ÌJỌ ÀPỌ́SÍTÉLÌ KRISTI, Ẹ̀KỌ́ ILÉ Ẹ̀KỌ́ ỌJỌ́ ÌSINMI FUN August 11, 2019 : Akori - Ki Ìwé Mímọ́ Ki O Le Ṣẹ. .

--> Note :- Are you born again? You are never going to win the battle against the devil if you are not born again. I plead with you to give your life to Jesus today because the longer you stay in sin and remain unsaved, the more hardened your nature becomes against the purpose and the way God wants you to be for His purpose. To give your life to Jesus now, say this prayer: “Father, I come to You in the name of Jesus. I know that I am a sinner and I cannot save myself but Jesus died for me and shed His blood that I might be saved. Today, I accept Jesus as my Lord and Saviour. Jesus, I ask You to come into my heart, be my Lord, wash me with Your blood and make me whole. I believe with my heart and confess with my mouth that Jesus is my Lord. Thank You for saving me. In Jesus' name I pray. Amen.” I congratulate you and welcome you to the family of God if you have sincerely said that prayer. Now you are fit to discover, know and walk in your destiny. Call our helpline on +2348037252124, Join Our Daily Whatsapp Devotionals Group : +2347033046607 for Daily Devotionals, crucial discipleship and counselling.s"
ÌJỌ ÀPỌ́SÍTÉLÌ KRISTI, Ẹ̀KỌ́ ILÉ Ẹ̀KỌ́ ỌJỌ́ ÌSINMI FUN August 11, 2019 : Akori - Ki Ìwé Mímọ́ Ki O Le Ṣẹ.  .

Eka awon Eko Ojo Isinmi Ti Ateyiwa ni bi yi
ÌJỌ ÀPỌ́SÍTÉLÌ KRISTI.
Ẹ̀KỌ́ ILÉ Ẹ̀KỌ́ ỌJỌ́ ÌSINMI.
Ki Ìwé Mímọ́ Ki O Le Ṣẹ.
August 11, 2019.

II.     WỌN YÓÒ PÈSÈ MÈSÁYÀ NÁÀ (Gen. 12:1-3; 18:18,19; Deut. 18:14 swj; Orin Daf. 67; Seka. 12:10; 13:1,2,9).


'Pèsè' nihin yii n tọ́ka sí bí Mèsáyà náà yóò ti wá láti mú ìran Israẹli, ní pàtó, gẹ́gẹ́ bí ọmọ Dafidi gbongbo Jesse, àti bí kìnnìún ẹ̀yà Júdà. Ọrọ Ọlọ́run wí pé o dara wí pé Mèsáyà náà yóò jẹ irú ọmọ Abraham, èyí ko si kùnà, nítorí a bí Jesu Olúwa ni Bẹthlẹhẹmu.

A.    WỌN YÓÒ FI YAHWEH HÀN ÀWỌN ORÍLẸ̀-ÈDÈ (Gen. 18:18, 19; O.D. 67)
       Ki ọna Rẹ ki o le di mimọ ni ayé, àti ìgbàlà ìlera Rẹ ni gbogbo orílẹ̀-èdè (O.D, 67:2).
i.     Gen. 18:18: Ọlọ́run ti ni i lọ́kàn nípa ti Ábúráhámù, láti ìbẹ̀rẹ̀ pẹpẹ, wí pé "gbogbo orílẹ̀-èdè ayé ni a o bukun fún nípasẹ̀ rẹ" Ọ̀rọ̀ nípa ìbùkún nihin yii tayọ ohun-èlò tàbí àwọn nnkan ti ko le pẹ lọ titi.
ii.   Ẹsẹ 19: Ábúráhámù yóò ṣe èyí nípa pípasẹ (ẹ̀kọ́ àti ìtọ́ni) fún àwọn ọmọ rẹ (yálà àwọn ọmọ tó bí nípa tara tàbí nípa t'ẹ̀mí eyi ti yoo papa kan àwọn Kèfèrí pẹ̀lú) láti àwọn ìran dé ìran láti máa pá ọna òdodo àti òtítọ́ Olúwa mọ.
iii.   O.D 67: N ṣàlàyé síwájú sii pe eredi kikepe Ọlọ́run nínú àdúrà ni ìlà kinni, ede isure ìbùkún tí Áárónì (Num. 6:24-26), fún Ọlọ́run láti ni inu dídùn sí àwọn ènìyàn Rẹ (wo O.D. 80), ní pé kí ọna Olúwa lè di mimọ lórí ilẹ̀ ayé (ila 2).
iv.  Ni ìmúṣẹ àwọn ìpèsè májẹ̀mú Ábúráhámù (Gen. 12:3), Ọlọ́run ni erongba to jinlẹ lọ́kàn fún àwọn ènìyàn Rẹ.
v.   Ila 2b: Ni ti òye ìjìnlẹ̀, ÌGBÀLÀ Olúwa ni a o sọ di mímọ láàrin àwọn orílẹ̀-èdè. Èyí ni ìgbàlà tí yóò mú ìdùnnú àti ayọ̀ wá gẹ́gẹ́ bí Olúwa ṣe dájọ (dárí) àwọn ènìyàn náà (ila 3,4), láti máa mú ìṣerérè òtítọ́ wa (ila 5,6) gẹ́gẹ́ bí ẹrú Rẹ ti gbilẹ nínú wọn (ila 7).
vi.   A o mú àwọn wọ̀nyí ṣẹ nígbà to ba yà nínú ìràpadà àti ìgbàlà tí Jesu Kristi, ṣùgbọ́n OLÙGBÀLÀ ẹ̀dá ènìyàn ń mú bọ wa ni kíkún (wo Jhn. 10:10).
vii.  Israẹli ni iṣẹ́ ńlá láti jẹ Olùkọ́ gbogbo àgbáyé, láti darí wọn sì ọdọ Ọlọ́run. Njẹ wọn ṣe ìmúṣẹ iṣẹ yii bí? Wọn kò ṣe e dára to. Nítorí náà, Jésù fi ìṣẹ́ náà lè ọwọ àwọn ọmọ ẹ̀hin Rẹ (Mat. 28:19), bẹ́ẹ̀ sì ni lati igba naa ni èyí tí di ìṣẹ́ iranjade ńlá fún àwọn onigbagbọ nínú Rẹ, láti múṣẹ. Báwo ni ìwọ ṣe n ṣe e?

