August 19, 2018 ÌJỌ ÀPỌ́SÍTÉLÌ KRISTI. Ẹ̀KỌ́ ỌJỌ́ ÌSINMI , Ẹ̀KỌ́ KẸTA : - IFẸ JÒSÁYÀ FÚN ỌLỌ́RUN.

--> Note :- Are you born again? You are never going to win the battle against the devil if you are not born again. I plead with you to give your life to Jesus today because the longer you stay in sin and remain unsaved, the more hardened your nature becomes against the purpose and the way God wants you to be for His purpose. To give your life to Jesus now, say this prayer: “Father, I come to You in the name of Jesus. I know that I am a sinner and I cannot save myself but Jesus died for me and shed His blood that I might be saved. Today, I accept Jesus as my Lord and Saviour. Jesus, I ask You to come into my heart, be my Lord, wash me with Your blood and make me whole. I believe with my heart and confess with my mouth that Jesus is my Lord. Thank You for saving me. In Jesus' name I pray. Amen.” I congratulate you and welcome you to the family of God if you have sincerely said that prayer. Now you are fit to discover, know and walk in your destiny. Call our helpline on +2348037252124, Join Our Daily Whatsapp Devotionals Group : +2347033046607 for Daily Devotionals, crucial discipleship and counselling.s"
August 19, 2018 ÌJỌ ÀPỌ́SÍTÉLÌ KRISTI.  Ẹ̀KỌ́ ỌJỌ́ ÌSINMI , Ẹ̀KỌ́ KẸTA : - IFẸ JÒSÁYÀ FÚN ỌLỌ́RUN.



ÌJỌ ÀPỌ́SÍTÉLÌ KRISTI.
Ẹ̀KỌ́ ỌJỌ́ ÌSINMI.
August 19, 2018.

Ẹ̀KỌ́ KẸTA.
IFẸ JÒSÁYÀ FÚN ỌLỌ́RUN.

Itara ti ọba Josaya ni fún OLÚWA rán án lọwọ láti ṣàwárí ofin Olúwa ti a ti pati naa, o si pa ibọrisa rún ni akoko tìrẹ. N jẹ o nifẹ Kristi pẹlu ìtara?


AKỌSÓRÍ
Kò si si ọba kan ṣáájú rẹ, ti o dabi rẹ, ti o yipada tinútinú ati tọkàntọkàn àti pẹlu gbogbo agbára rẹ, gẹgẹ bii gbogbo ofin Mose, bẹẹni lẹyin rẹ ko si ẹnikan ti o dìde ti o dabii rẹ (2 A. Ọba 23:25)

ÀLÀYÉ KÚKÚRÚ
Àwọn iṣẹ́ búburú ti Mánásè àti Ámónì (Baba nla àti baba Jòsáyà) gbé kalẹ nígbà ìjọba wọn gege bí ọba tí fẹsẹ múlẹ̀ ni ilẹ̀ naa, àwọn ènìyàn naa si ti kọ (kùnà) láti ronupiwada ní tòótọ́.

Jòsáyà tí fẹ́ràn Ọlọ́run tọkàntọkàn nínú ìgbọràn si ofin Ọlọ́run ní Deuteronomi 6:4-5. Ifẹ yii ni o ru u soke láti gbógun ti àwọn igbesẹ (àṣà) ibọrisa àti àwọn ohun búburú tí ó wa ni ilẹ̀ naa ṣáájú dídé orí òye rẹ.

Bíbélì sakosilẹ pé kò sí ọba ṣáájú àti lẹyin rẹ tí ó yí padà sí Olúwa. Eredi èyí ni pé o kọjú ìjà si ẹ̀kọ́ odi àti ìjọsìn eke ju ọba kọba miran lọ, àti Dáfídì pẹ̀lú ẹni tí ó jé pé ó jẹ́ olufokansin si Olúwa, ṣùgbọ́n ko ni iṣẹ́ búburú pupọ láti gbogunti ni asiko tìrẹ.

Ní pàtàkì julọ, ìwé òfin tí a ṣàwárí tí a sì kà fún Josaya ni ó sì òye àti imisi Josaya láti ṣe iṣẹ́ sii fún Olúwa. Gbọ̀ngàn kikede (pipokiki) Olúwa fún àwọn aláṣeyọrí òníwá bí Ọlọ́run kò tii kun, ayé si wa fún ìwọ àti èmi láti fi orúkọ silẹ nibẹ. Sisawari, kika, sisasaro àti fífi ọrọ naa si ise ni kọ́kọ́rọ́ naa. Lọ gba a.

