ÌJỌ ÀPỌ́SÍTÉLÌ KRISTI. Ẹ̀KỌ́ ILẸ̀ Ẹ̀KỌ́ ỌJỌ́ ÌSINMI. Fun 25 OSU kejo, 2019. Akori - Kí Ìwé Mímọ́ Kí O Le Ṣẹ.

--> Note :- Are you born again? You are never going to win the battle against the devil if you are not born again. I plead with you to give your life to Jesus today because the longer you stay in sin and remain unsaved, the more hardened your nature becomes against the purpose and the way God wants you to be for His purpose. To give your life to Jesus now, say this prayer: “Father, I come to You in the name of Jesus. I know that I am a sinner and I cannot save myself but Jesus died for me and shed His blood that I might be saved. Today, I accept Jesus as my Lord and Saviour. Jesus, I ask You to come into my heart, be my Lord, wash me with Your blood and make me whole. I believe with my heart and confess with my mouth that Jesus is my Lord. Thank You for saving me. In Jesus' name I pray. Amen.” I congratulate you and welcome you to the family of God if you have sincerely said that prayer. Now you are fit to discover, know and walk in your destiny. Call our helpline on +2348037252124, Join Our Daily Whatsapp Devotionals Group : +2347033046607 for Daily Devotionals, crucial discipleship and counselling.s"
ÌJỌ ÀPỌ́SÍTÉLÌ KRISTI.  Ẹ̀KỌ́ ILẸ̀ Ẹ̀KỌ́ ỌJỌ́ ÌSINMI. Fun 25 OSU kejo, 2019. Akori - Kí Ìwé Mímọ́ Kí O Le Ṣẹ.  




ÌJỌ ÀPỌ́SÍTÉLÌ KRISTI.
Ẹ̀KỌ́ ILẸ̀ Ẹ̀KỌ́ ỌJỌ́ ÌSINMI.
Kí Ìwé Mímọ́ Kí O Le Ṣẹ.
August 25, 2019.

II.   ÌGBÉ AYÉ ÀTI IKÚ MÈSÁYÀ NÁÀ (Isaiah 53:1-11)
     Àwọn tí a sọ di ọba láyé lórí àwọn ènìyàn wọn, máa n ní àwọn àbùdá tí o yẹ fún ipo wọn, kódà bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ọpọ wọn ní ko gbé ìgbé ayé iwa rere àti iwa yíyẹ tí ipò wọn ń béèrè fún. Jésù jẹ́ ẹni ọ̀tọ̀ àti Ọba Ológo julọ ẹni tí, bí o tilẹ jẹ́ pé kò wa ninu ọlá-ńlá tí ayé afẹ́fẹ́yẹyẹ gẹ́gẹ́ bí àwọn ẹlòmíràn, O yàn láti da araRẸ pọ pẹ̀lú ẹrú (làálàá) àwọn ènìyàn Rẹ. Ki Ìwé Mímọ́ kí o le ṣẹ, O ku fún gbogbo ènìyàn.


