ÌJỌ ÀPỌ́SÍTÉLÌ KRISTI Ẹ̀KỌ́ ILÉ Ẹ̀KỌ́ ỌJỌ́ ÌSINMI Eto Ayeraye Olorun Fun Eniyan Fun April 14, 2019, Ẹ̀KỌ́ KEJE PATAKI IKÚ ATI ÀJÍǸDE KRISTI

ÌJỌ ÀPỌ́SÍTÉLÌ KRISTI  Ẹ̀KỌ́ ILÉ Ẹ̀KỌ́ ỌJỌ́ ÌSINMI  Eto Ayeraye Olorun Fun Eniyan  Fun April 14, 2019, Ẹ̀KỌ́ KEJE  PATAKI IKÚ ATI ÀJÍǸDE KRISTIEwo Awon Eko Ile Ojo Isinmi Ti O Ti Ko Ja Ni Bi Yi

ÌJỌ ÀPỌ́SÍTÉLÌ KRISTI
Ẹ̀KỌ́ ILÉ Ẹ̀KỌ́ ỌJỌ́ ÌSINMI
Eto Ayeraye Olorun Fun Eniyan
April 14, 2019

Ẹ̀KỌ́ KEJE
PATAKI IKÚ ATI ÀJÍǸDE KRISTI

Ti Jesu ko ba wa si ayé láti ba wa gbe, Ki O ku, Ki O jíǹde Ki O si goke re ọrun ni, a ba wọnú ìparun ayérayé lọ. Ẹ yin Ọlọ́run!


AKỌSÓRÍ
Ẹni tí o kú fun wa, pe bi a ba ji, tabi bí a sun, ki a le jumọ wa láàyè pẹlu Rẹ. (I Tessalonika 5:10).

ÀLÀYÉ KÚKÚRÚ
Pọ́ọ̀lù, onkọwe Tesalonika kinni n gba àwọn ènìyàn níyànjú láti jí giri ki wọn si ni ireti nínú ìgbàlà wọn, nísinsìn yii, ati ni ọjọ iwájú, Ọlọ́run ko yan wa fun ìparun, bikose fún ìgbàlà, èyí tí ikú àti àjíǹde Kristi mú wa. Ikú Jesu jẹ ileri ìṣẹ́gun, nítorí tí O ku ki awa onigbagbọ o le jẹ ajumọjogun iye Rẹ; ìyẹn yoo si bẹ̀rẹ̀ nihin. Ikú Jesu Kristi Olúwa wa jẹ ètùtù ìràpadà fún àwọn Juu ati awọn keferi láti fun wa ni ìgbàlà báyìí àti ìyè Ayeraye níkẹyìn. Yala a si wa láàyè tàbí a ti sún, àwọn onigbagbọ yoo ba A jọba nígbà tí O ba padà wá láti wa kò wa lọ. Àwọn tí wọn tí kú nínú Rẹ ni a o ji dìde láti lọ pẹlu awọn ẹni mimọ tí wọn wa láàyè, wọn yoo si ba A jọba nínú ipo àìkú wọn nínú ogo (wo I Tes. 4:15). Bi Kristi ba jọ̀wọ́ ara Rẹ tinútinú fun ìgbàlà wa, àwọn Kristẹni tí wọn tí gba A gbọdọ ṣe ohun gbogbo láti mú ìgbàlà wọn dúró, nígbà tí àwọn tí kò tii gba A gbọ́dọ̀ ṣe bẹẹ lai foni dọla. Bi o ba wa pẹlu Rẹ ati ninu Rẹ titi de opin, bi o ba tilẹ̀ kú, ìwọ yoo maa ba A gbé titi lae.

ÀṢÀRÒ LÁTI INÚ BÍBÉLÌ FÚN ỌSẸ KINNI
Mon.    8:     Ọrọ Naa Si Di Ara (Jn. 1:14)
Tue.     9:     Messiah Naa Yoo Gba Àwọn Ènìyàn Rẹ La (Mat. 1:21)
Wed.    10:   Messiah Náà n Jọba Lori Ile Jákọ́bù (Lk. 1:30)
Thur.    11:  Ìràpadà Tòótọ́ Wá Nípasẹ̀ Jesu (Gal. 4:4-6)
Fri.       12:  Ìgbàlà Tòótọ́ Wá Nípasẹ̀ Igbagbọ (Efe 2:8)
Sat.      13:   Ilaja Tòótọ́ Si Ọlọ́run Nípasẹ̀ Jesu (Kol. 1:22).