ÀṢÀRÒ FÚN ÌFỌKÀNSÌN
1.    Àwọn tí ó fẹ́ràn Olúwa ní tòótọ́ maa n lakaka láti ran àwọn ẹlòmíràn lọwọ láti ṣe bẹ́ẹ̀ gẹgẹ.
2.    Wọn kọ́kọ́ ṣe ìyẹn nípasẹ̀ ifaraji sì Ọlọ́run nípasẹ̀ yíya ara ẹni sọtọ láti gbọ́ràn sì ẹ̀kọ́ ìwé Mimọ ni ọ̀nà afojuri. Wọn ń gbé ìgbé-ayé wọn fún ihinrere (Jhn. 4:34; I Kor. 2:2). Nítorí náà, o jé ohun tí ó tọna tí ó sì rọrùn fún wọn láti rán àwọn ẹlòmíràn lọwọ láti ṣe bẹ́ẹ̀, gẹ́gẹ́ bí ọna igbe ayé.

ẸSẸ BÍBÉLÌ FÚN ÌPÍNLẸ̀ Ẹ̀KỌ́: Johanu 5:39

ILEPA ÀTI ÀWON ERONGBA
ILEPA: Ilepa ẹ̀kọ́ yii ni lati safihan agbára ọrọ naa ati ipa rẹ fún àwọn tí wọn tẹ́wọ́ gba a nitootọ

ERONGBA: Ní ìparí ẹ̀kọ́ yii, àwọn akẹ́kọ̀ọ́ gbọdọ:
i.   le ṣàlàyé ìfẹ́ àti àwọn iṣẹ́ Jòsáyà fún Ọlọ́run láti ìgbà tí ó ti dé orí òye títí dé òpin sise àtúnṣe rẹ,
ii.  tọkasi àwọn igbiyanju Jòsáyà láti ni òye òfin naa ati bí o ti rún àwọn yoku sókè láti fetísilẹ sii,
iii. sọ ẹni tí obìnrin naa jẹ́ àti ipa tí o kò nínú isẹ àtúnṣe Josaya,
iv. ti dúró daradara láti ṣe ìpinnu, láti faraji si sisasaro àti gbigboran si ọrọ Ọlọrun.

IFAARA
ORÍSUN Ẹ̀KỌ́: I A. ỌBA 13:1-2; 2 A. ỌBA 22; 23:1-25.
Adupẹ lọwọ Ọlọ́run wa fún àṣeyọrí ẹ̀kọ́ kejì tí o pari ni ọṣẹ tí o kọja. A gbagbọ wí pé ó ti ń samulo àwọn òtítọ́ tí ó kọ láti inú ìfihàn ìfẹ́ Ọlọ́run ti o jẹ ìyanu. O ko ni saarẹ ninu ìkọ́ni Olúwa ni orúkọ Jésù. Àmín.

Fún òní àti ọjọ́ ìsinmi tí ó ń bọ̀, a ó maa ṣàgbéyẹ̀wò "ìfẹ́ Josaya fún Ọlọ́run," pẹ̀lú àfojúsùn ríran wá lọ́wọ́ láti rí agbára àti ẹwà òfin Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run nigbati a ba gba a pẹ̀lú ọkàn títẹ.

Josaya ni olu ẹ̀dá ìtàn ẹ̀kọ́ yii. O di ọba Júdà nígbà tí ó wà ní ọmọ ọdún mẹ́jọ. Ní ìgbàanì oso àti òrìṣà ni àwọn ènìyàn naa n bọ. Nigba ti Josaya pé ọmọ ọdún mẹrin-dín-lógún, o gbìyànjú láti mọ bí a ti ń sìn Ọlọ́run ni ọna ti o tọ, nígbà tí ó sì pe ọmọ ọdún mẹrin-dín-lọgbọn, o ṣètò bí bí a o ti tún tẹmpili ṣe.

