*CAC, OMI IYE OJOJUMO....*
*ỌJỌ́* : ỌJỌ́ ABAMETA (Sat) 13, 2018 .
*ÀKÒRÍ* : IPINFUNNI ÀTỌ̀RUNWÁ.
*KA* : Genesisi 13:1-3
*AKỌ́SORI*
_Abramu sì gòkè láti Egipti wá, òun àti aya rẹ àti ohun gbogbo tí ó ní, àti Loti pẹ̀lú rẹ, sì ìhà gúúsù. Abramu sì là gidigidi, ní ẹran ọ̀sìn, ní fàdákà àti ní wúrà_ . *(Genesisi 13:1,2* )
*ÌTÚPALẸ̀*
Ààyè ni ibùdó tàbí ibi tí nǹkan kan wà, àti ipò tàbí fífi nǹkan, ẹnikan sí ibi kan pàtó. Ìpín fúnni funrare je iye owó kan, tàbí ìpín tí a fi fún enikan tàbí nǹkan.
Kini nǹkan tí o rí gbà báyìí? Kín ni ó ń sele sí ọ báyìí? Nǹkan tí o rí gbà jẹ́ ojúṣe ibi tí a fi ó sì. Ìdí ni eyii tí ó fi se pataki fún ọ láti wà ní ibi tí ó tọ̀nà. Loti ni ìrírí ìwà ìbàjé Sódómù àti Gòmórà, àti gbogbo nǹkan tí o tẹle e, nítorí tí ó wà níbè. Àìsí níbi tí ó yẹ kí o wà ní o pá elimeleki àti àwọn ọmọ rẹ méjèèjì, wíwà ní ojuko rere sọ Isaaki di ẹni ìbùkún ( _Rutu 1:1-10; Gen. 26:1,2_ )
Ibi àyọkà òní wáyé láti mú wa mọ ẹwà wíwà ní ibi títọ. Abrahamu tí a pè ní bàbá ìgbàgbọ́, tí fi ìgbà kan lọ sí Egipti fúnra rẹ, níbi tí òun kò ti lè e se ohun rere kan pàtó pẹ̀lú àti fún Ọlọ́run, tí ìrìn àjò náà sì fún un ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ apá. Ọpẹ́ ni fún Ọlọ́run, ó padà wá Kénáánì tí Ọlọ́run ti seleri rẹ fún un sáájú.
Nígbà tí ó se ìpinnu pípadà sí orísun, wò àwọn nǹkan tí o wa ń wáyé nínú ayé re; Abramu sì gòkè láti Egipti wá, òun àti aya rẹ ohun gbogbo tí ó ní àti Loti pẹ̀lú rẹ sí ìhà gúúsù. Abramu sì là gidigidi ní ẹran ọ̀sìn, ní fàdákà àti ní wúrà.
Nǹkan tí ó rí gbà á sopo mọ́ ibi tí ó wà. Ríi dájú pé o wà níbi tí Ọlọ́run fẹ́ kí o wà. Béèrè lowo Ọlọ́run láti mọ, bí ó bá wà níbi tí ó yẹ tàbí beeko. Ibanuje àwọn tí ń sá kúrò níwájú Ọlọ́run bí ó ti wù wọ́n máa ń pò jọjọ. Nígbàkúùgbà tí Ọlọ́run bá sètò ibùdó kan fún ọ, ohun yòówù kí ó sele máse gbìyànjú láti kúrò nibe láìsí ìtọ́ni tí ó kúnjú òsùwọ̀n láti ọ̀dọ̀ Rè. Òun ni ètò tí ó dára jù lọ fún ọ níbikíbi tí ó bá fi ó si.
*AWON KÓKÓ ÀDÚRÀ:*
1. Oluwa, mase jẹ́ kí n kọjá ààyè mi.
2. Oluwa, rán mi lọ́wọ́, láti sàwárí, kí n sì dúró lórí ilẹ̀ ayanmo àti ìmúsẹ mi.
3. Oluwa, bíi ti Loti, gba ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn tí wọ́n ń dojú kọ orisirisi wàhálà àti ìsòro nítorí asiyan wọn silẹ.
*ÀFIKÚN IBI KIKA FÚN ONI:*
Genesisi 28-29 àti Mátíù 13.
Onkowe:CAC LAGBAYE
Jẹ́ Alábùkún fún
CAC, OMI IYE OJOJUMO FUN ỌJỌ́ ABAMETA (Sat) 13, 2018 : ÀKÒRÍ - IPINFUNNI ÀTỌ̀RUNWÁ.
Reviewed by Muyiwa Abodunrin (Muyilight)
on
January 13, 2018
Rating:
No comments: