July 28, 2019 ÌJỌ ÀPỌ́SÍTÉLÌ KRISTI, Ẹ̀KỌ́ ILÉ Ẹ̀KỌ́ ỌJỌ́ ÌSINMI : AKOLE - Ki Ìwé Mímọ́ Ki O Le Ṣẹ.

--> Note :- Are you born again? You are never going to win the battle against the devil if you are not born again. I plead with you to give your life to Jesus today because the longer you stay in sin and remain unsaved, the more hardened your nature becomes against the purpose and the way God wants you to be for His purpose. To give your life to Jesus now, say this prayer: “Father, I come to You in the name of Jesus. I know that I am a sinner and I cannot save myself but Jesus died for me and shed His blood that I might be saved. Today, I accept Jesus as my Lord and Saviour. Jesus, I ask You to come into my heart, be my Lord, wash me with Your blood and make me whole. I believe with my heart and confess with my mouth that Jesus is my Lord. Thank You for saving me. In Jesus' name I pray. Amen.” I congratulate you and welcome you to the family of God if you have sincerely said that prayer. Now you are fit to discover, know and walk in your destiny. Call our helpline on +2348037252124, Join Our Daily Whatsapp Devotionals Group : +2347033046607 for Daily Devotionals, crucial discipleship and counselling.s"
July 28, 2019 ÌJỌ ÀPỌ́SÍTÉLÌ KRISTI, Ẹ̀KỌ́ ILÉ Ẹ̀KỌ́ ỌJỌ́ ÌSINMI : AKOLE -  Ki Ìwé Mímọ́ Ki O Le Ṣẹ.




ÌJỌ ÀPỌ́SÍTÉLÌ KRISTI.
Ẹ̀KỌ́ ILÉ Ẹ̀KỌ́ ỌJỌ́ ÌSINMI.
Ki Ìwé Mímọ́ Ki O Le Ṣẹ.
July 28, 2019.

II.    IMUPADA-BỌ-SIPO ÈNÌYÀN TÍ KO NÍ IDUNADURA NÍNÚ (Gen. 3:14,15,20-24; Mat. 25:34; John. 12:31-33; Ifih. 13:8; 17:18).

Lọpọlọpọ ìgbà, àwọn ènìyàn, orílẹ̀-ede, alabasisẹpọ, ẹgbẹ̀ ko le e yanjú àwọn ọrọ kan, àyàfi tí wọn ba jọ sọ àsọyé pọ. Niti imubọsipo ènìyàn, ko si idunadura tí a nilo. Tani Ọlọ́run yoo ba dunadura ìràpadà ènìyàn pẹ̀lú rẹ? Satani bi? Èyí yóò jẹ àbùkù ńlá tí o ga. Nítorí naa imubọsipo rẹ ko ṣe e dunadura.


A.   A O RUN Ọ̀TA ÈNÌYÀN WOMUWOMU
      Ẹ̀mí o sì fi ọta sáàárín ìwọ àti obìnrin náà àti sáàárín irú ọmọ rẹ àti irú ọmọ rẹ, oun o fọ ọ ní orí, ìwọ o sì pá a ní gigisẹ (Gen. 3)15).
i.    Èṣù ti jẹ ọta láti ìṣẹ̀dálẹ ayé. Ó pàdánù anfaani àti ipò tí a n jowu rẹ tí a fi fún un, nítorí naa ni ó ṣe n fẹ́ ki gbogbo ẹda jẹ aladanu.
ii.   Sátánì (Èṣù) gba ti ọ̀dọ ejo láti tán ènìyàn jẹ, àṣírí rẹ tú a sì ṣe ìdájọ́ rẹ. A o fọ ọ ní orí (Gen. 3:15). Láti ìgbà náà wá ní ejò tí n fi aya fà titi lae. Iwe Mimọ ni o fi àṣírí yii hàn bẹẹni o sì safihan ìdájọ́ tí ko ṣe e daduro (Jhn.12:30,31; Kol. 2:15).
iii. Èṣù àti àwọn ikọ Farao ko le ṣe ju kí wọn ṣe asetunse ẹlẹ́ẹkẹta lọ (Eks. 8:18,19). Awọn ikọ Ahabu gba ìṣubú/ijakulẹ tí ko ni àtúnṣe mọ ni ori oke Kámẹ́lì (I.A. Ọba 18:20-40).
iv.  Lẹ́yìn ìgbà tí o ti kùnà lọdọ Jesu, a bá a wí, o si fi Jesu silẹ fún ìgbà díẹ̀ (Mat. 4:10-11), a si ba a wi bí ó ti ṣíṣẹ nínú Peteru (Mt. 16:23; Lk. 8:33).
v.  O jẹ ìyàlẹ́nu lonii pé àwọn ènìyàn n gba èṣù gbọ. Wọn a ma wí pé "O lágbára ṣùgbọ́n kò ní ìgbàlà" Ṣe òótọ́ ni èyí? Ṣùgbọ́n sa, mase f'oju wo èṣù kọjá bí ó ti mọ bẹẹni ki o má si fojú rena rẹ. A ti pinnu ọrọ rẹ nínú Ìwé Mímọ́ --- adágún ina.