B.   WỌN YÓÒ DI BÀBÁ-NLÀ MÈSÁYÀ NÁÀ (Gen. 12:1-3; Deut. 18:14 swj; Sek. 12:10; 13:1,2,9).
       Olúwa Ọlọ́run rẹ yóò gbé wolii kan dìde fún ọ láàrin rẹ, nínú àwọn arákùnrin rẹ, bí èmi, Òun ni kí ẹyin kí o fetisi (Deut. 18:15).
i.    Gen. 12:1-3: Nigba ti Ọlọ́run n pe Ábúrámù, ènìyàn tí ṣubú, Ọlọ́run sì ti ṣe àgbékalẹ eto ìgbàlà ayérayé Rẹ fún ènìyàn.
ii.   Ẹsẹ 2,3: Láti mú ìbùkún tí a n sọ̀ nihin yìí wa fún gbogbo ìdílé ayé... Ọlọ́run ní lọ́kàn tayọ Abramu sì irú ọmọ rẹ tó jìnnà réré Mèsáyà náà. Ni wọn bí o ti jẹ pé, Abramu fúnrarẹ ko le ni ju ìwọ̀nba ìgbà lọ láyé tí yóò fi kú.
iii.  Deut. 18:14-22: Kí ẹnikẹ́ni ma ba a máa wo Mósè gẹ́gẹ́ bi ẹni tí yóò mú Gen. 12:2,3 ṣẹ, o yara kankan lábẹ́ imisi atokewa láti sọ nípa ọjọ iwájú bí isẹ ìránṣẹ́ rẹ tí n wa si òpin ni gẹ́gẹ́rẹ àtiwọ Kénáánì.
iv.  Ẹsẹ 15:,18: Wolii náà (ni ìwòye Mèsáyà) yóò wa... laarin rẹ, nínú àwọn arákùnrin rẹ... láti inú àwọn arákùnrin wọn. Taa ni? Àwọn ọmọ Israẹli. Àwọn Juu. Iwe Mimọ sọ gbangba pe Israẹli yóò jẹ bàbà-ńlá Mèsáyà náà.
v.   Ní abade ìparí Májẹ̀mú Láéláé Ọlọ́run ji ìrètí àwọn Juu dìde, àti ní gbígbòòrò, gbogbo ayé pátápátá, ní ti wíwà Mèsáyà àkọ́kọ́ láti wa nípasẹ̀ àwọn Juu (Sek. 12:10a), láti san gbèsè ìràpadà fún ènìyàn pátápátá (ẹsẹ 10b; 13:1,9).
vi.  Eyi ń tọ́ka sí Mèsáyà tí a máa bí pẹ̀lú òkun ìran tààrà sì Dafidi, Israẹli àti Ábúráhámù, báyìí, a n mú májẹ̀mú ìràpadà ayérayé Ọlọ́run pẹ̀lú Ábúráhámù ṣẹ nípa bibukun gbogbo ìdílé ayé.
vii.  Òtítọ́ pé Israẹli bi (pèsè) Mèsáyà náà kò túmọ̀ sí pé ẹnikẹ́ni nínú wọn àti pẹ̀lú bàbà-ńlá wọn, 'Ábúráhámù' tóbi jù tàbí dàgbà jù Mèsáyà náà lọ. Mèsáyà náà tí wá ṣáájú wíwà ayé. Ní àfikún, ohùn kanṣoṣo tí o le mú kí wọn bọ kúrò nínú ṣíṣe alábàápín ìjìyà pẹ̀lú àwọn orílẹ̀-èdè tí wọn kò ní Ọlọ́run ni igbagbọ pátápátá nínú Jesu Kristi, àti Òun nìkanṣoṣo.

