ÌJỌ ÀPỌ́SÍTÉLÌ KRISTI. Ẹ̀KỌ́ ILÉ Ẹ̀KỌ́ ỌJỌ́ ÌSINMI Ki Ìwé Mímọ́ Ki O Le Ṣẹ.. FUN August 18, 2019. AKORI - NÍ IMURASILẸ FÚN BIBỌ MÈSÁYÀ NÁÀ

--> Note :- Are you born again? You are never going to win the battle against the devil if you are not born again. I plead with you to give your life to Jesus today because the longer you stay in sin and remain unsaved, the more hardened your nature becomes against the purpose and the way God wants you to be for His purpose. To give your life to Jesus now, say this prayer: “Father, I come to You in the name of Jesus. I know that I am a sinner and I cannot save myself but Jesus died for me and shed His blood that I might be saved. Today, I accept Jesus as my Lord and Saviour. Jesus, I ask You to come into my heart, be my Lord, wash me with Your blood and make me whole. I believe with my heart and confess with my mouth that Jesus is my Lord. Thank You for saving me. In Jesus' name I pray. Amen.” I congratulate you and welcome you to the family of God if you have sincerely said that prayer. Now you are fit to discover, know and walk in your destiny. Call our helpline on +2348037252124, Join Our Daily Whatsapp Devotionals Group : +2347033046607 for Daily Devotionals, crucial discipleship and counselling.s"
ÌJỌ ÀPỌ́SÍTÉLÌ KRISTI.  Ẹ̀KỌ́ ILÉ Ẹ̀KỌ́ ỌJỌ́ ÌSINMI Ki Ìwé Mímọ́ Ki O Le Ṣẹ.. FUN August 18, 2019. AKORI - NÍ IMURASILẸ FÚN BIBỌ MÈSÁYÀ NÁÀ



EKA AWON EKO TI ATEYINWA NIBI YII

ÌJỌ ÀPỌ́SÍTÉLÌ KRISTI.
Ẹ̀KỌ́ ILÉ Ẹ̀KỌ́ ỌJỌ́ ÌSINMI.
Ki Ìwé Mímọ́ Ki O Le Ṣẹ.
August 18, 2019.

Ẹ̀KỌ́ KẸTA
NÍ IMURASILẸ FÚN BIBỌ MÈSÁYÀ NÁÀ

Ètò ayérayé Ọlọ́run ni wí pé a bí I nínú obìnrin, a o kẹ́gàn Mèsáyà náà, a o si kọ ọ, kí a lè ra ìran ènìyàn tí ó ti dibajẹ padà.


AKỌSÓRÍ
Yọ gidigidi ìwọ ọmọbìnrin Síónì; hó, ìwọ ọmọbìnrin Jerúsálẹ́mù: kiyesii, Ọba rẹ n bọ wá sọ́dọ̀ rẹ: òdodo ni Òun, O si ni ìgbàlà; O ni irẹlẹ, O si n gùn kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́, àní ọmọ kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́

(Sakaraya 9:9).

ÀLÀYÉ KÚKÚRÚ
Àkókò àsọtẹ́lẹ̀ Sekaráyà jẹ́ àkókò rúdurùdu fún Israẹli nígbà tí àwọn orílẹ̀-èdè tí wọn jẹ ọ̀tá yi I ka. Ọlọ́run Israẹli yóò ṣe ìdájọ́ àwọn ọ̀tá Rẹ, yóò sì ṣalakalẹ eto lati mú àwọn ènìyàn Rẹ bọ sípò pẹ̀lú ìlérí tí Mèsáyà kan àti Ọba òdodo, ẹni tí yóò wá láti dá àwọn ẹlẹ́sẹ̀ lare. Olùgbàlà náà tí yóò wá ń bọ̀ wá pẹ̀lú ìgbàlà, dípò ìnilára, nítorí pé Òun yóò fi ara Rẹ sípò àwọn ènìyàn ---- ibakẹdun (Heb. 4:15). Níbi tí àwọn abanikọwọrin àti ikokiki alafẹfẹfyẹyẹ. Òun yóò gùn kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ oníwàtútù, pẹ̀lú irẹlẹ, láìṣe ọṣọ/ogo tí ayé àti àfihàn dídára ẹni.

