ÌJỌ ÀPỌ́SÍTÉLÌ KRISTI. Ẹ̀KỌ́ ILÉ Ẹ̀KỌ́ ỌJỌ́ ÌSINMI. FUN August 4, 2019. Ki Ìwé Mímọ́ Ki O Le Ṣẹ : Ẹ̀KỌ́ KEJI NI ÌBAMU PẸ̀LÚ ISRAẸLI

--> Note :- Are you born again? You are never going to win the battle against the devil if you are not born again. I plead with you to give your life to Jesus today because the longer you stay in sin and remain unsaved, the more hardened your nature becomes against the purpose and the way God wants you to be for His purpose. To give your life to Jesus now, say this prayer: “Father, I come to You in the name of Jesus. I know that I am a sinner and I cannot save myself but Jesus died for me and shed His blood that I might be saved. Today, I accept Jesus as my Lord and Saviour. Jesus, I ask You to come into my heart, be my Lord, wash me with Your blood and make me whole. I believe with my heart and confess with my mouth that Jesus is my Lord. Thank You for saving me. In Jesus' name I pray. Amen.” I congratulate you and welcome you to the family of God if you have sincerely said that prayer. Now you are fit to discover, know and walk in your destiny. Call our helpline on +2348037252124, Join Our Daily Whatsapp Devotionals Group : +2347033046607 for Daily Devotionals, crucial discipleship and counselling.s"
ÌJỌ ÀPỌ́SÍTÉLÌ KRISTI.  Ẹ̀KỌ́ ILÉ Ẹ̀KỌ́ ỌJỌ́ ÌSINMI. FUN  August 4, 2019.  Ki Ìwé Mímọ́ Ki O Le Ṣẹ : Ẹ̀KỌ́ KEJI  NI ÌBAMU PẸ̀LÚ ISRAẸLI



EKA AWON EKO ATEYINWA NI BI YI

ÌJỌ ÀPỌ́SÍTÉLÌ KRISTI.
Ẹ̀KỌ́ ILÉ Ẹ̀KỌ́ ỌJỌ́ ÌSINMI.
Ki Ìwé Mímọ́ Ki O Le Ṣẹ.
August 4, 2019.

Ẹ̀KỌ́ KEJI
NI ÌBAMU PẸ̀LÚ ISRAẸLI

Ọlọ́run ni Mèsáyà ni ọkàn nígbà tí O n ba Abramu da májẹ̀mú pẹ̀lú ìlérí láti sọ ọ di orílẹ̀-èdè nla.

AKỌSÓRÍ
Emi o bukun fún àwọn tí n sure fún ọ, ẹni ti o n fi ọ re ni èmi o sì fi re; nínú rẹ ni a o ti bukun fún gbogbo ìdílé ayé.   (Gen. 12:3)


ÀLÀYÉ KÚKÚRÚ
Ọlọ́run jẹ Ọlọ́run májẹ̀mú àti Olùpa Májẹ̀mú mọ. Genesisi 12:3. Jẹ ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ alaye Májẹ̀mú pẹ̀lú Ábúráhámù. Ọlọ́run ti yàn láti yi ayé Abramu padà sí rere kí o sì sọ ọ di ènìyàn ọ̀tọ̀ pẹ̀lú àwọn ìbùkún ńlá àti àgbàyanu, lórí gbedeke wípé o gbọ́ràn sì àwọn ìtọ́sọ́nà Ọlọ́run; Ó gbọ́dọ̀ fẹ́ o sì gbọ́dọ̀ ṣetán láti maa rin nínú ìtọ́ni Ọlọ́run. Fifi ìlú abinibi àti ohun gbogbo tí o ti ko jọ silẹ jẹ Ohun ti o lágbára púpọ̀. Ka ni ìwọ bá ní Abramu ni, ṣe ìwọ yóò gbọ́ràn bí? Wo ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ àlàyé májẹ̀mú náà ni ẹsẹ 2. Irú ìlérí tí o yanilẹnu wo ni èyí! Síbẹ̀ ìgbọràn àti ìfẹ́ atinuwa so mọ ọn.

