ÌJỌ ÀPỌ́SÍTÉLÌ KRISTI. Ẹ̀KỌ́ ILẸ̀ Ẹ̀KỌ́ ỌJỌ́ ÌSINMI. Fun September 8, 2019 . Kí Ìwé Mímọ́ Kí O Le Ṣẹ.

--> Note :- Are you born again? You are never going to win the battle against the devil if you are not born again. I plead with you to give your life to Jesus today because the longer you stay in sin and remain unsaved, the more hardened your nature becomes against the purpose and the way God wants you to be for His purpose. To give your life to Jesus now, say this prayer: “Father, I come to You in the name of Jesus. I know that I am a sinner and I cannot save myself but Jesus died for me and shed His blood that I might be saved. Today, I accept Jesus as my Lord and Saviour. Jesus, I ask You to come into my heart, be my Lord, wash me with Your blood and make me whole. I believe with my heart and confess with my mouth that Jesus is my Lord. Thank You for saving me. In Jesus' name I pray. Amen.” I congratulate you and welcome you to the family of God if you have sincerely said that prayer. Now you are fit to discover, know and walk in your destiny. Call our helpline on +2348037252124, Join Our Daily Whatsapp Devotionals Group : +2347033046607 for Daily Devotionals, crucial discipleship and counselling.s"
ÌJỌ ÀPỌ́SÍTÉLÌ KRISTI. Ẹ̀KỌ́ ILẸ̀ Ẹ̀KỌ́ ỌJỌ́ ÌSINMI. Fun  September 8, 2019 . Kí Ìwé Mímọ́ Kí O Le Ṣẹ. 

ÌJỌ ÀPỌ́SÍTÉLÌ KRISTI.
Ẹ̀KỌ́ ILẸ̀ Ẹ̀KỌ́ ỌJỌ́ ÌSINMI.
Kí Ìwé Mímọ́ Kí O Le Ṣẹ.
September 8, 2019.


II. NÍNÚ MÁJẸ̀MÚ TUNTUN (Matiu 24:1-31; I Timoteu 4:1-5; 2 Timoteu 3:1-9; 2 Peteru 3:1-10).
Májẹ̀mú tuntun jẹ májẹ̀mú ọtun àti májẹ̀mú láéláé. Jesu fẹsẹ rẹ múlẹ̀ wí pé Òun kò wa lati pa Òfin run (májẹ̀mú láéláé) bikose láti mú un ṣẹ. Májẹ̀mú tuntun náà bẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú Jésù Kristi, àwọn ìwé mẹ́tàdínlógún lo si wa lati Mateu de Ìfihàn nínú májẹ̀mú tuntun, tí Wọn ní ihinrere nípa Jesu Kristi nínú tí a kọ nípasẹ̀ àwọn ọmọ ẹ̀yìn Rẹ mẹrin, Ise Àwọn Aposteli, àwọn lẹta àti Ìfihàn Jòhánù (Ìwé Ìfihàn). Ọ̀pọ̀ àwọn iṣẹlẹ ìgbà ikẹhin ni a sọ bákan náà nínú májẹ̀mú tuntun.


