ÌJỌ ÀPỌ́SÍTÉLÌ KRISTI Ẹ̀KỌ́ ILÉ Ẹ̀KỌ́ ỌJỌ́ ÌSINMI March 24th, 2019. AKORI - Eto Ayeraye Olorun Fun Eniyan.

ÌJỌ ÀPỌ́SÍTÉLÌ KRISTI  Ẹ̀KỌ́ ILÉ Ẹ̀KỌ́ ỌJỌ́ ÌSINMI March 24th, 2019. AKORI - Eto Ayeraye Olorun Fun Eniyan.ÌJỌ ÀPỌ́SÍTÉLÌ KRISTI
Ẹ̀KỌ́ ILÉ Ẹ̀KỌ́ ỌJỌ́ ÌSINMI.
Eto Ayeraye Olorun Fun Eniyan.
March 24th, 2019.


II.   ÌJỌBA ỌLỌ́RUN NI ÀWỌN Ẹ̀KỌ́ IWA RERE (Matt. 5:7; Jákọ́bù 1:21-27)
Iwa rere nibi yii túmọ̀ si bi a ti n huwa, ìyẹn ni pe ilana iwa to n ṣàkóso iwa ti o tọ fun eniyan tabi ẹgbẹ́ kan. Ibugbe ofin Ọlọ́run, ìyẹn ni pe lori awọn ti wọn ti gba ẹbun Rẹ ninu Kristi, ni ilana eto iwa rere ti o yatọ to n ṣàkóso iwa ti o tọ fun awọn eniyan Rẹ (awọn Kristẹni). Gbogbo orílẹ̀ ede ni o ni ofin tìrẹ tí o ni awọn ofin to n ṣàkóso awọn iwa olori ati ọmọ-ẹyin. Kin-ni awọn ẹkọ iwa rere wọnyii?

A.   A SAFIHAN ÀWỌN Ẹ̀KỌ́ IWA RERE TI AYÉRAYÉ SÍWÁJÚ SII (Matt. 5-7)
Ṣùgbọ́n ẹ tete maa wa ijọba Ọlọ́run na, ati ododo re; gbogbo nnkan wọnyi ni a o si fi kun fun yin (Matt. 6:33).

i.   5:17-20: Ṣíṣetán lati pamọ, lati gbọ́ràn àti lati kọ Ọrọ Ọlọ́run. Kristi ko nifẹẹ si aseleke awọn agbẹsinkari, bikose awọn ti a ti fọwọ́ tọ ọkan wọn, ti wọn n finu-findọ pa ọrọ naa mọ pẹlu òtítọ́ ti wọn si fi n kọ awọn ẹlòmíràn (Matt. 5:20). Kin ni ipele ododo rẹ?
ii.  5:21-49: Nini ati dídúró nínú ọkan tó jinlẹ ati ibasepọ ẹ̀mí òtítọ́ eyi to maa n nii àfojúsùn iwa àpẹẹrẹ to dara julọ ti Ọlọrun. Ohun tí o ṣe pàtàkì julọ ni ki ọkan wa ni ipo ti o dara eyi tó maa n ru ilaja soke tó si maa n funni ni ero tí o tọ si ìdáríjì (ẹsẹ 26-27), nini ibawi (ẹ̀kọ́) ninu ara Kristi (ẹsẹ 27-30), ikọsilẹ (ẹsẹ 31-32), ibura (ẹsẹ 33-37), ìgbẹ̀san (ẹsẹ 38-42), àti fifẹ ọmọnìkejì (ẹsẹ 43-48). Laisi ibasepọ tòótọ́ pẹlu Kristi awọn wọnyi le di iruju (wo Rom. 8:11).
iii. 6:19-34: Dídúró nínú àpẹẹrẹ idapọ onìfọkànsìn láti rí aridaju ifẹ ijọba naa (Ọlọ́run). Bi eniyan ko ba ni ikiyesara, eniyan le wọnú iwa ati ìṣe awọn Farisi ni ṣíṣe àfihàn ara ẹni ju Ọlọ́run lọ nínú àdúrà. Ipe Kristi fun àpẹẹrẹ ìfọkànsìn (àdúrà) oníwà-bí-Ọlọ́run to maa n pe fun ìfẹ́ Ọlọ́run ni o gbọdọ jẹ wa logun julọ nigba ti a ba n ṣe ìtọrẹ-aanu (ẹsẹ 1-4), àpẹẹrẹ ọna ti a n gba gba àdúrà (ẹsẹ 5-15), ati bí a ti n ṣe nínú àdúrà (ẹsẹ 16-18).
iv. 6:19-34: Dídúró nínú àfojúsùn fun ọrun. Iwa ọkan tí ẹmi àti ipongbẹ ni yoo sọ bi ènìyàn ṣe jinlẹ to ati bi ipa rẹ ṣe to. Ile aye wa isinsin yii ti laju si kíko ọrọ-aye jọ. Lati igba yii lọ, a nilo iwa ọkan Olúwa lati ni àfojúsùn ni lilepa awọn ìṣúra ti ọrun.
v.  7:1-14: Gbigbe igbe aye àwọn ohun ti o ṣe pàtàkì si Ọlọ́run. Ni ọpọ igba, ni aarin awa Kristẹni, a maa fiyesi bi awọn ẹlòmíràn ṣe n gbe igbe aye wọn tàbí bí wọn ṣe n jọsin pupọ ju ọrọ ara wa lọ, eyi to si maa n sọ wa di alágàbàgebè ni igba miiran pẹ̀lú igbe aye wa. Nítorí naa, kiyesi isẹ rẹ sì awọn ẹlòmíràn ki o ye e ṣe idajọ lọ́nà aitọ (wo 7:21).
vi.  Jesu fẹ́ ki awọn ọmọ ẹyin Rẹ o kọ́kọ́ jijadu fun ìjọba Ọrun àti òdodo rẹ na, yoo ṣètọ́jú / pese awọn ohun ti a nilo. Nigba ti a ba gbọ́ràn si I lẹ́nu tí a sì gbẹkẹle E, ohun gbogbo yoo maa lọ déédéé.