A.   YÓÒ GBÉ ÌGBÉ AYÉ ÌRÁNṢẸ́ TÍ O JÌYÀ (ẹsẹ 1-7)
      A jẹ Ẹ níyà, a sì pọn Ọn lójú, ṣùgbọ́n Òun ko ya ẹnu Rẹ: a mú Un wa bi ọdọ àgùntàn fún pípa, àti bí àgùntàn tí o yadi níwájú olùrẹ́run rẹ, bẹ́ẹ̀ ni kò ya ẹnu Rẹ (ẹsẹ 7).
i.   Ẹsẹ 1-3: Mèsáyà náà, Olùgbàlà ẹlẹ́sẹ ni a kì yóò fi bẹẹ gba nítorí ìfarahàn onirẹlẹ Rẹ ati eyi ti o báni-nínújẹ. A ń retí Rẹ láti wa nínú ọṣọ púpọ̀ àti nínú àwòrán ògo ńlá, síbẹ̀, Oun yoo dàgbà gẹ́gẹ́ bí ohun ọgbin ni pẹ̀lẹ́pẹ̀lẹ́ àti pẹ̀lú irẹlẹ (wo Mak. 9:12). Àwọn ẹni tí ara kí yóò rí eredi láti pọngbẹ fún Olùgbàlà wọn.
ii.   Ẹsẹ 5: 'Ṣùgbọ́n a ṣá A ní ọgbẹ nítorí ìrékọjá wa", Mèsáyà náà yóò ru ẹṣẹ gbogbo ayé (wo Mat. 8:17; I Pet. 2:24). Kristi yóò ní ibanujẹ niti ara ati niti ọpọlọ (O.D.22:16), a o si da A lẹjọ gẹ́gẹ́ bi ẹni pé a ń jé Ẹ níyà fún ẹṣẹ Òun tikalara Rẹ. Èyí ni yóò foriti láti la ènìyàn nija sì Ọlọ́run, lẹ́sẹkẹsẹ àti pátápátá.
iii.  Ẹsẹ 6: "Olúwa sì ti mú aisedeede wa gbogbo pàdé lára Rẹ" Nínú ara wa, a ti tú wa ka. Nínú Kristi, a ti ko wa jọ. Niti ìṣẹ̀dá, a máa ń sina lọ sínú ìparun (O.D. 119:179; I Pet. 2:25). Nínú Kristi ni kanṣoṣo ni a ti lè wa ọna wa si ìyè, nítorí O ti ru ìjìyà tí o yẹ fún gbogbo ènìyàn sì orí ara Rẹ (I Pet. 3:18), ẹbọ ìràpadà wa.
iv.  Ẹsẹ 7: A jẹ Mèsáyà náà níyà... a sì pọn lójú, ṣùgbọ́n òun ko ya ẹnu Rẹ. Yóò jẹ ohun ti o lágbára nípa tiRẹ. Yóò jẹ́ ohun tí o lágbára nípa tìRẹ láti jẹ gẹ́gẹ́ bí ọdọ àgùntàn tí a fa lọ fún pípa àti àgùntàn níwájú olùrẹ́run rẹ... yóò fi idakẹjẹ yadi lọ́nà ìyanu, O si mọ-ọn-mọ yàn láti máṣe ẹnu Rẹ nítorí kí O ba a le ṣàṣepe ìṣẹ́ ìràpadà wa (wo Mat. 26:63; 27:14;  Ìṣe 8:32).
v.  Kristi ni Ọdọ Àgùntàn Ọlọ́run nínú ìgbọràn àti irẹlẹ, ẹni tí bí O ti n jìyà fún àwọn ẹlẹ́ṣẹ, O wa ni idakẹjẹ bí a ti n na An, tí a sì ṣe E yannayanna. A gbọ́dọ̀ sìwọ ṣíṣe awawi nígbà tí a ba n la àwọn ipenija ayé kọjá. Bí àwọn àsọtẹ́lẹ̀ Ìwé Mímọ́ tí wa náà ba gbọ́dọ̀ ṣẹ, a gbọ́dọ̀ farada kí a si forí tí I titi de òpin.

B.   YÓÒ KÚ ṢÙGBỌ́N YÓÒ JÍ DÌDE (ẹsẹ 8-11)
      A mu Un jáde láti ibi ìhámọ́ òun idajọ: tani o si sọ ìran Rẹ? Nítorí a ti ké e kúrò ní ilẹ alààyè: nítorí ìrékọjá àwọn ènìyàn mi ni a ṣe lu U (ẹsẹ 8).
i.   Ẹsẹ 8: Mèsáyà náà, nítorí ti wa, a o "ké E kúrò ní ilẹ alààyè" (a pa A nipakupa a sì kan An mọ Àgbélébùú), a sì rán An lọ sí ibojì bí o tilẹ jẹ pé ki ìṣe ọ̀daràn (wo Jhn. 19:17-42).
ii.  Ẹsẹ 9: " O si ṣe ibojì Rẹ pẹ̀lú àwọn ènìyàn búburú" Ọlọ́run yóò finufindọ yọnda Mèsáyà náà (Ọmọ Rẹ̀) sì ọwọ àwọn ènìyàn tí èṣù tí gbìn èrò láti lu U nítorí tí wa sínú wọn (wo ẹsẹ 8b).
iii. Bi ó tilẹ̀ jẹ́ pé "ko hu iwa ipa, bẹ́ẹ̀ ni kò sí arekereke ni ẹnu Rẹ,... o wu Olúwa láti pa A lára, o ti fi sínú ibanujẹ (wo Mat. 27:38).
iv.  Ẹsẹ 10:, Yóò mú ọjọ Rẹ gùn' Mímu ọjọ Rẹ gun pè fún wi pe, kódà lẹ́yìn tí wọn ro pe awọn ti pa A, yóò tún padà ye (jinde) kí ìfẹ́ Olúwa kí o lè ṣẹ ní ọwọ Rẹ. Eredi ni pé, Ọlọ́run kò ní fi ọkàn Rẹ silẹ ni ipo òku (O.D. 16:10; 86:13).
v.  Ẹsẹ 11: 'Yóò rí nínú èso làálàá Rẹ, yóò sì tẹ Ẹ ní ọ̀run... Idasilẹ tí o ga julọ tí Mèsáyà náà yóò ṣe ko ni ja si asán. Làálàá náà, ìrora, ìmíẹ̀dùn, ibanujẹ ọkàn Rẹ (ìpọ́njú ńlá tí a o mu Un lakọja) yóò so èso esi rere mímú ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọmọkùnrin àti ọmọbìnrin wa si ọdọ Ọlọ́run (wo Héb. 2:10).
vi.  Wákàtí ìṣe ṣíṣẹ le nira kí o ma sì rọrùn, ayọ̀ ìṣẹ́ a máa pọ nígbà nígbà tí ènìyàn ba n ri ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìkórè. Ìjìyà Kristi ko lọ lásán rara nítorí eto ńlá Ọlọ́run fún ẹ̀dá ènìyàn ṣe rere (ṣàṣeyọrí) ni ọwọ Rẹ. Ìwọ jẹ ara àwọn èso Rẹ, nítorí náà, máṣe kẹ/ra dànù, tàbí wa lai wúlò! (Mat. 28:29, 20).

