ÌJỌ ÀPỌ́SÍTÉLÌ KRISTI Ẹ̀KỌ́ ỌJỌ́ ÌSINMI. ISỌRI KÍNNÍ: IFẸ ENIYAN SI ỌLỌ́RUN. July 22, 2018. Ẹ̀KỌ́ KÍNNÍ - ÀWỌN BABA NLÁ WA FẸ́RÀN ỌLỌ́RUN TỌKÀNTỌKÀN.

--> Note :- Are you born again? You are never going to win the battle against the devil if you are not born again. I plead with you to give your life to Jesus today because the longer you stay in sin and remain unsaved, the more hardened your nature becomes against the purpose and the way God wants you to be for His purpose. To give your life to Jesus now, say this prayer: “Father, I come to You in the name of Jesus. I know that I am a sinner and I cannot save myself but Jesus died for me and shed His blood that I might be saved. Today, I accept Jesus as my Lord and Saviour. Jesus, I ask You to come into my heart, be my Lord, wash me with Your blood and make me whole. I believe with my heart and confess with my mouth that Jesus is my Lord. Thank You for saving me. In Jesus' name I pray. Amen.” I congratulate you and welcome you to the family of God if you have sincerely said that prayer. Now you are fit to discover, know and walk in your destiny. Call our helpline on +2348037252124, Join Our Daily Whatsapp Devotionals Group : +2347033046607 for Daily Devotionals, crucial discipleship and counselling.s"
ÌJỌ ÀPỌ́SÍTÉLÌ KRISTI  Ẹ̀KỌ́ ỌJỌ́ ÌSINMI.    ISỌRI KÍNNÍ: IFẸ ENIYAN SI ỌLỌ́RUN.  July 22, 2018.    Ẹ̀KỌ́ KÍNNÍ - ÀWỌN BABA NLÁ WA FẸ́RÀN ỌLỌ́RUN TỌKÀNTỌKÀN.




ÌJỌ ÀPỌ́SÍTÉLÌ KRISTI
Ẹ̀KỌ́ ỌJỌ́ ÌSINMI.

ISỌRI KÍNNÍ: IFẸ ENIYAN SI ỌLỌ́RUN.
July 22, 2018.

Ẹ̀KỌ́ KÍNNÍ.
ÀWỌN BABA NLÁ WA FẸ́RÀN ỌLỌ́RUN TỌKÀNTỌKÀN.


Bi Noa ṣe yàn láti fẹ́ràn Ọlọ́run, ki ki o si tẹle nínú ìran wíwọ rẹ àti bi Ábúráhámù ṣe yàn láti tẹle Yahweh ti ko mọ dáadáa, jẹ ẹri ìfẹ́ ti àwọn baba wa ní si Ọlọ́run tòótọ́. Iru ifẹ yi ko gbọ́dọ̀ kú ni ìran wa yii.

AKỌSÓRÍ
Nípa ìgbàgbọ́ ni Noa, nígbà tí Ọlọ́run ki lọ ohun ti ko i ti ri fun un, o bẹru Ọlọ́run, o sì kan ọkọ fún ìgbàlà ile rẹ, nípa èyí tí o da aye lẹbi, o si di ajogún òdodo tii se nípa ìgbàgbọ́ (Hébérù 11:7).

ÀLÀYÉ KÚKÚRÚ
Lẹ́yìn ti ènìyàn ba ti gba Kristi tan, o ni àwọn ipele aye ti Kristẹni maa n gbe. Ọ̀pọ̀ n gbe lori awọn Ìpínlẹ̀ àwọn ìrírí Kristẹni, ninu ile lasan, nibi ti o ṣókùnkùn to banininujẹ, to si dudu biribiri. Ọ̀pọ̀ àwọn mìíràn lori ilẹ títẹ pẹrẹsẹ. Wọn fi àwọn Ìpínlẹ̀ àkọ́kọ́ silẹ wọn si tẹsiwaju. Ìtànṣán í mọ́lẹ̀ wọlé ṣùgbọ́n iwo oju wọn wa lori awọn iṣẹlẹ nípa wọn. Wọn sunmọ ayé timọtimọ. Síbẹ̀ àwọn mìíràn n gbe loke nibi gíga níbi tí ìtànṣán I mọ́lẹ̀ àti ìlọ́wọ́wọ ti kun àwọn ìyẹ̀wù náà. Ariwo àti àwọn ohun ìdiwọ̀ igboro òde aye ko tilẹ̀ di wọn lọwọ. Ofurufu mọ kedere. Isọ́nà wọn dojúkọ ofeefe àwọsánmọ àti àwọn oke to jinna rere. Igbe aye àwọn wọ̀nyí tayọ ile aye yii, àwọn ẹni ti a pamọ pẹlu Kristi nínú Ọlọ́run.

