ÌJỌ ÀPỌ́SÍTÉLÌ KRISTI Ẹ̀KỌ́ ỌJỌ́ ÌSINMI. Eto Ayeraye Olorun Fun Eniyan Fun February 3, 2019, Ẹ̀KỌ́ KEJÌ: AKORI - ÀWỌN ÌDÈNÀ LÁTI DÉ AYÉRAYÉ

ÌJỌ ÀPỌ́SÍTÉLÌ KRISTI  Ẹ̀KỌ́ ỌJỌ́ ÌSINMI.  Eto Ayeraye Olorun Fun Eniyan Fun February 3, 2019, Ẹ̀KỌ́ KEJÌ: AKORI - ÀWỌN ÌDÈNÀ LÁTI DÉ AYÉRAYÉ
ÌJỌ ÀPỌ́SÍTÉLÌ KRISTI
Ẹ̀KỌ́ ỌJỌ́ ÌSINMI.
Eto Ayeraye Olorun Fun Eniyan.
February 3, 2019.

Ẹ̀KỌ́ KEJÌ: ÀWỌN ÌDÈNÀ LÁTI DÉ AYÉRAYÉ

Àwọn ìdènà Sátánì wà, ara ati ayé tí a gbọdọ ṣẹ́gun/bori tí ìran àti de ọrun yoo ba ṣẹ. Njẹ o ṣetán?

AKỌSÓRÍ
Nítorí ní ode ni àwọn ajá gbé wa, àti àwọn osó, àti àwọn àgbèrè, àti àwọn apànìyàn àti àwọn abọ̀rìṣà, àti olúkúlùkù ẹniti o fẹ́ràn èké tí o sì n hùwà èké (Ifih. 22:15).


ÀLÀYÉ KÚKÚRÚ
Àmúlò ọrọ "ṣùgbọ́n" nínú ẹsẹ àkọ́kọ́ yii n safihan ibasepọ ẹsẹ ti o ṣáájú àti eleyi, ṣùgbọ́n ibasepọ àárín wọn dámọ̀ràn "Ṣùgbọ́n" jẹ ọrọ ti o maa n safihan ìyàtọ̀ gedegbe tí o wa laarin ohun meji. Nígbà tí ẹsẹ íkẹrìnlá n sọ nípa àwọn amuyẹ ati àbájáde àwọn tí yoo wọ ìjọba Ọlọ́run, ẹsẹ ikarundinlogub n sọ ní pato àwọn iwa àti amuyẹ àwọn tí kò le wọ ìjọba Ọlọ́run. Gẹgẹ bi ẹ̀kọ́ naa ṣe fihan, àwọn wo ni kò le wọ ìjọba Ọlọ́run? Àwọn ajá, àwọn oṣo, àwọn alagbere, àwọn apànìyàn àwọn abọ̀rìṣà, àwọn tí o fẹ́ràn eke àti àwọn tí n ṣe e.

Ni fifi èyí wé àwọn ẹsẹ íkẹjọ àti ikẹtàdínlógún ori íkọkànlelogun (chap. 21), a le ri ìfarajọra; ṣùgbọ́n kí yoo si ohunkóhun tí n sọ ni di àìmọ, tabi ti o n fa ìríra tabi irọ tí yoo wọ ibẹ bi o ti wu ki o ri. Àwọn pẹ̀lú bẹ̀rẹ̀ "ṣùgbọ́n" ni ọna ọ̀tọ̀. Gbogbo wọn naa ni o ntọkasì àwọn ohun ìdènà tí gbogbo arinrin ajo lọ si ìjọba ọrùn gbọdọ kiyesara fun, kí wọn sì bori, èyí ni ti wọn ba fẹ de ijọba Ọ̀run naa.

A ko gbọdọ túmọ̀ ajá lereefe. Eleyii nkoka si àwọn akuda iwa, tí o farajọ àwọn iwa ajá, fún àpẹẹrẹ, jíjẹ igbẹ (Ifẹkufẹ àti ìwà ibajẹ), gbigbo laini idi pataki (iwa ipa), àwọn iwa ìṣekúṣe tí àgbèrè, pipada láti maa jẹ eebi rẹ, àti bẹẹbẹẹ lọ. Àwọn ẹsẹ ti a ko tii jẹwọ wọn jẹ àwọn ohun àìmọ tí wọn le ṣe ìdènà onigbagbọ láti wọ ìjọba ayérayé.