Nigba ti a ba yàn láti gbọ́ràn sì Ọlọ́run nínú ohun gbogbo, ere ńlá ni ti wa, nisinsin yii àti ní ayérayé. Ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ májẹ̀mú ni ọpọ àwọn nnkan to sọ mọ ọn irú ọmọ, ìbùkún, ààbò, ìpamọ́, ìsọdi-nla, jijẹ baba fún àwọn orílẹ̀-ede abbl. Gbogbo ìwọ̀nyí ni a fi n pe Abramu láti jẹ bàbà-ńlá Mèsáyà náà tí yóò wa. Mase fàṣẹyín nínú gbigbọran rẹ si Ọlọ́run, ìwọ yóò sì jẹ́ ere ilẹ̀ náà.

Ninu ìlérí Ọlọ́run yii fún Abramu, O ni Israẹli tí a ko ti ibi lọ́kàn. O ni I lọ́kàn láti mú orílẹ̀-ede ńlá kan jáde láti inú irú ọmọ Abramu, ẹni tí ko ti I ni ọmọ. Bákan náà, O ni I lọ́kàn láti mú Mèsáyà náà wa si ayé yí fún ìràpadà ẹ̀dá ènìyàn, nípasẹ̀ orílẹ̀-èdè-ńlá tí a n retí náà. Eto Ọlọ́run fún gbogbo wa, àti lọdọdanni àti lapapọ, kọjá ìrètí wa (wo Jer. 29:11). O kan máa ń gbé wọn jáde ní ṣíṣẹ-ń-tẹle ni. Bi a ba ti fara mọ Ọn tó ní a o ṣe mú ayanmọ wa ṣẹ to. Lẹ́hìn o rẹhìn Rẹ nípa Israẹli di mímúṣe.

ÀṢÀRÒ LÁTI INÚ BÍBÉLÌ FÚN Ọ̀SẸ̀ KÍNNÍ
Mon.    Jul. 29:     Israẹli Dàgbà Gẹ́gẹ́ bí Orílẹ̀-Èdè tí O Ga Julọ (Eks. 1:1-7).
Tue.     Jul. 30:     Israẹli, Ọmọ Májẹ̀mú Ọlọ́run (Eks. 2:23-25)
Wed.    Jul. 31:     Israẹli Gbádùn Idande Ọlọ́run (Eks. 12:29-42)
Thur.   Aug. 1:      Israeli Jáde Kúrò Nínú Ìgbèkùn (Eks. 12:41-51)
Fri.      Aug. 2:     Israẹli Gba Ogún-ìní (O.D. 136:21-22)
Sat.     Aug. 3:     A Fi Idi Israẹli Múlẹ̀ Gẹ́gẹ́ bí Orílẹ̀-èdè Mimọ (Deut. 7:6).

ÀṢÀRÒ FÚN ÌFỌKÀNSÌN
1.    Ọlọ́run ti ni Israẹli nínú ọkàn Rẹ, ṣáájú ayérayé, gẹ́gẹ́ bí ohun-èlò ọ̀tọ̀ láti bẹ ènìyàn wo àti láti bukun fún gbogbo ayé.
2.    Ọlọ́run mọ òpin láti ìbẹ̀rẹ̀ --- Olumọhun gbogbo. O yọnda Ọrọ Rẹ nitori tí Israẹli; nítorí naa, orílẹ̀-èdè alágbára julọ ni, Israẹli; nítorí naa, orílẹ̀-èdè alágbára julọ ni, Israẹli jẹ́ èso (ayọrísi) Ìwé Mímọ́, to n tọ́ka pátápátá sí Israẹli nípa ti ẹ̀mí (àwọn Juu àti àwọn Kèfèrí tí wọn wa sọ́dọ̀ Kristi).

ẸSẸ BÍBÉLÌ FÚN IPILẸ Ẹ̀KỌ́: Isaiah 43:1 síwájú

ILEPA ÀTI ÀWỌN ERONGBA
ILEPA: Láti fi eto ati alakalẹ Ọlọ́run fún Israẹli àti gbogbo ayé tí O ti pese silẹ nínú ọrọ Rẹ hàn àwọn akẹ́kọ̀ọ́.