ÀWỌN Ẹ̀KỌ́ TÍ A RÍ KỌ
1.   Gẹ́gẹ́ bí Ọlọ́run ti bá Ábúráhámù dá májẹ̀mú, Ó ní ọ àti àwọn ìran tí a ko tii bí lọ́kàn. Irú Baba olóore-ọ̀fẹ́ wo niyìí!
2.   Ọlọ́run ti ń fi pẹ̀lẹpẹ̀lẹ́ àti ọgbọ́ọgbọ́n ṣe ẹtọ Rẹ láti ra ènìyàn pada. Kódà kí ìwọ tó wọnú rẹ. Máse yọ silẹ.

ÀWỌN ÌBÉÈRÈ
1.   Kin ni Ọlọ́run ni ni ọkàn nígbà tí O ṣe ìlérí wí pé irú ọmọ Ábúráhámù yóò di orile-ede ńlá?
2.   Iwe Mimọ sọ ọ di mimọ kepere wí pé àwọn Juu yóò pèsè Mèsáyà náà. Kín ni èyí túmọ̀ sí fún àwọn Juu àti gbogbo ayé?

ÀWỌN ÌDÁHÙN TÍ A DÁBÀÁ FÚN ÀWỌN ÌBÉÈRÈ:
ÌDÁHÙN SÍ ÌBÉÈRÈ 1:
i.    Ọlọ́run kò ṣe ohunkóhun fún yẹyẹ/awada ri, O maa n ní erongba, O si maa n ní àfojúsùn ọjọ́ ọ̀la.
ii.   O ni eto ìràpadà ayérayé Rẹ lọ́kàn.
iii.  O ni Mèsáyà náà, ẹni tí yóò ṣe ìmúṣẹ eto ayérayé náà lọ́kàn pẹ̀lú.
iv.  O ni gbogbo ayé lọ́kàn. Ko sàgbékalẹ eto Rẹ fún Israẹli nìkan, ṣùgbọ́n O yàn Israẹli gẹgẹ bi àpẹẹrẹ mímú alakalẹ eto Rẹ ṣẹ --- Ọ̀rọ̀ náà.
v.   O ni ìgbàlà ikẹhin (ayérayé) wa lọ́kàn. Ko si ẹnikẹ́ni nínú wa ti yoo sọnù nínú ètò ayérayé Ọlọ́run, ní orúkọ Jesu.

ÌDÁHÙN SÍ ÌBÉÈRÈ 2:
i.   Ko si ẹnikẹ́ni wa ti o yẹ fún Oore-ọ̀fẹ́ Ọlọ́run ti a n gbádùn.
ii.  Àwọn Júù kan ni oore-ọ̀fẹ́ láti jẹ àwọn ẹni tí a yàn jáde nínú gbogbo ayé láti jẹ bàbà-ńlá Mèsáyà náà ni.
iii. Ìràpadà wọn kii ṣe mímọ-ọn-ṣe wọn bẹẹ ni kí I ṣe ẹtọ rara.
iv. Mèsáyà jẹ Olùgbàlà gbogbo ayé tí a fà mí-òróró-yàn. Nípasẹ̀ Rẹ, àwọn Juu àti àwọn Kèfèrí di bákan náà, ní ìrírí ìgbàlà Ọlọ́run.
v.  Ìfẹ́ Ọlọ́run nípa èyí tí o yọnda Mèsáyà náà kò wá fún àwọn Juu nìkan, bikose pé o kò gbogbo ayé papọ (Jhn. 3:16).
vi. Ìṣẹ́ ìgbàlà náà wá fún gbogbo ènìyàn (àwọn Juu àti àwọn Kèfèrí) láti rọ mọ eto ìràpadà ayérayé tí Ọlọ́run fún ènìyàn. Titi dìgbà náà ni a tó le sọ wí pé a ti mú Ìwé Mímọ́ ṣẹ bo ti tọ.
vii. Bákan náà, gbogbo wa, kí I ṣe àwọn Juu nìkan, ní a gbọdọ jáde lọ láti kéde irohin ayọ tí wíwà ìgbà àkọ́kọ́ àti ti wíwà ológo ìgbà kejì tí Jesu Kristi Olùgbàlà wa ti a n fojú sọ́nà fún.