Ṣáájú, Ọlọ́run ti pàṣẹ fún àwọn ọ̀ba Israẹli kí wọn máṣe sọ àwọn ẹsin wọn di pupọ àwọn ọba tí wọn si tasẹ agẹrẹ (lòdì) sì àṣẹ yii tarawọn ni Ọsi, pàápàá gẹ́gẹ́ bí wọn tí ń sọ àwọn ènìyàn wọn di olosi/aláìní (Deut. 17:16; I.A Ọba 4:26). Ọba ti yoo wa náà kò ní wa fún ìgbádùn ara Rẹ gẹ́gẹ́ bí àwọn ẹni tí ayé ṣe máa ń ṣe, bikose fún ìdáǹdè àwọn ènìyàn Rẹ kúrò lọ́wọ́ àìṣòdodo àti ìnilára.

Àsọtẹ́lẹ̀ yìí tí wá sí ìmúṣẹ fún Israẹli àti àgbáyé lapapọ. Àwọn onigbagbọ le dúró kí wọn sì máa ní ìrètí fún ipadabọ Rẹ nisinsin yii gẹ́gẹ́ bí O ti n kọ wa lati gba wa la titi ayé kúrò lọ́wọ́ Sátánì, ẹṣẹ, ikú àti ọrun àpáàdì. Ẹ jẹ ká máa retí Rẹ!

ÀṢÀRÒ LÁTI INÚ BÍBÉLÌ FÚN Ọ̀SẸ̀ KINNI
Mon.    12:    Jesu: Ẹbọ Alailabawọn (Lk. 24:44; Heb. 9:14)
Tue.     13:    Jesu: Onirẹlẹ Pátápátá (Orin. Daf: 8:5-6; Heb. 2:7-9)
Wed.    14:    Jesu: Ẹni Tí A Kẹ́gàn (Isa. 49:7; Mat. 26:67)
Thur.    15:    Jesu A Fi Ṣẹlẹ̀ya Nítorí Wa (Orin Daf. 22:7; Mat. 27:38-42)
Fri.       16:    Jesu: Òkúta Tí A Yàn (Isa. 8:14,15; I Pet. 2:7,8)
Sat.      17:    Jesu: A Ka A Pẹ̀lú Àwọn Ọ̀daràn (Isa. 53:12; Mk. 15:27,28).

ÀṢÀRÒ FÚN ÌFỌKÀNSÌN
1.   A mọ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run nípasẹ̀ ìmúṣẹ rẹ; wíwà Jesu lẹẹkeji dájú gẹ́gẹ́ bi tí àkọ́kọ́. Múra silẹ!
2.  Ta ni ó lé pàṣẹ láti mú àwọn nnkan ṣẹlẹ̀ lai gba ìyọnu àyọ́nda Olúwa? Òun ni igi lẹhin ọgbà wíwà Jesu ìgbà àkọ́kọ́ àti tigba kejì pẹ̀lú. O jé Ọlọ́run ti kí I kùnà, ẹni tí ọrọ Rẹ kò yípadà rí. Nítorí náà, gba A gbọ kí o sì gba ọrọ Rẹ gbọ pẹ̀lú.

ẸSẸ BÍBÉLÌ FÚN IPILẸ Ẹ̀KỌ́: Jòhánù 1:49; 12:15

ILEPA ÀTI ÀWỌN ERONGBA
ILEPA:  Láti sáfihan ọna wíwà Mèsáyà náà ni ìmúṣẹ àwọn ìwé mímọ àti ìdí tí a fi nílò láti múra wá silẹ fún èyí.

ÀWỌN ERONGBA: Ní òpin ẹ̀kọ́ ọlọsẹ méjì yii, àwọn akẹ́kọ̀ọ́ gbọ́dọ̀:
i.   le ṣàpèjúwe Jesu gẹ́gẹ́ bí irú ọmọ Obìnrin naa ti a ṣeleri, tí a pa lára fún ìràpadà ẹ̀dá ènìyàn;
ii.  le ṣàlàyé bí ibi irẹlẹ Kristi ṣe ni ibasepọ pẹ̀lú àwọn ojúṣe Ọba Rẹ, kí àwa kì o le wà bí Òun ti wà.
iii. le ṣàlàyé ìdí tí Olùgbàlà náà fi ní láti la ìjìyà àti ikú kọjá láti ọwọ àwọn ẹlẹ́sẹ̀ àti satani fun ìràpadà wa; àti
iv. maa sáfihan àwọn àmì jíjẹ ẹni tó ti múra silẹ dáadáa fún wíwà Mèsáyà náà lẹẹkeji.

