

ÀWỌN Ẹ̀KỌ́ TÍ A RÍ KO.
1.   Àwọn ti wọn ba fẹ Ọlọ́run ni tòótọ́ yoo dúró fun osunwọn iwa mímọ Rẹ, laiwo ti ewu ti o wa ninu rẹ.
2.  Ọlọ́run ki I ṣe Ẹni ti o n fi ipa gba ìjọba, A maa san ere ifẹ gẹgẹ bi o ti tọ àti bi o ti yẹ.

ÀWỌN ÌBÉÈRÈ
1.   N jẹ o yẹ ki a pa àwọn aláfojúdi nínú ìjọ Kristi lonii?
2.   Fifẹ Ọlọ́run ni ipo ti o lewu jẹ anfaani fun wa. Jiroro.

ÀWỌN ÌDÁHÙN TI A DÁBÀÁ FÚN ÀWỌN ÌBÉÈRÈ :
ÌDÁHÙN SI ÌBÉÈRÈ KÍNNÍ
i.   A ko ni lati pa àwọn alágídí ti n bẹ ninu ijọ Ọlọ́run lonii
ii.  Kristi ti fun wa ni ofin ti o dara ti ise ifẹ ti ki ìṣe ofin fun oju. O pasẹ fun wa lati fẹ́ràn ọta wa.
iii.  A ko ni lati pa àwọn alágídí ti n bẹ nínú ìjọ lonii. A ni lati maa gbadura fun wọn titi oye ìwà àìtọ wọn ti wọn yoo si ronupiwada kúrò nínú were wọn.
iv.  Ṣùgbọ́n àwọn ti wọn ba se àṣìṣe ni a le bawi ninu ifẹ Ọlọ́run, bi o ti n ba awọn ọmọ ti o ba fẹ wi (Heb. 12:1 siwaju).
v.   Ni tootọ àwọn ti wọn ba sẹ ẹsẹ ti o ga ní a le da duro ni ibamu pẹlu ọrọ mimọ Ọlọ́run.
vi.  Kristi ko fun wa ni àṣẹ láti pa ẹnikẹ́ni. Ipaniyan ti Fíníhásì ṣe wa ni ibamu pẹlu ilana ogun jija nínú Májẹ̀mú Laelae. Jesu kọ lati pe ina sọkalẹ bi Elijah ti ṣe.

ÌDÁHÙN SI ÌBÉÈRÈ KEJI
i.  Bẹẹni
ii.  Ti a ba fẹ́ràn Ọlọ́run a n se e tori ara wa.
iii.  Ti a ba fẹ́ràn Ọlọ́run ni asiko elewu, O le dabi ẹni pe a n fi ara wa si ipo ti o le, ṣùgbọ́n ẹníkẹyìn a o ri i pe ṣe ni a ran ara wa lọwọ lati jẹ ẹniti o dara lọwọ Ọlọ́run.
iv.  Nigba ti Dáníẹ́lì ko kọ lati maa gbàdúrà si Yahweh nigba ti wọn fi fun kinniun lati jẹ, o dabi bii pe asiwere ni. Ṣùgbọ́n ní òpin gbogbo rẹ, orílẹ̀ ede naa mọ Ọlọ́run rẹ ni Olúwa.
v.  Ẹnikẹ́ni ti o ba duro fun Kristi ni ipo ti o lewu, ni Ọlọ́run ko le silẹ ni oun nìkan níkẹyìn. Ọlọ́run yoo se ara Rẹ logo nípasẹ̀ rẹ, bẹẹni a mọ ohun ti eyi jẹ fun ẹniti o ba duro fun Un.

ÀMÚLÒ FÚN ÌGBÉ AYÉ ẸNI :
I ṣẹ ijọba ati awọn ẹ̀ka okowo miran ati ìjọ ní wọn ti kun fun iwa ibajẹ. Ati duro fun iwa mimọ Ọlọ́run wa n di ohun ìnira sii laipe wọn ní "ara ìgbàanì tàbí ẹniti ko gbòde". Yoo na àwọn bii Dáníẹ́lì ni nnkan lati safihan ifẹ wọn fun Ọlọ́run ni iru àwọn iṣẹlẹ bayii. Àwọn ọga miran maa n fẹ́ ki àwọn ọmọ abẹ wọn o dimọpọ pẹlu wọn láti bi ẹlòmíràn ṣubú bi Báláámù. A n fẹ́ àwọn ènìyàn bii Fíníhásì ti wọn yoo dúró láti ṣe àtúnṣe àwọn ohun aidara àyíká wọn, koda níbi tí ó dabii pé àwọn nìkan ni o wa ni ojú, ọna òdodo. Ki Ọlọ́run ki o ran wa lọwọ láti dúró fún Un. Àmín.

Lati ka awon eko ojo isinmi to ti koja, woo ibi yi

IGUNLẸ
Fifi Báláámù àti Fíníhásì wé ara wọn ní a ṣẹ̀ṣẹ̀ parí yii. Àwọn méjì yii nínú Bíbélì yàtọ̀ si ara wọn. Báláámù jẹ àwokọ̀se búburú nígbà ti Fíníhásì jẹ awokọse rere. Nígbà ti Báláámù yan láti kọ Ọlọ́run àti àwọn ènìyàn Rẹ nítorí ere aiwa-bi-Olorun Bálákì, ṣùgbọ́n Fíníhásì yan láti dúró láàrin àwọn ero láti ṣe ohun tí ó tọ láti dawọ ibi dúró ní ìbámu pẹ̀lú ìwà mímọ Ọlọ́run. A ni àpẹẹrẹ méjì ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀. Ẹ̀kọ́ yii jade láti rán wa lọwọ láti yan ipa Fíníhásì. A ko ni wọnú ìṣìnà Báláámù. Àmín.
ÌJỌ ÀPỌ́SÍTÉLÌ KRISTI Ẹ̀KỌ́ ỌJỌ́ ÌSINMI FUN August 12, 2018 :ISỌRI KÍNNÍ: IFẸ ENIYAN SI ỌLỌ́RUN. ÌJỌ ÀPỌ́SÍTÉLÌ KRISTI  Ẹ̀KỌ́ ỌJỌ́ ÌSINMI FUN August 12, 2018 :ISỌRI KÍNNÍ: IFẸ ENIYAN SI ỌLỌ́RUN. Reviewed by Muyiwa Abodunrin (Muyilight) on August 12, 2018 Rating: 5

No comments:

Powered by Blogger.