ÌJỌ ÀPỌ́SÍTÉLÌ KRISTI Ẹ̀KỌ́ ILÉ Ẹ̀KỌ́ ỌJỌ́ ÌSINMI FUN OJO April 21, 2019. Eto Ayeraye Olorun Fun Eniyan

ÌJỌ ÀPỌ́SÍTÉLÌ KRISTI  Ẹ̀KỌ́ ILÉ Ẹ̀KỌ́ ỌJỌ́ ÌSINMI  FUN OJO April 21, 2019. Eto Ayeraye Olorun Fun Eniyan    EKA AWON EKO ATEYIN WA NI BI YI

ÌJỌ ÀPỌ́SÍTÉLÌ KRISTI
Ẹ̀KỌ́ ILÉ Ẹ̀KỌ́ ỌJỌ́ ÌSINMI
Eto Ayeraye Olorun Fun Eniyan

April 21, 2019.

II.   PÀTÀKÌ IKÚ ÀTI ÀJÍǸDE RẸ (Mateu 1:21; I Kọ́ríńtì 15:17-19).
Lati sọ pàtàkì nnkan ni lati sọ òtítọ́ jijẹ pàtàkì àti jijẹ iyebíye rẹ, iku tí o n ba ènìyàn lẹru, di ohun tí o wu Jesu, idi niyii tí O fi wa si aye ẹsẹ yii (Luku 13:27; Titu. 2:14). Ju bẹẹ lọ ní ajinde Rẹ, nitori tí O ṣílẹ̀kùn iye ayérayé silẹ fún wa.

A.    ÌTUMỌ̀ IKÚ JESU (Mat. 1:21)
       Yoo si bí ọmọkùnrin kan, Jesu ni ìwọ ó pe orúkọ rẹ, nítorí òun ni yoo gba àwọn ènìyàn rẹ la kuro ninu ẹsẹ wọn (ẹsẹ 21).
i.   o n safihan ẹri bi ifẹ Ọlọ́run fun eniyan ṣe ga tó (Jn. 15:13; Rom. 5:8).
ii.  O n safihan pàtàkì jijọsin fun Oluwa (Rom. 5:15; 2 Kor. 5:17).
iii. O jẹ ikú ètùtù láti fi dipo ènìyàn alaiyẹ (Rom. 4:25).
iv. O ṣe ilaja ènìyàn si Ọlọ́run Ẹlẹda rẹ (Rom. 3:24-25)
v.  O jẹ ohun ti irapada eniyan maa na Ọlọ́run (Efe. 1:8; I Tim. 2:6; Heb. 9:22).
vi O jẹ ìmúṣẹ ìfẹ́ tí o tobi julọ tí Ọlọ́run ṣeleri fun ènìyàn (I Pet. 1:10-11).
vii.O safihan àpẹẹrẹ fun wa lati maa tẹle (I Kor. 15:57, 58; Fil. 2:1 swj).
viii.Ẹnikẹ́ni ti a ba ti bi ninu Ọlọ́run ti ṣẹgun aye, eyi si ni ìṣẹ́gun tí o n bori aye, koda igbagbọ wa. Àwọn tí o gbagbọ nínú ikú, ati ajinde Jesu Kristi nìkan ni o ni ìdánilójú, ìṣẹ́gun, nibi yii àti ni ayérayé (I Jhn. 5:4, 5). Nibo ni o duro sì?