B.   A O MU ÈNÌYÀN PADÀ-BỌ-SÍPÒ (Gen. 3:21; Lk. 19:10; Ifihan 13:8).
      Nítorí dídùn inú Baba ní pé kí ẹkùn gbogbo le maa gbe inú rẹ; àti nípasẹ̀ Rẹ, láti ba ohun gbogbo laja, lẹyin tí o ti fi ẹjẹ àgbélébùú Rẹ parí ìjà; mo ni nípasẹ̀ Rẹ, wọn iba ṣe ohun tí n bẹ ní ayé, tàbí ohun tí n bẹ ní ọ̀run (Kol. 1:19-20).
i.    Ìtọ́ni tí a ko tẹle ni o yọrísí àìgbọràn nínú Ọgbà Édẹ́nì èyí tí o mu kí ènìyàn O maa ni àwọn iriri tí ko fararọ, ṣùgbọ́n Lẹ́sẹẹkẹsẹ láàrín ìdájọ́ ni Iwe Mímọ́ sì tẹle e (Gen. 3:15).
ii.   Lẹ́sẹẹkẹsẹ ni Ọlọ́run gbé igbesẹ láti bo ihoho ènìyàn èyí tí o nílò láti "tita ẹjẹ silẹ", àpẹẹrẹ ohun tí a ó ṣe fún ìran ènìyàn lapapọ (Gen. 3:21). Ojúṣe ẹjẹ nihin ni a ko le fojú rena rẹ tàbí parẹ.
iii.  Ènìyàn kò lè sọnù tàbí yapa titi láéláé. Jesu ni a tọ́kasi nínú Ìwé Mímọ́ gẹ́gẹ́ bi Ọdọ Àgùntàn tí a pa ṣáájú ìpilẹ̀ṣẹ̀ Ayé (Ifih. 13:8). Johanu Baptisti jẹri sì èyí bí o ti n safihan Olùgbàlà aráyé (Jhn. 1:29). Àti pe, nipa ẹjẹ Rẹ ni a gbà wa la tí a sì mú wa sunmọ ọdọ Ọlọ́run (Efe. 2:11-13; Kol. 1:19).
iv.   Imupada-bọ-sipo ìkẹyìn ni a ti safihan rẹ nínú ìwé mimọ. Nísinsìn yii a ti jokoo pẹlu Jesu Kristi ni ibi giga ọrùn. Nígbà tí o ba ya, a o wa pẹ̀lú Rẹ titi ayé gẹ́gẹ́ bí Ìwé Mímọ́ tí wí. Njẹ o ti ṣetán?
v.   Imubọsipo rẹ jẹ Ọlọ́run lógún. Ìwọ jẹ ẹyinlójú Rẹ. Olú àlùfáà ni ọ àti ènìyàn ọ̀tọ̀. Ọlọ́run ko le gba kí o sọnù pátápátá sí ọwọ ọta ọkàn rẹ (I Pet. 2:8-10; Ifih. 1:6).

ÀWỌN Ẹ̀KỌ́ TÍ A RÍ KỌ
1.   Ìwé Mímọ́ tí sọ ṣáájú nípa iriri tí satani yóò máa rí ní ṣíṣẹ-ń-tẹle, niti ìtìjú ìṣubú àti òpin rẹ (Gen. 3:15; Ifih. 20:10).
2.   Ìwé Mímọ́ tún safihan ohun tí yóò máa ṣẹlẹ̀ sí ènìyàn ni ṣíṣẹ-ń-tẹle niti imupada-bọ-sipo ìràpadà àti wiwa pẹ̀lú Ọlọ́run titi ayérayé (Jhn. 14:3; 17:24).