ÀṢÀRÒ LÁTI INÚ BÍBÉLÌ FUN ỌSẸ KINNI
Mon.  28:  Kin Ni Ó Le Mú Ènìyàn Yẹ Fún Iye Ayeraye? (Mat. 19:16)
Tue.   29:  Ọ̀rọ̀ Le Dènà Àwọn Alaiwa-bi-Olorun (Mat. 19:24)
Wed.  30:   A Ko Gbọdọ Jokoo Ninu Ẹṣẹ (Romu 6:1)
Thur.  31:   Idi Ti Òdodo Rẹ Fi Gbọdọ Kọjá Ti Àwọn Farisí (Mat. 5:20)
Fri. Feb.1:   Mase Rin Bi Àwọn Alaiwa-bi-Olorun Ti N Ṣe (Efe. 4:17)
Sat.      2:   A Gbọdọ Bọlá Fun Ina Ajonirun (Héb. 12:29)

ÀṢÀRÒ FÚN ÌFỌKÀNSÌN
1.  Ilẹkun ìjọba Ọlọ́run ṣì silẹ fun gbogbo ènìyàn. Ẹsẹ ni o n di àwọn aláìgbọràn lọwọ láti wọlé.
2. Ko si ohunkóhun to yàtọ̀ si awọn ẹsẹ ti a ko jẹwọ́ wọn àti àwọn iwa ìfẹ́kúfẹ́ tí ara ti o le mu ẹnikẹ́ni kuna láti wọ ìjọba Ọlọ́run. Àwọn ìwà àìmọ àti àwọn aìwà-bí-Ọlọ́run jẹ ìdènà láti wọ ayérayé tí Ọlọ́run. Kiyesara!

ẸSẸ BÍBÉLÌ FÚN IPILẸ Ẹ̀KỌ́ : Isaiah 35:8-10

ILEPA ATI ÀWỌN ERONGBA
ILEPA: Láti jẹ ki a mọ wi pe awọn ìdènà wa ni ojú ọna ti a gbọdọ rẹkọjá ti a ba fẹ de ìjọba ayérayé tí Ọlọ́run ní tòótọ́.

ÀWỌN ERONGBA: Ni opin ẹ̀kọ́ yii, àwọn akẹ́kọ̀ọ́ gbọ́dọ̀ le:
i.  fi idi rẹ múlẹ̀ wi pe awọn onigbagbọ tòótọ́ nìkan ṣoṣo ni yoo ni anfaani lati wa ni ayérayé pẹ̀lú Ọlọ́run;
ii. Safihan wi pe awọn ìdènà wa ti sátánì tí fi sì oju ọna àwọn onigbagbọ tí o n fẹ́ láti ni iye ayérayé pẹlu Ọlọ́run
iii.jiroro nípa òtítọ́ naa pe awọn ohun ìdènà naa ni sátánì, ẹṣẹ làwọn ohun ti nsọ ni di àìmọ, àwọn iwa eeri, abbl, ayé àti ẹran ara, abbl, àti
iv. jiroro lori awọn ọna láti borí àwọn ìdènà wọ̀nyí láti de iye ayérayé.

IFAARA
ORISUN Ẹ̀KỌ́: MATEU 7:18-23; ÌṢE 4:12; I KOR. 6:9-10; ÉFÉSÙ. 4:22-32; ÌFIHÀN 22:1-5.
Ẹkọ́ tí o kọjá ní ó bẹ̀rẹ̀ ìjíròrò Ile Ẹkọ Ọjọ́ Isinmi January si June ọdun OLOGO 2019. A ṣe agbeyẹwo igbasoke, iṣẹlẹ ìgbà ikẹhin gbòógì tí a n retí, gẹgẹ bi iwe mimọ tí sọ, láti fi opin si àkókò oore ọ̀fẹ́ yii. Ninu ẹ̀kọ́ naa, a sọ̀rọ̀ nípa igbasoke ki a to kọjá sinu erongba àtọ̀runwá rẹ àti àwọn àbùdá/amuyẹ tí ènìyàn yoo fi le kopa ninu iṣẹlẹ ologo tí a n reti yii ti yoo tú àwọn ènìyàn mimọ silẹ kuro ninu iwa búburú inú ayé yii.

Eyi ni ẹkọ kejì ni saa yii ti àkọlé rẹ sọ pé ÀWỌN ÌDÈNÀ LÁTI DÉ AYÉRAYÉ. Àwọn ìdènà ni àwọn ohun tí ó jẹ ìdiwọ̀, idabuu ifàṣẹyìn tàbí di ohun kan lọwọ láti ṣe e ṣe tàbí didi ìtẹ́siwaju ohun kan lọwọ. Ni bayii, ayérayé ni ìdí rẹ, amuyẹ tàbí òtítọ́ pé ko si ìbẹ̀rẹ̀ tàbí òpin, akoko ti ko ni opin tí a o ni ìrírí rẹ lẹ́yìn ikú boya pẹlu Ọlọ́run ni ọrùn tàbí pẹlu èṣù ni ọrùn àpáàdì.