ÀWỌN Ẹ̀KỌ́ TÍ A RÍ KỌ
1.   A ko fi wa silẹ nínú òkùnkùn láti mọ ohun tí igbe ayé (iye) àti ikú Mèsáyà náà yóò jẹ. Jésù ti wá láti mú ọrọ àsọtẹ́lẹ̀ wọnnì ṣẹ.
2.  Ọlọ́run sọtẹ́lẹ̀ wí pé Mèsáyà yóò jìyà yóò sì kú. Dájúdájú nnkan miiran ni àwọn Júù ń retí, ṣùgbọ́n Jésù wa gẹ́gẹ́ bí ìránṣẹ́ tí o jìyà.

ÀWỌN ÌBÉÈRÈ
1.   Ọna wo ni Ìwé Mímọ́ gba sọtẹ́lẹ̀ wí pé Mèsáyà yóò wa, yóò gbé láyé tí yóò sì kú?
2.  Ṣe àfihàn wí pé Jésù mú àwọn ọrọ àsọtẹ́lẹ̀ wọnnì ṣẹ nípa wíwà, ìgbe ayé àti ikú Mèsáyà náà.

ÀWỌN ÌDÁHÙN TÍ A DÁBÀÁ FÚN ÀWỌN ÌBÉÈRÈ:

ÌDÁHÙN SÍ ÌBÉÈRÈ KÍNNÍ:
*   Lọ sí ìpín IA, B àti IIA
*   Ìwé Mímọ́ kúnrẹrẹ pẹ̀lú àwọn àpẹẹrẹ àwọn àsọtẹ́lẹ̀ nípa wíwà Kristi, ìṣẹ́ àti ikú Rẹ.
*   Gẹ́gẹ́ bi Isaiah 53:2, Òun yóò wá nínú ailọla àti iri ailẹwa.
*   Yóò jẹ ẹni ibanujẹ, tí a kọ silẹ tí a sì kẹgan (ẹsẹ 3)
*   Bo tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn ẹsẹ wa lo mú ko sọra Rẹ di ẹni yẹpẹrẹ, a ko ni fẹ láti ka A si nítorí yóò wa sínú Bẹ́tílẹ́hẹ́mù tí a ko ka si.
*   Yóò gbé ìgbé ayé ìránṣẹ́ tí a jẹníyà, ẹni tí a o fi àìṣòdodo ba lo, a o si wo O palẹ nípasẹ̀ àwọn olotẹ ènìyàn (wo Ìṣe 2:23).
A o pa A gẹ́gẹ́ bí ọ̀daràn, ṣùgbọ́n a o sìn Ín láàrin àwọn ọlọ́rọ̀.
*   Èṣù ro wí pé òun ni Òun fọ Jésù lórí; O kan wu Olúwa láti ṣẹ bẹẹ fún ìdáǹdè wa ni (Isa. 53:10). Irú ọgbọ́n ìgbàwọlé ayérayé àti eyi ti o gbẹhin (akotan) wo ni èyí fún èṣù!
ÌJỌ ÀPỌ́SÍTÉLÌ KRISTI. Ẹ̀KỌ́ ILẸ̀ Ẹ̀KỌ́ ỌJỌ́ ÌSINMI. Fun 25 OSU kejo, 2019. Akori - Kí Ìwé Mímọ́ Kí O Le Ṣẹ. ÌJỌ ÀPỌ́SÍTÉLÌ KRISTI.  Ẹ̀KỌ́ ILẸ̀ Ẹ̀KỌ́ ỌJỌ́ ÌSINMI. Fun 25 OSU kejo, 2019. Akori - Kí Ìwé Mímọ́ Kí O Le Ṣẹ.  Reviewed by Muyiwa Abodunrin (Muyilight) on August 25, 2019 Rating: 5

No comments:

Powered by Blogger.