ÀMÚLÒ FÚN IGBE AYÉ ẸNI :
A sọtẹ́lẹ̀ tí lọ ṣááaju Ogbẹni Tosh, ṣáájú ibi rẹ, wí pé yóò di ẹni ńlá yóò sì ní ọrọ láyé. Nígbà tí Tosh dàgbà tí a sì sọ eto Ọlọ́run fún un láti sọ ọ di ẹni ńlá àti ọlọrọ, dípò kí o máa ṣíṣe tọ ìmúṣẹ eto yii, gbogbo rẹ ko sii lórí o sì bẹ̀rẹ̀ si ni bẹ̀rẹ̀ si ni Síwáhu. O bẹ̀rẹ̀ si ni i safihan ararẹ bí 'eniyan jankan' nígbà tí kò tilẹ tí I sunmọ itosi rẹ rárá. Gbogbo ènìyàn pẹ̀lú àwọn òbí rẹ kò jámọ ohunkóhun sì i. Kódà, kò ní íbọ̀wọ̀ fun Ọlọ́run ẹni tí ó ti fi ọ̀rọ̀ náà fún òbí rẹ. Lójú tìrẹ, o ti di ẹni ńlá jù ẹnikẹ́ni lọ, tí o si n fojú tẹmbẹlu gbogbo àwọn ènìyàn tó yiika. Nínú ìgbéraga aya rẹ o dẹ́ṣẹ̀ sì ọkùnrin arúgbó kan tí o jẹ ìkà ẹni tí o fi agbára ẹ̀mí búburú rẹ gbìn àrùn àtigbadegba kan sínú ayé rẹ eyi ni ó sì fòpin sí ẹ̀mí rẹ. Tosh kò wa laye lati ri ìmúṣẹ ọrọ Ọlọ́run nínú ayé rẹ. Nítorí ijakulẹ rẹ láti pá Májẹ̀mú tí o yẹ ki o pamọ mọ. Ìgbọràn jẹ irinsẹ tó lágbára láti mú kí ọrọ Ọlọ́run (Iwe Mimọ) ni agbara nínú ayé wa. Ọpẹ ni fún Ọlọ́run fún ìgbọràn àwọn bàbà-ńlá Israẹli.

IGUNLẸ
Èyí ni opin ẹ̀kọ́ kejì. A ko salai fi ọlá, ògo àti, ìyìn fún Ọlọ́run, ẹni tí o ti bukun wá lọpọlọpọ pẹlu ọrọ ti o bọ si àkókò. A gbàdúrà wí pé, nínú ohunkóhun tí a bá n ṣe, ìmúṣẹ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run bí o ti tọ yóò máa jẹ àfojúsùn wá nígbà gbogbo. A gbàdúrà wí pé ìwọ yóò gbà oore-ọ̀fẹ́ láti máa fọwọ́sowọpọ pẹ̀lú Ọlọ́run nígbà gbogbo láti mú ìfẹ́ inú rere Rẹ ṣẹ nínú ayé rẹ, kí O sì mú èrò ìràpadà ayérayé Rẹ wà sì ìṣe fún ọ nigbẹhin.

ÀṢÀRÒ LÁTI INÚ BÍBÉLÌ FÚN Ọ̀SẸ̀ ÌKEJÌ
Mon.    5:    Ọlọ́run ṣe Ìràpadà àti Idasilẹ Israẹli (Isa. 43:1-4).
Tue.     6:    Ifẹ̀ Ọlọ́run fún Israẹli Kọjá Sísọ (Mal. 1:1-5)
Wed.    7:    Israẹli Gbádùn Ìwàláàyè Ọlọ́run Ní Kíkún (Isa. 43:5-8)
Thur.   8:    Títóbi Ni Ọlọ́run Israẹli (Isa. 43:9-13)
Fri.      9:    Ọlọ́run Yóò Ṣe Àwọn Ohun Tuntun Fún Israẹli (Isa. 43:14-20)
Sat.     10:   Ìrètí Ọlọ́run Gbọ́dọ̀ Wá Sí Ìmúṣẹ (Isa. 43:21-28).
ÌJỌ ÀPỌ́SÍTÉLÌ KRISTI, Ẹ̀KỌ́ ILÉ Ẹ̀KỌ́ ỌJỌ́ ÌSINMI FUN August 11, 2019 : Akori - Ki Ìwé Mímọ́ Ki O Le Ṣẹ. . ÌJỌ ÀPỌ́SÍTÉLÌ KRISTI, Ẹ̀KỌ́ ILÉ Ẹ̀KỌ́ ỌJỌ́ ÌSINMI FUN August 11, 2019 : Akori - Ki Ìwé Mímọ́ Ki O Le Ṣẹ.  . Reviewed by Muyiwa Abodunrin (Muyilight) on August 10, 2019 Rating: 5

No comments:

Powered by Blogger.