ÀWỌN ERONGNA: Ni opin ẹ̀kọ́ ọlọsẹ mejii yii, àwọn akẹ́kọ̀ọ́ gbọ́dọ̀ le:
i.    ṣàlàyé bí Ọlọ́run ti bá Abramu dá Májẹ̀mú láti sọ ọ di baba àwọn orílẹ̀-èdè.
ii.   ṣàlàyé bí Ọlọ́run ti pinnu/fẹ láti pa àwọn ọmọ Ábúráhámù tí a ti ṣeleri mọ.
iii.   safihan Israẹli gẹ́gẹ́ bí àwòrán eto Ọlọ́run fún gbogbo ayé àti
iv.   jíròrò lórí ìdí àti bí Ọlọ́run ti fi oore-ọ̀fẹ́ rán àwọn ọmọ Ábúráhámù (Israẹli) láti pèsè Mèsáyà náà.

IFAARA
ORÍSUN Ẹ̀KỌ́: GENESISÌ 12:1-7; 15:16-21; 17:7; 18:18,19; DEUTERONOMI 18:14 swj; ORIN DÁFÍDÌ 67; 89:18-36; SEKARÁYÀ 12:10; 13:1,2,9.
Ogo ni fún Ọlọ́run àwọn bàbà wa, Ẹni tí O fún wa ní Ìwé Mímọ́ láti fi mú ayé wa duroore ni isinsin yii, ní ìbámu pẹ̀lú àwọn ohun tí O ti sọ nípa wa, ṣáájú ayérayé, àti ìrètí fún ayé isinsin yii àti ti ọjọ́ iwájú to jìnnà rere.

Ẹ̀kọ́ tí o kọjá ní ó side ọwọ yii pẹ̀lú ilepa fifi ẹsẹ òtítọ́ náà múlẹ̀ KI ÌWÉ MIMỌ KÍ O LE ṢẸ. Ẹ̀kọ́ náà, pẹ̀lú bí o ti jẹ́ àkọ́kọ́ nínú ọwọ yii, a pe àkòrí rẹ ni, NÍNI ÌFOJÚSỌ́NÀ FÚN ÌRÀPADÀ. A fun wa ni oore-ọ̀fẹ́ láti rí bí a ti fún wa ní àwọn IWE MIMỌ ni ìfojúsọ́nà fún ìràpadà ènìyàn. A tọ́ka sí bí sátánì tí o ti ṣubú láìní àtúnṣe (ìràpadà) ṣe mú ìṣubú ènìyàn. A tọ́ka si bí sátánì tí o ti ṣubú láìní àtúnṣe (ìràpadà) ṣe mú ìṣubú ènìyàn tí Ọlọ́run ti ní ìwòye rẹ wáyé, ṣáájú ìṣẹ̀dá ènìyàn, pẹ̀lú bí a ti mú wa mọ òtítọ́ náà pé, a ṣe àpèjúwe Jesu gẹ́gẹ́ bí Ọdọ-agùntàn tí a pa ṣáájú ìgbà tí a fipilẹ ayé sọlẹ. Bákan náà, ẹ̀kọ́ náà tún mú wá wọnú bí Ọlọ́run ṣe bẹ̀rẹ̀ láti fún ènìyàn ni ìrètí ìràpadà, paapaa lásìkò tí a kéde ìjìyà lórí ènìyàn lẹ́yìn ìṣubú náà. Irú Ọlọ́run olóore-ọ̀fẹ́ wo niyii!

Ẹkọ kejì yii jẹ ìjíròrò lórí bí a ti fún wa ní àwọn Ìwé Mímọ́ NÍ ÌBAMU PẸ̀LÚ ISRAẸLI. Ọlọ́run kò lè ṣe ojúsàájú láéláé. O ni gbogbo ayé ni ọkàn láti ìbẹ̀rẹ̀ pẹpẹ. Ju gbogbo rẹ lọ, O ri òpin láti ìbẹ̀rẹ̀ wa. O mọ bí ilé ayé yii yoo ti pẹ to, àti pẹ̀lú iye àwọn ènìyàn láti inú onírúurú ẹ̀yà àti àwọn orílẹ̀-èdè tí yóò gbé lórí ilẹ̀ ayé pẹ̀lú àlàyé kíkún nípa ẹni kọ̀ọ̀kan wọn. Ṣùgbọ́n, O ni lati bẹ̀rẹ̀ láti ìbi kan tí yóò sì tànkalẹ de gbogbo ayé, láti ìran de ìran.