ÀṢÀRÒ FÚN ÌFỌKÀNSÌN
1.     Laisi ikú àti àjíǹde Kristi, a ba ti je wọnú ìparun ayérayé lọ: gbogbo igbesi ayé wa iba ja si asan. Ẹ yin In logo!
2.    Ikú Kristi ti gba wa là kúrò lọwọ ègún òfin àti ti idibajẹ tí o waye nípasẹ̀ satani. A ni lati gbe igbe ayé pẹ̀lú ìrètí jijọba pẹ̀lú Rẹ ni ayérayé.

ẸSẸ BÍBÉLÌ FÚN IPILẸ Ẹ̀KỌ́ : I Korinti 15:1-58

ILÉPA ATI ÀWỌN ERONGBA
ILÉPA:   Láti fihan pe ìran ènìyàn I ba ti ṣègbé bikose ikú àti ajinde Jesu Kristi.

ÀWỌN ERONGBA: Ni parí ẹ̀kọ́ ọ̀sẹ̀ meji, àwọn akẹ́kọ̀ọ́ gbọdọ lee
i.   Jíròrò lórí àwọn àsọtẹ́lẹ̀ nípa ikú àti àjíǹde Jesu;
ii.  Jiroro idi ti Jesu fi fi ẹ̀mí rẹ lélẹ̀ fún ìrúbọ fun ẹlẹ́sẹ;
iii. Safihan òye kikun nípa Pataki àjíǹde Rẹ;
iv. Kun fun ayọ̀ àti safihan ìrètí nípa àjíǹde àti ìyè ayérayé pẹ̀lú Kristi nínú ogo.

IFAARA
ORÍSUN Ẹ̀KỌ́: ORIN DAFIDI 16:10; ISAIAH 53:1-9; MATTEU 1:21; 28:1-7; I KỌRINTI 15:17-19.
A dupẹ lọwọ Ọlọ́run fun ẹ̀kọ́ tí o kọjá, ti o kọja, tí ìṣe ẹ̀kọ́ kẹfà nínú ọwọ yii, pẹ̀lú àkòrí. ÌKÓRÈ AYÉ. A ko le gbàgbé kiakia pé ẹ̀kọ́ naa wa ninu iwe Mateu 13:24-43 èyí tí o ṣe ìpamọ́ àkọsílẹ̀ Owe Olúwa wa ti Àlìkámà àti Epo. Láti inú èyí, o ti ye wa síwájú nípa òye ìkórè ayé, pe ki a maa retí rẹ láti ìgbà yii lọ, yoo sẹlẹ dandan. A o ni kábámọ lọ́jọ́ naa. Amin.

Èyí ni ẹkọ keje nínú èyí tí a o maa jíròrò lórí PATAKI IKÚ ÀTI ÀJÍǸDE KRISTI. Ọlọ́run ti fi ìfẹ́ Rẹ̀ hàn sí ẹ̀dá ènìyàn ṣáájú ayérayé. O tilẹ̀ dunmọni, o han gbangba pé, ko si àṣìṣe, koda nígbà ìṣubú ènìyàn nínú Ọgbà Édẹ́nì titi di lọọlọ yii. Ko fi ọrọ Rẹ jáfara pàápàá nínú ìdájọ́ Rẹ nínú ọgbà naa. O ṣèlérí Olùgbàlà kan fún wa (Gen. 3:15; wo I Jn. 3:8b). o fẹ ki iṣẹ èṣù di piparun. Ki ìparun yii le wáyé, Ọlọ́run rán Jesu Kristi wa si ayé yii, Ẹni tí o ní ìgbàlà /àṣẹ láti pa Sátánì àti ìṣẹ́ rẹ rún àti láti sọ wá di òmìnira.

Erongba ayérayé Ọlọ́run kì ba ti wa si ìmúṣẹ biko bá ṣe pé a tà ẹ̀jẹ̀ iyebíye Jesu silẹ lórí igi àgbélébùú ni Kalfari fún ẹsẹ wa. Èyí ń si wa leti eredi ẹ̀kọ́ yii. A o maa ṣàgbéyẹ̀wò pàtàkì ikú Jesu Kristi àti asepe eto Ọlọ́run fún ènìyàn.