Nóà gbé ìgbé aye rẹ lori ibi títẹ́jú gíga yii a si ṣàwárí rẹ Ọlọ́run si so o pọ pẹlu Rẹ ẹni tí a ti kilọ fun ṣáájú nípa ìparun ọjọ iwájú to n rọdẹdẹ lori ayé igba naa. O safihan ìgbàgbọ́ rẹ nípa fifi ikilọ Ọlọ́run si ise lori ikun omi tó n bọ, lati gba àwọn ara ile rẹ la. Ìfẹ́ rẹ̀ fun Ọlọ́run ni a wa sọ bayii, "ìgbàgbọ́ nínú ìṣe"

Lórí ipese gíga tí ìgbàgbọ́ yii ni Ọlọ́run n fẹ́ ki gbogbo wa maa gbe titi lọ laiyẹsẹ. Ki Ọlọ́run fun ọ ni oore-ọ̀fẹ́ lati jẹ aṣojú Rẹ.

ÀṢÀRÒ FÚN ÌFỌKÀNSÌN
1.   Igbesẹ sọ̀rọ̀ kéékèèké ju ohun lọ. Mase sọ fun wa bi o ti fẹ́ràn Ọlọ́run to, safihan rẹ nípa iwa, ọrọ ati ise rẹ.
2.   Tutu àti Esteri ni a le fi soju fún ajẹmọ-obirin nínú àkíyèsí yii (Rúùtù 1:16-17; Esteri 4:6).
3.   Gbogbo wa gẹ́gẹ́ bi onigbagbọ gbọ́dọ̀ fi ifẹ wa han fun Ọlọ́run nipa wiwaasu ihinrere ti Kristi lojoojumọ (I Kor. 9:16)

ẸSẸ BÍBÉLÌ FÚN ÌPÍNLẸ̀ ÈKÓ : 1 Pétérù 3:20

ILEPA ÀTI ÀWỌN ERONGBA
ILEPA: Ẹkọ yii fẹ lati ran àwọn olukawe lọwọ láti rí àti láti ni òye àwọn iṣẹ́ ìfẹ́ tí a ṣe àfihàn nípa Noa àti Mose pẹlu iwoye pé ki a se ìpinnu lati maa se bẹẹ gẹ́gẹ́.

ÀWỌN ERONGBA: Ni opin ẹ̀kọ́ ọlọsẹ meji yii, àwọn onkawe:
i.   Gbọdọ le sọ ìyàtọ̀ láàrin ìfẹ́ nínú ìṣe àti ìfẹ́ nínú ọrọ;
ii.  Ni a n reti láti ṣe ídámọ̀ àti àlàyé irufẹ làákàyè ti o jé àti lẹhin fún isafihan ifẹ Noa àti Ábúráhámù.
iii.  Ni a n reti gbọ́dọ̀ ti pinnu lati se afihan iru ife yẹn fún Ọlọ́run nípa "dídàgbà" tí ìgbàgbọ́ wọn;àti
iv.  Gbọdọ pinnu láti ṣe yiyan àti àwọn ise ti yoo jẹ ki a ri a ri aridaju saka ifẹ wọn fun Ọlọ́run nígbàkúùgbà.