Ó jẹ eto ayérayé Ọlọ́run fún ènìyàn tí a gbọdọ ṣàkíyèsí pé Ọlọ́run n fẹ́ kí a wa pẹlu Oun ni ayérayé. Nínú ọ̀rọ̀ Jésù sì àwọn ọmọ ẹ̀yìn Rẹ nígbà tí o n di opin isẹ ìránṣẹ́ Rẹ lori ilẹ ayé, nigba ti o ti fẹ́ jọ̀wọ́ ẹ̀mí Rẹ gẹgẹ bí ìrúbọ fún ẹsẹ ìran ènìyàn, O sọ ní gbangba pe, Emi n lọ pese ààyè silẹ fun yin, bí mo bá sì lọ pese ààyè silẹ fún yin, Emi o tún padà wa, Emi o sì mu yin lọ sọ́dọ̀ Emi tikara mi; pe nibi ti Emi gbé wa, ki ẹyin lè wa nibẹ pẹ̀lú (Jhn. 14:2b-3). Ṣùgbọ́n àwọn ìdènà kan wà tí kò ní gbà ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn láàyè láti wọlé àti àwọn onigbagbọ sínú ayérayé pẹlu Ọlọ́run nínú Kristi. Nínú ẹ̀kọ́ yii, Ọlọ́run yoo ran wá lọwọ láti sọ àwọn ohun tí o le de wa lọ́nà láti jẹ adùn ayọ̀ ayérayé pẹ̀lú Ọlọ́run ni ọjọ ìkẹyìn. Ki Ọlọ́run kí O ran wa lọwọ. Amin.

IFAARA SI ÌPÍN KỌ̀Ọ̀KAN:
A pin ẹkọ yii si ipin meji, I ati II. Bẹẹni a si tun ṣe atunpin rẹ si A àti B.

ÌPÍN KÍNNÍ: AYÉRAYÉ ỌLỌ́RUN
Ipin yii duro le ayérayé tí Ọlọ́run. O ṣe afihan gedegbe nípa ayérayé ni apa kinni, nigbati apa kejì rẹ dúró le ipa ọ̀nà sí ayérayé tí Ọlọ́run. Ìfihàn 22:1-5 ni a lo láti fi ọ̀rọ̀ nípa ayérayé Ọlọ́run múlẹ̀ nígbà tí ọna sì ayérayé tí Ọlọ́run ní a mú jáde láti inú ìwé Mateu 7:18-23 àti Ìṣe àwọn Aposteli 4:12. Alaye ni kíkún wa lori irú ayérayé méjì tí ó wa; Ayérayé pẹlu Ọlọ́run; àti ayérayé nínú ina ọrùn àpáàdì níbi tí èṣù fúnrarẹ yoo ti jẹ olugbalejo àgbà. Ohun tí ó dara ju ni wí pé kí ènìyàn lépa ayérayé pẹ̀lú Ọlọ́run ni paradise Rẹ, eyi ti yoo seese nípa ìwà mímọ àti òdodo tí a ti pèsè nípasẹ̀ Jésù Kristi.

ÌPÍN KEJÌ: ÀWỌN ÌDÈNÀ LÁTI DÉ AYÉRAYÉ ỌLỌ́RUN
Gẹ́gẹ́ bi ìṣe wa, a pin ẹ̀kọ́ yii si ipa meji. Apa A n sọ̀rọ̀ lori awọn ìdènà, èyí ni àwọn ìdènà sì ayérayé Ọlọ́run. A mu èyí láti inú ìwé I Kọ́ríńtì 6:9-10. Apa B n sọ̀rọ̀ lórí ọna àbáyọ. I Kọ́ríńtì 6:11-ati Éfésù 4:22-32 ní àwọn ẹsẹ Bíbélì tí a yàn fún ẹ̀kọ́ yii. Lai deenapẹnu, àwọn ìdènà sì ìjọba Ọlọ́run ni a ti ṣe àfihàn wọn kedere fún ẹnikẹ́ni tí o ba bikita láti mọ. Àmọ́ nítorí Ọlọ́run jẹ Ọlọ́run ti O maa n fúnni ní ọ̀nà àbáyọ, O ti fun wá ní ọ̀nà àbáyọ kúrò nínú àwọn ìdènà tí o le mu ni kùnà láti wọ ayérayé, ní abala yii.