Ayẹyẹ ikú àti àjíǹde Jesu Kristi kiise kí a maa ṣe wẹjẹwẹmu tàbí kí a maa ṣe ìṣekúṣe /hùwà aìwà-bí-Ọlọ́run (Gal. 5:19-21; Efe. 5:3). A jẹ ènìyàn ọ̀tọ̀ pátápátá tí a sì yàtọ̀ sí àwọn Kèfèrí àti abọ̀rìṣà. A gbàdúrà pé kí Ẹ̀mí Mímọ́ rán wa lọ́wọ́ láti mú ìdúró wá pẹ̀lú gbógbo imoye pàtàkì àti ikiyesara, ìgbàlà naa ti a fi ra wa nípasẹ̀ ikú àti àjíǹde Jesu Olúwa wa. Amin.

IFAARA SI ÌPÍN KỌ̀Ọ̀KAN:
A pín ẹ̀kọ́ naa si ìpín I àti II, èyí tí a tun satunpin sì A àti B.

ÌPÍN KÍNNÍ: ÀWỌN ÀSỌTẸ́LẸ̀ NIPA IKÚ ÀTI ÀJÍǸDE RẸ
Ipin A n ṣàgbéyẹ̀wò àwọn àsọtẹ́lẹ̀ ọjọ́ pipe nípa ibi Jesu Kristi, èyí tí o fun ni ni àwọn ẹri tó yeni yekeyeke tí a ko le ṣé pé lóòótọ́ ni O wa si ayé Onírúurú àsọtẹ́lẹ̀ láti ẹnu Dáfídì, Isaiah, Mateu, abbl, ní ó kún inú Ìwé Mímọ́ nípa wíwà Olúwa àti Olùgbàlà wa ni igba àkọ́kọ́. Jesu tun sọ àsọtẹ́lẹ̀ nípa erongba (ìtara) rẹ (Mt. 8:21; Mk. 8:31; 9:31). Yoo jìyà, yoo si ku láti ọwọ àwọn ẹlẹ́sẹ. Ìpín B n sọ̀rọ̀ lórí bí Baba ko ṣe ni jẹ ki ara (ọmọ) Rẹ o jìyà idibajẹ nínú ibojì. Awon ihinrere mẹrẹẹrin naa tun pa àwọn ẹri ìgbé-ayé, ijiya, iku àti àjíǹde Rẹ mọ. Ṣé o ko ṣiyèméjì mọ?

ÌPÍN KEJÌ: PATAKI IKÚ ÀTI ÀJÍǸDE RẸ
Ikú àti àjíǹde Jesu ko salai ni erongba. Nínú ìpín yìí, a o ri bí a ti safihan ìfẹ́ Ọlọ́run fún ènìyàn (Jhn. 3:16); bi Ó ti faaye gba ọmọ Rẹ láti fà ènìyàn yọ kúrò nínú ẹsẹ pẹlu lílo ẹjẹ Rẹ. Ìpín kejì ṣàlàyé bi àjíǹde Kristi ti mú igbagbọ wá sí ṣíṣe, seso àti wá láàyè; èyí ń fún wa ní ìdánilójú ìdáríjì, ìṣẹ́gun, ìràpadà àti ìyè ayérayé, fun àwọn tí yoo wa si ọdọ Rẹ (Efe. 1:7; Kol 1:4). Ọlọ́run yóò fún wa lágbára láti jẹ̀gbádùn oore-ọ̀fẹ́ Rẹ ti o wa ninu Jesu Kristi

KÓKÓ Ẹ̀KỌ́
I.    ÀWỌN ÀSỌTẸ́LẸ̀ NIPA IKÚ ÀTI ÀJÍǸDE RẸ
      A.   NÍPA IKÚ RẸ
      B.   NÍPA ÀJÍǸDE RẸ

II.   PÀTÀKÌ IKÚ ÀTI ÀJÍǸDE RẸ
      A.   ÌTUMỌ̀ RẸ
      B.   PÀTÀKÌ RẸ

ITUPALẸ Ẹ̀KỌ́
I.     ÀWỌN ÀSỌTẸ́LẸ̀ NIPA IKÚ ÀTI ÀJÍǸDE RẸ (Orin Dafidi 16:10; Isaiah 53:1-9; Mateu 28:1-7).
Àsọtẹ́lẹ̀ ni ọrọ ti a sọ pe ohun kan yoo sẹlẹ ni ọjọ iwájú. Àsọtẹ́lẹ̀ maa n ti ọdọ Ọlọ́run wa, o si jẹ ìfihàn ìfẹ́ Rẹ̀ àtọ̀runwá fun ìran ènìyàn. Gbogbo àsọtẹ́lẹ̀ tí o waye nípasẹ̀ Jesu Kristi ni o wa si ìmúṣẹ, a sì dá awọn yooku dúró. Wọn yoo wa si ìmúṣẹ!

