ÌJỌ ÀPỌ́SÍTÉLÌ KRISTI Ẹ̀KỌ́ ILÉ Ẹ̀KỌ́ ỌJỌ́ ÌSINMI Eto Ayeraye Olorun Fun Eniyan. March 17th, 2019 : Ẹ̀KỌ́ KARUN UN, AKORI - ÀWỌN Ẹ̀KỌ́ IWA RERE TI AYÉRAYÉ

ÌJỌ ÀPỌ́SÍTÉLÌ KRISTI  Ẹ̀KỌ́ ILÉ Ẹ̀KỌ́ ỌJỌ́ ÌSINMI  Eto Ayeraye Olorun Fun Eniyan.  March 17th, 2019 : Ẹ̀KỌ́ KARUN UN, AKORI - ÀWỌN Ẹ̀KỌ́ IWA RERE TI AYÉRAYÉ
ÌJỌ ÀPỌ́SÍTÉLÌ KRISTI
Ẹ̀KỌ́ ILÉ Ẹ̀KỌ́ ỌJỌ́ ÌSINMI
Eto Ayeraye Olorun Fun Eniyan.
March 17th, 2019.

Ẹ̀KỌ́ KARUN UN.
ÀWỌN Ẹ̀KỌ́ IWA RERE TI AYÉRAYÉ

Iwa mimọ ni kọ́kọ́rọ́ / ọna kan ṣoṣo si Ọrun. Laisi rẹ ayérayé pẹlu Kristi ni ọrun ko le ṣeṣe láéláé.

AKỌSÓRÍ
Ki ìjọba Rẹ de; Ifẹ tiRẹ ni ki a ṣe, bii ti ọrun, bẹẹni ni aye (Matiu 6:10)

ÀLÀYÉ KÚKÚRÚ
Jesu Kristi n kọ awọn ọmọ-ẹyin bi a ti n gbàdúrà ti Baba le tẹ́wọ́gba lodi ṣi awọn ẹkọ awọn Farasi ti o fẹ́ràn láti maa duro ninu Ṣínagọgu àti ní àwọn kọrọ àdúgbò lati gbàdúrà, loju gbogbo eniyan. O tẹsiwaju lati kọ wọn ni awọn ohun ti wọn gbọ́dọ̀ ṣe ninu adura:
*  Wọ inu ile rẹ lọ lati gbàdúrà
*  Ti ilẹkun rẹ
*  Gbàdúrà si Baba rẹ ni ikọkọ.
*  Maṣe ṣe awitunwi asan.

Ni ọna kan naa yii, O kọ wọn ni iru adura ti o jẹ ìtẹ́wọ́gbà lọdọ Baba naa ni ẹsẹ 9-13. Ṣùgbọ́n atẹnumọ wa wan i ẹsẹ 10. Ki ìjọba Rẹ de, ifẹ tíRẹ ni ki a ṣe, bi ti ọrun bẹẹni ni aye. A o ṣàgbéyẹ̀wò awọn ọrọ ti o wa ni ẹsẹ yii daradara.

Jesu n kọ àwọn ọmọ lẹ́yìn Rẹ, O si n kọ gbogbo Kristẹni pẹlu pe ki a maa gbàdúrà nigba gbogbo pe ki ijọba Ọlọ́run o de. Gbogbo Kristẹni gbọdọ maa gbádura si Ọlọ́run pe ki ìjọba Rẹ o de bii Danieli ni 9:2, ṣe tun gbàdúrà fun itusilẹ Israeli. A gbàdúrà pe ki ijọba Ọlọ́run o de ki gbogbo eniyan o le ni oye Ọmọ naa, ki wọn si gba A gẹgẹ bi Oluwa ati Olùgbàlà wọn, ki wọn si maa gbe igbe aye Kristẹni. Bakan naa, a tun gbọdọ maa gbádura pe ìfẹ́ Ọlọ́run ni ki a ṣe ni aye bi wọn ti n ṣe. Ìyẹn ni pe, Kristẹni gbọdọ gbọ́ràn si àwọn àṣẹ ijọba Ọ̀run ki o maa sọ fun Ọlọ́run lọ́nà taara pe ki O ṣe bi o ti fẹ pẹlu oun.

