ÌJỌ ÀPỌ́SÍTÉLÌ KRISTI Ẹ̀KỌ́ ỌJỌ́ ÌSINMI Ẹ̀KỌ́ KEJÌLÁ FUN June 24, 2018 : AKORI - JÉSÙ Ń TẸSIWAJU NÍNÚ ÌFẸ́ LẸ́YÌN ÀJÍǸDE.

--> Note :- Are you born again? You are never going to win the battle against the devil if you are not born again. I plead with you to give your life to Jesus today because the longer you stay in sin and remain unsaved, the more hardened your nature becomes against the purpose and the way God wants you to be for His purpose. To give your life to Jesus now, say this prayer: “Father, I come to You in the name of Jesus. I know that I am a sinner and I cannot save myself but Jesus died for me and shed His blood that I might be saved. Today, I accept Jesus as my Lord and Saviour. Jesus, I ask You to come into my heart, be my Lord, wash me with Your blood and make me whole. I believe with my heart and confess with my mouth that Jesus is my Lord. Thank You for saving me. In Jesus' name I pray. Amen.” I congratulate you and welcome you to the family of God if you have sincerely said that prayer. Now you are fit to discover, know and walk in your destiny. Call our helpline on +2348037252124, Join Our Daily Whatsapp Devotionals Group : +2347033046607 for Daily Devotionals, crucial discipleship and counselling.s"
ÌJỌ ÀPỌ́SÍTÉLÌ KRISTI  Ẹ̀KỌ́ ỌJỌ́ ÌSINMI  Ẹ̀KỌ́ KEJÌLÁ FUN June 24, 2018 : AKORI - JÉSÙ Ń TẸSIWAJU NÍNÚ ÌFẸ́ LẸ́YÌN ÀJÍǸDE.



ÌJỌ ÀPỌ́SÍTÉLÌ KRISTI
Ẹ̀KỌ́ ỌJỌ́ ÌSINMI

Ẹ̀KỌ́ KEJÌLÁ
June 24, 2018

JÉSÙ Ń TẸSIWAJU NÍNÚ ÌFẸ́ LẸ́YÌN ÀJÍǸDE.

Jesu ń tọ àwọn ọmọ ẹ̀yìn lẹ́yìn àjíǹde Rẹ. Bẹẹni o rán Ẹ̀mí Mímọ́ Rẹ ni ìmúṣẹ ìlérí ìfẹ́ Rẹ̀.

AKỌSÓRÍ
Èmi ki yóò fi yín silẹ ni aláìní baba: èmi yóò tó yín wà. Nigba díẹ̀ sii, ayé kí yóò si ri Mi mọ, ṣùgbọ́n ẹyin yóò rí Mi, nítorí tí Èmi wà láàyè, ẹyin yóò wà láàyè pẹ̀lú (Jòhánù 14:18-19).

ALAYE KÚKÚRÚ
Ifẹ̀ tootọ máa ń lágbára, ó si má a n pe. Omi pupọ ko le paná ìfẹ́ tòótọ́. Ìfẹ́ tòótọ́ tí Kristi ti fẹ́ àwọn ọmọ-ẹ̀yìn Rẹ̀ mú kí ó lè sọ gbólóhùn pé òun n ṣe ohun tí ó wà nínú akọsórí wà fun ẹ̀kọ́ yii. Nítorí ti o fẹ́ràn wọn, O wí pé, "Èmi ki yoo fi yín silẹ láìní bàbà", "Èmi o tọ yín wá" Bákan náà fún ìfẹ́ Rẹ̀ sì wọn... O sì wí pé nígbà díẹ̀ sii, ayé kí yóò sì rí Mi mọ, ṣùgbọ́n ẹyin yóò rí mi, nítorí tí ó fẹ́ràn wọn, Wọn yóò wà láàyè gẹ́gẹ́bí òun ti wá láàyè. Eyin jẹ́ ìyàlẹ́nu. Jésù nìkan tí ó lè ṣe àfihàn ìfẹ́ àìlẹ́gbẹ bí èyí, O jẹ olotitọ sì ọrọ ìfẹ́ yii, nítorí O jáde lọ láti wà wọn kiri, lẹhin àjíǹde, gẹgẹ bi ẹ̀kọ́ yii. Jésù ni àpẹẹrẹ wa. Ìfẹ́ ko le pọju láéláé, àyàfi tí kò bá tó. Ìfẹ́! Ìfẹ́!! Ìfẹ́!!!.

