ÌJỌ ÀPỌ́SÍTÉLÌ KRISTI. Ẹ̀KỌ́ ILẸ̀ Ẹ̀KỌ́ ỌJỌ́ ÌSINMI Fun September 22, 2019. Ki Ìwé Mímọ́ Kí O Le Ṣẹ. ÌSỌRI KEJ: A MÚ ÀWỌN ÌWÉ MÍMỌ́ ṢẸ

--> Note :- Are you born again? You are never going to win the battle against the devil if you are not born again. I plead with you to give your life to Jesus today because the longer you stay in sin and remain unsaved, the more hardened your nature becomes against the purpose and the way God wants you to be for His purpose. To give your life to Jesus now, say this prayer: “Father, I come to You in the name of Jesus. I know that I am a sinner and I cannot save myself but Jesus died for me and shed His blood that I might be saved. Today, I accept Jesus as my Lord and Saviour. Jesus, I ask You to come into my heart, be my Lord, wash me with Your blood and make me whole. I believe with my heart and confess with my mouth that Jesus is my Lord. Thank You for saving me. In Jesus' name I pray. Amen.” I congratulate you and welcome you to the family of God if you have sincerely said that prayer. Now you are fit to discover, know and walk in your destiny. Call our helpline on +2348037252124, Join Our Daily Whatsapp Devotionals Group : +2347033046607 for Daily Devotionals, crucial discipleship and counselling.s"
ÌJỌ ÀPỌ́SÍTÉLÌ KRISTI. Ẹ̀KỌ́ ILẸ̀ Ẹ̀KỌ́ ỌJỌ́ ÌSINMI Fun September 22, 2019. Ki Ìwé Mímọ́ Kí O Le Ṣẹ. ÌSỌRI KEJ: A MÚ ÀWỌN ÌWÉ MÍMỌ́ ṢẸ


ÌJỌ ÀPỌ́SÍTÉLÌ KRISTI.
Ẹ̀KỌ́ ILẸ̀ Ẹ̀KỌ́ ỌJỌ́ ÌSINMI
Ki Ìwé Mímọ́ Kí O Le Ṣẹ.
ÌSỌRI KEJ: A MÚ ÀWỌN ÌWÉ MÍMỌ́ ṢẸ
September 22, 2019.
II. A BI I NÍNÚ OBÌNRIN (Matiu 2:1-5; Luku 1:1-4, 26-38)
Ẹsin Kristẹni ki ìṣe ẹsin ti ó dúró lórí arosọ, alọ àti itan ìran. Ìgbàgbọ́ ẹsin Kristẹni dúró lórí ìgbé ayé Jesu Kristi. Ọlọ́run sọ ọrọ náà bẹẹni obìnrin náà sì lóyún lọ́nà ìyanu.