Nínú tẹmpili naa, olórí alufaa, Hilkiah rí ìwé òfin Ọlọ́run. Akowe ọba Safani mú ìwé naa tọ Josaya lọ, o si bẹ̀rẹ̀ sii ka òfin naa jáde lohun òkè. Bi Josaya tí tẹti sílẹ̀, o rii pé àwọn ènìyàn naa ti ń ṣàìgbọràn sí Ọlọ́run fún ọpọlọpọ ọdún. Nítorí naa, o ránsẹ láti béèrè lọwọ Ọlọ́run ohun tí wọn yoo se, Ọlọ́run si dahun nipasẹ wolii Hulda.

Nígbà tí ọba Josaya gbọ ọrọ naa, o lọ sinu tẹmpili naa, o pe awọn eniyan Juda papọ, o si ka òfin naa fun wọn lohun oke. Josaya ati àwọn ènìyàn naa si seleri láti gbọ́ràn si Ọlọ́run pẹlu gbogbo ọkàn wọn. Josaya fẹ́ràn Ọlọ́run gidigidi, o si gbọ́ràn si Ọlọ́run àti sí òfin Rẹ tọkàntọkàn. Ọlọ́run n pe wa si ibi kan naa. A o gba oore-ọ̀fẹ́ lati se e, bi a ti ń ṣàgbéyẹ̀wò ẹ̀kọ́ naa ni orúkọ Jesu. Amin.

IFAARA SI ÌPÍN KỌ̀Ọ̀KAN
Eyi jẹ ẹ̀kọ́ ọ̀sẹ̀ meji, a si pin in si I àti II pẹlu ìpín A àti B.

ÌPÍN KÍNNÍ: O DA FẸ́RÀN ỌLỌ́RUN
Ipin yii ṣàlàyé nípa Josaya gẹ́gẹ́ bii eso àsọtẹ́lẹ̀ àti bi ọba tí o fẹ́ràn Ọlọ́run ti ko yipada si ọtun àti sí òsì. Sugbọn dípò bẹẹ tí ó ń rin ni gbogbo ọna Dáfídì ti o si n se bi o ti tọ níwájú Ọlọ́run. Ko kuna láti mú àsọtẹ́lẹ̀ ṣé nítorí o fi tinútinú rẹ ara rẹ silẹ láti ṣe àwọn ifẹ Ọlọ́run nigba ti o ṣàwárí iwe òfin naa. O jẹ ìpín ti o n ta Ilepa láti mu ayànmọ sẹ nínú wa ji nípasẹ̀ ohun elo ti o jẹ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run.

ÌPÍN KEJÌ: O DÁRÍ ÀWỌN YOKU LÁTI ṢE BẸ́Ẹ̀ GẸ́GẸ́
Eyi jẹ ìpín tí o mẹ́nuba àwọn iṣẹ́ àtúnṣe Josaya pẹlu alaye. O safihan àwọn igbesẹ ti o yọrísi sisawari ìwé òfin naa, ìrònúpìwàdà Josaya bi a ti ka iwe naa sii, ìbéèrè fun ìmọ̀ràn láti ọwọ Hulda wolii obìnrin naa, kikopa awọn eniyan naa, imubọsipo Àjọ ìrékọjá àti kika iwe òfin Ọlọ́run ni gbangba. Eyi wa fun isoji àti ìbùkún rẹ

KÓKÓ Ẹ̀KỌ́
I.    O DA FẸ́RÀN ỌLỌ́RUN
      A.   ÈSO ÀSỌTẸ́LẸ̀
      B.   ỌBA TI O GBỌ́RÀN SI ỌLỌ́RUN LẸ́NU.
II.   O DARI ÀWỌN YOKU ṢE BẸ́Ẹ̀ GẸ́GẸ́
      A.   O SATUNRI Ọ̀RỌ̀ NAA
      B.   O MU ÌJỌSÌN TÒÓTỌ́ BỌSIPO.

ITUPALẸ Ẹ̀KỌ́
19 August, 2018 | I.  O DA FẸ́RÀN ỌLỌ́RUN (I A. Ọba 13:1-2; 2 A. Ọba 22:1-2).
Dida ni òye Ọlọ́run nípasẹ̀ ìrírí afojuri ni igbesẹ àkọ́kọ́ sì fifẹran Olúwa. Ifẹ naa yoo bẹ̀rẹ̀ sii dàgbà nígbà ti ènìyàn ba wa lábẹ́ ìsọni-dọmọ-lẹyin oníwà-bí-Ọlọ́run. Bi ọrọ Josaya ṣe ri ni yii. Njẹ o fẹ lati fẹ́ràn Ọlọ́run sii? Ẹni ti o n tọ ọ sọ́nà àti ohun ti o fi n tọ ọ sọ́nà ṣe pàtàkì nínú ọrọ yii.