ÀṢÀRÒ FÚN ÌFỌKÀNSÌN
1.    Oluwa ti o jíǹde fẹ́ràn àwọn ọmọ ẹ̀yìn Rẹ̀ pẹlu ìfẹ́ pípé àti ìfẹ́ tí kì kú.
2.    Jésù ń dá ìfẹ́ Rẹ̀ tí ko ṣeé ṣàpèjúwe lu wọn (àwọn ọmọ ẹ̀yìn), lẹ́yìn àjíǹde Rẹ ati síwájú sii.

ILEPA ÀTI ÀWỌN ERONGBA Ẹ̀KỌ́
ILEPA: Ilepa ẹ̀kọ́ yii ni lati sọ pe ìfẹ́ Ọlọ́run fún àwọn ọmọ ẹ̀yìn Rẹ tẹsiwaju lẹ́yìn àjíǹde.

ÀWỌN ERONGBA: Ní òpin ẹ̀kọ́ yii, àwọn akẹ́kọ̀ọ́ gbọdọ
i.   le mọ pe ìfẹ́ pípe ni o ru Olúwa tí o jíǹde sókè láti máa wá àwọn ọmọ-ẹ̀yìn Rẹ ti o ti ṣáko kiri.
ii.  le mọ pe nitori ìfẹ́ ni Jésù ṣe wá láti inú ògo láti ṣàwárí, kí O si se ìràpadà àwọn ẹlẹ́ṣẹ, bẹẹni kò sì sú ú láti wá àwọn asako pẹ̀lú ọrọ ifẹ.
iii.   le mọ pe, gẹgẹ bí àfihàn ìfẹ́ Rẹ̀. Kristi mú ìlérí Baba (Ẹ̀mí Mímọ́) sẹ fún gbogbo wa.

IFAARA
ORÍSUN Ẹ̀KỌ́: JÒHÁNÙ 21:1-19; ÌṢE 1:8; 2:1-25.
Ogo,iyin àti ọlá fún ìjọ Rẹ lakoko tí o n yọnda ọrọ ẹ̀mí àsè ọkàn lore, àti àmọ́ ayanmọ fún ìjọ Rẹ lakoko tí o yẹ nípasẹ̀ ọrọ Rẹ, tí ọna naa si n ye wa si i ni ojojumọ. Ẹ̀kọ́ yii ni ìkẹyìn ilé ẹ̀kọ́ ọjọ ìsinmi ọwọ yii (January si June, 2018).Èyí ti o kọja jẹ ẹ̀kọ́ kọkànlá niti ṣáá yii. O dalori ìfẹ́ ìrúbọ Jésù, ó si sọ bi Jésù Olúwa wa se fi tinútinú fi ara Rẹ ṣe tútù fún ẹsẹ aráyé, nípa èyí tí O fi ru ẹbọ oòrùn dídùn sí Ọlọ́run lẹẹkan ṣoṣo. Èyí jẹ́ ìfẹ́ nínú ìṣe gẹgẹ bí Olúwa ti fi hàn.

