ÌJỌ ÀPỌ́SÍTÉLÌ KRISTI Ẹ̀KỌ́ ỌJỌ́ ÌSINMI FUN February 24, 2019, AKORI - Eto Ayeraye Olorun Fun Eniyan

ÌJỌ ÀPỌ́SÍTÉLÌ KRISTI  Ẹ̀KỌ́ ỌJỌ́ ÌSINMI FUN February 24, 2019, AKORI - Eto Ayeraye Olorun Fun Eniyan ÌJỌ ÀPỌ́SÍTÉLÌ KRISTI
Ẹ̀KỌ́ ỌJỌ́ ÌSINMI
Eto Ayeraye Olorun Fun Eniyan.
February 24, 2019.

II.   IHINRERE MIRAN (2 Kor. 11:1-4, Gal. 1:6:10; 3:1-9; 2 Pet. 2:1-11).
Lotitọ, kii ni ìdí tí a fi n sọ̀rọ̀ nípa ihinrere miran pẹ̀lú gbogbo ohun tí Kristi ti ṣe fún eniyan? Kristi àti àwọn aposteli lo aye wọn láti fi ṣàlàyé ìtumọ̀ ihinrere tòótọ́, wọn si lo daradara. Ko yẹ ki a maa gbọ ihinrere eke láàrín wa, tí a ba fẹ jẹ alaimoore. Síbẹ̀, èyí ṣe wa wọpọ láàrin àwọn Kristẹni lonii?

A.   IDI FUN UN (2 Kor. 11:1-4; Gal. 1:6-10; 3:1-9).
Nitori bi ẹni ti n bọwa ba nwaasu jesu miran, tí awa ko tii wàásù ri, tabi bi ẹyin bá gba ẹ̀mí miran, ti ẹyin kò ti gba ri, tàbí ihinrere miran, tí ẹyin kò ti tẹ́wọ́gba, ẹyin iba se rere láti fi ara da a (2 Kor. 11:4).
i.  Ni 2 Kor. 11:1-4, Kíyèsí ìtọ́kasi Jesu miran, emi àti ihinrere tí àpapọ̀ rẹ yàtọ̀ si eyi ti a fi le awọn Aposteli lọwọ ni atetekọ̀se lati ọdọ Jesu Oluwa wa.
ii.  Nitòótọ́, eke yi ti n fi ara han lati igba naa ninu aye, ni ibamu pẹlu ikilọ isaaju (wo Ìṣe 20:29-30; 2 Pet. 3:3-5). Fun àpẹẹrẹ, Paulu banujẹ fun ìwọléwá "ihinrere miran" laarin awọn ara ni Galatia (Gal. 1:6-10; 3::1-9).
iii. Gal. 1:6-10 túmọ̀ sí pé "ihinrere miran" jẹ ṣíṣe àyídáyidà ihinrere tòótọ́ tí Kristi, 3:1-9 fihan bi ohun to bofin mu láti fi mú awọn eniyan Ọlọ́run lẹrú.
iv. Ni kedere, o jẹ ìròyìn, ẹ̀kọ́ tabi àsọtẹ́lẹ̀ tí ẹnikan pilẹ rẹ nipasẹ imọ ori ti ara rẹ, bí o tilẹ soo pọ mọ Bíbélì, ṣùgbọ́n lai dọ́gba pẹ̀lú osunwọn tí iwe mímọ. O tun lee jẹ àsọtẹ́lẹ̀ nípa ọrọ Ẹ̀mí ṣùgbọ́n tí ko wá láti inú imisi Ẹ̀mí Mímọ́, ti o jẹ pe lẹhin ayẹwo fínnífínní, ni o ṣe tako tabi yàtọ̀ si àlàyé títọ̀nà tí Bíbélì (wo I Tim. 6:3-5).
v.  Awọn idi kan fun wiwa àti titan ka awọn eke ihinrere ni:
    a.   Ipadàsẹ́yìn: Ṣíṣe àfikún àwọn ohun aiwabi Ọlọ́run nígbà tí a si n sọ pé a jẹ ọmọ ìjọ. Yiyi ọrọ Ọlọ́run si ọna ti ara ẹni fún erongba imọtara ẹni nikan (I Tim. 5:15).
    b.   Ṣíṣe isẹ Ọlọ́run fun ọrọ (I Tim. 6:3-5). Ọ̀pọ̀ n ṣiṣẹ́ Ọlọ́run láti lè ní ọrọ ati ìgbádùn. Irufẹ awọn bẹẹ a maa fikun tàbí yọ kuro ninu òtítọ́, ṣíṣe àfihàn ihinrere miran (Romu. 16:17-18).
    d.   Nini ẹ̀mí ẹ̀tàn: (I Jn. 4:1 síwájú sii) ọpọ awọn ẹ̀mí tí àwọn kan n lo láti ṣíṣẹ Ọlọ́run ní a ko lee sọ pé o jẹ ti Ẹmi Mimọ ṣùgbọ́n àwọn ẹ̀mí àjèjì. Awọn ẹkọ àti àsọtẹ́lẹ̀ tí o n jáde láti ọ̀dọ̀ irú àwọn ẹmi bẹẹ ko le dọ́gba pẹ̀lú ihinrere tòótọ́.
    e.  Gbigba ilana ìgbàlódé mọ́ra: (Gal. 3:1 síwájú sii); ọ̀pọ̀lọpọ̀ awọn ẹkọ ni o wa ni aye lonii tí o n yi ọrọ Ọlọ́run láti tẹ ete imọtara ẹni lọrun (I Tim. 4:3-4, 2 Tim. 3:5-9).
    ẹ.  Gbigbadun awọn ẹsẹ ikọkọ: Nitori awọn ẹsẹ ikọkọ tí àwọn miran ko fẹ́ fi silẹ nítorí àwọn anfani tí wọn n ri nibẹ, ẹtán èṣù tabi idi ti o han si awọn nikan, wọn a maa gbe àwọn ẹ̀kọ́ kalẹ nigba gbogbo láti ṣe atilẹyin fun àwọn igbe aye ẹsẹ bẹẹ kí àṣírí wọn ma baa tú (wo Ìṣe. 8:9-25).
vi. A ti fi òtítọ́ ihinrere han fun ẹnikẹ́ni lati yan ohun tí o tọ̀nà. Ṣùgbọ́n ẹda eniyan ti ọpọ ko le bawi ninu aye wọn le mu ki o rọrùn láti faaye gba ihinrere miran, èyí tí o rọ mọ ìgbàgbọ́ àwọn ọmọlẹ́yìn.
vii. Bákan naa ibi tí a ko ba ti da ẹda ẹsẹ eniyan mọ, dájúdájú o jẹ ipilẹ fun ihinrere miran. Sọra!