IFAARA
ORÍSUN Ẹ̀KỌ́: GENESISÌ 3:15; ISAIAH 7:14-16; 53:1-11; MIKA 5:1-5.
A dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọ́run fún ìrírí tí ó mú wa la kọjá, tí a pe àkòrí rẹ ni, NÍ ÌBÁMU PẸ̀LÚ ISRAẸLI. Ninu rẹ, a ti rí bí Israẹli ṣe di orilẹ-èdè ńlá nínú èyí tí Mèsáyà yóò wá, tí a o si fi hàn fún àgbáyé. Ìmúṣẹ náà bẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú ibi ọmọ ìlérí náà fún Ábúráhámù, ẹni tí o pada wa pese orílẹ̀-èdè náà, Israẹli. Orílẹ̀-èdè náà, pẹ̀lú pé o jé ọmọ májẹ̀mú, o ni oore-ọ̀fẹ́ láti jẹ ẹni tí Mèsáyà yóò ti ipasẹ rẹ wa si ayé.

Nihin yìí, a wa si ẹkọ kẹta nínú ọwọ yii. A pé àkòrí rẹ ni NÍ IMURASILẸ FÚN BIBỌ MÈSÁYÀ NÁÀ. Ìyẹn ni àwọn àsọtẹ́lẹ̀ Ìwé Mímọ́ nínú imurasilẹ fún wíwà Mèsáyà náà. Ọlọ́run, nínú ìmúṣẹ eto ayérayé Rẹ láti ra Ádámù tí o ti síwáhu padà àti ní Ìtẹ́siwaju, gbogbo ẹda ènìyàn tí wọn n dẹ́ṣẹ̀ pẹ̀lú ni ìhà rẹ, tí sọ gbangba pé, Mèsáyà náà yóò wà gẹ́gẹ́ bí irú Ọmọ Obìnrin, pẹ̀lú ìbẹ̀rẹ̀ onirẹlẹ àti igbe ayé tí o ní ọlá.

Àwọn ọ̀rọ̀ àsọtẹ́lẹ̀ atokewa nípa Mèsáyà náà ni a o ṣàlàyé, ìyẹn ni pé, ní Bẹ́tílẹ́hẹ́mù àti ní ibùjẹ ẹran. Èyí yóò ṣẹlẹ̀ ni ìgbáradì fún ìjìyà àti àwọn ìrúbọ tí O gbọ́dọ̀ ṣe. Olùgbàlà yóò gbé ìgbé ayé ìránṣẹ́, tí a nilára tí a sì na nípasẹ̀ àwọn tí O wa lati gbala. Ṣùgbọ́n fún erongba ìmúṣẹ, yóò yọnda ara Rẹ fún àwọn ẹlẹ́sẹ̀, àwọn ẹni tí yóò tá ẹ̀jẹ̀ Rẹ silẹ. Èyí wá pẹ̀lú ìyọnda àti àbójútó Ọlọ́run, ẹni tí yóò tún gbé E dìde (Isẹ. 13:25-30).

Adura wá ní pé kí Ọlọ́run fún wa ní oore-ọ̀fẹ́ láti rọ mọ òtítọ́ ọrọ Rẹ nípa dídúró de àti mumura fún wíwà Rẹ lẹẹkeji.

IFAARA SI ÌPÍN KỌ̀Ọ̀KAN:
A pín ẹ̀kọ́ yii si ìpín méjì, I àti II. A tún ṣe atunpin ọ̀kọ̀ọ̀kan sì A àti B.

ÌPÍN KÍNNÍ: MÈSÁYÀ NÁÀ YÓÒ WA
Ìpín àkọ́kọ́ yìí ń ṣàlàyé Gẹnẹsisi 3:15; Isaiah 7:14-16; àti Mika 5:1-5. A pín in sì A (Gẹ́gẹ́ bí Irú ọmọ Obìnrin Náà) àti B (Ní Ọ̀nà Irẹlẹ). Ipa àkọ́kọ́ ń ṣàlàyé ẹri àsọtẹ́lẹ̀ nípa Jesu tí o jẹ Irú ọmọ obìnrin naa nínú Gẹn. 3:15. Ẹni tí yóò fọ orí satani, tí satani náà yóò sì pá A ní gigisẹ. Ipa kejì ni o side ọrọ lórí Irẹlẹ Kristi lórí bí Ó ti yàn àti ọna ti a gbà bí I. Bi o tilẹ jẹ́ pé Òun yóò di ńlá tí yóò sì tàn ka òpin ilẹ̀ ayé ---- ìmúṣẹ ni èyí!