ÀWỌN Ẹ̀KỌ́ IWA RERE TI AYÉRAYÉ: ISILETI (Jákọ́bù 1:21-27)
Ọrẹ mi ni ẹyin ṣe, bi ẹ ba ṣe ohun tí Emi palasẹ fun yin (Jn. 15:15).
i.   Jak. 1:22 Síwájú sii: Jákọ́bù ń gba wa níyànjú pe ki a máa fi ẹ̀kọ́ iwa rere tí ìjọba (Ọlọ́run) si ìṣe.
ii.  Jesu Kristi Olúwa wa gba wa níyànjú láti tẹti gbọ, lati gba, lati fi si ọkan àti láti ṣe gbogbo ẹ̀kọ́ iwa rere tí ìjọba (Ọlọ́run) lati jẹ ọmọ ìbílẹ̀ ijọba ayérayé Rẹ (Jn. 15:14). Eyi pe fun ṣíṣe ìpinnu ọlọ́gbọ́n.
iii. Mk. 7:24-27: Gba a, yoo si jẹ ibukun fun ọkan rẹ nínu ire ije Kristẹni gẹgẹ bi o ti n gbaradi nípasẹ̀ rẹ fun ẹ̀kọ́ iwa rere ti ayérayé tí o ti pongbẹ rẹ.
iv. Ijọba ọrun ki ìṣe ibi kankan laye yii bikose ilẹ̀ ọba ti ẹmi nibi ti Ọlọ́run ti n jọba, tí a o ti pin ninu iye ayérayé Rẹ. A ti dara pọ mọ ijọba naa nigba ti a ba gba Jesu ni Olúwa.
v.  2 Kọr. 5:18-19: Ṣe o da ọ loju pe Kristi jẹ Olùgbàlà àti Oluwa rẹ ṣáájú sísọrọ nipa ẹ̀kọ́ ìwà rere tí ìjọba (Ọlọ́run)? Jijẹ ọmọ ìbílẹ̀ rẹ n pese rẹ fún igbe ayé tí ó yẹ fun ẹ̀kọ́ iwa rere ti ijọba naa. Ṣe ilaja pẹlu Kristi lonii (wo Efe. 4:1).
vi.  Awọn ẹkọ iwa rere tí Ọrun gba pé ki a pa awọn ofin Ọlọ́run mọ de góńgó. Bi ìwọ yoo ba jẹ ọrẹ Ọlọ́run ti o si fẹ ba A jọba ní ayérayé, o gbọdọ gbọ́ràn sì awọn ofin Ọlọ́run ni kikun.

ÀWỌN Ẹ̀KỌ́ TI A RI KỌ
1.  O ko le gbe aye rẹ fun Ọlọ́run bi o se wu ọ. Awọn ọna mimọ Rẹ gbọdọ ṣe pàtàkì laye rẹ.
2. Idi ti a fi n tẹtisilẹ tí a si n fi Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run sì ìṣe loorekoore n pe fun fifurugbin ọrọ naa nígbà gbogbo, nígbàkúùgbà tí a ba ni ore-ọfẹ rẹ.

ÀWỌN ÌBÉÈRÈ
1.   Kin ni ẹkọ iwa rere ayérayé? Dárúkọ alakalẹ ipilẹ ẹ̀kọ́ ijọba Ọlọ́run to ṣe koko mẹta.
2.  Ṣàlàyé ni kúkúrú àwọn ẹ̀kọ́ iwa rere ti ijọba Ọlọ́run.