IFÀÀRÁ
ORÍSUN Ẹ̀KỌ́: GENESIS 6:7,8; HEBERU 11:7
Àṣẹṣẹ parí ọwọ àwọn ẹ̀kọ́ kan fun tí saa àkọ́kọ́ tiise ilaji ọdún àkọ́kọ́ pẹ̀lú àkòrí gbooro "IFẸ NÍNÚ ÌṢE" Ogo ni fun Ọlọ́run fun àwọn ifihan ti a ti ri gba àti oore-ọ̀fẹ́ nípa eyi ti o ti fi n ran wa lọwọ lati safihan (fifi si ise) ìdánilójú wa. Kedere ni a ri pe ohunkóhun tí Ọlọ́run ti ṣe, ti o si n se lọ́wọ́ lọ́wọ́ ni wọn n waye nípasẹ̀ ìfẹ́, èyí ni pe gbogbo igbese Ọlọ́run ni ifẹ jẹ orísun fun ni ọna gbogbo. Nitori naa, ipenija rẹ wa ninu I Jhn. 3:18. A ri Ọlọ́run ninu osu mẹ́fà àkọ́kọ́ ti odun yii. Kin ni ki a sọ nípa ti eniyan? N jẹ eniyan ti dahun? Eyi ni ipenija ti apa kejì tiise ilaji kejì ọdún. Eyi jẹ ìtẹ̀síwaju apa kinni IFẸ NINU ÌṢE.

Lẹẹkan sii, erongba ati awọn eto Ọlọ́run maa n dagba ju eniyan lọ. Nítorí náà, nigbakugba ti Ọlọ́run bá fẹ́ ṣe nnkan, ohun tuntun, O maa n fi suuru wa àwọn ti wọn ni ìgbàgbọ́ (bi o ti wu ki o kere mọ) ninu Oun, ìgbàgbọ́ kékeré yii ni o ti jẹ mímọ-ọn-mọ àti àìmọ-ọn-mọ ṣe àkọsílẹ̀ ninu ifẹ.

Nigbakugba tí O bá rí irú eyi, Oun, yoo wọn lọwọ nipa mímọ-ọn-mọ ṣe igbekalẹ ibasepọ pẹlu wọn. Eyi n fa didanwo, jíjẹ́rìí àti sise agbeyẹwo ÌGBỌRÀN àti IGBAGBỌ nípa YIYAN ATI àwọn igbesẹ wọn, eyi ti wọn yoo finufindọ safihan ati ninu ìfẹ́.

Iru wọn ni Noa, Abrahamu, Jacobu, Dáníẹ́lì, Esteri, Rúùtù abbl. Wọn yan Ọlọ́run wọn rọ mọ On, ni ohun gbogbo ko lọ deede, ninu dídáwa ninu awọn igbesẹ ti o lewu, àṣẹ ainilaari tí a fifun wọn latokewa abbl. Àwọn igbesẹ àti yiyan wọn safihan ifẹ ninu Ọlọ́run ati ifẹ fun Un, eyi ti o si wa ni ipa níkẹyìn lori ìran àti ayanmọ wọn.

Koko ẹ̀kọ́ àkọ́kọ́ ti saa yii ni AWỌN BABA NLA WA FẸ́RÀN ỌLỌ́RUN TỌKÀNTỌKÀN. A o tẹnumọ àwọn IGBESẸ ìfẹ́ ti Noa ati Abrahamu safihan rẹ. A le maa ni àwọn anfani tí a ń gbádùn lonii (ìpéjọpọ pẹlu awọn ara, irinajo lọ sí Jerúsálẹ́mù, ninu oríṣiríṣi ẹ̀dá Bíbélì àti àwọn orí òkè adura) ṣùgbọ́n a o ri àwọn ènìyàn ti wọn ri Ọlọ́run, ati nípasẹ̀ igbesẹ ati yiyan, ti o yọrí sí ISAFIHAN, ohun ti wọn mọ pátápátá (I Jhn. 3:18).

A gbàdúrà pé a o gba irusókè láti fi ìfẹ́ wá si Ọlọ́run, ọrọ Rẹ, ilé àti àwọn ènìyàn Rẹ hàn. Àmín.

