ÌJỌ ÀPỌ́SÍTÉLÌ KRISTI Ẹ̀KỌ́ ỌJỌ́ ÌSINMI. FUN March 3rd, 2019. Eto Ayeraye Olorun Fun Eniyan. Ẹ̀KỌ́ KẸRIN: IFẸ ỌLỌ́RUN FUN ÌRAN ENIYAN

ÌJỌ ÀPỌ́SÍTÉLÌ KRISTI  Ẹ̀KỌ́ ỌJỌ́ ÌSINMI. FUN  March 3rd, 2019. Eto Ayeraye Olorun Fun Eniyan.  Ẹ̀KỌ́ KẸRIN: IFẸ ỌLỌ́RUN FUN ÌRAN ENIYAN
ÌJỌ ÀPỌ́SÍTÉLÌ KRISTI
Ẹ̀KỌ́ ỌJỌ́ ÌSINMI.
Eto Ayeraye Olorun Fun Eniyan.
March 3rd, 2019.

Ẹ̀KỌ́ KẸRIN: IFẸ ỌLỌ́RUN FUN ÌRAN ENIYAN
Ọlọ́run ti fi ìfẹ́ Rẹ̀ fun ẹ̀dá ènìyàn. Iye àwọn tí o gba ififunni Rẹ ni yoo de ọrun.


AKỌSÓRÍ
Oluwa ti fi ara han fun mi láti okere pe, nitotọ èmi fi ìfẹ́ni ayérayé fẹ ọ, nitorina ni emi ti ṣe pa oore-ọ̀fẹ́ mọ fun ọ (Jeremiah 31:3).

ÀLÀYÉ KÚKÚRÚ
Ọrọ ni yii ti o n wá ní àkókò tí o dabi pe ireti tí sọnù fun awọn eniyan naa, àkókò tí o dabi pe wọn tí parun pátápátá, ṣùgbọ́n Ọlọ́run ṣèlérí ọjọ iwájú àti ìfẹ́ Rẹ̀ fun wọn. Lẹ́yìn lílọ sì ìgbèkùn àti ìjìyà tí àìgbọràn wọn ṣokùnfà rẹ, Ọlọ́run kàn sí àwọn ènìyàn Rẹ pẹlu inú rere tí o suyọ nipasẹ ìfẹ́ ayérayé tí o jinlẹ. Bi wọn yoo ba gba A láàyè, O ti pinnu láti ṣe àti láti fun wọn ní ohun tí o dara julọ. Ìlérí imubọsipo ni a ti ṣe fun wọn lẹyin tí a kìlọ fun wọn nípa ẹṣẹ. A mu ìránnilétí ìfẹ́ ailopin Ọlọ́run wa eyi ti o mu eemi (atẹgun) ìfọkànbalẹ wa. Nítorí náà, a gbọ́dọ̀ rí Ifẹ Ọlọ́run fun ìran ènìyàn tí a gbọ́dọ̀ ri gẹ́gẹ́ bii pe O n fa wa sunmọ ọdọ ara Rẹ. Ọlọrun kii ṣe ẹni búburú. O fẹ́ràn gbogbo wa de ayérayé.

Ifẹ Ọlọ́run kii darúgbó (dogbo), nitori naa kii yipada. Ọlọrun tí maa n ṣetán nígbà gbogbo láti fi irú ìfẹ́ aisẹtan tí O fihan fún àwọn baba-nla wa koda ni ipo ẹṣẹ wa han awa àti ìran tí o n bọ. Ifẹ Rẹ yii ni o n mú ko fa àwọn ẹlẹ́ṣẹ si ọdọ ara Rẹ, dipo fifi wọn silẹ sì ipo ìdálẹ́bi wọn. Ẹ̀kọ́ tí o wa nibi yii ni pe bi Ọlọ́run ba fi irú ìfẹ́ ńlá bẹẹ han si wa, a gbọ́dọ̀ safihan Rẹ fun àwọn ẹlòmíràn laisi awawi, nitori ìfẹ́ ni Ọlọ́run. Ìjọ Ọlọ́run wa láàyè loni, kii ṣe nítorí iduurore àti àwọn akitiyan wa bikoṣe fun ìfẹ́ ayérayé Rẹ fun wa. A gbàdúrà pe yoo ran wa lọwọ láti da ìfẹ́ ailopin Rẹ padà ní orúkọ Jesu. Amin.