A. NÍNÚ ÀWỌN Ọ̀RỌ̀ JESU (Mat. 24:1-31
Bi o si ti jokoo lórí Òkè Olifi, àwọn ọmọ ẹ̀yìn Rẹ tọ Ọ wá nikọkọ, wí pé, "sọ fún wa, nígbà wo ni nnkan wọnyii yóò ṣẹ? Kín ni yóò sì ṣe amí wiwa Rẹ, àti òpin ayé?" (ẹsẹ 3).
i. Ẹsẹ 1-3: Jesu sọ fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn Rẹ bí igbẹhin ọjọ́ ṣe máa ri, nítorí àwọn ọmọlẹ́yìn Rẹ fẹ́ mọ ohun tí o sọ nípa tẹmpili, àti ìgbà tí a o mú un ṣẹ. Bákan náà wọn n pongbẹ kíkankíkan nípa àmì wiwa Rẹ Lẹẹkeji àti igbẹhin ayé.
ii. Ẹsẹ 4-13: O fún wọn ni ọ̀pọ̀lọpọ̀ àmín láti máa wọna fun:
(a) ẹ̀tan (ẹsẹ 4,5)
(b) ogun, ìdágìrì ogun, ija láàrin àwọn orílẹ̀ èdè àti ajakalẹ-arun (ẹsẹ 6-8)
(d) àwọn Kristẹni yóò jìyà inúnibíni àti ikorira (ẹsẹ 9)
(e) ikọsẹ, ofofo, ikorira, (ẹsẹ 10)
(ẹ) àwọn wòlíì èké, ìsọdi pupọ ẹṣẹ, ifẹ yóò di tutu (ẹsẹ 11,12)
(f) ìwàásù ihinrere jákèjádò gbogbo ayé láti jẹ ẹlẹ́rìí si gbogbo orílẹ̀ ede sì àwọn ènìyàn àti ẹnikọ̀ọ̀kan (ẹsẹ 14)
(g) ìríra ìsọdahoro tàbí ohun tí a n sọ̀rọ̀ odi si ti ó n mú ìparun wa (ẹsẹ 15-20), èyí tí wòlíì Dáníẹ́lì tí sọtẹ́lẹ̀ nípa rẹ (Dan. 11:31).
(Gb) Àkókò ìpọ́njú náà (ẹsẹ 21-24); wo Ifi. 16:1-17) àti ìfarahàn àwọn kristi eke àti àwọn wòlíì eke n safihan àwọn àmì ńlá.
iii. Ẹsẹ 29:31: "Ami ọmọ ẹ̀yìn ènìyàn" n túmọ̀ si àmì ìfarahàn Jésù (Tes. 4:16). Nípa ìwọ̀nyí, Jesu sọtẹ́lẹ̀ wíwà Rẹ lẹẹkeji. Èyí n pe fún ìgbáradì wa gẹ́gẹ́ bi ayanfẹ Rẹ.
iv. Bi Jesu ba le wi pe "Ọ̀run òun ayé yóò rekọjá, ṣùgbọ́n ọrọ Mi ki yóò rekọjá" (Mat. 24:35), kin ni ayọrísí èyí? O ń pe wa lati mú àwọn ọrọ Rẹ, ìkọ́ni Rẹ, àti òfin Rẹ ni ọ̀kùnkùndun. Njẹ ìjọ tonii n ṣe èyí bi? Njẹ a o ti fi àwọn iji ẹ̀kọ́ eke gba wa lọ bi?