ÀWỌN ÌDÁHÙN TI A DÁBÀÁ FÚN ÀWỌN ÌBÉÈRÈ :
ÌDÁHÙN SI ÌBÉÈRÈ KÍNNÍ
i.   Awọn ẹkọ iwa rere ti ayérayé jẹ àkójọpọ awọn ìlànà àti òfin tó n ṣàkóso Kristẹni láti yẹ fun iye ayérayé.
ii.  Lọ si ipin IB fun awọn koko miiran.
iii. Si awọn ìpilẹ̀ṣẹ̀ ẹ̀kọ́ ijọba Ọ̀run to ṣe koko lọ si ipin IA. Awọn ni
    a.  Ṣíṣe ifẹ Baba wa ti ń bẹ ní Ọ̀run ti a mọ nípa sisawari ofin Oluwa (Ọrọ Ọlọ́run), sisasaro ninu rẹ, àti sisalai jẹ ko kuro lẹ́nu wa.
b. Sisawari ijọba Ọlọ́run àti òdodo rẹ na.
c. Fifarada idanwo inúnibíni

ÌDÁHÙN SI ÌBÉÈRÈ KEJÌ
i.  Lọ si ipin kejì.

ÀMÚLÒ FÚN ÌGBÉ AYÉ ẸNI :
Ni akoko iṣẹ-ìránṣẹ́ Jesu, nígbà tí o wa laye, ọdọmọkùnrin kan wa si ọdọ Rẹ, láti béèrè ìbéèrè kan tí o ṣe pàtàkì. 'Ohun rere wo ni mo gbọdọ ṣe lati ri iye ayérayé?' ìbéèrè ti o dara nìyẹn. Jesu dahun, Ẹni rere kan ni o wa. Bi o ba fẹ ni iye ayérayé, gbọ́ràn si àwọn òfin naa. Ọkùnrin béèrè síwájú sii, Àwọn wo. Jesu tete ka awọn ofin kan silẹ èyí ti ọdọmọkùnrin naa tete fi idahun sii pe oun ti n ṣe wọn. Jesu wa sọ fun un pe bi o ba fẹ jẹ ẹni pipe, ki o lọ ta gbogbo ini rẹ, ki o si pin owo rẹ fun awọn alaini. Nigba naa, ni o tọ lati wa ki o ki o si tẹle E. Ọdọmọkùnrin naa lọ pẹlu ibanujẹ. Njẹ o jẹ ẹni pipe bí Baba wa ni Ọrun ti jẹ pipe? Fun ẹnikẹ́ni lati wọ ibi ìsinmi ayérayé. O gbọdọ tẹle awọn ofin ati ilana ti o n tọ ni sì ijọba Ọrun (Mat. 5:48). Njẹ ẹnikẹ́ni ha le gba ade lai ṣe pé o sare ni ibamu pẹlu awọn ofin náà?

IGUNLẸ
Gbigbe ni ibamu pẹlu àwọn ẹ̀kọ́ iwa rere ayérayé ni ọpagun gbogbo ẹni to ba n fẹ́ lati wọ iye ayérayé. Ninu ẹ̀kọ́ ti a ṣẹṣẹ pari yii, a ti ri i pe ijọba Ọlọ́run ni awọn ẹkọ, awọn ẹkọ, awọn ẹkọ iwa rere ti o yatọ. Àbájáde (ìtumọ̀) rẹ ni pe a ko le gbe igbe aye wa bi a ti fẹ́, bi a o ba wọ ibi isinmi ayérayé. Fifi awọn ẹkọ iwa rere yii si ìṣe nikan ni yoo mu wa pe ni ibamu pẹlu osunwọn Rẹ. Oye ati oore-ọfẹ àtọ̀runwá ti ẹ̀kọ́ yi ni lọkan láti gbìn sínú wa yoo wọnú ọkan wa lọ pátápátá yoo si gbìlẹ nibẹ. Amin.

ka awon eko ti ti ateyin wa ni ibiyi

ÀṢÀRÒ LÁTI INÚ BÍBÉLÌ FÚN ỌSẸ IKEJI
Mon.    18:     Ijọba Naa Ninu Àwòrán (Lk. 1:49-53)
Tue.     19:     Ki Yoo Ri Bẹ Laarin Yin (Mat. 20:26)
Wed.    20:     O Jẹ Ilana Ìṣọ̀kan (Mat. 12:25-28)
Thur.    21:    O Jẹ Ilana Bíbéèrè (Mat. 7:7-8)
Fri.       22:    O Jẹ Ilana Ti Ìjọsìn (Mat. 6:1-8)
Sat.      23:     O Jẹ Ilana Aìṣe Àníyàn Ọkan (Lk. 12:22-34).
ÌJỌ ÀPỌ́SÍTÉLÌ KRISTI Ẹ̀KỌ́ ILÉ Ẹ̀KỌ́ ỌJỌ́ ÌSINMI March 24th, 2019. AKORI - Eto Ayeraye Olorun Fun Eniyan. ÌJỌ ÀPỌ́SÍTÉLÌ KRISTI  Ẹ̀KỌ́ ILÉ Ẹ̀KỌ́ ỌJỌ́ ÌSINMI March 24th, 2019. AKORI - Eto Ayeraye Olorun Fun Eniyan. Reviewed by Muyiwa Abodunrin (Muyilight) on March 23, 2019 Rating: 5

No comments:

Powered by Blogger.