ÀṢÀRÒ LÁTI INÚ BÍBÉLÌ FÚN ỌSẸ KÍNNÍ
Mon.    25:    Ifẹ Ayeraye Ọlọrun (Jere. 31:3-6)
Tue.     26:    Baba Fẹ Ọmọ Gidigidi (Jn. 3:35,5:20; 17:24)
Wed.    27:    Ẹri Ifẹ Ọlọ́run (Jhn.3:16)
Thur.    28:   Titobi Ìfẹ́ Ọlọ́run (Romu 8:5-10)
Fri. Mar.29:   Fẹ́ràn Kristi Lati Fẹ́ràn Ìran Eniyan (Jn. 14:21,23)
Sat.       2:     Fẹ́ràn Gbogbo Eniyan Láìsí Ìyàtọ̀ (Mat. 5:44-48).

ÀṢÀRÒ FUN ÌFỌKÀNSÌN
1.    Ifẹ Ọlọ́run fún ènìyàn ko tii dúró lórí ìtọ́si (mimọ-ọn-se) ri. Eyi lo jẹ ìyàlẹ́nu julọ.
2.   Ifẹ ni Ọlọ́run. Ohun gbogbo tí o wa nipa Rẹ jẹ ìfẹ́; gbogbo ibaṣepọ Rẹ suyọ láti inú ifẹ, O si fihan fun gbogbo ènìyàn bákan naa. Ko si ọkànkan ninu wa ti o yẹ fun ìfẹ́ Rẹ̀, nitori nigba ti a si wa ninu ẹṣẹ wa, nigba naa ni O wa ra wa pada (Romu. 5:6,8), kii ṣe nigba ti a di olododo.
3.    Ko si ohun ti o dara nínú wa ti o yẹ fun ìfẹ́ Rẹ̀ (Isa. 64:6). Bi o ba jẹ pe a yẹ fun un ni, a ko ba ti pe e ni oore-ọ̀fẹ́.

ẸSẸ BIBELI FÚN ÌPINLẸ̀ Ẹ̀KỌ́ : Johanu 3:16-21

ILÉPA ATI ÀWỌN ERONGBA
ILEPA: Lati ran awọn onkawe lọwọ láti ni òye ìfẹ́ Ọlọ́run ti o kọjá àpèjúwe fun ìran ènìyàn sii.

ÀWỌN ERONGBA: Ni ipari ẹ̀kọ́ yii, àwọn akẹ́kọ̀ọ́ gbọ́dọ̀:
i.   ti ni oye kikun ki wọn si le ṣàlàyé bí ìfẹ́ Ọlọ́run ti pọ to fun ìran ènìyàn;
ii.  le ṣafihan ìfẹ́ gẹ́gẹ́ bí abuda pàtàkì tí gbogbo Kristẹni gbọ́dọ̀ ni, lai wo ti ipo, ilu ati ààyè;
iii. maa ṣafihan àwọn ami nini oye ati imisi sii lati fẹ́ràn Ọlọ́run àti àwọn ẹlòmíràn tọkàntọkàn;
iv. ti fẹ́sẹ múlẹ̀ nípasẹ̀ ìyàsọtọ (yíyẹ) láti ṣafihan ìfẹ́ Ọlọ́run si gbogbo aye.

IFAARA
ORÍSUN Ẹ̀KỌ́: ROMU 5:1-5; I KOR. 13:1-13, I JN. 4:7-16.
Ọpẹ ni fun Ọlọ́run fun ẹ̀kọ́ kẹta, Ihinrere Miran, tí a ṣẹ̀ṣẹ̀ parí. O fi oore-ọ̀fẹ́ ran wa lọwọ láti ṣe atupalẹ ọna elewu tí ayédèrú ihinrere ati awọn ajihinrere bẹẹ ni ibi gbogbo, ati pẹlu ninu ijọ. O ran wa lọwọ láti ṣe afiwe ihinrere tootọ pẹlu ohun tí Aposteli Pọ́ọ̀lù pe ni "ihinrere miran." Ipenija ibẹ naa ni pe ki a yẹra fun ìtànkalẹ ihinrere Kristi bẹẹ mọ ninu àti ni òde ìjọ. Ki Ọlọ́run ran wa lọwọ. Amin.