A. IRÚ ỌMỌ OBÌNRIN NÁÀ (Lk. 1:1-4, 26-38).
Sa sì kiyesii, ìwọ o lóyún nínú rẹ, ìwọ o si bi ọmọkùnrin kan, ìwọ o si pe orúkọ Rẹ ni Jésù (ẹsẹ 31)
i. Ẹsẹ 1-4: Luku safihan àwọn ohun tí a sọ nípa Mèsáyà tí a ṣèlérí... ti a múṣẹ láàrin wa. Ihinrere Rẹ jẹ àbájáde ìwádìí tí o mú ìrora lọ́wọ́ lẹ́yìn tí o ti fojurin ojú pẹ̀lú àwọn tí ìṣẹ́ ìránṣẹ́ Jésù ṣe ojú wọn. A wa ṣe èyí pé nípa ìfihàn àti imisi àti ọrun wa.
ii. Ọlọ́run ṣe atẹnumọ "obìnrin" náà gidigidi nínú Gen. 3:15. Wàhálà ẹ̀dá ènìyàn wa nítorí ẹ̀tàn èṣù tí o (obìnrin) bọ sínú rẹ. Ọlọ́run ṣètò láti yanjú ìṣòro náà nípa lílo irú ọmọ obìnrin náà.
iii. Ẹsẹ 35: Ki Ìwé Mímọ́ ki o le ṣẹ, Ọlọ́run re ọkùnrin kọjá. Abájọ tí Ẹ̀mí Mímọ́ fi bẹ obìnrin náà wo. Màríà, ẹniti o ri ojurere lọdọ Ọlọ́run (ẹsẹ 28:30). Jósẹ́fù àti Màríà ko ni lati pàdé/dapọ kí ọmọ Ọlọ́run náà o to le wa. Abájọ tí Ọlọ́run fi gba kí wọn jẹ afẹsọna, wọn kò ti I gbe ara wọn níyàwó, ki wọn tó lóyún Jésù (ẹsẹ 26,27; Mat. 1:18).
iv. Wúńdíá ni o bí ọmọ Ọlọ́run (obìnrin kan Gal. 4:4) ni ìmúṣẹ Isa. 7:14 (wo Gen. 3:15). Ọlọ́run sọ ọrọ obìnrin náà sì lóyún lọ́nà ìyanu (Mat. 1:18 síwájú).
v. Ẹsẹ 34,35a: Ẹ̀mí Mímọ́ yóò ṣíji bo ọ. Màríà kò ní láti yọ ara rẹ lẹ́nu bi èyí yóò ṣe ṣẹlẹ̀ (ẹsẹ 34). Ẹ̀mí Mímọ́ ni yóò bí ọmọ Ọlọ́run nípasẹ̀ obìnrin nìkan, Èyí ni o fi yàtọ̀ hàn láàárín Ádámù kinni àti Ádámù kejì (Jésù) (wo 1 Kor 15:45-47).
vi. Ero náà kì ìṣe tí ọna ènìyàn, ṣùgbọ́n tí Ẹ̀mí Ọlọ́run. Agbára Ọlọ́run ṣíji bo Màríà, nígbà tí Ẹmi Ọlọ́run sọ̀rọ̀ sì inú rẹ, láti mú oyún tí a nílò wa.
vii. Eto àtọ̀runwá Ọlọ́run mú kí Jèṣefu àti Màríà fẹ́ ara wọn àti pe ki iwe mimọ kí o le ṣẹ. Ẹ̀mí Mímọ́ bẹ obìnrin náà wo láìsí idapọ ọkùnrin àti obìnrin kí a to lóyún ọmọ mimọ náà.
B. IBI IRẸLẸ RẸ (Mat. 2:1-5)
Wọn sì wi fún un pe, "Ni Bẹ́tílẹ́hẹ́mù tí Judea ni:nítorí bẹẹni a kọ̀wé rẹ láti ọwọ wòlíì wá" (ẹsẹ 5).
i. Isa. 53:2: Sọ Nípa ibi irẹlẹ àti ìdágba Mèsáyà tí a n fojúsọ́nà fún, bíó-tilẹ̀-jẹ-pe níkẹyìn àwọn Juu n retí kí wíwà rẹ o jẹ bii ọba.
ii. Mat. 2:1:... A sì bi Jésù ni Bẹ́tílẹ́hẹ́mù tí Judea... yàtọ̀ sí òtítọ́ pe a o bi Jésù nípasẹ̀ obìnrin, ibi tí a o bi I sì tun jẹ ọrọ miran ni ọkàn Ọlọ́run.
iii. Ẹsẹ 1-5: Àwọn obi kan yóò fẹ́ láti wa ibi tí o dara láti bí ọmọ wọn si ---- orílẹ̀ èdè, ìlú ńlá, ilé ìwòsàn abbl. Ọlọ́run ti ṣètò ṣáájú ibi tí a o bi Jésù si, ibi tí o kere tí ko si ni ìtumọ̀ fún irufẹ àlejò tí a gbà ní ọjọ́ tí a bi Jésù (wo Mik. 5:2 síwájú; Lk. 2:1-7).
iv. Okunfa gbòógì miran ti o tún fa ibi irẹlẹ Jésù ni ìyàn Rẹ láti wa ninu ẹ̀dá ara Rẹ (ẹni kíkú lásán) (Lk. 2:6-7). Láti mú ìtìjú náà pọ sii, a bii sì inú ibùjẹ ẹran (Lk. 2:7).
v. Kin ni ohun miran ti a le fi ṣàpèjúwe bí o ṣe sọkalẹ wa ninu ogo gíga láti gbé àwọ ìránṣẹ́ wọ láti gbé ní àárín wa (Jhn. 1:14; Filp. 2:7,8).
vi. A bi Jésù sì ibi tí o pamọ, irẹlẹ àti ìtìjú. Ko wọ inú ayé láti ọ̀dọ̀ ìdílé ti ìgbádùn wa fún tàbí agbegbe. Ibi yii wáyé ní ibi tí o jìnà sì àwọn ero, tí o sì da nìkan wa (Lk. 2:7).
vii. Jésù Kristi Olùgbàlà gbogbo aráyé, ni a bí si ìdílé aláìní. A bi I ni ìletò ti Bẹ́tílẹ́hẹ́mù, ki ìṣe ìlú ńlá
Ko si ẹni ti o tọju ìyá Jésù Kristi niti ara nígbà tí o bi I. A bi I ni Oun ni kan láìsí ara nibẹ. Irẹsilẹ ńlá ni èyí. A tẹ Ẹ sínú ibùjẹ ẹrán tí o n run.
ÀWỌN Ẹ̀KỌ́ TÍ A RI KỌ
1
. Ọlọ́run ya eto ìṣẹ̀dá silẹ láti fún araye ni olùgbàlà tí wọn nílò láti ípasẹ 'obìnrin naa', láti pa satani run pátápátá.
2. A bi Jésù ni ibi tí o n ri ènìyàn lára, ibi tí o n rún, a sì tẹ Ẹ sì ibùjẹ ẹran. Èyí n safihan irẹlẹ Olùgbàlà aráyé.
ÀWỌN ÌBÉÈRÈ
1. A bi Olùgbàlà ni àkókò tí Ọlọ́run yàn. Ẹ jíròrò.
2. A ko bi Jésù Kristi ni àyíká tàbí agbegbe ti o rọrùn. Njẹ ẹ̀kọ́ kankan wa nihin fún wa lonii?
ÀWỌN ÌDÁHÙN TÍ A DÁBÀÁ FÚN ÀWỌN ÌBÉÈRÈ:
ÌDÁHÙN SÍ ÌBÉÈRÈ KÍNNÍ