Ẹ̀kọ ti òní yii ni o kẹ́yìn, ṣùgbọ́n kí i ṣe Òun ni ó kéré jù lọ. O safihan bí ìfẹ́ Jésù Kristi fún àwọn ọmọ ẹ̀yìn Rẹ ṣe ga tó. Ǹjẹ́ ìfẹ́ tí o mú Jésù wá sí ayé, tí ó mú Un lọ si ori igi Àgbélébù ha a parí sì Kalfari bí? Rárá. O jẹ ìfẹ́ tí ko lópin tí o n tẹsiwaju lẹ́yìn àjíǹde Rẹ. O wa lara awọn ọmọ ẹ̀yìn tí wọn tí pinnu láti bá ọna ti wọn lọ, o si mú wọn padà wá sínú isẹ naa. Ìfẹ́ tòótọ́ ni yẹn. Ki Ọlọ́run ki o rán wa lọwọ láti mọ àgbàrá ìfẹ́ Rẹ̀ sì wá, kí àwa náà bá a lè di irinsẹ tí o darapọ ni títàn ìfẹ́ Rẹ̀ kalẹ ni orúkọ Jésù. Àmín.

IFAARA ṢÍ ÌPÍN YII
ÌPÍN KÍNNÍ: JÉSÙ Ń TẸSIWAJU NÍNÚ ÌFẸ́NI LẸ́YÌN ÀJÍǸDE
Ípin kansoso tí o wà ní ẹ̀kọ́ èyí. O jẹ láti sọ nípa Ìtẹ́siwaju ìfẹ́ni Jésù fún àwọn ọmọ ẹ̀yìn Rẹ̀, lẹ́yìn tí O ti jíǹde. Ọ̀nà méjì ni a o gba wo o (a) O samoju àwọn ọmọ-ẹ̀yìn ti wọn fọn káàkiri (b) O ri pe Ẹ̀mí Mímọ́ sọkalẹ. Ẹsẹ Bíbélì ti a yàn jẹ́ láti mú ìjíròrò ẹ̀kọ́ yii jáfáfá, àwọn ni Jòhánù 21:1-25. O ṣèlérí láti jẹ ìyanu, ọrọ ti o n yi igbe ayé padà tí o si n mú ogo bá Ọlọ́run, gẹgẹ bi a ti n ṣe àbájáde, ifẹ ìyanu Jésù.

KÓKÓ Ẹ̀KỌ́
I.    JÉSÙ N TẸSIWAJU NÍNÚ ÌFẸ́NI LẸ́YÌN ÀJÍǸDE.
       A.  Ó SAMOJUTO ÀWỌN ỌMỌ Ẹ̀YÌN TÍ WỌN TUKA
       B.  O RI PE Ẹ̀MÍ MÍMỌ́ BA LE WỌN