Láti mú kí èyí ṣe e ṣe, O fi oore-ọ̀fẹ́ ṣàwárí ènìyàn, tí o pe orúkọ rẹ ni Ábúráhámù, nígbà tó ya, O ba a da Májẹ̀mú, O si bẹ̀rẹ̀ si i fi ọgbọ́ọgbọ́n safihan eto ìràpadà ayérayé Rẹ wẹrẹwẹrẹ. Wọn ko mọ nígbà náà, Ọlọ́run fún wa ní Ìwé Mímọ́ tí yóò máa ṣàkóso ayànmọ lọ́nà títọ. A ti wá mọ nisinsin yii paapaa, ní ìran tí wa yii.

Israẹli wa lati ọdọ baba Isaaki láti jẹ olùgbé májẹ̀mú ayérayé tí Ọlọ́run. Orílẹ̀-èdè to suyọ yii ni wọn ti jẹ́ àárín gbùngbùn (gbòógì) sì igbesẹ Ọlọ́run ni rírà ènìyàn padà láti ìgbà náà. Ẹ̀kọ́ yii yoo tán ímọ́lẹ̀ sì bí Ọlọ́run ti safihan àwọn wọ̀nyí kí wọn tó bẹ̀rẹ̀ si i sẹlẹ, nínú Iwe Mimọ.

KÍ Ọlọ́run Olumọ ohun gbogbo mase jẹ ki ohunkóhun pamọ fún wa ninu awọn ohun ti O ti pese silẹ fún wa. Ki Ọlọ́run jẹ́ kí ojú òye wa mọ́lẹ̀ tó bẹ́ẹ̀ gẹ̀ẹ́ láti di àwọn òtítọ́ tí O n rán sí àwọn ọ̀nà wa ninu ẹ̀kọ́ yii mu ṣinṣin ni orúkọ Jesu.

IFAARA ṢÍ ÌPÍN KỌ̀Ọ̀KAN :
Ẹkọ ọlọsẹ meji yii ni a pin sì ìpín meji, I àti II ti a si ṣe atunpin ìpín kọ̀ọ̀kan sì A àti B.

IPIN KINNI: WỌN YÓÒ DI ORÍLẸ̀-ÈDÈ ŃLÁ
Apin ọwọ yii si meji: Wọn Yóò Di Orílẹ̀ Orílẹ̀-èdè Kan, A O Pa Wọn Mọ Tiyanutiyanu. Ni ibamu pẹ̀lú Májẹ̀mú Ọlọ́run pẹ̀lú Ábúráhámù. Israẹli yóò di orílẹ̀-èdè kan: Ìmúṣẹ Ìwé Mimọ èyí ni a le ri ninu Eksodu, gẹ́gẹ́ bí Israẹli ṣe jáde kúrò nínú ahamọ Farao pẹ̀lú ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ènìyàn, Bákan náà ni ọrọ Ọlọ́run pa Israẹli mọ kúrò lọ́wọ́ gbogbo ìdojúkọ àwọn ọ̀tá àyíká to n fẹ́ láti pá wọn rún tàbí mú ẹ̀mí wọn kúrò pátápátá. Nínú gbogbo ìrìn-àjò Israẹli, ìgbà gbogbo ni Ọlọ́run ń ṣe ìpamọ́ àwọn tó ṣekú.

IPIN KEJI: WỌN YÓÒ PESE MÈSÁYÀ NÁÀ
Israẹli kò farahàn gẹ́gẹ́ bí orílẹ̀-èdè ńlá fún yẹyẹ (awada). Ọlọ́run ní ìṣẹ́ fún wọn láti ṣe/múṣẹ. Ọlọ́run ti rán wọn láti pèsè Mèsáyà náà. Alaye ìṣẹ́ Israẹli sì ayé pín sí meji: Ikinni láti safihan Yahweh fún àwọn orílẹ̀-èdè, àti ìkejì, láti jẹ bàbà-ńlá Mèsáyà náà. Èyí ni ìpín kejì ẹ̀kọ́ yii dálè lórí.