IFÀÀRÁ ṢÍ ÌPÍN KỌỌKAN:
Ẹkọ yii jẹ ẹ̀kọ́ ọlọsẹ méjì, ọ̀kọ̀ọ̀kan ìpín wọ̀nyí, I àti II ní a tẹsiwaju lati se atunpin si ipa A ati B ni sisẹ-ń-tẹle.

ÌPÍN KÍNNÍ: ṢÁÁJÚ IKÙN OMI: ÀPẸẸRẸ NOA
Ipin yii se àpèjúwe Noa, olódodo eniyan ati bi o tí yàn Ọlọ́run láárí àwọn olùṣe búburú ninu àwùjọ ni asiko tìrẹ. Ọlọ́run ní láti ṣe afọmọ ayé búburú àti àwọn ènìyàn ika naa, ṣùgbọ́n o gbọ́dọ̀ da àwọn perete si fun eredi ibisi. O ṣàwárí Noa o si fun un ni àṣẹ /ẹ̀kọ́ lori ohun ti yoo se ni ìgbáradì fun ìparun tó n bọ wa sori aye igba naa. Noa fẹ Ọlọ́run o si fi eyi sì ìṣe nípa titẹsiwaju lati kan ọkọ ninu eyi ti Ọlọ́run pa òun àti ìdílé rẹ mọ pẹlu awọn àṣàyàn ẹranko. Lẹ́yìn ikùn omi, Nóà si papa n tẹsiwaju lati wa ni iha tí Ọlọ́run.

ÌPÍN KEJÌ: LẸ́YÌN IKÙN OMI: ÀPẸẸRẸ ÁBÚRÁHÁMÙ
Ipin yii dale orí Ábúráhámù; ọkùnrin tí o mọ Ọlọ́run, Ọlọ́run fẹ ẹ òun pẹlu si safihan ìgbàgbọ́ si I. Ọlọ́run si fa a yọ laarin ọpọ ènìyàn, o pàṣẹ fún un lati fi ile baba ati orilẹ èdè rẹ silẹ lọ sí ilẹ kan tí Ọlọ́run n fẹ́ lati fun un. Abrahamu gbọ́ràn. Bákan naa, lẹ́yìn ti Ọlọ́run ti mu ìlérí Rẹ ṣẹ lati fun Abrahamu ni ọmọkùnrin kan. O mu un wa si gbàgede idanwo. Ninu gbogbo iṣẹlẹ wọ̀nyí, a ri Abrahamu bi o ti n safihan ifẹ aisẹtan ati igbagbọ ninu Ọlọ́run. Ipin yii yoo sọ fun wa nípa ifi ìgbàgbọ́ si ise àti àwọn ẹri ísọniji nípa Abrahamu.

KÓKÓ Ẹ̀KỌ́
I.   ṢÁÁJÚ ÌKÚN OMI: ÀPẸẸRẸ NOA
     A.   O YAN ỌLỌ́RUN NINU AYE BÚBURÚ
     B.   O RỌ MỌ ỌLỌ́RUN ONIFẸ
II.   LẸ́YÌN IKÙN OMI: ÀPẸẸRẸ TI ABRAHAMU
      A.  O FI ÌGBỌRÀN TẸLE ỌLỌ́RUN
      B.  A DAN IFẸ RẸ WO.

ITUPALẸ Ẹ̀KỌ́
22 July, 2018 | I.  SAAJU IKUN OMI: ÀPẸẸRẸ NÓÀ (Gen. 6,7,8)
Iwa ibi ti wa gbilẹ kan lori ilẹ ayé. O tilẹ̀ n gbiro /halẹ lati pa ohun rere gbogbo run. Ọkùnrin olódodo ka sẹku, Noa. Ọlọ́run ran ikun omi naa lati mu rere bọsipo lórí ilẹ̀ ayé. Nígbà tí o jade ninu ọkọ, ohun àkọ́kọ́ paa ti Noa ṣe ni pe o kọ pẹpẹ kan o si sin Ọlọ́run. Isafihan ifẹ àti ìgbàgbọ́ aisẹtan tó sọ wọ́n.