B. NÍNÚ ÀWỌN ÀKỌSÍLẸ̀ ÀWỌN ỌMỌ-Ẹ̀YÌN RẸ̀ (I Tim. 4:1-5; 2 Tim. 3:1-9; 2 Pet. 3:1-10).
Ṣùgbọ́n Ẹ̀mí n tẹnumọ ọn pé, ní ìgbà ikẹhin, àwọn mìíràn yóò kúrò nínú igbagbọ, wọn o máa fiyesi àwọn ẹ̀mí tí n tan nijẹ, àti ẹ̀kọ́ àwọn ẹ̀mí èṣù (I Tim. 4:1).
i. I Tim. 4:1-5: Nihin yii, Iwe Mímọ́ ń tẹnumọ àwọn ọrọ Ẹ̀mí Ọlọ́run nípa Ọjọ́ ikẹhin, èyí ti yiyapa ọpọ ènìyàn kúrò nínú igbagbọ tòótọ́ yóò jẹ ìtọ́kasi (àbùdá) rẹ. Ara Kristi (àwọn Kristẹni) yóò máa fojú ri ipadasẹhin àwọn ènìyàn kúrò nínú igbagbọ. Ṣé a o ti máa rí èyí báyìí?.
ii. 2 Tim. 3:1: N ṣàpèjúwe ọjọ́ ìkẹyìn gẹ́gẹ́ bí ìgbà ewu. Nípa pípé e ni "ewu" o túmọ̀ sí pe ìpọ́njú pupọ ni yóò wà. Njẹ èyí ko banilẹrù bi? O le ri bẹẹ, ṣùgbọ́n àwọn ikilọ Ọlọ́run kii ṣe láti daya fo wa bikose láti múra wa silẹ (gbe wa ró) sì gbogbo eto búburú ìgbà ìkẹyìn.
iii. Ẹsẹ 2-5: N ṣàlàyé àwọn iwa alaiwa-bi-Ọlọ́run tí yóò bẹ jáde ní igbẹhin ọjọ, pẹ̀lú ìfẹ́ afẹju (ojukokoro) owó (mamoni), ifunni, ailekọ ara-ẹni-ni jaanu, àìnífẹẹ, aidarijinni, àìgbọràn sì obi, ifẹ faaji ju Ọlọ́run àti ìwàbí-Ọlọ́run lọ, àti ọpọ àwọn mìíràn.
iv. Ẹsẹ 5-9: Nihin yii, a n kilọ fún àwọn onigbagbọ láti máa sọra fún àwọn ènìyàn alaiwa-bi-Ọlọ́run (àwọn alágàbàgebè nínú ìjọ), "àwọn tí wọn ní àfarawé ìwà-bí-Ọlọ́run, ṣùgbọ́n tí wọn n ṣẹ agbára Rẹ.
v. 2 Pet. 3:1-9: A n ran àwọn onigbagbọ leti wí pé ní ọjọ́ ìkẹyìn, àwọn ẹlẹ́gan yóò de (àwọn ènìyàn yóò máa fi ọ ṣe ẹlẹ́ya) Àwọn ẹlẹ́gan yóò wa gba ayé kan.
vi. Ẹsẹ 10: A ni ìdánilójú ìlérí Ọlọ́run lórí ọna ti yoo gba padà wa: Òun yóò wà gẹ́gẹ́ bí olè ni oru, ki a ma tan wa jẹ́ nípasẹ̀ àwọn ayédèrú nnkan ti àwọn ikọ Sátánì n gbe kiri nípa ìgbà wiwa Kristi.
vii. Ẹmi mimọ tí tẹsiwaju láti kilọ ewu ìgbà ìkẹyìn àti ẹ̀mí to rọ mọ̀-ọn. Aṣòdì-sí-kristi ti bẹ̀rẹ̀ ìṣẹ́ (1 Jhn. 5). Kin wa ni àwọn onigbagbọ le ṣe nígbà náà? Wọn gbọ́dọ̀ máa tẹti sì ohun tí Ẹmi n sọ fún Ìjọ kí wọn sì máa fojú sọ́nà (ni ifunra) fún gbogbo àwọn ami ìgbà ikẹhin.

ÀWỌN Ẹ̀KỌ́ TÍ A RÍ KỌ
1. Jesu ko fi wa silẹ nínú òkùnkùn nípa àwọn iṣẹlẹ igbẹhin ọjọ, gẹ́gẹ́ bí àwọn ọmọ ẹ̀yìn Rẹ ti tẹnumọ wi pe àwọn ọjọ́ ìkẹyìn wọ̀nyí yóò kún fún ìpọ́njú.
2. Ọrọ ìyànjú: Ẹ jẹ ki a pa ìgbàgbọ́, ìwà-bí-Ọlọ́run àti iwa mimọ wa mọ́ (2 Pet. 3:11,12).
ÀWỌN ÌBÉÈRÈ
1. Gbogbo orílẹ̀-ede tí o ba lodi si Ọlọ́run àti si awọn eniyan Rẹ ni a o da lẹjọ ni ikẹhin. Ẹ jíròrò.
2. Gẹ́gẹ́ bí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, àwọn ọmọ Ọlọ́run yóò jẹ̀gbádùn to tayọ niti imubọsipo àti ìṣelógo tí a ko ti i riru rẹ ri. Ṣàlàyé.