KÓKÓ Ẹ̀KỌ́
I.    WỌN YÓÒ DI ORÍLẸ̀-ÈDÈ ŃLÁ
      A.    WỌN YÓÒ DI ORÍLẸ̀-ÈDÈ KAN.
      B.    A O PA WỌN MỌ TIYANUTIYANU

II.   WỌN YÓÒ PESE MÈSÁYÀ NÁÀ
      A.    WỌN YÓÒ FI YAHWEH HÀN ÀWỌN ORÍLẸ̀-EDE
      B.    WỌN YÓÒ DI BABA-ŃLÁ MÈSÁYÀ NÁÀ

ITUPALẸ Ẹ̀KỌ́
Aug. 4, 2019
I.    WỌN YÓÒ DI ORÍLẸ̀-ÈDÈ ŃLÁ (Genesis 12:1,7; 15:16-21; 17:7; 18:18; Orin Daf. 89:18-36).
      "Láti di" ni lati dàgbà tàbí gbèrú sínú nnkan kan. O jé ohun tó máa n ṣẹlẹ̀ díẹ̀díẹ̀. Láti ọjọ́ tí Ọlọ́run ti dá májẹ̀mú pẹ̀lú Ábúráhámù sì ìgbà tí Israẹli jáde kúrò ní Egipti gẹ́gẹ́ bí ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn lẹ́yìn tí wọn tí lo ọgbọ́n le nirinwo ọdún (430) nínú ìsìnrú. Israẹli dàgbà sínú didi orílẹ̀-èdè ńlá. A mú ọrọ Ọlọ́run ṣẹ a sì n mú un ṣẹ síbẹ̀sibẹ.

A.   WỌN YÓÒ DI ORÍLẸ̀-ÈDÈ KAN (Gen. 12:1,7; 15:16-21; 17:7; 18:18).
      Nítorí pe, Ábúráhámù yóò sá di orílẹ̀-èdè ńlá àti alágbára, àti gbogbo orílẹ̀-èdè ayé ni a o bukun fún nípasẹ̀ rẹ (18:18).
i.    12:1,7: Ọlọ́run ti ṣèlérí ilẹ kan fún Abramu, tí yo O fi hàn án nígbà tó ba ya, láti ìbẹ̀rẹ̀ pẹpẹ ibasepọ ònímajẹmu wọn. O dari Abramu si ilẹ̀ náà, o si gba a nínú ìlànà òfin (ẹsẹ 4-8).
ii.   Ẹsẹ 2,3: O tún ṣèlérí láti sọ ọ di orílẹ̀-èdè ńlá nipasẹ èyí tí a o fi bukun fún gbogbo ìdílé ayé (ẹsẹ 3; wo 18:18). Síbẹ̀ wọn yóò ní láti máa tẹle E nínú ìgbọràn (wo Deut. 26:3-13; 28:1-14).
iii.    Láti sọ èyí di òtítọ́, Ọlọ́run ṣèlérí ọmọ kan fún Abramu ni ọjọ ogbó rẹ (15:1 swj; 18:1 swj), ọmọ ìyànu náà sì papa wa Isaaki; 'ẹrin' (21:1-7). Irú Ọlọ́run to n pa májẹ̀mú mọ, tó tún n mú ìwé mimọ ṣe wo niyii!
iv.   15:16-21: Ọlọ́run ṣèlérí ilẹ̀ kan fún Abramu fún àwọn ọmọ rẹ (ti a pe ni Israẹli nígbà tí o ya), gẹ́gẹ́ bí ara májẹ̀mú tí Ábúráhámù (wo 13:14-15; 17:7). O ṣe bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ ni bi O ṣe mú àwọn ọmọ rẹ jáde kúrò ní Egypti, kúrò ní ọwọ àwọn akọníṣíṣẹ nígbà tó yá, láti gba ilẹ̀ ìlérí náà (wo Deut. 9:4). Ọlọ́run ko le kùnà láéláé.
v.    17:7: Gẹ́gẹ́ bí orílẹ̀-èdè, Israẹli ni a gbọ́dọ̀ rí gẹ́gẹ́ bí èso májẹ̀mú Ọlọ́run pẹ̀lú Ábúráhámù (wo 28:10-15). Wọn jẹ ènìyàn ọ̀tọ̀ (wo Eks. 19:5,6). Ògo ni fún Kristi Ẹni tí o mú wa wá sínú ibasepọ àrà ọ̀tọ̀ bẹẹ pẹ̀lú Ọlọ́run, bí o tilẹ jẹ pé àwa fúnra wa jẹ keferi (I Pet. 2:9,10). N jẹ o ti di atunbi?
vi.   Ìgbọràn jẹ́ irinsẹ tó lágbára nínú mímú ìwé mimọ ṣẹ. Ábúráhámù gbọ́ràn, a sì bùkun fún àwọn ọmọ rẹ; Israẹli di orílẹ̀-èdè alágbára a sì bùkun fún gbogbo ayé latipàsẹ Mèsáyà náà tí o n bọ wa nipasẹ wọn. Ìgbọràn síwájú sii ni a nílò lọ́wọ́ olúkúlùkù wa lati mú ọrọ Ọlọ́run ṣẹ síwájú sii gẹ́gẹ́ bí a ti n retí ipadabọ Kristi lẹẹkeji.