B.   PÀTÀKÌ ÀJÍǸDE JESU (I Kor. 15:17-19)
      Bi a ko ba si ji Kristi dide, asan ni ìgbàgbọ́ yin; ẹyin wa ninu ẹsẹ yin síbẹ̀! (I Kor. 15:17).
i.   Rom. 4:25: A ji Jesu dide ki a le da wa làre.
ii.  10:9-10: Ajinde Rẹ fidi rẹ múlẹ̀ pe O jẹ Oluwa ati lori ikú pàápàá.
iii. I Kor. 15:17: Bí a ko ba ji Jesu Kristi dide ni asan ni igbagbọ wa ìbá ja si, ṣùgbọ́n a dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọ́run fun mímú kí Jesu jinde kúrò nínú òkú. Nítorí naa, O fun wa ni iye ayérayé.
iv.  I Kor. 15:17: Ajinde Rẹ n fun wá ní ìdánilójú ìdáríjì ẹṣẹ wa.
v.   Ẹsẹ 18,19: Ti a ba yọ ajinde Kristi kúrò, àwọn tí wọn sun nínú Rẹ ti ṣègbé bẹẹni àwọn onigbagbọ jẹ abosi julọ.
vi.  Ẹsẹ 57: A ní ìṣẹ́gun lórí ikú, iye ayérayé àti ìdáǹdè kúrò lọrun-àpáàdì nípasẹ̀ àjíǹde Rẹ (wo Rom. 6:9-10; 2 Kor. 1:3-5; 1 Pet. 1:3).
vii. Ajinde Jesu n fun wa ni ìdánilójú tó mọ gaara ní ti ipadabọ Rẹ lẹẹkeji láti ṣe ìdájọ́ ayé (Ìṣe Àwọn Apo. 11:31; Rom. 2:2:16).
viii.A ko gbọdọ ṣe iyèméjì nípa òtítọ́ pe O n padabọ mọ. Ìmúṣẹ àwọn àsọtẹ́lẹ̀ wiwa Rẹ ni igba àkọ́kọ́ yẹ ki o mú wa ni ireti àti dúró fun ipadabọ Rẹ ìkẹyìn, èyí tí yoo mu awọn onigbagbọ mọ ibi ayérayé Rẹ (Efe. 2:21; Ifi. 21:2-4).

ÀWỌN Ẹ̀KỌ́ TÍ A RÍ KỌ
1.   Ikú Kristi túmọ̀ sí iye, ìrètí, ìràpadà, ilaja àti ìyè ayérayé fun ènìyàn.
2.  Àjíǹde Jesu n fun wa ni ìdánilójú ajinde ni ọjọ ìkẹyìn àti ireti ayérayé pẹlu Kristi ninu ayọ̀ tí ọrun.

ÀWỌN ÌBÉÈRÈ
1.   Sọ àwọn ohun tí o mọ nípa àsọtẹ́lẹ̀ ikú àti àjíǹde Jesu Kristi Olúwa wa.
2.  Kin ni awọn àbájáde tí ikú àti ajinde Jesu ni lori ìyè ayérayé ènìyàn.

ÀWỌN ÌDÁHÙN TÍ A DÁBÀÁ FÚN ÌBÉÈRÈ:
ÌDÁHÙN SI ÌBÉÈRÈ KÍNNÍ
i.   Dafidi, Isaiah abbl sọ àsọtẹ́lẹ̀ nipa rẹ (Orin Dafidi 40:6-8; 72:11; Isa. 9:6). Àwọn àsọtẹ́lẹ̀ ikú àti ajinde Jesu jẹ àtọ̀runwá. Nítorí naa gbogbo wọn ni o wa si ìmúṣẹ. Ọlọ́run ko le parọ.
ii.   Nítorí jíjẹ Pataki rẹ, àwọn ènìyàn láti inú Majẹmu Láéláé àti Tuntun ni o sọ àsọtẹ́lẹ̀ nípa Rẹ (Gen. 49:10; 2 Sam. 7:12-13; Hos. 11:1; Mik. 5:2; Mat. 2:14,15; Luku 1:35; Heb. 2:5-9).
iii.  Jesu funra Rẹ sọ àsọtẹ́lẹ̀ nípa ikú àti ajinde Rẹ (Mk. 8:31; 9:31; Luku 9:22; 18:31).
iv.  Àwọn Áńgẹ́lì fidi rẹ múlẹ̀ (Mat. 1:21; Luku 1:26-31).
v.   Gbogbo àwọn àsọtẹ́lẹ̀ wọnyii ni o wa si ìmúṣẹ. Jesu lọ si Kalfari láti jọ̀wọ́ ẹ̀mí Rẹ lọwọ kí a ba le maa gbe ni ominira kúrò lọwọ Sátánì àti ẹṣẹ (wo Mat. 1:21).
vi.  Ni ìkẹyìn Ọlọ́run ji I dìde kúrò nínú òkú, nítorí O ku fún iṣẹ ìgbàlà tí ènìyàn.