A.    NÍPA IKÚ RẸ (Isa. 53:1-9)
       A kẹ́gàn rẹ a si kọ Ọ lọdọ àwọn ènìyàn ẹni ikaanu, tí o sì mọ ibanujẹ; o si dabi ẹni pé o mú kí a pa ojú wa mọ kúrò lára rẹ; a kẹ́gàn rẹ àwa kò sì kà á sí (Isa. 53:3).
i.    Isa.  53:1-7 n sọ àsọtẹ́lẹ̀ tí ìjìyà Olùgbàlà. Kristi yoo jìyà kíkankíkan tí a o kẹ́gàn rẹ, a o si kọ ọ silẹ. Gbogbo ohun to rọ̀ mọ Jesu; ibi Rẹ, igbe ayé Rẹ, ìṣẹ́ ìránṣẹ́ Rẹ, iku àti ìsìnkú Rẹ jẹ ìmúṣẹ àsọtẹ́lẹ̀ (wo Fil. 2:5-8).
ii.   Mk. 8:31: Jesu tí sọ àsọtẹ́lẹ̀ ìjìyà Rẹ nínú ìkọ́ni Rẹ (wo Lk. 9:22).
iii.  O sọ̀rọ̀ nípa ìrìbọmi ìjìyà tí a o ṣe fun Un (Mk.10:38; Lk. 12:50)
iv.  A ti kọ ọ wí pé a o kẹ́gàn Rẹ̀ (Isa. 53:3; Lk. 23:11).
v.   Jn. 3:14: A ó gbe E soke gẹgẹ bi a ti gbe ejo soke ni aginjù. A mu èyí ṣẹ nígbà tí a gbé E kọ sórí igi Àgbélébùú (Mat. 27:35 siwaju)
vi.  Mat. 12:39, 40: Sọ àsọtẹ́lẹ̀ ìtẹ́loriba niti ìsìnkú Rẹ. A mu eyi ni ṣẹ (28:57 síwájú)
vii. I Pet. 1:10,11 n tọka wa pada si àwọn àsọtẹ́lẹ̀ ìjìyà àti ikú Kristi ti a si ti múṣe nísinsìn yii sínú ogo Ọlọ́run.
viii. Yàtọ̀ sí ogo àjíǹde Rẹ, igoke re ọrun àti igbega Rẹ, ogo wiwaasu ọrọ naa káàkiri tún wa, tí o n fa àyípadà eto ìwà-rere àti tẹmi nínú ayé wa (Ìṣe 16:20; 17:6).

B.   NIPA ÀJÍǸDE RẸ (Orin Daf. 16:10; Mat. 28:1-7)
      Nítorí ìwọ kì yoo fi ọkàn mi silẹ ni ipo-òkú; bẹẹ ni ìwọ kì yoo jẹ ki Ẹni mímọ rẹ kì o ri idibajẹ (Orin Daf. 16:10).
i.    Orin Dafidi 16:10 ṣàlàyé yekeyeke pé Ọlọ́run kì yoo fi Olùgbàlà naa silẹ ni ipo òkú.
ii.   Mat. 28:5,6 ṣe ìmúṣẹ àmì Jonah tí a fun un nipasẹ Jesu (Mat. 12:39-40, wo Jonah 1:17). Jesu jíǹde nítòótọ́ lọ́jọ́ kẹta.
iii.  Gbogbo àwọn ìwé ihinrere mẹrẹẹrin ṣe ìpamọ́ àwọn ẹri aridaju ìmúṣẹ àwọn àsọtẹ́lẹ̀ àjíǹde Jesu Kristi (Mat. 28:1-7; Mk. 16:1-8; Lk. 24:1-8; Jn. 20:1-8).
iv.  Lati ihin yii lọ, o han kedere pé, Ọlọ́run ti ko ipa tíRẹ niti ìgbàlà ẹ̀dá ènìyàn nípa ríran ọmọ Rẹ wa si ayé nítorí ẹsẹ ènìyàn. Bákan naa, Jesu yoo gba wa la de òpin, bí a ba rọ mọ Ọ laisiye meji.
v.  Láti jẹ̀gbádùn títóbi Ọlọ́run nínú ríran ọmọ Rẹ si wa àti fún wa, o yẹ (pọndandan) ki a jọ̀wọ́ ara wa fún ìfẹ́ Rẹ̀, ki a ba le jọba pẹlu Rẹ nínú ìjọba baba Rẹ (Jer. 6:16; Mat. 11:28,29.