ÌPÍN KEJÌ: ÌGBÉ AYÉ ÀTI ÌKU MÈSÁYÀ NÁÀ
Ìpín kejì yii bákan náà pín sí méjì. Ipa A (Yóò Gbé Ìgbé Ayé Ìránṣẹ́ Tí O Jìyà) a mú un jáde láti inú Isaiah 53:1-7). Mèsáyà náà tí a sọtẹ́lẹ̀ yóò yọnda araRẹ̀ fún ìjìyà tí o tọ láti ọwọ àwọn ẹlẹ́sẹ̀, yóò gbé ẹṣẹ gbogbo ẹda ènìyàn sórí araRẹ̀. Ipa B (Yóò Kú Ṣùgbọ́n Yóò Jí Dìde) jẹ́ koko ọrọ ni àwọn ẹsẹ 8-11 tí Ìwé kan náà. Mèsáyà náà, nítorí ẹ̀dá ènìyàn ni a o mú ẹbi Rẹ kúrò (a o pa A). Bi ó tilẹ̀ jẹ́ pé kò ní ẹṣẹ rara. Pẹ̀lú gbogbo ìwọ̀nyí, yóò tẹ Ẹ lọ́run tí o ba ri ere iṣẹ Rẹ ki àwọn ọkàn di ẹni ìgbàlà kí a sì kà wọn mọ ìjọba Rẹ nisinsin yii àti ní ìjọba ayérayé Rẹ.

KÓKÓ Ẹ̀KỌ́
I.    MÈSÁYÀ NÁÀ YÓÒ WA.
      A.   GẸ́GẸ́ BÍ IRÚ ỌMỌ OBÌNRIN NÁÀ.
      B.   NÍ Ọ̀NÀ IRẸLẸ
II.   ÌGBÉ AYÉ ÀTI ÌKU MÈSÁYÀ NÁÀ
      A.   YÓÒ GBÉ ÌGBÉ AYÉ ÌRÁNṢẸ́ TÍ YO JÌYÀ
      B.   YÓÒ KÚ ṢÙGBỌ́N YÓÒ JÍ DÌDE

ITUPALẸ Ẹ̀KỌ́
I.    MÈSÁYÀ NÁÀ YÓÒ WA (Gẹnẹsisi 3:15; Isaiah 7:14-16; Mika 5:1-5).
Mèsáyà jẹ́ ẹnikan tí a ń retí láti gba àwọn ènìyàn là kúrò nínú ewu ayé, Jesu ni ọba náà, Ẹni tí a sọtẹ́lẹ̀ nínú Májẹ̀mú Láéláé wí pé a ó rán An láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run wa lati gba àwọn Júù àti gbogbo ayé lapapọ. Bí o tilẹ jẹ́ pé Ọlọ́run ti gbé àwọn wolii àti àwọn Ọba dìde láti gba àwọn ènìyàn Rẹ la, yálà kí wọn kùnà tàbí kí a pá wọn, fún ìdí èyí, Israẹli ń tẹsiwaju lati má a jìyà nínú ẹṣẹ àti ìnilára títí ọmọ Ọlọ́run fúnraRẹ yóò fi wa si ayé. Irú ìrètí ńlá wo ni èyí!