ÀWỌN ÌDÁHÙN TÍ A DÁBÀÁ FÚN ÀWỌN ÌBÉÈRÈ :
ÌDÁHÙN SÍ ÌBÉÈRÈ KÍNNÍ:
i. Lọ si ìpín I B.
ii. Kosi ohun tí o ti dára bi ki eniyan wa ni iha tí Olúwa.
iii. Ẹnikẹ́ni tí ko ba wa ni iha tí Ọlọ́run tàbí láàárín àwọn ènìyàn Rẹ, kò ba a jẹ nípa yiyan, àṣàyàn, tàbí ìsọdọmọ, tí gbé (wọ wàhálà) na (Jhn. 3:18)
iv. Ọlọ́run ti ṣe ìpèsè lẹkun-unreẹrẹ nínú, àti nípasẹ̀ ọmọ Rẹ, láti mú gbogbo ayé wa sọ́dọ̀ Rẹ; ko si Juu, ko si Keferi.
v. O fọ odi iyapa dànù, kí gbogbo ènìyàn lè ní àǹfààní Oore-ọ̀fẹ́ ìgbàlà. Kín ni àwọn ènìyàn wọ̀nyẹn tí wọn kò sì nínú Ọlọ́run n duro de? A ko le da Ọlọ́run lẹbi fún ìdálẹ́bi ẹnikẹ́ni mọ.
vi. Ìṣeun ìfẹ́ àti Oore-ọ̀fẹ́ Rẹ ti ṣètọ́jú gbogbo ènìyàn. O ku sọwọ wa lati gba A kì a sì máa mọrírì ìfẹ́ Rẹ̀ (Ọlọ́run).
vii. Gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè tí wọn ṣe lòdì sí Ọlọ́run nínú iṣẹ́ àti ní gbogbo ọjọ́ ayé wọn ní yóò ní ìpín nínú idajọ ìbínú Ọlọ́run ti ko ṣe e yẹ nígbẹhin.
viii.Ọkan lára àwọn amuyẹ láti wa ni ìhà tí Ọlọ́run ni lati gba ọmọ bibi Rẹ kansoso gbọ (O.D. 2:12).
ix. Nn kan mìíràn ni lati ni ifẹ ìlú mímọ Rẹ (Jerúsálẹ́mù tuntun) kí a sì máa pọngbẹ (fẹ) láti débẹ (Ifi. 21:1swj).
x. Ní àfikún, o gbọ́dọ̀ jẹ́ ọrẹ àwọn ènìyàn Ọlọ́run; máṣe jẹ́ ọta àwọn ènìyàn Ọlọ́run. Ọkàn lára àwọn àmì láti safihan pe ó fẹ́ ẹnìkan ni lati fẹ́ àwọn ọmọ wọn.

ÌDÁHÙN SÍ ÌBÉÈRÈ KEJÌ:
i. Lọ sí ìpín 1 A.
ii. Ìyá ìgbà ìsinsìnyí yí kòṣe e fi sakawe pẹ̀lú ògo tí a o fi hàn nínú wa (Rom. 8:18).
iii. Ìràpadà àti ìṣelóge nbẹ níwájú, gẹ́gẹ́ bí imọlẹ ṣe máa ń tàn lẹhin òkùnkùn biribiri.
iv. Ọlọ́run yóò sọ ohun gbogbo di ọtun fún àwọn ọmọ Rẹ; kí yóò sì ikú, ibanujẹ, ẹkùn, abbl mọ. Nigbati àwọn ẹlẹ́sẹ (àwọn ènìyàn búburú, alaiwa-bi-Ọlọ́run) yóò ma a pahinkeke nínú iṣẹ́-oro, awa ọmọ Ọlọ́run yóò wa ninu ayọ̀, àlàáfíà nínú ìjọba Baba wa.
v. Ìyàn, ogún àti irọkẹkẹ ogun yóò dẹkùn pátápátá. Àsọtẹ́lẹ̀ ayé tuntun àti ọrun tuntun yóò ṣẹ (Isaiah 66:22).
AMULO FÚN ÌGBÉ AYÉ ẸNI :
Jesu tọ́ka si ìgbà ayé Noa nígbà tí àwọn ènìyàn ń gbéyàwó tí wọn sì n fa àwọn ọmọbìnrin wọn fún ọkọ; wọn n jẹ, wọn si ń mú, titi ikùn omi fi wa sórí wọn, lójijì. Fún ìran yìí bákan náà, ìwé mímọ tí sọtẹ́lẹ̀ ígbẹhin, tí ko se e yẹ silẹ, ọ̀pọ̀ ènìyàn ló n fi èyí ṣe yẹyẹ. Àwọn kan ti lẹ wa ti wọn n kẹ́gàn ọrọ Ọlọ́run. A gbagbọ pé ìwọ kii ṣe bẹ́ẹ̀, síbẹ̀ o ko si ni jẹ ọkan lára àwọn wọ̀nyí!? Òpin n bọ wa, a sì ti yàn ọjọ naa, ti Ọlọ́run nìkan ṣoṣo mọ. Ọlọ́run ko fi ìlérí Rẹ jáfara, ṣùgbọ́n O kan n mú sùúrù fún gbogbo wa lati ṣe àwọn àtúnṣe tí o ba yẹ ni. Ṣé èyí kì o to pẹ̀ju.