ITUPALẸ Ẹ̀KỌ́
Jun. 24 | I. JÉSÙ N TẸSIWAJU NÍNÚ ÌFẸ́NI LẸ́YÌN ÀJÍǸDE
A fi ìfẹ́ ìgbéyàwó tí o ti dinku tí ko ba ri bẹẹ, eese ti ikọsilẹ ìgbéyàwó fi wọ́pọ̀ ni àgbáyé. Gbogbo wa ni a rii nínú igbe ayé Jésù pé ìfẹ́ tòótọ́ ki yẹ láé, bi ó-tilẹ̀ wi pe ki nnkan o le to. Ìfẹ́ Rẹ̀ jẹ́ ti ayérayé, ti kí í kú àti irú ìfẹ́ ti o mu kí o máa wá àwọn ẹlẹ́ṣẹ kiri lonii, gẹgẹ bi ó ti ṣe tí o si mú àwọn ọmọ ẹ̀yìn ti o ti ṣáko padà lẹ́yìn àjíǹde Rẹ.
A.   OSAMOJUTO ÀWỌN ỌMỌ Ẹ̀YÌN TÍ WỌN TUKA (Jhn. 21:1-19).
Lẹ́yìn nǹkan wọ̀nyí, Jésù tún fi ara Rẹ hàn fún àwọn ọmọ ẹ̀yìn Rẹ̀ létí òkun Tiberia, bayii ni O si farahàn (ẹsẹ 1).
i.    Jésù ti fi ara hàn fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn Rẹ ni onírúurú ọ̀nà lẹ́yìn àjíǹde. Èyí ni yoo se ìgbà kẹta (ẹsẹ 14). Ìfẹ́ ni o n bẹ lẹ́yìn èyí (Jhn. 20:21-30).
ii.    Ẹsẹ 1-3: Símónì Pétérù si wọn dárí, o si mú wọn kúrò nínú èrò àti eto Jésù. Gbogbo làálàá wọn yọrí sí ofo.
iii.    Ẹsẹ 4-6: Jésù tún fi ìfẹ́ hàn sí wọn lẹẹkan sii gẹgẹ bi O ti ma a ń ṣe sí wọn nígbà gbogbo (Lk 5:1-11). Wi pe àwọn ọmọ ni ibi yii ni ami ìfẹ́ Rẹ̀ fún wọn. Ko ba wọn wí. Ó fà wọn mọ́ra nínú ìfẹ́ Rẹ̀. Anfaani ńlá ń dúró de àwọn ẹlẹ́ṣẹ àti àwọn aṣáko (wo Lk. 15:11-24)!
iv.    Ẹsẹ 7-14: Ẹ wa jẹun òwúrọ̀. Ko wo ti àṣìṣe wọn, Jésù bukun wọn pẹlu ẹja pupọ àti oúnjẹ òwúrọ̀. Ko tún si nnkan miran mọ bikose ìfẹ́, èyí, sì jẹ ipenija fún wa lonii.
v.   Ẹsẹ 15-19: Ko si ohunkóhun ti o se pataki si I mọ ju pé kí a mú wọn bọsipo. O se àṣeyọrí ni mímú wọn bọsipo, bẹẹni ko si Pétérù dárí. Rántí pé O ti gbádùn fún ṣáájú.
vi.    Jésù ṣe èyí láti safihan ìfẹ́ tòótọ́ Rẹ, O fún wọn ní àfojúsùn, O mú ìlérí Rẹ ṣẹ bẹẹni O fi ògo fún Ọlọ́run. Ìtẹ́siwaju isẹ ti O bẹ̀rẹ̀ jẹ́ Ẹ lógún pupọ nínú ọkàn Rẹ.
vii.   Ìfẹ́ bo ọpọlọpọ ẹsẹ mọ́lẹ̀. Ìfẹ́ Jésù fún àwọn ọmọ ẹ̀yìn Rẹ̀ èyí tí o san de ọdọ àwọn onigbagbọ lonii, jẹ́ àgbàyanu àti aisee-fẹnusọ. Iya tootọ ti o tún jẹ́ olufẹ mọ bi a ti ń fi ìfẹ́ àti pẹ̀lẹ́ pẹ̀lẹ́ tọju ọmọdé títí ti yoo fi dàgbà. Ohun ti Jésù ṣe fún àwọn ọmọ ẹ̀yìn Rẹ̀ ni èyí, lẹ́yìn tí O ti jíǹde. O n tẹsiwaju láti ṣe àbójútó bẹẹni O sì n tọ wọn pẹlu ìyípadà ọkàn àti ní jẹjẹ titi ti wọn yoo fi dìde láti ṣe ìfẹ́ Rẹ̀.