Ẹkọ kẹrin ni o kan bayii ni ọsẹ meji iwájú wa yii. Ọlọ́run n reti ki a sọ àsọyé láti lee ni oye kikun lori ifẹ Rẹ alailosunwọn fun ẹ̀dá ènìyàn. Koko naa ni Ifẹ Ọlọrun Fun Iran Eniyan. Ifẹ Ọlọ́run yoo ṣe àfihàn bii awojiji fun wa lati ri i boya a ni iru ifẹ tí o tọ tí o n fihan araye wi pe a ti bi wa nípasẹ̀ Ọlọ́run ati pe a jẹ ọmọ ẹyin Kristi nitòótọ́ (Jn. 3:3-5; 4:7-8). Eyii ni ọna kansoso tí a lee fi jere ẹlẹsẹ si ijọba Ọlọ́run. Aini eyi ti mu ki ọpọlọpọ ṣe ileri lati ma ni ohunkóhun ṣe pẹlu awọn kristẹni. Ìjíròrò wa lori koko yí yoo wa ni ibamu pẹlu iwe mimọ lọpọlọpọ.

Níwọ̀n tí o ti jẹ pe ipa ohun kan lori aye èniyàn duro lori bi onítọ̀hún ba ṣe ni òye rẹ̀ si, ọrọ pàtàkì inu koko ẹ̀kọ́ wa yii "IFẸ" nilo ṣíṣe ìtumọ̀ rẹ ni ranpẹ ti yoo lee fun wa ni òye ẹ̀kọ́ naa. ifẹ jẹ ìmọ̀lára wiwuni tí o jinlẹ fun ohunkan tabi ẹnikan, paapaa julọ ẹnikan ninu ẹbi rẹ tabi ọrẹ, ifẹ iya si awọn ọmọ rẹ. Laideena pẹnu, a le ri bi alaye inu iwe atúmọ̀ yii se ba bí Ọlọ́run ṣe sakawe ifẹ Rẹ fun Israeli, eniyan Rẹ mú (Isa. 49:15). Àpèjúwe ìfẹ́ ni inu Bibeli ni ỌLỌ́RUN, nitori pe ìfẹ́ ni Ọlọ́run (I Jn. 4:8). Ifẹ ni akoja ofin (Romu 13:10). Ifẹ ni a ṣe àpèjúwe rẹ pẹlu awọn amuyẹ ni inu I Korinti 13:1 siwaju sii gẹgẹ bi eyi ti o ga julọ laarin awọn akẹgbẹ rẹ.

Ki imọ tí ifẹ Ọlọ́run ru wa soke láti fẹ Ẹ àti àwọn ẹlòmíràn tọkàntọkàn titi de ogo Rẹ, nísinsìnyii ati titi lae. Amin.

IFAARA SI ÌPÍN KỌỌKAN :
Gẹ́gẹ́ bi ìṣe wa, eyi jẹ ẹ̀kọ́ ọlọsẹ meji pẹlu ipin meji gbòógì, I ati II. A tun ṣe atunpin ọ̀kọ̀ọ̀kan si ipin A ati B.

ÌPÍN KINNI: IFẸ ỌLỌ́RUN FI ARA HAN
Ipin yii jiroro lori abuda Ọlọ́run ti o ṣalábàápín pẹlu eniyan, ìyẹn ni ifẹ. Jesu tí o jẹ ọmọ naa ni olufara-gba ìfẹ́ Ọlọ́run ati òṣùwọ̀n ìfẹ́ Rẹ̀ fún ìran ènìyàn. Orisun gboogi meji fun isafihan ìfẹ́ Ọlọ́run Oore-ọ̀fẹ́ ati aanu ni a mẹ́nuba (sọ̀rọ̀ nípa rẹ). Ifẹ Ọlọ́run farahàn, o si rọrùn láti damọ (rí) ninu aye onigbagbọ ti o gbẹkẹle Ẹ.