B.    A O PA WỌN MỌ TIYANU TIYANU (Orin Daf. 89:18-36).
       Lẹrinkan ni mo ti fi ìwà-mímọ mi búra pe, Èmi kì yóò purọ fún Dafidi. Irú-ọmọ rẹ yóò dúró titi láéláé, àti ìtẹ́ rẹ bí òórùn níwájú Mi (ẹsẹ 35,36).
i.     Ila 18-29: Májẹ̀mú Ọlọ́run jẹ́ èyí tí kò lè jakulẹ láéláé, láti ọ̀dọ̀ Rẹ wa. Iwa aisotitọ/iyapa ènìyàn ni ó máa n ṣe àkóbá fún ìmúṣẹ náà, gẹ́gẹ́ bí íjẹniya fún ìwà aisotitọ. Ọlọ́run sọ ọ yekeyeke fún àwọn ènìyàn Rẹ.
ii.    Ìṣọ̀wọkọ (ohun) ila 30, 31 papọ pẹ̀lú ọrọ ìyànu ìkẹyìn tí Mose sì àwọn ènìyàn náà nígbà tí o kú dẹdẹ kí wọn wọ Ilẹ̀ Ìlérí náà, ní àwọn sẹnturi ìṣáájú (Deut. 28:58; 31:16-21), ní ìwòye wí pe ó ṣeéṣe kí Israẹli bẹ̀rẹ̀ sì ni hùwà aisotitọ si òfin, ìdájọ́ ìlànà àti àṣẹ Yahweh (ìyapa kúrò ní ilana) wọn sì wa kọ Ọlọ́run silẹ nitòótọ́. Wọn sì sọ imọ Ọlọ́run ìṣáájú di yẹyẹ.
iii.   Ila 32: Iwa Mimọ àti ìdájọ́ Ọlọ́run ko le faaye gba ẹlẹ́sẹ̀ ki o lọ laijiya, eredi ni yii ti O ṣe ṣèlérí láti fìyà jẹ Israẹli tí wọn ba ti dẹ́ṣẹ̀. O ti kilọ fún wọn ṣáájú nípasẹ̀ Mose (Deut. 28:15-68; 29:23; 32:26). O sọ ọ nígbà tí o ku dẹdẹ kí o ṣẹlẹ̀ (I A. Ọba 14:15-16; 2 A Ọba 17:13).
iv.   Ni òtítọ́ sì ọrọ Rẹ, wọn fojú wina (pàṣán) íjẹniya láti ọwọ àwọn ọ̀tá tí Ọlọ́run rán sí wọn (àwọn ará Asiria, Nebukadinésárì, Aleksanda Nla àti àwọn Giriki, Nero àwọn ọba miiran, àti àwọn ara Romu, àwọn Turki, Hitila, àwọn Arabu abbl).