B.   O RI I PÉ Ẹ̀MÍ MÍMỌ́ BA LE WỌN (Ìṣe 1:8; 2:1-25)
Gbogbo wọn sì kún fún Ẹ̀mí Mímọ́, wọn si bẹ̀rẹ̀ si i fi èdè miran sọ̀rọ̀, gẹgẹ bi Ẹ̀mí ti fún wọn ni ohun (2:4).
i.   Jésù ti ṣe ìlérí láti mase fi àwọn ọmọ ẹ̀yìn Rẹ silẹ láìní bàbà. Ìtumọ̀ rẹ ni pe wọn ko ni jìyà, sina bẹẹni wọn ko ni wà láìsí iranwọ. Oun yoo ri pe Ẹ̀mí Mímọ́ wa (Lk. 24:49; 14:16-18; 15:26-27; 16:7-15).
ii.    Jésù ṣe ìlérí naa fún wọn nítorí pé O fẹ́ràn wọn gidigidi ohunkóhun ní O si le se nítorí àlàáfíà wọn.
iii.   1:8: Jésù sọ fún wọn pàtàki Ẹ̀mí Mímọ́. Nítorí ìfẹ́ ailẹgbẹ Rẹ fún wọn, O rii pe wọn gba agbára Ẹ̀mí Mimọ. Èyí yoo mú kí isẹ naa tẹsiwaju.
iv.   1:1-12: Àwọn ọmọ ẹ̀yìn naa dúró gẹ́gẹ́ bí wọn ti gbọ, bẹẹni wọn sì pa ọrọ Rẹ mọ. O bẹ̀rẹ̀ si i ye wọn díẹ̀ díẹ̀, àwọn naa se ìfẹ́ Rẹ̀ bẹẹni wọn sì ń gbe nínú ìfẹ́ Rẹ (Jhn. 15:9,10). Nínú ìgbọràn pípé ni a ti le gbádùn ìfẹ́ Jésù.
v.  2:1 siwaju si: Nígbà tí ọjọ́ Pẹntikọsti si de... Jésù mú ọrọ ti O ti sọ tẹ́lẹ̀ nípa Ẹ̀mí Mímọ́ ṣẹ. O jẹ Ónífẹ̀ẹ́, O kọja Ẹni tí a ń jákulẹ.
vi.  Meloo nínú àwọn ìlérí wa ni a n mú ṣẹ? Báwo ni a ṣe n faraji fún isẹ ti a rán wa? Jésù ko ni sá ojúṣe Rẹ ti paapa julọ ti O ba ti ṣèlérí, nítorí Ónífẹ̀ẹ́ ni. Abájọ ti O fi mú ìlérí Rẹ ṣẹ èyí ti O se pe Oun yoo rán Ẹ̀mí Mímọ́ wa. Ìfẹ́ yoo mú kí o lè dúró daradara ti ọrọ Rẹ àti pé àwọn ìlérí ti O se yoo wa si ìmúṣẹ.

ÀWỌN Ẹ̀KỌ́ TÍ A RÍ KỌ
1.    Ìfẹ́ Jésù sì àwọn ọmọ ẹ̀yìn Rẹ̀ kò parí sì Kalfari. Ó wa wọn rí nínú ìfẹ́ O sì mú wọn bọsipo.
2.    Jésù rí I dájú pé Ẹ̀mí Mímọ́ wa, O si n ba wọn gbé nitori pe Oun ko fẹ ki wọn jìyà bi aláìní bàbà.

ÀWỌN ÌBÉÈRÈ
1.   Ṣàlàyé bi ìfẹ́ Jésù ti to fún àwọn ọmọ ẹ̀yìn Rẹ̀. Ń jẹ àwa naa le se eyi lonii?
2.   Kin ni idi pataki ti O fi ri I pe Ẹ̀mí Mímọ́ wa?
3.   Ènìyàn gbọ́dọ̀ ṣàn án padà bẹẹni o sì gbọ́dọ̀ mọrírì ìfẹ́ Ọlọ́run. Ṣàlàyé.