B.  AWỌN ÀBÁJÁDE RẸ (2 Pet. 2:1-11).
Oluwa mọ bí a ti iyọ awọn ẹni ìwà bí-Ọlọ́run kúrò nínú idanwo àti bí a ti ipa àwọn alaisootọ tí a n jẹ níyà mọ de ìdájọ́ (ẹsẹ 9).
i.   Bíbélì ko fi wa sínú òkùnkùn ni ti awọn àbájáde esi ikẹhin fun àwọn tí ko dúró nínú ihinrere tòótọ́. Idi niyi ti a gbọdọ fi yago fún irú àwọn ènìyàn bẹẹ (I Tim. 6:1-5).
    a.   Ọlọ́run yoo tuwọn lasiri pẹ̀lú ìjìyà, yoo si dojuti wọn (Lk. 8:17)
    b.   Gbogbo wa la o jinyin ìṣẹ iriju wa fun Ọlọ́run àti àwọn àgbàtẹru ihinrere adamọdi yoo subu lábẹ́ ìbínú ńlá Ọlọ́run (2 Kor. 5:10,11).
    d.   Jesu Oluwa mọ awọn ti ó n sin In lotitọ, yoo si tú àṣírí àwọn èké níkẹyìn (Mat. 7:21-23).
    e.   Ọlọrun lee da wọn lẹbi pẹlu ẹlẹ́ya bí wọn tí n fi ẹ̀kọ́ èké wọn sì ìṣe fún ìtiju àti idibajẹ/ìpalára wọn (2 Kor. 11:4).
    ẹ.   Awọn olùkọ́ eke tí gba ìdájọ́ (2 Pet. 2:1-11) wọn ti gba ègún (Gal. 1:18)
ii. Ki ìparun ma baa ba ọ, dúró daradara, ki o si wa ninu ẹ̀kọ́ tòótọ́ tí a ti kọ ọ (2 Tesa 2:14,15). Yago fun adamọdi ihinrere ìgbàlódé ki a lee ka wa yẹ ni igba ipadabọ Rẹ lẹẹkeji.
iii. Báwo ni eniyan yoo ṣe fi ara rẹ fun ẹ̀tan èṣù lati gba ihinrere miran tiko ni ire kan ti o wa titi lati ṣe fun wa? Jẹ ki gbogbo àwọn olùtọ́ ihinrere miran lẹyin o mọ pe wọn yoo pari rẹ pẹlu igbẹyin tí o lẹru pupọ pẹlu èṣù ni ọrùn àpáàdì.