v.    Ila 33: Ṣùgbọ́n... májẹ̀mú Ọlọ́run (ìlérí tí ko ṣe e dà) àti Ọ̀rọ̀ náà (Iwe Mimọ) tí o ti ẹnu Rẹ jáde, yóò sì ṣe ìpamọ́ wọn pẹ̀lú ìyànu (wo ila 29; Jer. 31:35-37; Amosi 9:14,15). Báwo?
vi.   Bí a tilẹ fìyà jẹ wọn, a kò ní pa wọn run bí wọn ba ronupiwada (Deut. 28:44-45), wọn yóò sì yípadà nínú ìpọ́njú wọn nitòótọ́ (Deut. 28:40), èyí tí yóò jẹ àbájáde kiko wọn jọ láti inú àwọn orílẹ̀-èdè tí a o si mú wọn padà sí ilẹ wọn tí a ti fún wọn láti ọrùn wá (30:3-10).
vii.   Pẹ̀lú gbogbo ohun tí ìran Juu tí la kọjá láti ọwọ àwọn ọ̀tá tó yí wọn ka, a ko le pa wọn run mọ gẹ́gẹ́ bí ìwọ kò ti le rún oòrùn, òṣùpá àti àwọn irawọ. Finuro ẹnu ìwọ̀nba ọ̀kẹ́ mẹ́tàlélọ́gbọ̀n o din ẹgbàárún-un (650,000) àwọn ọmọ Juu, tí orílẹ̀-èdè Arabu mẹ́fà yíká, àwọn tí wọn tí jẹjẹẹ (pinnu) láti run wọn (àwọn Juu) kuro lori ilẹ ni gbogbo ọna, síbẹ̀ wọn tí la gbogbo sẹnturi wọ̀nyí kọjá láàyè. Ọrọ Ọlọ́run ko le kùnà láéláé. Haleluya!
viii.  A mọ Ọlọ́run gẹ́gẹ́ bí ẹni tó ń pa májẹ̀mú pẹ̀lú Ọlọ́run àti ẹ̀dá ènìyàn ẹlẹ́gbẹ wọn. Igbakugba tí èyí ba sẹlẹ, ìjìyà fún ṣíṣe ohun bẹẹ ko ṣe e yẹ. Bí ọrọ Israẹli tí ri ni yii, bẹẹ ni o si wa fún gbogbo ẹ̀dá ènìyàn pátápátá lonii. Ṣùgbọ́n àánú Ọlọ́run máa pápá wa si ojú ìṣe (tí o jẹ ìpamọ́), ki ọrọ Rẹ ma ba di alaiwa sì ìmúṣẹ nígbàkúùgbà bí ó ti wù kí ó rí.