IGUNLẸ
Èyí ni opin ẹ̀kọ́ kẹrin tí ọwọ yii. O ti fi hàn wa ninu ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ alaye bí a ti fi àwọn ìwé mímọ fún ènìyàn ni ìbámu pẹ̀lú àwọn iṣẹlẹ ìgbà-ìkẹyìn. A gbagbọ wí pé a ti gbé àwọn akẹ́kọ̀ọ́ ro pẹ̀lú ohun tí ìwé mimọ sọ nípa àwọn iṣẹlẹ ìgbà ikẹhin nínú májẹ̀mú láéláé àti nínú májẹ̀mú tuntun. Àdúrà òtítọ́ náà ni wí pé kosi ẹnikẹ́ni nínú wa ti yoo ba lai múra silẹ, ní Orúkọ Jesu, nípa ti òpin òjìji tí a ti yàn ayé ìsinsìn yii fún. Ọkàn lára àwọn àṣírí tí ko fi ní bá wà lai múra silẹ ni lati maa kíyèsí àwọn iṣẹlẹ ìgbà ikẹhin kí a sì máa múra silẹ láti di ẹni igbasoke.
ÀṢÀRÒ LÁTI INÚ BÍBÉLÌ FÚN ỌSẸ ÌKEJÌ
Mon. 2: Jòhánù Gba Ìran Ìgbà Ikẹhin (Ifi. 4:1)
Tue. 3: Jòhánù Rí Ìran Ọ̀run (Ifi. 4:2-11)
Wed. 4: Jòhánù Rí Ọdọ Àgùntàn Tí A Pa (Ifi. 5:1-7)
Thur. 5: Jòhánù Gbọ Ohun Àwọn Áńgẹ́lì (Ifi. 5:8-14)
Fri. 6: Jòhánù Rii tí Jesu N Ṣí Àwọn Edidi Náà (Ifi. 6.1-12)
Sat. 7: Jòhánù Rí Àwọn Ẹ̀yà Ísírẹ́lì Ti A Fi Èdìdì Di (Ifi. 7:1-8).
ÌJỌ ÀPỌ́SÍTÉLÌ KRISTI. Ẹ̀KỌ́ ILẸ̀ Ẹ̀KỌ́ ỌJỌ́ ÌSINMI. Fun September 8, 2019 . Kí Ìwé Mímọ́ Kí O Le Ṣẹ. ÌJỌ ÀPỌ́SÍTÉLÌ KRISTI. Ẹ̀KỌ́ ILẸ̀ Ẹ̀KỌ́ ỌJỌ́ ÌSINMI. Fun  September 8, 2019 . Kí Ìwé Mímọ́ Kí O Le Ṣẹ. Reviewed by Muyiwa Abodunrin (Muyilight) on September 08, 2019 Rating: 5

No comments:

Powered by Blogger.