ÌPÍN KEJI: OYE PUPỌ SI I NIPA IFẸ ATOKEWA
Ipin yii kan n gbìyànjú láti ṣàpèjúwe ohun ti ìfẹ́ Ọlọ́run jẹ ni, pẹlu ìfọkànsì pe ìfẹ́ Rẹ kọja àpèjúwe, ṣùgbọ́n pe oye wa bí o tilẹ kere jọjọ, ó gbọ́dọ̀ ti wa ninu sisafihan ìfẹ́ tòótọ́ fun gbogbo ènìyàn. Orisirisi ìfẹ́ ni o wa ti awọn eniyan si n fi si ìṣe laye, ṣùgbọ́n iru ìfẹ́ tí Ọlọ́run wa jẹ ailẹtan, ko dalori didara tabi idakeji ẹni tí a fẹ́ràn naa. Ìpín naa pari pẹlu igbani níyànjú (ọrọ ìyànjú) pe kí a fẹ́ gbogbo ènìyàn àti àwọn ọ̀tá laisi imọtara-ẹni-nikan ati pẹlu ifara-ẹni-ji gẹgẹ bi ọkan pàtàki lara àbájáde (eredi) ifẹ Kristi fun àwọn Kristẹni.

KÓKÓ Ẹ̀KỌ́
I.    IFẸ ỌLỌ́RUN FI ARA HAN
      A.   IFẸ: ÀBÙDÁ ỌLỌ́RUN
      B.   IFẸ: AMUYẸ KRISTẸNI
II.   ÒYE PUPỌ SII NIPA IFẸ ATOKEWA
      A.  IFẸ KRISTI NI A TÚBỌ̀ ṢE ÀLÀYÉ
      B.  IFẸ KRISTI: Ẹ̀KỌ́ RẸ FUN ÀWỌN KRISTẸNI

ITUPALẸ Ẹ̀KỌ́
Mar. 3, 2019
I.   IFẸ ỌLỌ́RUN FI ARA HAN (I Korinti 13:1-13, I Jhn. 4:7-9)
Ọlọrun wa lati fi ìfẹ́ Rẹ̀ sì ìṣe dipo sísọ ọ lẹ́nu lasan. Irufẹ ìfẹ́ Rẹ̀ farahàn nipa awọn ìhùwàsí (ìṣe) tí O safihan sì àwọn ẹlòmíràn laisi imọtara-ẹni-nikan pẹlu erongba ati mu wọn dara sii.