A.   O YÀN ỌLỌ́RUN NINU AYÉ BÚBURÚ (Gen. 6:1-9; Heb. 11:7).
Wọnyi ni itan Noa ṣe olóòótọ́ àti ẹni tí o pé ní ọjọ́ ayé rẹ. Noa n ba Ọlọ́run rín (6:9).

i.  Inu Ọlọ́run si bajẹ si àwọn ẹ̀dá ọwọ Rẹ, O si pinnu lati pa àwọn ẹ̀dá ti O ti da ru kuro lori ilẹ àti ènìyàn, ati ẹranko àti ohun tí n rako àti ẹyẹ ojú ọrùn (Gen. 6:6,7). N jẹ ènìyàn tii yipada? Bii Énọ́kù (Gen. 5:22,24) ti o ba Ọlọ́run rin, Noa naa tun jẹ ipenija miran (ẹsẹ 9)? Igba gbogbo ni Ọlọ́run fi n ni ẹlẹ́rìí (Ìṣe 14:17). Àwọn tí wọn n ba A rin saaba maa n sisẹ fun Un.
ii.   Noa yan lati ba Ọlọ́run rin (ẹsẹ 9) ni ìran wíwọ tí a parun níkẹyìn. O yan láti da yàtọ̀, ya ara rẹ sọtọ láti sisẹ fun Ọlọ́run. Adamu ati Efa yan láti gbọ́ràn si esu lẹ́nu; Jesu yan láti gbọ́ràn si Ọlọ́run bàbà Rẹ lẹ́nu. Nnkan ti a yàn n safihan iru ènìyàn ti a jẹ.
iii.  A ko mọ bi Noa ti mọ bibeli to, ṣùgbọ́n a le ri iyan rẹ ailegbẹ, aigbajumọ àti elewu ti o yan pẹ̀lú igbesẹ afojuri ni ti ifẹ rẹ fun Ọlọ́run ni òtítọ́ àti ni ise (I Jhn. 3:18). Bawo ni a ṣe n safihan ifẹ si Ọlọ́run, ọrọ Rẹ ati awọn eniyan Rẹ. Ọlọ́run satilẹyin (jẹri sì ) ìyàn àti igbesẹ rẹ ti ko gbajumọ (2 Pet. 2:1-5).
iv.  Noa ti orúkọ rẹ túmọ̀ sí "ìtùnú" ri Oore-ìfẹ́ gba lati wa láàyè lẹ́yìn ikùn omi kin-ni lati jẹ ẹni àkọ́kọ́ ti Ọlọrun yoo lo lati bẹ̀rẹ̀ ìran (akoko) miran. Kin ni ìdí? O yan lati wa pẹ̀lú Ọlọ́run, nítorí eyi, Ọlọ́run bọlá fun un. N jẹ a ṣe tán fun ninu iran yii?
v.   Gen. 6:13-22, Ọlọ́run yan lati ba eniyan ẹlẹ́ran ara soro, nípa ohun ti o fẹ ṣe ṣáájú àwọn iṣẹlẹ! Bi ẹnikẹ́ni bá yan Ọlọ́run, iru ẹni bẹẹ yoo gbadun àwọn anfaani aiseejuwe.
vi.  Àmì ìfẹ́ tootọ fun Ọlọ́run, àti ìgbàgbọ́ ninu Ọlọ́run ni lati se ìlérí fun Un nígbà tí gbogbo àwọn yòókù ba n se lòdì si ifẹ Rẹ; nítorí o ni ère pupọpupọ.