ÀWỌN ÌBÉÈRÈ
1.   Sátánì tí jẹ ọ̀tá àìmọ ṣáájú ìpilẹ̀ṣẹ̀ ayé àti nisinsin yii (lẹ́yìn tí Jesu Kristi ti ṣẹgun rẹ) njẹ a le fojú tẹ́ńbẹ́lú rẹ bí?
2.   Ẹjẹ náà, ẹ̀jẹ̀ Jesu Kristi ni a ti fi fún wa, o pe, o kun o si jẹ òpin Kin ni idi ti àwọn ẹniyan fi n ṣe ìrúbọ lonii síbẹ̀? (I Kor. 10:19,20).

ÀWỌN ÌDÁHÙN TÍ A DÁBÀÁ FÚN ÀWỌN ÌBÉÈRÈ
ÌDÁHÙN SÍ ÌBÉÈRÈ KINNI
*    Rara, ko si idi fún fi fojúrena èṣù tàbí kí a gbé e ga ju bí o ti yẹ lọ. Ẹnikẹ́ni tí o ba ṣe èyí ṣe é sí ìparun ara rẹ.
*    A kò ṣe alaini òye kíkún nípa ẹni tí èṣù jẹ sì Ọlọ́run àti sí wa. Ọ̀tá ayérayé ni: ọta nígbà kan, ọta nígbà gbogbo ní.
*    O di ọta Ọlọ́run àti ènìyàn ni ọjọ ti o di ọ̀tẹ̀ mọ Ọlọ́run àti eto ayérayé Rẹ. O tún fi ẹniti o jẹ hàn ní ọjọ́ tí o bẹ eniyan wo nínú ọgbà pẹlu arekereke tí o mú kí Éfà ó gbà èso aigbọdọ jẹ naa lòdì sí òfin Ọlọ́run (Genesis 3:1 síwájú; Ifih. 12:7-9).
*    A gbọdọ mú ìwé mimọ ṣẹ lórí èṣù.
*    Ṣọ́ra fún un, o le parada di áńgẹ́lì ímọ́lẹ̀ (2 Kor. 11:13-15). O jẹ ẹlẹtan àti èké nípa ẹ̀dá rẹ (Jhn. 8:44) o n dẹ àwọn okùn kan fún àwọn onigbagbọ láti mú wọn ṣubú kí wọn o sì pín nínú ẹbi rẹ. Ko ni rí ọ mú lórúkọ Jésù.
*    Ko si ibi kankan nínú ìwé mimọ tí a ti rọ wa lati jẹ ọrẹ rẹ. Dípò bẹẹ. Ìwé Mímọ́ fẹ́ kí a koju, ba a wi, kí a si ba èṣù ja (Jak. 4:7; Efe. 4:27).
*   Ìwé Mímọ́ pe e ni ọta wa I Pete 5:8. Ko le e yípadà láéláé.
*  Ọ̀rọ̀ Ìyanu; Máse fojú rena, tàbí fi ààyè gba a, kọjú ìjà sí I oun yoo sa kuro lọdọ rẹ. Bákan náà mase gbé e gẹ́gẹ́, a ti ṣẹ́gun rẹ pátápátá.
Laisi itajẹ silẹ kò sì imukuro ẹṣẹ.
A ti ni ẹjẹ Jesu o sì ti san gbèsè ẹṣẹ wa lẹẹkansoso.
Nítorí náà, kò sì ìrúbọ fún ẹsẹ ti o pọn dandan mọ.
Ki wa ni ìṣòro àwọn tí wọn si n rúbọ?
*   Àìmọkan.
*   Aini igbagbọ nínú Jesu àti ìṣẹ́ Rẹ
*   Aini imọ ìwé Mimọ to.
*  Wọn ko mọ agbára ẹ̀jẹ̀ náà (Eks. 12).
*  Wọn ko mọ nípa idàlare Ọlọ́run (Rom. 5:1; 8:1)
*  Àwọn kan ko le ronú ẹnikan kú lẹẹkan ṣoṣo láti san gbèsè ẹṣẹ gbogbo ènìyàn lẹẹkan ṣoṣo. Wọn ko mọ iṣẹ Ọlọ́run.
*   Ẹbi: Koko miran ni ẹbi. Àwọn miran jẹ ẹni ìdálẹ́bi debi pe wọn gbọ́dọ̀ ṣetútù fún ara wọn fun àṣìṣe/ìṣìnà wọn, laiwo ohun tí Jesu tí wa lati ṣe fun wọn. Èyí wa lati inu àìmọkan.