A.   IFẸ: ÀBÙDÁ ỌLỌ́RUN (I Jhn.4:7-9)
Ẹniti ko ba ni ifẹ, ko mọ Ọlọ́run, nitori pe ìfẹ́ ni Ọlọ́run (ẹsẹ. 8)
i.  A pin awọn abuda Ọlọ́run sì meji: Àbùdá tí n ran (eyi ti O lee se àjọpín rẹ pẹlu ènìyàn) Àbùdá tí ko lee ran (awọn ti ko lee ṣe àjọpín rẹ).
ii. A gbọ́dọ̀ ṣe awari erongba wa nipa Ọlọ́run láti inu ìfihàn rẹ pàtàkì tí o ti fifun wa Funrarẹ. Ọlọrun ni ifẹ (I Jhn. 4:8-16) jẹ isafihan kedere tí iwa ìfẹ́ Ọlọ́run. Ifẹ jẹ àbùdá Ọlọ́run ti o ga julọ, àbùdá kanṣoṣo ti ohun gbogbo rò mọ́ pẹ́kípẹ́kí.
iii. Ifẹ Ọlọ́run kọja inu rere tabi ififunni. Wiwuni see fihan sì awọn ẹda alainiye-ninu, ṣùgbọ́n ìfẹ́ dojúkọ ẹ̀dá ènìyàn. Ifẹ ayérayé Ọlọ́run ko waye lasan ri laisi olugba rẹ (Jhn. 17:23-26).
iv. Ninu ihinrere ti Johanu, ifẹ Baba fun ọmọ nikan ni ẹri pe ifẹ jẹ àbùdá ti o di dandan fun Ọlọ́run (Jhn. 3:16, 35; 5:20; 10:17; 15:9, 27; 23).
v.  Bẹẹni, Ọmọ ni olugba ifẹ Baba, síbẹ̀ o si ni eniyan lọkan bii olugba ìfẹ́ Rẹ. Jesu ni ìmọ̀lára tí o jinlẹ lori ìfẹ́ baba fun Oun gẹgẹbi ìpilẹ̀ṣẹ̀ ati awokọṣe ìfẹ́ Rẹ si awọn eniyan (Jhn. 14:21-23).
vi. Ìrí Ọlọ́run meji ni o sunmọ ìfẹ́ daradara. Ekinni ni níní òye pe Ọlọrun jẹ Ọlọ́run OORE-ỌFẸ. Oore-ọ̀fẹ́ Ọlọ́run duro fun ipa pataki kan ninu ìfẹ́ Ọlọ́run, ojurere Rẹ si awọn ti ko tọ si. Nítorí naa, a lo o fun isẹ ìgbàlà Ọlọ́run ninu Kristi. Oore-ọ̀fẹ́ ni fifun eniyan ni ohun tí ko lẹtọ si: Idariji ati Ìgbàlà.
vii. Ifẹ tí o kun fun oore-ọ̀fẹ́ ti Ọlọ́run ani si eniyan ẹlẹsẹ ni a ṣatẹnu mọ rẹ tagbara tagbara ninu májẹ̀mú méjèèjì (fun àpẹẹrẹ Eks. 34:6; Isa. 63:9; Jere. 31:3; Jhn. 3:16; I Jhn. 4:10). Ifẹ Ọlọ́run ni ipinlẹsẹ ohun gbogbo ti O ti ṣe ati ti O n ṣe.
viii.Iri kejì ìfẹ́ Ọlọ́run ni AANU. Gbongbo ìtumọ̀ rẹ ni ikaanu, nitori naa o sunmọ ìfẹ́ pẹ́kípẹ́kí. Aanu naa ko ṣeé ya kuro lara oore-ọ̀fẹ́, ṣùgbọ́n o sunmọ ododo gigi. Nigbati a ba ṣe agbeyẹwo ìdájọ́ ododo Ọlọ́run ni aanu Rẹ yoo di (ko see yẹra fun) fifarahan yekeyeke/kedere. O n nawọ aanu sì awọn ti a ba da lẹbi nitori aanu jẹ ara ìṣẹ́da Rẹ bii ododo. Ẹtọ eniyan a maa fa sẹhin bi aanu ba ti fa sẹhin: Idajọ.
ix. Ifẹ jẹ ẹ̀yà Ọlọ́run ti o yẹ ki o yẹ ki o safihan gbogbo onigbagbọ gẹgẹ bi aṣojú Ọlọ́run laye; lepa, ni in ki o si safihan ìfẹ́ koda si àwọn tí ko yẹ (tọ) fun un. Gẹgẹ bi aṣojú Rẹ, a gbọdọ yẹra fun ìfẹ́kufẹ ti ara lati tẹ Ẹni ti o fẹ wa lọrun (I Pet. 2:11).

B.   IFẸ: AMUYẸ KRISTẸNI (I Kor. 13:1-13)
Njẹ nísinsìnyí, igbagbọ, ireti àti ìfẹ́ n bẹ, awọn mẹta yi, ṣùgbọ́n eyiti o tobi ju ninu wọn ni ifẹ (ẹsẹ 13).
i.   I Kor. 13 fihan pe ìfẹ́ ni o ga julọ ninu àwọn ohun amuyẹ tí o lee fa awọn eniyan wa si ìjọ. Iru ìfẹ́ wo?
ii.  Ọlọrun ko fẹ́ràn lasan, ṣùgbọ́n Oun gan-An ni ifẹ. Nítorí naa, Oun ni orisun ti gbogbo ìfẹ́ tòótọ́ ti san wa.
iii. Ifẹ Kristi ni o ga ju nitori pe;
    * O jẹ irufẹ ìfẹ́ tí Ọlọrun, orisun iye ati Aṣẹ̀dá ọrun àti ayé (Ps. 24:11, Jhn 4:8).
    * Oun ni akọjá ofin (Romu 13:10, wo Jhn. 14:15-23) ati
    * Ko lee kuna lae (I Kor. 13:8). Oun gan an ni ẹ̀dá Ọlọ́run ti ìyọnu rẹ kii kuna (Ps. 78:38, Jere. 3:22).
iv. Gbogbo ofin ni a ṣe akopọ rẹ sinu ìfẹ́, kii ṣe bii pe a so awọn amuyẹ tí o ku di ainilari, ṣùgbọ́n ni ìrònú wi pe ìfẹ́ ni ipilẹ àti pe yoo ṣe atọkùn gbigbọran si awọn ti o ku (Mat. 5:43-48,22:37-39,Jhn. 14:15,21; 15:12-14; Romu 13:8; I Kor. 13:1-13; Gal. 5:14).
v.  Ifẹ ni olórí idanwo jijẹ ọmọlẹhin gẹgẹ bi Kristẹni (Mat. 5:41; Jhn. 13:35; I Jhn. 3:14). Oun ni ipilẹ erongba tí o ga julọ fun iwa ọmọlúwàbí. Bi gbogbo ẹṣẹ ti ní gbongbo wọn ninu imọ-tara-ẹni nikan, bẹẹni gbogbo amuyẹ rere jade wa lati inu ìfẹ́.
vi. Ifẹ Kristẹni ti o jade lati inu iwa mímọ ni ifẹ ti o ni ọpẹ (I Jhn. 4:9,10) ìfẹ́ yii ni a mu ki o ṣeṣe nipa oore-ọ̀fẹ́ atokewa. O jẹ eso ti Ẹ̀mí.
vii. Kristẹni, maa n da yàtọ̀ nibikibi nipasẹ isafihan ìfẹ́ tòótọ́, eso igi Kristẹni. Tálẹ́ńtì tabi ẹ̀bùn ti a ba safihan laisi ìfẹ́ tòótọ́ tí Ọlọ́run jẹ ifisofo danu (I Kor. 13:2).