ÀWỌN Ẹ̀KỌ́ TI A RI KỌ
1.   Ori èṣù ti daru si Ọlọ́run, o si n ṣe ohun gbogbo láti ṣe adamọdi òtítọ́ Ọlọ́run. Mase ba a tò pọ̀.
2.  Gbogbo àwọn tí o bá to pọ, tí wọ́n wa ni irọrun pẹ̀lú rẹ, tí wọ́n si n gbé ẹ̀kọ́ odi rẹ kiri tí kan ìjàngbọ̀n, tí wọ́n ba kọ láti ronupiwada si iha ti Ọlọrun.

ÀWỌN ÌBÉÈRÈ
1.   Kinni ihinrere tòótọ́?
2.  Kin ni ìtumọ̀ ihinrere miran?
3.  Ewo lo wọ́pọ̀ ju loni, ihinrere tòótọ́ tàbí ihinrere miran?
4. Kin ni yoo jẹ òpin àwọn tí n gbe ihinrere miran kiri?

ÀWỌN ÌDÁHÙN TÍ A DÁBÀÁ FÚN ÀWỌN ÌBÉÈRÈ :
ÌDÁHÙN SI ÌBÉÈRÈ KÍNNÍ
Ihinrere tòótọ́ ni ìròyìn ayọ̀ ìfẹ́ Ọlọ́run si gbogbo ènìyàn; O fun wa ni Jesu Ọmọ Rẹ lati ba gẹgẹ bi ọmọ láti tan imọlẹ si aye ti o ṣókùnkùn. Nínú rẹ a o ri imulọkanle, àlàáfíà, àti erongba ayé ni kedere abbl.

ÌDÁHÙN SI ÌBÉÈRÈ KEJI:
Ihinrere miran túmọ̀si ìwàásù, ẹ̀kọ́ àti àmúlò ohun tí ṣe eke ohun tí Jesu wa fun wa; ti wọn si yi gbogbo ọrọ ijọba Ọlọ́run po fun imọtara-ẹni lábẹ́ arekereke ọlọrun aye yii (èṣù).

ÌDÁHÙN SI ÌBÉÈRÈ KẸTA.
Ihinrere tòótọ́ ni eyi ti o daju. Ohun gbogbo nipa ihinrere naa jẹri sì pe òtítọ́ ni ihinrere naa. Ati pé, ìṣẹ́gun Kristi lórí ikú lórí igi àgbélébùú, àti agbára ọrọ Ọlọ́run ti ko ni afiwe tí ko si ṣe e pati duro gbọn-in gbọn-in ninu àdánwò naa.

Gẹ́gẹ́ bí ọkàn lara awọn ami ìgbà ìkẹyìn èṣù n gbe awọn ikọ rẹ dìde láti kun ààrin awọn Kristẹni pẹ̀lú ẹ̀kọ́, ìwàásù, ìṣe àti ìlànà eke ni ọna láti bomi pa ihinrere tòótọ́ Kristi. O n jẹ ki ó dàbi pé àwọn oni ihinrere eke yii ni wọn n rọwọ mú. A gbọdọ sọra bẹẹni a gbọdọ gbe ina ihinrere Kristi tòótọ́ lọwọ lati pa òkùnkùn ihinrere eke.

ÌDÁHÙN SI ÌBÉÈRÈ KẸRIN:
1.  lọ wo abala IIB
2. Ọlọrun yoo da wọn lẹjọ́, ọrun àpáàdì sì n dúró de wọn.