i. Lọ wo ìpín IB.
ii. Ni àkókò tí O da, O gba kí ọmọ Rẹ ki o wa si ayé láti gba ènìyàn la.
iii. Ọlọ́run ran ọmọ Rẹ láti rán ènìyàn lọ́wọ́ kúrò nínú ìpín ainiran lọ́wọ́-ìràpadà.
iv. Eto ati erongba Ọlọ́run kọjá òye ènìyàn. O ṣe àgbékalẹ eto Rẹ fún ènìyàn ni àkókò tí O da.
v. Wíwà ọmọ Ọlọ́run wa lábé eto ti à ti ṣètò láti ọrùn láti ọwọ Ọlọ́run, kí bá ti ṣíṣẹ, tí o bá tete wá tàbí kó wa lẹ́yìn tí àkókò tí kọjá. Akoko Ọlọ́run àti ìṣẹ́ tí o bọ sì àkókò ni o dara julọ, nítorí náà ni Jésù ṣe wa ni àkókò tí Ọlọ́run pinnu rẹ.

ÌDÁHÙN SÍ ÌBÉÈRÈ KEJI:
i. Lọ wo ìpín IIB.
ii. A bi I ni ibi ti ko si imọlẹ àti ní òun nìkan. A bi I sínú irẹsilẹ.
iii. Ibi Rẹ ko soju àwọn ènìyàn, O da wa ni òun nìkan, èyí sì jẹ nínú ayé idibajẹ tí o kún fún ẹṣẹ àti anikanjọpọn.
iv. Ìyá Rẹ, Màríà lẹ́yìn ibi Rẹ, fi ọjà wẹ ọmọ náà o si tẹ Ẹ sì ibùjẹ ẹran, níbi tí o n rún láìsí iranlọwọ ẹnikẹ́ni. Ko wọnú ayé láti ọ̀dọ̀ idile tí ayé rọrùn fún.
v. Jésù wa sínú ayé nipasẹ ẹ̀dá ọwọ Rẹ.
vi. Ibi Rẹ jẹ ìmúṣẹ eto ti erongba Ọlọ́run nínú ìgbọràn.
Ẹ̀kọ́ Fún Wa Lónìí
i. Ọlọ́run nílò irẹlẹ wa. Irẹlẹ Kristi gbọ́dọ̀ máa ṣàkóso ohun gbogbo tí a ba n ṣe gẹ́gẹ́ bí I Kristẹni ni ayé.
ii. Irẹlẹ lè mú wa lọ sí ipò gíga.
iii. Ìgbọràn pátápátá yóò mú kí a gba ìmúṣẹ gbogbo ìlérí Ọlọ́run.