ÀMÚLÒ FÚN ÌGBÉ AYÉ ẸNÌ
Jalejado àmì ìfẹ́ ni ọkàn. Ọkàn ní àárín gbùngbùn ayé ènìyàn. Ibujoko ipongbẹ, ìmí àti agbára. Òun ni o n fún gbogbo ara ní ẹ̀jẹ̀. Àwọn oníṣègùn mọ pàtàkì ọkàn sí igbe ayé. Bi Ọlọ́run ti sẹda ọkàn àti ìhà ti o fi n sọ nípa bí o ti ṣe iyebíye ni ọwọ Rẹ. Ki ọkàn maa sise lọwọ ni ohun ti o dara julọ fún igbe ayé. A gbàdúrà pé a kò ní rí idàkeji. Síbẹ̀ ko si ohun ti a le se nípa èyí, nítorí kò sí kí ikú má wa. Ìfẹ́ ni ẹ̀bùn nínú ọkàn. Jésù n ní àwọn ọmọ ẹ̀yìn lọ́kàn nígbà gbogbo, Abájọ tí O fi wa wọn rí ti O si mú wọn bọsipo lẹ́yìn àjíǹde Rẹ. Ìfẹ́ a máa tọju bẹẹni o sì máa n ní ìmọ̀lára fún àwọn ẹlòmíràn. Maa ni àwọn ènìyàn kan ni ọkàn rẹ láti oni lọ. Gẹ́gẹ́ bí Jésù ṣe ṣe fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn ti O fẹ́ràn pupọ pupọ ti O si ṣàfẹ́rí.

IGUNLẸ
Lonii, ní àwa sì òpin ẹ̀kọ́ Kejìlá ọwọ ilé ẹ̀kọ́ ọjọ ìsinmi tí saa yii nípa oore-ọ̀fẹ́ Ọlọ́run. Àwọn ìrírí inú rẹ kún fún ìyanu àti ti ògo. Mo gbàdúrà pé a o maa gbádùn oore-ọ̀fẹ́ Ọlọ́run nípasẹ̀ ọrọ Rẹ ni Orúkọ Jésù, nitori pe ìbùkún ìyanu yii ko ni dá wọ dúró ní orúkọ Jésù. Bẹẹni ni I mọ́lẹ̀ òdodo yii ko ni wọ́ òokun ni orúkọ Jésù. A ti kọ wá daradara láti ọ̀dọ̀ Ẹ̀mí Mímọ́ nípasẹ̀ àwọn ikọ ti o ti dá wọlé láti safihan afojuri ìfẹ́, ni títẹ̀lé ìfẹ́ tí Ọlọ́run fihan láti atetekọse wa. Ọlọ́run n tẹsiwaju nínú ìfẹ́, bikose pe Jésù láti fi ìfẹ́ hàn sí àwọn ọmọ ẹ̀yìn Rẹ kódà lẹ́yìn àjíǹde. Nítorí naa a rọ wa lati máa tẹsiwaju ni fífi ìfẹ́ sínú ìṣe ki ìṣe kí isẹ nípa ọrọ ẹnu lásán. Oore-ọ̀fẹ́ àti agbára láti ṣe èyí, Ọlọ́run yoo fi fún wa. Rántí àmì kansoso tí aráyé fi le mọ pe ọmọlẹ́yìn Kristi ni wà ní fífẹ̀ran ẹnikeji wa. Mo gbàdúrà pé kànga ìfẹ́ rẹ̀ kò ní gbẹ ni orúkọ Jésù.
ÌJỌ ÀPỌ́SÍTÉLÌ KRISTI Ẹ̀KỌ́ ỌJỌ́ ÌSINMI Ẹ̀KỌ́ KEJÌLÁ FUN June 24, 2018 : AKORI - JÉSÙ Ń TẸSIWAJU NÍNÚ ÌFẸ́ LẸ́YÌN ÀJÍǸDE. ÌJỌ ÀPỌ́SÍTÉLÌ KRISTI  Ẹ̀KỌ́ ỌJỌ́ ÌSINMI  Ẹ̀KỌ́ KEJÌLÁ FUN June 24, 2018 : AKORI - JÉSÙ Ń TẸSIWAJU NÍNÚ ÌFẸ́ LẸ́YÌN ÀJÍǸDE. Reviewed by Muyiwa Abodunrin (Muyilight) on June 20, 2018 Rating: 5

No comments:

Powered by Blogger.