ÀṢÀRÒ LATI INÚ BÍBÉLÌ FUN ỌṢẸ KINNI
Mon.    11:    A Gbọdọ Maa Pongbẹ Fun Ọlọ́run Kíkankíkan (Orin Daf. 42:1-2).
Tue.     12:    Ofin Ijọba Ọlọ́run Gbọdọ Maa Ṣàkóso Wa (Mat. 7:21)
Wed.    13:  Eso Ijọba Ọlọ́run Ni Ododo (Mat. 21:42).
Thur.   14:  Ipilẹsẹ Ẹ̀kọ Ijọba Ọlọ́run Ni Ododo (Heb. 1:18)
Fri.      15:  Ọlọ́run Kọja Ipele Ododo Àwọn Farisi (Mat. 5:20)
Sat.     16:  Ọkàn Ọlọ́run: Amuyẹ Ijọba to Ga Julọ (Mat. 19:16-17).

ÀṢÀRÒ FUN ÌFỌKÀNSÌN
1.  Ọlọ́run ti ṣe agbekalẹ gbedeke tí gbogbo ẹni ti n pongbẹ fun ìjọba ayérayé Rẹ gbọdọ tẹle laigbọjẹgẹ. Ko si ọna meji.
2.  Titẹle Ọlọ́run laigbọjẹgẹ jẹ gbigbe igbe aye ibamu pẹlu osunwọn iwa-mimọ Rẹ. Oun ni kọ́kọ́rọ́ si iye àìnípẹ̀kun, o si ṣeeṣe nipasẹ Jesu nikan, ọna kan ṣoṣo si ọdọ Baba iye ayérayé naa.
3.  Tóóró ni ọna ti o lọ si ọdọ Baba naa; awọn olododo tí a sọ di olódodo ninu Kristi nikan ni o le ṣàṣeyọrí ninu títọ ipa ọna iye ayérayé.

ẸSẸ BÍBÉLÌ FUN IPILẸ Ẹ̀KỌ́ : 1 Peteru 3:20

ILEPA ATI AWỌN ERONGBA
ILEPA:  Lati ṣàwárí ilana ati ofin gbígbé igbe aye Kristẹni tí yoo yọrí sí iye àìnípẹ̀kun.

ÀWỌN ERONGBA: Ni ipari ẹ̀kọ́ ọlọsẹ meji yii, àwọn akẹ́kọ̀ọ́ gbọ́dọ̀:
i.   le tọkasi ìlànà àti àwọn òfin ijọba Ọrun;
ii.  ti maa safihan àwọn ami dide ijọba Ọlọ́run pe o ṣe pàtàkì si wọn;
iii. ti gbe awọn eto wọn kalẹ bi o ti tọ, pẹlu nini ifẹ Ọlọ́run ninu Kristi gẹgẹ bi ohun àkọ́kọ́;
iv. ti gbọ́ràn si awọn ofin Ọlọ́run sii.

IFAARA
ORÍSUN Ẹ̀KỌ́: MATEU 5-7; HEBERU 1:8-9; JÁKỌ́BÙ 1:21-27.
Ni ẹ̀kọ́ tí o kọja ìkẹrin ninu ọwọ yii, a ṣe agbeyẹwo ailakawe ifẹ Ọlọ́run fun ẹda iran eniyan. A gbìyànjú awọn alaye kan ti o si jẹ ki a mọ ni ipari ẹ̀kọ́ naa pe ifẹ Ọlọ́run ninu Kristi san ki a ni iriri rẹ ju afẹnusọ lọ, niwọn igba ti Ọlọrun ko ṣàlàyé bi ìfẹ́ tí jẹ ṣùgbọ́n ti o safihan rẹ ninu ìṣe. Bi ìfẹ́ yii ṣe ga to ni a ri ninu Jesu Oluwa wa. Ki Ọlọ́run ma jẹ ki awa tí a ti ṣàwárí ìfẹ́ yii pàdánù rẹ. Ki awọn ti wọn ko si tii ni iriri rẹ síbẹ̀ gba ina ìràpadà ti Kristi mu wa. Amin.

Bi a ti n wọnú Ẹkọ Karùn-ún, o ṣe koko ki a tọ́ka si i pe awọn ẹkọ iwa rere ti ayérayé, fun eredi ẹ̀kọ́ yii n tọka si ìtọ́nisọ́nà ilana ẹ̀mí ati ẹ̀kọ́ iwa ti ijọba Ọlọ́run ninu ayérayé tí Jesu ṣeleri fun awọn ọmọlẹ́yìn Rẹ (Jn. 14).