A.   GẸ́GẸ́ BI IRÚ ỌMỌ OBÌNRIN NÁÀ (Gen. 3:15; Isa. 7:14-16)
      Nitori naa, OLÚWA tìkálara Rẹ yóò fún yín ní àmì kan, kíyèsí I, wúńdíá kan yóò lóyún, yóò sì bí ọmọkùnrin kan, yóò pé orúkọ Rẹ ni Imanuẹli (Isa. 7:14).
i.   Níhìn-ín nínú Isa. 7:14, Ọlọ́run tun iṣẹ àti ìlérí Rẹ ṣe láti dá àwọn ènìyàn Rẹ nídè títí ayérayé kúrò nínú ẹṣẹ àti ìnilára àwọn ọ̀tá tí wọn jẹ àwọn ará Ásíríà nígbà náà. Imanuẹli yóò wà gẹ́gẹ́ bí àmì oore-ọ̀fẹ́, níwọ̀n ìgbà tí òfin kò ti lè gbà wọn (Hab. 2:4; Gal. 3:11).
ii.  "... wọn o maa pé orúkọ Rẹ ni Imanuẹli" n fi ẹsẹ àsọtẹ́lẹ̀ náà múlẹ̀ gboningbonin niti Irú ọmọ obìnrin naa ti yoo fọ, orí Sátánì, pátápátá (Gen. 3:15)! Imanuẹli (Ọlọ́run wa pẹ̀lú wa; Mat. 1:23), láìwo tí idayafoni àti ìpalára láti inú ìjọba òkùnkùn, dájúdájú, o jé Àlàáfíà tí ayé tí ń dúró de.
iii. Gen. 3:15b: Ejo ni (tí o dúró fún Sátánì olórí ọ̀tá wa) ni a o fi ààyè gba látòkè wa lati pa irú ọmọ obìnrin naa (Kristi) ni gigisẹ, bí o tilẹ jẹ́ pé sì ìparun ayérayé Sátánì ni, ati ni ibamu pẹ̀lú eto ìràpadà ayérayé tí Ọlọ́run (wo Mat. 4:1 síwájú; I Kor. 15:45).
iv. 'Oun yoo fọ ọ ní ori'. Mèsáyà náà (Jésù) yóò gbà agbára lọ́wọ́ Sátánì àti àwọn iṣẹ́ ọrọ rẹ (wo I Pet. 5:8). Ṣùgbọ́n ejò láéláé ni yi o pá Jésù ni gigisẹ, kí Ìwé Mímọ́ Ki o le ṣẹ. A dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọ́run wí pé Sátánì ki i ṣe arinurode olumọran ọkàn. Nígbà tó bá yá, yóò kábámọ fún ṣíṣe okunfa ìjìyà Jésù.
v.  Ọrọ Ọlọ́run jẹ́ Bẹẹni àti Àmín. Àwọn àsọtẹ́lẹ̀ Ìwé Mímọ́ gbọ́dọ̀ ṣẹ (Mat. 5:18) Jésù wá láti jìyà lọpọlọpọ lọ́wọ́ èṣù (wo. Mat. 4:1 síwájú; 27:1,2,34,35; Lk. 22:66,67).
vi. Wí pé Kristi kò wá gẹ́gẹ́ bí irú ọmọ ènìyàn jẹ́ títóbi ọgbọ́n Ọlọ́run ti O ṣẹgun ipa sátánì. Sátánì kò bá ti bá A jẹ́ pẹ̀lú irọrun kò bá sì ti mú ẹ̀gbin bá eto ìràpadà Ọlọ́run, ṣùgbọ́n o kùnà rẹ. Ọlọ́run Olumọ Ohun gbogbo yàn láti wá láìsí idapọ pẹ̀lú ènìyàn fún eredi àti yàgò fún ìwà Adamọ-ẹsẹ ti ẹda ènìyàn, èyí ni o sọkunfa ẹ̀jẹ̀ aidibajẹ oniyebiye náà tí o sọ wa dominira ni gbogbo ọna!