Ọ̀rọ̀ Ìyànjú: jáde kúrò nínú gbogbo nnkan wọnyii lonii, ki o si maa jadun ìpèsè Ọlọ́run nípasẹ̀ ẹ̀jẹ̀ Jesu Kristi.

ÀMÚLÒ FÚN ÌGBÉ AYÉ ẸNI :
Ṣe pataki lati mọ iwe mimọ ki a si maa ṣe amulo rẹ fún igbe ayé wa òjòojúmọ́. Nígbà naa ni a o to le bẹ̀rẹ̀ si mọ riri eto Ọlọ́run fún irapada ènìyàn nisinsin yii àti ní ọjọ́ iwájú. Iwe Mímọ́ yoo rán wa lọ́wọ́ láti mọ ipo búburú tí èṣù ọta ènìyàn fi ènìyàn si nígbà tí o fi arekereke mú kí o ṣe lòdì sí Ọlọ́run. Bákan náà, a o rán wa lọ́wọ́ láti mọ bi Ọlọ́run nínú ìfẹ́ àti àánú Rẹ ṣe fún ènìyàn ni òmìnira kúrò nínú ìdẹkùn èṣù. Ọlọ́run lòdìsi èrò èṣù pátápátá, o da ènìyàn padà si ibasepọ pípé àti idapọ pẹ̀lú ara Rẹ, nisinsin yii àti ní ayérayé. Ẹ yín Ọlọ́run! Iwe Mimọ kan náà ni yóò ṣe atọ̀nà àti olùṣọ́ wa, titi tí a o fi di ẹni ìràpadà Ọlọ́run pátápátá nínú ìjọba ayaraye Rẹ. Maa lo Iwe Mímọ́ Ki o si maa mú un ṣẹ ní rere. Idakọrọ rẹ ni.

IGUNLẸ:
A ti de òpin ẹkọ kinni ni ọwọ/saa ile ẹkọ ọjọ ìsinmi yii. A ti rí ipò tí ìràpadà ènìyàn wa ni ọkàn Ọlọ́run. A ti rí bí Ọlọ́run ti ṣètò fún imubọsipo ayérayé fún ènìyàn. Bẹ́ẹ̀ ni a sì ti rí bí Ọlọ́run ti ṣe fi iya jẹ ọta ènìyàn, satani, àti ìrúbọ, tí a ṣe lẹẹkan ṣoṣo ni kíkún fún ètùtù gbogbo ènìyàn. Jesu ni irubọ náà. Ni ipari a gbà o niyanju láti lọ pẹ̀lú òye yii: Ọlọ́run fún wa ní iwe mímọ ni ìrètí fún ìràpadà rẹ. Máse ja A kulẹ.

ÀṢÀRÒ LÁTI INÚ BÍBÉLÌ FÚN Ọ̀SẸ̀ ÌKEJÌ
Mon.   29:     A Ti Pa Jesu Láti Ìpilẹ̀ṣẹ̀ (Ifih. 13:8).
Tue.    30:     Imupada-bọ-sipo Nilo Ẹ̀jẹ̀ (Gen. 3:21)
Wed.    31:    Wo Ìmúṣẹ Náà (Jhn. 1:29)
Thur.    1:     Ilaja Nípasẹ̀ Ẹ̀jẹ̀ Náà (Kol. 1:19-23)
Fri.       2:     Ko Si Irubọ Mọ (I Kor. 10:19,20)
Sat.      3:     Ko Ni sì Àmọ́ọmọ Dẹ́ṣẹ̀ Mọ (Heb. 10:26-31).
July 28, 2019 ÌJỌ ÀPỌ́SÍTÉLÌ KRISTI, Ẹ̀KỌ́ ILÉ Ẹ̀KỌ́ ỌJỌ́ ÌSINMI : AKOLE - Ki Ìwé Mímọ́ Ki O Le Ṣẹ. July 28, 2019 ÌJỌ ÀPỌ́SÍTÉLÌ KRISTI, Ẹ̀KỌ́ ILÉ Ẹ̀KỌ́ ỌJỌ́ ÌSINMI : AKOLE -  Ki Ìwé Mímọ́ Ki O Le Ṣẹ. Reviewed by Muyiwa Abodunrin (Muyilight) on July 28, 2019 Rating: 5

No comments:

Powered by Blogger.