Kí I ṣe wi pé Jesu kò ni ifẹ si ẹsin àṣeleke, ẹmi tabi ìrúbọ ti ko ni ọkan ibasepọ pẹlu Rẹ nikan (May. 5:17), ṣùgbọ́n o pe àwọn ọmọlẹ́yìn Rẹ fun ìfọkànsìn to le koko ati gbígbẹkẹle Ọlọ́run, ti wọn ri pe lotitọ wọn wa fun Un (Jesu) ki sii ṣe fun awọn tikalara wọn ni aye isinsinyii, lati le ri aridaju ipilẹ rere fun ayérayé. Jesu la oju awọn ọmọ ẹ̀yìn Rẹ si ọna ìgbésí-ayé kan gboogi ninu eyi ti wọn ni lati maa rin gẹgẹ bi ajogún ijọba Rẹ.

Gẹ́gẹ́ bi ikorajọpọ, idasilẹ / ilé-ẹ̀kọ́ tabi ẹgbẹ́ yòówù ninu aye tí ní ẹ̀kọ́ iwa rere (ofin ati ilana) ti wọn n ṣamulo lori eyi ti o si pọndandan fun ìtẹ́wọ́gbà, ifisiṣe ati ìfọwọsi, bẹẹ ni ijọba Ọlọ́run nibi ti awọn Kristẹni yoo ti lo ayérayé wọn naa ni ti rẹ, eyi ti awọn olùgbé gbọdọ maa mulo. Ni ṣíṣe àkíyèsí awọn ẹkọ iwa rere tí ìjọba ayérayé, a o maa ṣàgbéyẹ̀wò iwe ihinrere ti Mateu, ori 5-7, ki Ọlọ́run ran wa lọwọ.

IFAARA SI ÌPÍN KỌ̀Ọ̀KAN :
A pin ẹ̀kọ́ ọlọsẹ yii si ipin meji I ati II; nigba ti a tun pin ipin kọọkan si ipa meji A ati B.

ÌPÍN KÍNNÍ: ÌJỌBA ỌLỌ́RUN YÀTỌ̀
Ijọba Ọlọ́run yàtọ̀ nitori pe, o sọ̀rọ̀ nipa ṣíṣe ifẹ Ọlọ́run laye yii. Jesu kọ àwọn ènìyàn naa ni awọn ofin ijọba Ọrun ti gbogbo Kristẹni gbọdọ tẹle ninu igbe aye rẹ. Ìwàásù lori oke safihan ohun ti igbe aye Kristẹni tòótọ́ gbọdọ jẹ. Jijẹ iyọ̀ ati imolẹ fihan pe Kristẹni daradara gbọdọ maa fi iyọ̀ saye ko si maa tan imolẹ saye.

IPIN KEJI: ÌJỌBA ỌLỌ́RUN NI AWỌN Ẹ̀KỌ́ IWA RERE:
Ni ile-iṣẹ yòówù, awọn ilana ati ofin wa ti o maa n mu ìṣẹ lọ déédéé. Bákan naa, ni awọn ẹkọ ìwa rere ìjọba Ọrun wa ti gbogbo Kristẹni gbọdọ tẹle bi a o ba de ijọba Ọrun. Jesu gbe awọn ofin ijọba Ọrun kalẹ ni Matiu (5-8) fun awọn olugbọ Rẹ igba naa, ati fun wa bayii, lati kẹ́kọ̀ọ́ ati lati tẹle awọn ìkọ́ni naa ofin ijọba Ọrun.

KÓKÓ ẸKỌ
I.    IJỌBA ỌLỌ́RUN YÀTỌ̀
      A.   AWỌN ÌPILẸ̀SẸ̀ Ẹ̀KỌ́ ÌJỌBA NAA TO ṢE KOKO
      B.   A ṢAFIHAN ÀWỌN Ẹ̀KỌ́ IWA RERE TI AYÉRAYÉ

II.   IJỌBA ỌLỌ́RUN NI ÀWỌN Ẹ̀KỌ́ IWA RERE
      A.   A ṢAFIHAN ÀWỌN Ẹ̀KỌ́ IWA RERE TI AYÉRAYÉ SÍWÁJÚ SII
      B.   AWỌN Ẹ̀KỌ́ IWA RERE TI AYÉRAYÉ: ÌṢILETI