ÀWỌN Ẹ̀KỌ́ TI A RI KỌ
1.   Àbùdá Ọlọ́run gbòógì ni ifẹ, ifẹ ni O da le lori. Ifẹ Rẹ ko lakawe.
2.   Ifẹ ni o n fi iyatọ han laarin onigbagbọ tòótọ́ àti alafẹnujẹ. Njẹ o n ṣe afihan ìfẹ́ Kristi?

ÌṢẸ́ ṢÍṢE
Ṣe àkàwé bí ìfẹ́ Ọlọ́run ṣe to ni ìwòye Johanu 3:16 ati Romu 5:6-8. Kini o yẹ ki o jẹ ìdáhùn wa si eyi?

kaa awon eko ile ojo isinmi ti ateyin wa ni ibi yi

ÌDÁHÙN TI A DÁBÀÁ FÚN IṢẸ́ ṢÍṢE
i.   Ọlọrun fi ìfẹ́ han si aye tí ko yẹ fun ìfẹ́.
ii.  Ifẹ Rẹ jẹ ti ifara-ẹni-rúbọ ati ti aimọ-tara-ẹni-nìkan.
iii. Ko ronu nipa ọ̀tẹ̀ eniyan lodi si I, O tu ìfẹ́ Rẹ̀ jáde nípasẹ̀ ọmọ bibi Rẹ kan ṣoṣo.
iv. Nígbà tí eniyan ti di ẹni egbe tí a ko le rapada, Ọlọ́run ṣi fi ìfẹ́ han.
v.  Ninu ipo àìní Oluranlọwọ eniyan, Ọlọ́run ran an lọwọ.
vi. Ọlọ́run faaye gba Ọmọ Rẹ aláiṣẹ láti ku fún eniyan ẹlẹsẹ ti o tun jẹ ẹni egbe; O san gbese ti ko jẹ pẹlu ẹ̀mí Rẹ.
vii. Ifẹ Ọlọ́run pọ de ayérayé ko si ṣe e ṣàpèjúwe.
ÌJỌ ÀPỌ́SÍTÉLÌ KRISTI Ẹ̀KỌ́ ỌJỌ́ ÌSINMI. FUN March 3rd, 2019. Eto Ayeraye Olorun Fun Eniyan. Ẹ̀KỌ́ KẸRIN: IFẸ ỌLỌ́RUN FUN ÌRAN ENIYAN ÌJỌ ÀPỌ́SÍTÉLÌ KRISTI  Ẹ̀KỌ́ ỌJỌ́ ÌSINMI. FUN  March 3rd, 2019. Eto Ayeraye Olorun Fun Eniyan.  Ẹ̀KỌ́ KẸRIN: IFẸ ỌLỌ́RUN FUN ÌRAN ENIYAN Reviewed by Muyiwa Abodunrin (Muyilight) on March 03, 2019 Rating: 5

No comments:

Powered by Blogger.