A.   ESO ÀSỌTẸ́LẸ̀ (I A. Ọba 13:1-3; 2 A. Ọba 22:1).
Ẹni ọdún mẹ́jọ ni Josaya nigba ti o bẹ̀rẹ̀ si i jọba (2 A. Ọba 22:1).
i.    I A. Ọba 13:1-2: Ìránṣẹ́ Ọlọ́run kan láti Juda tí sasọtẹ́lẹ̀ ni pato nipa wiwa Josaya lati ba pẹpẹ jẹ nipa sísun egungun àwọn tí ó ń rúbọ sí í lórí rẹ. O fi ami kan han ni pato lati ti i lẹyin (ẹsẹ 3).
ii.  Ọrọ Ọlọ́run ko nii lọ láiṣẹ. Ni akoko ti o yẹ, Josaya ti a sọ àsọtẹ́lẹ̀ rẹ wa gẹ́gẹ́ bii ọmọ ọmọ Hesekiah oba nla ni, o si mu ohun gbogbo ti a sọ nipa rẹ ṣẹ (2 A. Ọba 21:24;23:15-16).
iii. 2 A. Ọba 22:1: A ti àsọtẹ́lẹ̀ yii ni nnkan bii ọọdúnrún ọdun saaju ibi rẹ (I A. Ọba 13:2;2 A. Ọba 22:1,3,17-18). Orúkọ naa Josaya túmọ̀ si "Oluwa satilẹyin." Ni ti àsọtẹ́lẹ̀, o túmọ̀ si pe Josaya yoo jẹgbádùn àtilẹyin Ọlọ́run ni kikun láti mu ayanmọ rẹ ti Ọlọrun fifun sẹ (wo Jer. 29:11; Sek. 4:6).
iv.  Àwọn àsọtẹ́lẹ̀ ti o jade lati ẹnu Ọlọ́run ko le saiwa si ìmúṣẹ. Ranti àwọn iṣẹlẹ Kirusi (2 Kro. 36:33-23; Isa. 44:28; 45:1) ati ilu Bethlehemu (Mik. 5:2). Ko si bi o ti le wu tó, gbogbo àsọtẹ́lẹ̀ Ọlọ́run fún aye rẹ yoo wa si ìmúṣẹ.
v.  Irufẹ àwọn àsọtẹ́lẹ̀ bẹẹ yoo wa si ìmúṣẹ nigba ti o ba duro ninu igbagbọ naa ti o si n gbe lagbegbe ọrọ tabi ofin Ọlọ́run.

B.   ỌBA TI O GBỌ́RÀN SI ỌLỌ́RUN LẸ́NU (2 A. Ọba 22:1-2).
Oun si se eyi ti o tọ ni oju Olúwa, O si rìn ní ọ̀nà Dafidi baba rẹ gbogbo, ko si yipada si apa ọtun tabi apa osi (ẹsẹ 2).
i.   Ni ibamu pẹlu baba-nla rẹ Hesekáyà, Josaya wa ni ipo ọba ti o se pataki julọ láàrin gbogbo ọba Juda (wo 2 A. Ọba 18:1-8). Pe o ṣe ohun ti o tọ loju Olúwa túmọ̀ sí pe o fẹ́ràn, o si gbọ́ràn sì Ọlọ́run lẹ́nu.
ii.  A sakawe rẹ pẹlu Dáfídì nínú gbogbo ìfọkànsìn rẹ si Olúwa, pẹlu àkọsílẹ̀ pe ko yapa kuro ninu rẹ. O faraji pátápátá si gbígbọran si awọn òfin Yahweh ti a kọ sinu iwe mimọ (Wo Deut. 5:32).
iii. Bawo ni o se dára to pe ko yan ipa búburú ti bàbà rẹ, Amoni, àti baba baba rẹ, Manase (2 A. Ọba 21:1-7, 19-20) O seese pe iya rẹ Jedida (ti o túmọ̀ si "olufẹ" 2 A. Ọba 22:1) jẹ obìnrin oluọkansin, ìwà-bí-Ọlọ́run rẹ si ran an lọwọ (wo 2 Tim. 1:15). O han gbangba pe awọn adari oluọkansin ti o maa n wa ninu tẹmpili ati awọn Olugbani-ni-niyanju aafin tun ran an lọwọ lati borí ipa búburú baba rẹ.
iv.  Eyi ti o wuni lori julọ, ẹdùn ọkan tìrẹ fun ododo ti o waye nipasẹ imọ tìrẹ àti isamulo ifẹ Ọlọ́run ran an lọwọ, bi o ti lẹ jẹ pe o ni ìrírí iwa ipa, ìtajẹsilẹ àti ìsọ̀tẹ̀  ti o jẹ abuda ìjọba ranpẹ baba rẹ. Ifẹ tootọ fun Ọlọ́run nípasẹ̀ imọ ti o waye nípasẹ̀ ìrírí naa maa n ran ènìyàn lọwọ láti gbọ́ràn si Ọlọ́run lẹ́nu ni igbakugba laye.
v. O ko ni awawi kankan lati mase fẹ́ràn Ọlọ́run. N jẹ o fẹ́ràn Rẹ ni tòótọ́? Safihan eyi nípasẹ̀ àwọn iwa rẹ.
vi. O ni agbara lati yan yala gbígbọran si Ọlọ́run lẹ́nu tàbí láti mase bẹẹ; ṣùgbọ́n bi ifẹ rẹ fun Ọlọ́run ti jinẹ to ni yoo sọ ohun ti iwọ yoo yán.