ITUPALẸ Ẹ̀KỌ́
Mar. 17, 2019.
I.    IJỌBA ỌLỌ́RUN YÀTỌ̀ (Matiu 6:10; Heberu 1:8-9).
Ìjọba jẹ ilu tabi awọn eniyan ti ọba tabi ọbabìnrin n jọba le lori. Bakan naa, o jẹ ilẹ̀ ọba tabi ibi gbàgede eto ninu eyi ti ohun kan pato ti a lero pe o ni lati jọba / jẹ gaba lori awọn yoku. Ijọba jẹ ilu ọba ilẹ̀-ijọba. Ko fẹrẹ si ọba ti ko ni ilu. Ijọba Ọlọ́run ni ilu ti O ti n ṣakoso ati Oluwa (ijọba) gẹgẹ bi Ọba awọn ọba ati Oluwa awọn oluwa. Ijọba wa, awọn ìjọba sì wa. Ijọba Ọlọ́run lori awọn eniyan tiRẹ nipasẹ Jesu Kristi Olúwa, yàtọ̀, nítorí awọn ìyàtọ̀ rẹ. Bawo?

A.   AWỌN ÌPILẸ̀SẸ̀ Ẹ̀KỌ́ ÌJỌBA TO ṢE KOKO (Mat. 6:10; Héb. 1:8-9).
Ki ìjọba Rẹ de; ifẹ TiRẹ ni ki a ṣe, bi i ti ọrun... (Mat. 6:10).
i.   O ṣe Pataki pe ki a ni imọ ìpilẹ̀ṣẹ̀ ẹ̀kọ́ ti ijọba, ki a le maa fi si ìṣe ki a si le maa gbe ninu rẹ (Mat. 7:21; Jn. 8:32).
ii.  Agbekalẹ ati àṣà ti ijọba ko wa ni ibamu pẹlu awọn alakalẹ ẹ̀kọ́ igbe ayé ti igbalode ati ti igba isinsin yii ṣùgbọ́n o wa fun diduro ninu ẹ̀mí nigba gbogbo ati àpẹẹrẹ iwa rere (Mat. 6:10; Lk. 1:49-53; 3:5-6).
iii. Ijọba Ọlọ́run gbọdọ jẹ Kristẹni logun julọ ninu igbesi aye wọn (Mat. 6:33).
iv. Awọn eso ijọba naa ni idanwo inúnibíni ati iforiti (Mat. 21:42; Jak. 1:3-4)
v.  Ìpilẹ̀ṣẹ̀ ẹ̀kọ́ ijọba ti o leke ni iwa ododo (Heb. 1:8)
vi. Awọn ilana ipilẹ-ẹ̀kọ́ fẹsẹ múlẹ̀ ninu Bíbélì (Ọrọ Ọlọ́run) (Jos. 1:8; Esr. 7:10; 2 Tim. 3:16, 17).
vii. Jesu kọ àwọn olugbọ Rẹ ni ilana gbígbàdúrà si Baba naa ni ibamu pẹlu awọn ẹkọ iwa rere ti ọrun. Gbogbo Kristẹni tootọ ko gbọdọ fi ọkan si awọn ohun ti aye bikoṣepe wọn gbọdọ maa fi ọkan si àwọn ohun ti ijọba ọrun. Nítorí naa, wọn gbọdọ maa fi ọkan sì awọn ohun ti ìjọba ọrun. Nítorí naa, wọn gbọdọ maa gbàdúrà pe ki ìjọba Ọlọ́run o de ki ifẹ Rẹ si wa si ìmúṣẹ laye.

B.   A ṢAFIHAN ÀWỌN ẸKỌ IWA RERE TI AYÉRAYÉ (Mat. 5:1-16)
O sì ya ẹnu Rẹ, o si kọ wọn, wi pe... (ẹsẹ 2).
*  Ìwàásù Jesu Kristi ni ori-oke n sagbekalẹ awọn ìtọ́kasi ẹ̀kọ́ iwa rere to niise pẹlu ijọba Ọlọ́run. Ẹ̀kọ́ iwa rere ìjọba Ọlọ́run tayọ ofin lasan fun ẹgbẹ̀rún ọdun to n bọ wa.
*  Mat. 5-7 safihan ẹ̀kọ́ iwa rere lati gba wa níyànjú ati lati faramọ bi ẹni to tí gba ijọba iye naa.
i.   5:3-11:  Ipongbẹ ati nini ọkan Ọlọ́run ati iwa Rẹ. Ipo ti ọkan olùgbé ijọba ayérayé wa gbọdọ safihan jijẹ abosi ninu ẹ̀mí, ọkan tutù, ebi ati Ipongbẹ fun ododo, aanu, iwa mimọ, ilaja ati inúnibíni nitori ododo, ẹnikẹ́ni o le ni awọn iwa yii ayafi awọn ti wọn ti ni ọkan àti iwa Ọlọ́run. Njẹ o ni ọkàn àti iwa yii bi?
ii.  5:13-16: Ní jijẹ ẹni àpẹẹrẹ oníwà-bí-Ọlọ́run ninu ijọ ati àwùjọ. O di igba ti iwa amuyẹ ẹni tí o jẹ ba tan sita nikan ni o to le ni ipa lori àwùjọ rẹ, nipa bẹẹ ìwọ yoo wa di awokọṣe rere fun awọn ẹlòmíràn. Ṣé ìwọ jẹ olóòótọ́ si Mat. 5:13-16?
iii. Jesu fẹ́ kí gbogbo Kristẹni o jẹ iyọ̀ ati imolẹ aye. Gẹgẹ bi iyọ̀ àti imolẹ, a ní lati jẹ mimọ, ni iwa funfun, gbe igbe aye ti o yatọ, fifi iyọ̀ si aye búburú yii ati titan imolẹ sii ki àwọn ẹlòmíràn o le mọ Ọlọ́run nipasẹ wa.