ÀMÚLÒ FÚN IGBE AYÉ ẸNI :
Ilé ifowopamọ n sa gbogbo agbára rẹ láti ri i pé ayédèrú owo káṣẹ nlẹ. Ti a ba sọ̀rọ̀ nípa ẹgbẹ́ (Standard Organization of Nigeria). Gbogbo akitiyan n lọ lọwọ láti dẹ́kun awọn ayédèrú ẹru àti ìṣẹ ni awujọ wa. Niti eto ìlera, àti àwọn ẹ̀ka miran ayédèrú wọpọ. Gbogbo wa ti wá di ara nnkan yii, o si o sì wọpọ nínú ayé tí a wa lonii, nitori ti iba wa ọwọ rẹ bọlẹ ni wọn n ṣe agbatẹru rẹ.

Jesu wa nigba ti o fẹ láti ra ènìyàn padà kuro ni ọwọ èṣù, ẹniti o mu ayé lẹrú nigba kan. Síbẹ̀ èṣù kò ní sinmi nínú akitiyan rẹ láti ma a ṣe ẹ̀dá ohun ti Ọlọ́run ba ti da. Nítorí naa, lẹ́yìn èṣù jẹ, ẹlẹ́tan, baba eke, ọga alayidayida, jẹ ki gbogbo ọmọ Ọlọ́run, ni agbegbe wọn, kọ ihinrere eke. Ẹjẹ ki a ma a fi igba gbogbo ṣe si ihinrere ati àwọn onihinrere eke, ohun tí Jesu ṣe fun wọn nigba ayé Rẹ lori ilẹ ayé. A ko ni ja A kulẹ. Amin.

IGUNLẸ :
Ihinrere miran maa n pese awọn ayédèrú Kristẹni tí wọn tí gba Jesu miran laimọ pẹlu ọlọ́run mìíràn --- òrìṣà èké. Ihinrere tí ko ba ti ni ìrònúpìwàdà àti ìṣẹra ẹni nínú ko pe, eso rẹ ki ìṣe tí Ọlọ́run. Awọn ti wọn n kọ tí wọn si n wàásù ihinrere miran dabi ikooko nínú àwọ àgùntàn, tí wọ́n n tanjẹ, ti wọn n di àwọn àgùntàn lọ́wọ́ kúrò nínú ipe olùsọ-àgùntàn tòótọ́. Kí olùtùnú naa, okudamọran àti Ẹ̀mí òtítọ́ maa fi òtítọ́ Jesu Kristi han gbogbo awọn ti wọn ti sina. Ki O máṣe sìwọ titu àṣírí àwọn olutan ihinrere eke kalẹ. Amin.

Ka awon Eko ojo isimi ti ateyinwa ni ibiyi

ÀṢÀRÒ LÁTI INÚ BÍBÉLÌ FÚN ỌSẸ ÌKEJÌ
Mon.   18:   Àwọn Olùkọ́ Èké Yọ Wọle (Juda 4)
Tue.    19:   Àwọn Olùkọ́ Èké Jẹ Onimọtara Ẹni (Juda 12)
Wed.   20:  Àwọn Agbatẹru Ẹ̀kọ Eke Ti Wa Nihin (2 Pt. 2:1)
Thur.  21:  Àwọn Olùkọ́ Eke N Tan Ènìyàn Jẹ (2 Pt. 2:3)
Fri.     22:  Awọn Olùkọ́ Eke Jẹ Ènìyàn Búburú (2 Pt. 2:17-19)
Sat.    23:  Awọn Olùkọ́ Eke Ṣòro Mura Bọsipo (Heb. 6:4-8)
ÌJỌ ÀPỌ́SÍTÉLÌ KRISTI Ẹ̀KỌ́ ỌJỌ́ ÌSINMI FUN February 24, 2019, AKORI - Eto Ayeraye Olorun Fun Eniyan ÌJỌ ÀPỌ́SÍTÉLÌ KRISTI  Ẹ̀KỌ́ ỌJỌ́ ÌSINMI FUN February 24, 2019, AKORI - Eto Ayeraye Olorun Fun Eniyan Reviewed by Muyiwa Abodunrin (Muyilight) on February 23, 2019 Rating: 5

No comments:

Powered by Blogger.