B.   NÍ Ọ̀NÀ IRẸLẸ (Míkà. 5:1-5)
      Àti ìwọ Bẹ́tílẹ́hẹ́mù 'Efrata; bí ìwọ ti jẹ́ kékeré láàrin àwọn ẹgbẹẹgbẹ̀rún Júdà nínú rẹ ni ẹni tí yóò jẹ́ olórí ni Israẹli yóò ti jáde tọ mi wa; ìjáde lọ rẹ sì jẹ́ láti ìgbàanì. Láti ayérayé (Mik. 5:2).
i.   Ẹsẹ 1: A o jé Israẹli aláìgbọràn níyà látòkè wa pẹ̀lú Ásíríà, ṣùgbọ́n a o da wọn nídè fún ìgbà díẹ̀ a o si da wọn nídè pátápátá (Rom. 11:26), nípasẹ̀ Ẹni kan láti Bẹ́tílẹ́hẹ́mù kékeré ni.
ii.  Ẹsẹ 2: "Nínú rẹ ni ẹni tí yóò jẹ olórí ni Israẹli yóò ti jáde tọ mi wá" Ìwé Mímọ́ kún fún fọfọ pẹlu awọn ìtọ́kasi nípa wíwà tí Mèsáyà náà. Ọlọ́run ti yàn Án pé, kò ní wa nínú aṣọ òye tí Ọba ayé, eredi tí o fi yan ìlú kereje tí oore-ọ̀fẹ́ tí n ṣíṣẹ.
iii. Ẹsẹ 4: "Nítorí nisinsin yii ni Òun ó tóbi títí dé òpin ayé. Bi o tilẹ jẹ́ pé Olùgbàlà náà yóò wà pẹ̀lú irẹlẹ, ìyìn (orúkọ rere) Rẹ ki yóò ní òpin, Títóbi Rẹ ki yóò ní ibadọgba (Fílíp. 2:9,10), yóò sì wa fún ayérayé (Heb. 13:8). Ṣé ìwọ mọ èyíkéyìí orúkọ tí a ń pe ju bẹẹ lónìí?
iv. Ẹsẹ 5: Ọkùnrin yìí yóò jẹ́ àlàáfíà fún àwọn tí yóò rọ mọ Ọn àti ọ̀rọ̀ Rẹ. Ìpọ́njú yóò wà lótitọ (wo Jhn. 16:33), ṣùgbọ́n O jé ètùtù fún wa, tí gbogbo eékún ń wolẹ fún. A mú àsọtẹ́lẹ̀ ìwé mimọ yìí ṣẹ lórí igi Àgbélébùú, tí o n fún àwọn onigbagbọ ni àṣẹ lórí òkùnkùn (Mk. 16:18).
v. Jésù Kristi ń bọ̀wa kankan láti ṣe ìdájọ́ ayé àti láti san èrè fún àwọn ènìyàn mimọ. Dájúdájú Òun ni Àpáta ìgbàlà sì àwọn kan àti Apata idigbolu sì àwọn aláìgbọràn àti lakotan àwọn alaironupiwada. Máse jẹ́ kí O kọlu ọ bí O ti kọlu àwọn ará Egipti (Eks. 14:30), àti àwọn ará Ásíríà (Nah. 2:8-13). Máa bọ wa sọ́dọ̀ Rẹ lónìí!
vi. Bí o tilẹ jẹ́ pé Kristi kọkọ wá fún àwọn Juu, ọ̀pọ̀ lo kọ Ọ nítorí ko gbé ìwọ̀n irú Mèsáyà tí wọn. Fún ìdí èyí, O di ikọsẹ fún wọn. Wọn tilẹ̀ gbé ara wọn gégùn-ún bí wọn tí ń kan An mọ àgbélébùú (Mat. 27:25), nípa èyí tí wọn mú ègún wá sórí àwọn ọmọ wọn tí wọn kò tilẹ ti i bi.

ÀWỌN Ẹ̀KỌ́ TÍ A RÍ KỌ
1.  Bi ó tilẹ̀ jẹ́ pé irú ọmọ obìnrin naa dàgbà laarin awọn ẹ̀gún àti esùsú, àwọn èso Rẹ ti kún gbogbo ayé, O si tún ń so èso síbẹ̀. Èyí jẹ́ ìmúṣẹ àsọtẹ́lẹ̀ Ìwé Mímọ́!
2.  Àwọn tí wọn yóò di ńlá láyé gbọ́dọ̀ yàn ipa ọ̀nà onirẹlẹ, onìrúbọ àti òdodo tí Kristi nínú Ọ̀rọ̀ Rẹ ti kí kùnà.

IṢẸ́ ṢÍṢE
Kín ni ìdí tí Ọlọ́run fi yọnda irú ọmọ obìnrin naa fún àwọn ìjìyà tó kọjá sísọ láti ọwọ èṣù tí kò sì fún Un ní ìṣẹ́gun ẹsẹkẹsẹ láìní ìpalára?
ÌJỌ ÀPỌ́SÍTÉLÌ KRISTI. Ẹ̀KỌ́ ILÉ Ẹ̀KỌ́ ỌJỌ́ ÌSINMI Ki Ìwé Mímọ́ Ki O Le Ṣẹ.. FUN August 18, 2019. AKORI - NÍ IMURASILẸ FÚN BIBỌ MÈSÁYÀ NÁÀ ÌJỌ ÀPỌ́SÍTÉLÌ KRISTI.  Ẹ̀KỌ́ ILÉ Ẹ̀KỌ́ ỌJỌ́ ÌSINMI Ki Ìwé Mímọ́ Ki O Le Ṣẹ.. FUN August 18, 2019. AKORI - NÍ IMURASILẸ FÚN BIBỌ MÈSÁYÀ NÁÀ Reviewed by Muyiwa Abodunrin (Muyilight) on August 18, 2019 Rating: 5

No comments:

Powered by Blogger.