ÌDÁHÙN SI ÌBÉÈRÈ KEJÌ
i.   Lọ sí àwọn ìdáhùn tí a dábàá fun iṣẹ ṣíṣe
ii.  Ajinde naa jẹ ọkan lára àwọn ẹri pé Jesu jẹ Ọmọ Ọlọ́run (Rom. 1:4).
iii. Ikú àti ajinde Jesu ni ipilẹ ìgbàgbọ́ Kristẹni (I Kor. 15:14-21)
iv. O fihan pe ijọba Ọlọ́run wa lábé akoso Ẹmi tí o ga julọ tí O sì wa láàyè naa (Ifi. 1:17,18).
v.  Ikú àti ajinde Rẹ mú ìgbàlà wa fún wa. Ikú tí ara kii ṣe ikekuro (imukuro) ìran ènìyàn (Oniw. 12:5; 2 Kor. 6:2).
vi. Ikú àti ajinde Rẹ ra ìdáǹdè àti ìṣẹ́gun lórí satani, ẹṣẹ àti ẹran ara fún wa.
vii. A gbé wa la nípa oore-ọ̀fẹ́ Rẹ, Ìyẹn sì wáyé nípasẹ̀ ìgbàlà wa ninu Rẹ, àti ohun gbogbo tí o wa ṣe àti ohun gbogbo tí o ṣi n ṣe fun wa àti nitori wa (Efe. 2:8).
viii.O mú iwẹnumọ bá wa (Jhn. 17:19; I Kor. 1:30; Fil. 3:9).
ix.  Nínú Rẹ, a ri imubọsipo ibasepọ tí o ti sọnù pẹ̀lú Ọlọ́run gbà ---- aṣọ ìkélé naa ti faya, a sì ti mú un kúrò (Efe 1:6; Heb. 9:11,12).
x.   A yiwa padà kúrò nínú òkùnkùn lọ sínú ímọ́lẹ̀ iyebíye Rẹ (Kol. 1:13; I Pet. 2:9).
xi.  Jesu gba ogo nínú ayé wa gẹgẹ bí Ọlọ́run ti gba ògo (Jhn. 17:1-21; 19).
xii. Ènìyàn (iye àwọn tí wọn ba gbagbọ nínú Jesu tí wọn sì tẹ́wọ́gba ohun gbogbo tí Jesu dúró fún) ni a dalare (Rom. 3:24;  Titu. 3:5,7).
xiii.A da ẹsẹ àti Sátánì lẹbi (Ifi. 19:20; 20:10).
xiv.O fidi Bibeli múlẹ̀ gẹgẹ bi òtítọ́ wo I Kor. 15:14-17).
xv. O fun wá ní ìrètí ààyè; bí a bá ku ninu Rẹ, a o jí wá dìde, a o si jọba pẹlu Rẹ (Kor. 2:10-12).
xvi.Awọn tí wọn ba ku ninu Rẹ nìkan, ní o ku pẹ̀lú (nínú) Alafia. Àwọn tí o ba si ku pẹ̀lú (nínú) Alafia nìkan (Jesu; Àlàáfíà wà) ni o le sun (sinmi) pẹ̀lú àlàáfíà. Báwo ni ènìyàn yoo ṣe sún (sinmi) ni alaafia, bí o tilẹ wu ki aladura ati àdúrà ó gbóná tó lórí irú nnkan bẹẹ, nígbà tí irú ẹni bẹẹ ko ku pẹ̀lú àlàáfíà?