ÀWỌN Ẹ̀KỌ́ TÍ A RI KỌ
1.    Àwọn àsọtẹ́lẹ̀ ikú àti ajinde Kristi n jẹri sì òtítọ́ ìgbàgbọ́ wa ninu Kristi àti pípé ojúlówó ọrọ Ọlọ́run.
2.   A ní ìrètí to dájú àti àfojúsùn nípa ìmúṣẹ ikú àti àjíǹde Kristi.

ÌṢẸ́ ṢÍṢE
Ṣàlàyé ipa àti pàtàkì IKÚ ÀTI ÀJÍǸDE Jesu Kristi sì igbagbọ Kristẹni wa àti ìyè ayérayé.

ÌDÁHÙN TÍ A DÁBÀÁ FÚN IṢẸ́ ṢÍṢE
i.   A le Ádámù àti Éfà jáde kúrò nínú ọgbà Édẹ́nì nitori ese (Gen. 3:23), nítorí naa wọn ku ikú ara, ṣùgbọ́n tí o yẹ ki wọn kú nípa tẹmi nípa ihu ìwà bẹẹ.
ii.   Bíbélì wí pé ọkàn ti o ba ṣẹ yoo ku (Esik 18:20).
iii.  Nítorí Ọlọ́run fẹ, aráyé tó bẹẹ gẹ ti O fi ọmọ bibi Rẹ kansoso fun ni kí ẹnikẹ́ni tó bá gba A gbọ ma baa ṣègbé bikose kí o ní iye àìnípẹ̀kun (Jhn 3:16)
iv.  Laisi itajẹ silẹ kò le sì imukuro ẹsẹ̀ (Heb. 9:22).
v.   Ikú Kristi gba ìran eniyan là kúrò lọwọ ìdálẹ́bi ẹsẹ (Rom. 8:1).
vi.  Ẹjẹ Rẹ gbà wa la kúrò lọwọ gbogbo àìmọ, o si ti pese ìṣẹ́gun fun wa, lórí ikú tí o waye nípasẹ̀ ẹṣẹ àti ìṣubú naa (I Kor. 6:11; I Jhn. 1:7).
vii. Nípasẹ̀ ikú Rẹ, a sọ wa di olódodo nípasẹ̀ Rẹ, ìyẹn ni pé gẹgẹ bí ẹni pe a ko ni ẹṣẹ kankan, a tu wá silẹ a sì sọ wá di ominira (2 Kor. 5:21), nítorí naa ko si ìjìyà tó ń bọ̀ láti ọ̀dọ̀ sátánì mọ níwọ̀n bí a bá ti wa ni ikawọ Kristi.
viii. Nípasẹ̀ àjíǹde Jesu, a ji awọn onigbagbọ kúrò nínú òkú dìde sí ìyè (Jhn. 11:25).
ix.  A yi wa pada láti inú iri satani sì iri àwòrán iwa mimọ Ọlọ́run (Rom. 12:2).
x.  Nípasẹ̀ àjíǹde Rẹ, àwọn onigbagbọ ni ìrètí ayérayé tí àlàáfíà pẹ̀lú Kristi (I Kor. 15:19; Heb. 6:11).
xi.  A o rí Ọlọ́run bi O ti ri ni ọjọ kan, kódà ni bayii, a ti mú aṣọ ikele naa kúrò lọ́nà (I Jhn. 3:2). A le de iwájú Rẹ gẹ́gẹ́ bi ọmọ Rẹ olufẹ.
ÌJỌ ÀPỌ́SÍTÉLÌ KRISTI Ẹ̀KỌ́ ILÉ Ẹ̀KỌ́ ỌJỌ́ ÌSINMI Eto Ayeraye Olorun Fun Eniyan Fun April 14, 2019, Ẹ̀KỌ́ KEJE PATAKI IKÚ ATI ÀJÍǸDE KRISTI ÌJỌ ÀPỌ́SÍTÉLÌ KRISTI  Ẹ̀KỌ́ ILÉ Ẹ̀KỌ́ ỌJỌ́ ÌSINMI  Eto Ayeraye Olorun Fun Eniyan  Fun April 14, 2019, Ẹ̀KỌ́ KEJE  PATAKI IKÚ ATI ÀJÍǸDE KRISTI Reviewed by Abodunrin Muyiwa (Muyilight) on April 14, 2019 Rating: 5

No comments:

Powered by Blogger.