ÀWỌN Ẹ̀KỌ́ TÍ A RÍ KỌ
1.    Àwọn Ọrọ Ọlọ́run nípa Israẹli gẹ́gẹ́ bí orílẹ̀-èdè si n ṣe, gẹ́gẹ́ bí O ti wi. Èyí n fún wa ní ìdánilójú ìmúṣẹ àwọn àsọtẹ́lẹ̀ Ìwé Mimọ tí wọn ko ti i ṣẹ.
2.    Ohun gbogbo tí Ọlọ́run ti yàn yóò wà sì ìmúṣẹ dájúdájú. Bí o ba ṣe e láti ẹyin wa ti O ṣi n ṣe e lọ́wọ́lọ́wọ́, dájúdájú yóò ṣe e fún ọ.

ÌṢẸ́ ṢÍṢE
Kín ni idi ti Israẹli fi jẹ àpẹẹrẹ àsọtẹ́lẹ̀ ni ibamu pẹ̀lú èyí tó ti kọjá, èyí to n ṣẹ lọ́wọ́lọ́wọ́ àti ti ọjọ iwájú.

ÌDÁHÙN TÍ A DÁBÀÁ FÚN IṢẸ́ ṢÍṢE
i.    Ọlọ́run ṣagbekalẹ Israẹli láti jẹ àwòrán àpẹẹrẹ ìṣe (alakalẹ/eto) Rẹ fún gbogbo ayé.
ii.   Ọlọ́run ni gbogbo ayé lọ́kàn gẹ́gẹ́ bí sì eto ati erongba ìràpadà ayérayé Rẹ, ṣùgbọ́n O ni láti bẹ̀rẹ̀ níbi kan. O fi oore-ọ̀fẹ́ yàn Israẹli nípasẹ̀ àwọn tí O ṣètò láti dé gbogbo ayé.
iii.   Nígbà tí gbogbo ayé n ba ọna tìrẹ lọ, àwọn bàbà Israẹli tẹle Ọlọ́run tọkàntọkàn tí Ọlọ́run fúnraRẹ sì rán wọn lọ́wọ́. Ọlọ́run rán àwọn bàbà náà lọ́wọ́ láti fọwọ́sọwọ́pọ̀ pẹlu Rẹ ni pípa májẹ̀mú atokewa mọ.
iv.   Nípasẹ̀ Israẹli, ìgbàlà nínú Jesu Kristi, yóò dé gbogbo ayé.
v.   Israẹli ni iṣẹ́ ti a ran án lati jẹ bàbà Mèsáyà náà, Olùgbàlà aráyé.
vi.   O (Israẹli) ni lati safihan Yahweh fún gbogbo ayé (wo O.D. 67).
vii.  O tẹsiwaju lati gbádùn ìfẹ́ àti àánú Ọlọ́run, kódà nígbà tí wọn ṣáko lọ kúrò lọdọ Yahweh. Kín ni ìdí? Ìfẹ́ Ọlọ́run àti eto ayérayé Rẹ ni lati de ọdọ ènìyàn àti láti mu un padà sí inú ojúlówó erongba Rẹ.
viii. Lọ́wọ́lọ́wọ́ yii, Israẹli jẹ àmì ìmúṣẹ àwọn àsọtẹ́lẹ̀ ìgbà ikẹhin. Fún àpẹẹrẹ, ipada àwọn Juu tí o ti tukaakiri sì ìlú abinibi wọn, dídá Jerúsálẹ́mù mọ gẹ́gẹ́ bí Olú-ìlú Israẹli, gbígba òkè mimọ ni ti a n retí kúrò lọ́wọ́ àwọn ẹlẹ́sìn Musulumi, ìgbàlà egbaajile-ni-ọ̀kẹ́ meje (144,000) àwọn ọmọ Israẹli tí a n retí abbl. Gbogbo wọ̀nyí ń tọ́ka sí wíwà Mèsáyà náà nígbà kejì ni.
ix.  Israẹli bákan náà, ní ìṣẹ́ to lapẹẹrẹ fún ọjọ́ ọ̀la àgbáyé. Ìfẹ́ Ọlọ́run fún orílẹ̀-èdè náà ń tọ́ka wa si ohun ti Ọlọrun ni fún gbogbo wa ni ọjọ ọlá (wo Rom. 8:18).
ÌJỌ ÀPỌ́SÍTÉLÌ KRISTI. Ẹ̀KỌ́ ILÉ Ẹ̀KỌ́ ỌJỌ́ ÌSINMI. FUN August 4, 2019. Ki Ìwé Mímọ́ Ki O Le Ṣẹ : Ẹ̀KỌ́ KEJI NI ÌBAMU PẸ̀LÚ ISRAẸLI ÌJỌ ÀPỌ́SÍTÉLÌ KRISTI.  Ẹ̀KỌ́ ILÉ Ẹ̀KỌ́ ỌJỌ́ ÌSINMI. FUN  August 4, 2019.  Ki Ìwé Mímọ́ Ki O Le Ṣẹ : Ẹ̀KỌ́ KEJI  NI ÌBAMU PẸ̀LÚ ISRAẸLI Reviewed by Muyiwa Abodunrin (Muyilight) on August 04, 2019 Rating: 5

No comments:

Powered by Blogger.