ÀMÚLÒ FÚN ÌGBE AYÉ ẸNI :
I jọba Ọlọ́run dabi horo irúgbìn nínú ilẹ̀. Fún un láti bá ìrètí afúnrúgbìn pàdé, o ni lati jẹrà, kí o sì jáde lọtún, pẹ̀lú mímú ọpọ èso jáde ju ohun tí a gbìn lọ. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ni o n jẹun láti ara irúgbìn kan tí a gbìn ni igba kan sẹ́yìn. O ṣe Pàtàkì kí irúgbìn o wọnú ilẹ̀ kí o sì jẹrà. Ohun tí o ṣe pàtàkì julọ ni pé nígbà tí o bá hu tí o sì so èso ko ṣe anfaani fún àwọn ẹranko, ẹyẹ àti eniyan. Jesu Kristi ni eso obìnrin naa ti a gbìn ni ẹgbẹ̀rún ọdún méjì sẹ́yìn tí a sì ji I dìde láti fún agọọrọ eniyan ni iye àti ìrètí lagbaye. Gẹgẹ bí irúgbìn ko ti le hu láìṣe pé o bo o mọ́lẹ̀ sínú ilẹ, (Ìyẹpẹ) kí o sì hu jáde, Jesu ni lati jìyà kí o sì dojúkọ ìrora ikú, kí eniyan ba le mú nínú èso òdodo nípasẹ̀ jíjẹwọ igbagbọ wọn nínú Rẹ. Ju gbogbo rẹ lọ, O ti jínde kí àwọn tí o ti gba A àti àwọn, tí yoo si tẹ́wọ́gba A gẹ́gẹ́ bi Oluwa àti Olùgbàlà wọn (Juu àti Kèfèrí) le ni iye lẹkunrẹrẹ nínú ayé yii, àti pàápàá julọ jí ayérayé. A kò nii dàwátì ni orúkọ Jesu.

IGUNLẸ
A dúpẹ́ lọwọ Ọlọ́run fún ẹ̀kọ́ tí o jẹ ìyanu tí Ọlọ́run ti yàn láti fi bukun wa bí a ti jíròrò lórí ohun tí O ní fún wa ninu Rẹ. A ti rí bí àwọn àsọtẹ́lẹ̀ tí Ọlọ́run sọ nípa ikú àti àjíǹde Jesu ko ti ṣe e yipada. Wọn wa si ìmúṣẹ, laiwo tí èrò èṣù àti àwọn ọmọ ogún rẹ láti dabaru erongba àti eto ìràpadà ayérayé Ọlọ́run. Ikú àti ajinde Jesu Kristi láìsí aniani fún wa ní ìdánilójú, ìrètí ayérayé. Nínú ẹ̀kọ́ yìí, a ní òye tó ye kooro nípa pàtàkì àti jijẹ koseemani ikú àti ajinde Jesu. Bi mejeeji ko ba sẹlẹ, ènìyàn í bá ti ṣègbé titi ayérayé. Kristi ti fun wá ní ìṣẹ́gun pátápátá nípasẹ̀, iku àti ajinde Rẹ (I. Kor. 15:57). O yẹ fun ìyìn wá titi ayérayé.

ÀṢÀRÒ LÁTI INÚ BÍBÉLÌ FÚN ỌSẸ ÌKEJÌ
Mon.    15:     O Ta Ẹ̀jẹ̀ Rẹ Silẹ Fún Ẹsẹ Wa (Matt. 26:28).
Tue.     16:     O Fi Ẹ̀mí Rẹ Ṣe Ìràpadà Fún Ọ̀pọ̀lọpọ̀ Eniyan (Mat. 20:28).
Wed.    17:     O Sọ Ìdálẹ́bi Di Asán Nítorí Wa (Rom. 8:1)
Thur.   18:     Igbagbọ Nínu Kristi N Da Àwọn Onigbagbọ Lare (Jn. 5:20-24).
Fri.      19:     Ọ̀pẹ ni fún Ọlọ́run Nítorí Ẹ̀bùn Alaile Fẹnu Sọ Rẹ (2 Kor. 9:15)
Sat.     20:     Wàásù Ìrìbọmi tí Ìrònúpìwàdà (Lk. 24:47).
ÌJỌ ÀPỌ́SÍTÉLÌ KRISTI Ẹ̀KỌ́ ILÉ Ẹ̀KỌ́ ỌJỌ́ ÌSINMI FUN OJO April 21, 2019. Eto Ayeraye Olorun Fun Eniyan ÌJỌ ÀPỌ́SÍTÉLÌ KRISTI  Ẹ̀KỌ́ ILÉ Ẹ̀KỌ́ ỌJỌ́ ÌSINMI  FUN OJO April 21, 2019. Eto Ayeraye Olorun Fun Eniyan    Reviewed by Abodunrin Muyiwa (Muyilight) on April 21, 2019 Rating: 5

No comments:

Powered by Blogger.