B.   O RỌ MỌ ỌLỌ́RUN ONIFẸẸ (Gen. 6:13-21; 7:1-4; 8:20-22).
Noa si tẹ pẹpẹ fun Olúwa; O si mu ninu ẹranko mimọ gbogbo ati ninu ẹyẹ mimọ gbogbo, o si ru ẹbọ ọrẹ sisun lori pẹpẹ naa (Gen. 8:20).
i.  Rirọmọ niise pẹlu lilẹmọ (sisopọ, didi ẹyọ kan) pẹlu ẹnikan tabi nǹkan kan. Ede yii ni a saaba maa n gbọ ni akoko ti ìgbéyàwó (láàárín okunrin àti obìnrin) ba ti waye (Gen. 2:24). Yiyan Ọlọ́run ni igbesẹ àkọ́kọ́ láti ni ibasepọ pẹlu Rẹ.
ii.  Noa gbọ ọrọ láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run, o si n tẹsiwaju láti máa gbọ láti ọ̀dọ̀ Rẹ láìsí ìdíwọ̀, ṣáájú ikun omi (6:13 siwaju), lẹyin kíkan ọkọ (6:22; 7:1-5) lẹyin ìkún omi (7:24; 8:1-5), lẹyin ti wọn ti kuro ninu ọkọ (8:15, 20-22). Títẹtisilẹ, gbigbọ àti ṣíṣe ni àwọn ọ̀nà láti mú ibasepọ wa pẹlu Ọlọ́run lágbára sii.
iii.  Noa gbọ nnkan ti Ọlọ́run wi. Kíkan ọkọ? N jẹ ẹnikan ti ṣe eyi ri? Rireti ọjọ? N jẹ ojo ti rọ ri (Gen. 2:5)? Finuro jíjẹ àjèjì, ainilaari àti imọ ọgbọ́n ti o nilo (Gen. 6:13-22; 2:15). Àbáyọ ti Ọlọ́run fi ṣàwárí rẹ.
vi.  Noa tẹti lélẹ̀ gbọ Ọlọ́run, o si gbọ́ràn si I; a fi ìgbàlà san ẹsan fun un kuro lọwọ ikùn omi nípa ọkọ naa (àpẹẹrẹ ẹni pípé bii Jesu, ọkọ ààbò wa).

ÀWỌN Ẹ̀KỌ́ TÍ A RÍ KỌ
1.   Àwọn nnkan ti a yàn ni yoo sọ irú igbesẹ wa èyí tí yoo ni ipa lori ayanmọ wa.
2.   Ọlọ́run sọ̀rọ̀ ni onírúurú ọ̀nà àti ní lè mọ lè mọ. Títẹtisi I àti rirọmọ On nibikibi àti nígbà gbogbo yoo safihan igbekalẹ wa ati ifẹ wa ninu ise. Àwọn wọ̀nyii yoo mu ibasepọ aidibajẹ dúró, eyi tiise koko pàtàkì fún ìmúṣẹ.

Te lori Akojuwe yii ki o fi lo si ibi ti awon eko ati eyin wa kale si 

ÌṢẸ́ ṢÍṢE
Abrahamu safihan ìfẹ́ nínú ìṣe nípa fífi ti àwọn ẹlòmíràn ṣáájú (Gen. 13:1-18) nípa gbígbé igbesẹ elewu fun àwọn alaiyẹ (Gen. 14:1-17) àti gbígbàdúrà ilaja fun àwùjọ tí o dibajẹ (Gen. 18:23-33; 19:29), N jẹ a ri ẹ̀kọ́ kankan kọ?
ÌJỌ ÀPỌ́SÍTÉLÌ KRISTI Ẹ̀KỌ́ ỌJỌ́ ÌSINMI. ISỌRI KÍNNÍ: IFẸ ENIYAN SI ỌLỌ́RUN. July 22, 2018. Ẹ̀KỌ́ KÍNNÍ - ÀWỌN BABA NLÁ WA FẸ́RÀN ỌLỌ́RUN TỌKÀNTỌKÀN. ÌJỌ ÀPỌ́SÍTÉLÌ KRISTI  Ẹ̀KỌ́ ỌJỌ́ ÌSINMI.    ISỌRI KÍNNÍ: IFẸ ENIYAN SI ỌLỌ́RUN.  July 22, 2018.    Ẹ̀KỌ́ KÍNNÍ - ÀWỌN BABA NLÁ WA FẸ́RÀN ỌLỌ́RUN TỌKÀNTỌKÀN. Reviewed by Muyiwa Abodunrin (Muyilight) on July 22, 2018 Rating: 5

No comments:

Powered by Blogger.