ÀWỌN Ẹ̀KỌ́ TÍ A RÍ KỌ
1.  Ohunkóhun ti Oluwa ba sọ wi pe yoo sẹlẹ ni ibamu pẹlu akoko Rẹ ati iseun ifẹ Rẹ yoo sẹlẹ dandan.
2.  Ìgbọràn àti ifẹ fun Ọlọ́run jẹ ohun ti a le yan; o dara julọ lati fi ifẹ yàn wọn.

IṢẸ́ ṢÍṢE
Ọkàn ti o ni irẹlẹ ti o si ronupiwada maa n rí oju Ọlọ́run. Salaye.

IDAHUN TI A DABAA FUN IṢẸ́ ṢÍṢE
i.  Ìrònúpìwàdà láti ọkan irẹlẹ ni Ọlọ́run n beere fun (Isa. 66:2)
ii.  Ọkan ti o ba ronupiwada yoo sunmọ Ọlọ́run nítorí a o ti dari ẹsẹ ìrù ọkan bẹẹ jii (Jak. 4:6-10; Jhn. 1:9).
iii.  Ọlọ́run yoo fi oore-ọ̀fẹ́ ati aanu han si iru ọkan bẹẹ (Jóẹ́lì 2:12-13).
iv.   Ọlọ́run yoo da si ọrọ iru ọkan bẹẹ yio o si sọọ di ọtun (Ìṣe 3:19).
v.    Ìrònúpìwàdà tòótọ́ dalori ọrọ Ọlọ́run ti a fi òtítọ́ waasu ti a si samulo.
vi.   Wọn ka ọrọ naa si Josaya, o si ronupiwada lori ifihan ti o tẹle ọrọ naa.
vii.  O di alágbára nípasẹ̀ ọrọ naa lati se ifẹ Ọlọ́run.
viii. O tun dari awọn eniyan naa pada sọ́dọ̀ Ọlọ́run nípasẹ̀ gbígbọran si Ọrọ Rẹ.
ix.   Awọn igbesẹ wọ̀nyí tun fa iwalaaye Ọlọ́run si ọdọ awọn eniyan Rẹ lẹẹkan sii.
August 19, 2018 ÌJỌ ÀPỌ́SÍTÉLÌ KRISTI. Ẹ̀KỌ́ ỌJỌ́ ÌSINMI , Ẹ̀KỌ́ KẸTA : - IFẸ JÒSÁYÀ FÚN ỌLỌ́RUN. August 19, 2018 ÌJỌ ÀPỌ́SÍTÉLÌ KRISTI.  Ẹ̀KỌ́ ỌJỌ́ ÌSINMI , Ẹ̀KỌ́ KẸTA : - IFẸ JÒSÁYÀ FÚN ỌLỌ́RUN. Reviewed by Muyiwa Abodunrin (Muyilight) on August 19, 2018 Rating: 5

No comments:

Powered by Blogger.