ÀWỌN Ẹ̀KỌ́ TÍ A Rí KỌ
1.   Àwọn alakalẹ ofin ati ilana to n ṣakoso ijọba Ọlọ́run wà. Awọn ti wọn ba n ṣàmulo wọn nikan ni yoo gbádùn àwọn ìbùkún ijọba ni aye yii àti ni ayérayé.
2.   Ẹ̀kọ́ iwa rere ti ijọba Ọlọ́run yàtọ̀ gedegbe si ẹ̀kọ́ iwa rere ti ayé. Ìwà-bí-Ọlọ́run yàtọ̀ pupọ si ìwà-bí-Ọlọ́run. Yan ìwà-bí-Ọlọ́run laayo.

ÌṢẸ ṢÍṢE
Kin ni idi ti o fi ṣòro fun awọn eniyan lati maa gbe ninu ilana ipilẹ ẹ̀kọ́ mímọ tí ìjọba Ọlọ́run lonii, ati àwọn Kristẹni miiran pẹlu? Sọ ọna àbáyọ.

KA EKO TI ATEYIN WA NI IBIYI

ÌDÁHÙN TÍ A DÁBÀÁ FÚN IṢẸ́ ṢÍṢE
i.    ọ̀pọ̀ ti a n tọ́kasi gẹgẹ bí Kristẹni ni wọn ko ti i di atunbi.
ii.   Ibẹru Ọlọ́run ti n dinku ninu ijọ.
iii.  Ọ̀pọ̀ ìjọ kii kọ àwọn ọmọ ìjọ wọn ni pataki gbigbe igbe aye iwa mimọ.
iv.  Nigba ti awọn ọmọ ìjọ ko ba kun fun Ẹ̀mí Mímọ́, wọn ko le gbe igbe aye nípasẹ̀ awọn ilana mímọ Kristi.
v.   Awọn kan gbagbọ wọn si n kọ́ni pe gbigbe igbe aye iwa mímọ ko ṣeeṣe nínú aye.
vi.  Awọn olori kan tí a n reti pe ki wọn jẹ àwòṣe rere ti dojuti awọn ọmọ-lẹ́yìn wọn lọpọ ìgbà.
vii. Ọna-àbáyọ ni lati ṣàwárí ìtara ọtun fun iwa mímọ Kristi, ki wọn si wàásù rẹ tagbaratagvara àti loorekoore.
viii. Awọn olori ìjọ, laiwo ti ẹni to hu iwakiwa gbọdọ mu ibaniwi tí o tọ si ìṣe.
ÌJỌ ÀPỌ́SÍTÉLÌ KRISTI Ẹ̀KỌ́ ILÉ Ẹ̀KỌ́ ỌJỌ́ ÌSINMI Eto Ayeraye Olorun Fun Eniyan. March 17th, 2019 : Ẹ̀KỌ́ KARUN UN, AKORI - ÀWỌN Ẹ̀KỌ́ IWA RERE TI AYÉRAYÉ ÌJỌ ÀPỌ́SÍTÉLÌ KRISTI  Ẹ̀KỌ́ ILÉ Ẹ̀KỌ́ ỌJỌ́ ÌSINMI  Eto Ayeraye Olorun Fun Eniyan.  March 17th, 2019 : Ẹ̀KỌ́ KARUN UN, AKORI - ÀWỌN Ẹ̀KỌ́ IWA RERE TI AYÉRAYÉ Reviewed by Abodunrin Muyiwa (Muyilight) on March 17, 2019 Rating: 5

No comments:

Powered by Blogger.