ÀMÚLÒ FÚN ÌGBÉ AYÉ ẸNI :
A ye kún fún ẹṣẹ, ṣùgbọ́n wíwà Jésù Kristi di àlàfo tí ẹṣẹ da silẹ láàrin ènìyàn àti Ọlọ́run. Àwọn onigbagbọ ni ajogún Ọlọ́run nípasẹ̀ Kristi. Àwọn onigbagbọ gba isọdọmọ nípasẹ̀ Kristi, nípa ìgbàgbọ́. Ẹ̀mí Kristi ti a rán láti máa gbé nínú ọkàn wa ni lati fún wa ní ibasepọ pẹ̀lú Ọlọ́run. Ọlọ́run nìkan ni o le pinnu Ohun tí o tọ fún igbe ayé ènìyàn láti gba wa la. O rán Ọmọ Rẹ̀ láti gba ènìyàn la kúrò nínú ìdálẹ́bi búburú tí òfin náà.
IGUNLẸ
A ye nílò Olùdáǹdè. Ọlọ́run rán Ọmọ Rẹ̀ wá láti da ènìyàn nídè. Ko rán áńgẹ́lì tàbí ẹ̀dá miran, ṣùgbọ́n O rán Ọmọ Rẹ̀ kanṣoṣo. A bi I ni abẹ òfin, O gbe ni abẹ òfin, láti ṣètò òdòdó pípé òfin fún ènìyàn. Nítorí Ọlọ́run fẹ́ràn ènìyàn púpọ̀pupọ, Ó rán Ọmọ Rẹ láti da ènìyàn nídè kúrò lábẹ́ ìdálẹ́bi búburú tí òfin. O sì ṣe èyí ní àkókò tí O da. Gba A gbọ, a o si gba ọ la. A gbàdúrà pe awọn ìbùkún tí a ti rí gbà nínú ẹ̀kọ́ yìí yóò ba wa kalẹ bí a ti n tẹsiwaju sínú ẹ̀kọ́ tí o kan.

ÀṢÀRÒ LÁTI INÚ BÍBÉLÌ FÚN ỌSẸ ÌKEJÌ
Mon. 16: Iloyun Rẹ Ìyanu Ní (Mat. 1:18).
Tue. 17: Oyun Rẹ Fẹ́rẹ Da Wàhálà Silẹ (Mat. 1:19)
Wed. 18: Oyun Rẹ Fa Ìfihàn Pataki (Mat. 1:20,21)
Thur. 19: Oyun Rẹ Ki I Ṣe Nípasẹ̀ Ènìyàn (Mat. 2:25)
Fri. 20: Baba Alagbatọ Rẹ Gbọ́ràn Ṣí Àṣẹ Àtọ̀runwá (Mat. 1:24)
Sat. 21: Ibi Rẹ: Ìmúṣẹ Ìwé Mímọ́ (Mat. 1:22-23)
ÌJỌ ÀPỌ́SÍTÉLÌ KRISTI. Ẹ̀KỌ́ ILẸ̀ Ẹ̀KỌ́ ỌJỌ́ ÌSINMI Fun September 22, 2019. Ki Ìwé Mímọ́ Kí O Le Ṣẹ. ÌSỌRI KEJ: A MÚ ÀWỌN ÌWÉ MÍMỌ́ ṢẸ ÌJỌ ÀPỌ́SÍTÉLÌ KRISTI. Ẹ̀KỌ́ ILẸ̀ Ẹ̀KỌ́ ỌJỌ́ ÌSINMI Fun September 22, 2019. Ki Ìwé Mímọ́ Kí O Le Ṣẹ. ÌSỌRI KEJ: A MÚ ÀWỌN ÌWÉ MÍMỌ́ ṢẸ Reviewed by Muyiwa Abodunrin (Muyilight) on September 22, 2019 Rating: 5

No comments:

Powered by Blogger.