I.   AYÉRAYÉ ỌLỌ́RUN
     A.  Ọ̀RỌ̀ NÍPA AYÉRAYÉ
     B.  IPA ỌNA SI AYÉRAYÉ ỌLỌ́RUN
II.  ÀWỌN ÌDÈNÀ LÁTI DÉ AYÉRAYÉ ỌLỌ́RUN
     A.  ÀWỌN ÌDÈNÀ NAA
     B.  ỌNA ÀBÁYỌ

ITUPALẸ Ẹ̀KỌ́
Feb. 3, 2019 |  I.  AYÉRAYÉ ỌLỌ́RUN (Mat. 7:18-23; Ise 4:12; Ifih. 22:1-5).
Kin ni ayérayé? Ayérayé túmọ̀ sí ìgbà tí kò lópin. O n sọ nípa ìgbà tí ko ni ìbẹ̀rẹ̀ tí kò sì lópin. O jẹ ìgbà tí o wà titi láéláé. Ayérayé jẹ ìgbà ailopin. Ayérayé tí Ọlọ́run n tọ́ka sí wí pé àwọn onigbagbọ yoo wa pẹlu Ọlọ́run títí láéláé ni ìjọba Rẹ lẹ́yìn irinkerudo inú ayé tí. Ibeere naa ni wí pé, njẹ ìwọ yoo wa nibẹ bi?
A.   Ọ̀RỌ̀ NÍPA AYÉRAYÉ (Ifih. 22:1-5).
Oru kí yoo si mọ; wọn ko si ni wa ímọ́lẹ̀ oòrùn; nitori pe Oluwa Ọlọ́run ni yoo tan ímọ́lẹ̀ fún wọn: wọn si maa jọba láé àti láéláé (ẹsẹ 5).
i.   Oríṣi ayérayé méjì ni o wa. Àkọ́kọ́ ni ayérayé tí a o lo pẹ̀lú Ọlọ́run (I Tess. 4:17), nígbà tí ikeji yoo jẹ pẹlu satani (Mat. 25:41). Ayérayé pẹ̀lú Ọlọ́run jẹ ibi ayọ̀ àti ibalẹ ọkàn (Ifih. 22:1-5), nígbà tí ayérayé pẹ̀lú satani jẹ ibi ikoro, inira, ẹkún àti ijiya àìnípẹ̀kun (Ifih. 20:10).
ii. Bio tilẹ jẹ pe ibi ìdálẹ́bi ayérayé àti ìpọ́njú yii ni a ko da fún eniyan, àwọn ẹlẹ́ṣẹ tí ko ba ronupiwada ni wọn yoo ni ipa àti ìpín wọn ní ayérayé satani (Mat. 25:41).
iii.A n gbe ni ayé tí satani n gbe, o n tan àwọn ènìyàn jẹ bẹẹ si ni o n fi ẹ̀sùn kan àwọn ara. Bi o tilẹ jẹ pe Ọlọ́run ko fẹ́ kí ẹnikẹ́ni ki ó ṣègbé (2 Pet. 3:9; Mat. 18:14), satani ọ̀tá ọkàn wa ko fẹ́ kí ẹnikẹ́ni kì o gba itusilẹ (I Pet. 5:8; wo Job 1:7; 2:2; Mt. 4:1).
iv. Ọrọ miran fun ayérayé ni àìnípẹ̀kun/ailopin, ohun kan tabi akoko ti ko ni opin. O wa titi láéláé ni. Ọlọ́run Ẹlẹdaa jẹ ayérayé (O.D. 93:2; Isa. 40:28; Hab. 1:12).
v. Jesu Kristi jẹ ayérayé (wo Isa. 9:6); Ìjọba Ọlọ́run jẹ ayérayé (O.D. 145:13), ìgbàlà Ọlọ́run jẹ ayérayé (Jer. 31:3), ọrun àpáàdì (ìdálẹ́bi) jẹ ayérayé (Mat. 18:25; 2 Tesa. 1:9).
vi. Ẹda ayérayé ni wa. Agọ ara wa nìkan ni yoo dibajẹ tí yoo si pada di erupẹ. Ẹ̀mí wa yoo lọ sọ́dọ̀ Ọlọ́run fún ìdájọ́. Èyí tí o ja si wí pé ẹnikẹ́ni tí o ba jẹbi ni a o sọ sínú iná ìléru èyí tí a n pe ni ọrùn àpáàdì, láti jìyà titi ayérayé, èyí ni láé àti láéláé. O ko gbọ́dọ̀ pàdánù ìgbádùn ayérayé yí.

B.  IPA Ọ̀NÀ SI AYÉRAYÉ ỌLỌ́RUN (Mat. 7:18-23; Ìṣe 4:12).
Ko si si ìgbàlà lọdọ ẹlòmíràn: nitori ko si orúkọ miran lábẹ́ ọrùn tí a fi fúnni nínú ènìyàn, nípa èyí tí a lè fi gba wa là (Ìṣe. 4:12).
i.  Ipa ọ̀nà kan ṣoṣo sì ayérayé Ọlọ́run ni kí a gba Jésù Kristi gẹgẹ bí Oluwa àti Olùgbàlà wa (Jhn. 14:6; Ìṣe. 4:12)
ii. Jesu nínú ọrọ Rẹ nínú ìwàásù ni ori oke fihan pe Ọlọrun n reti irufẹ igbe ayé kan pàtó láti ọ̀dọ̀ wá lẹ́yìn tí a bá ti gba A tan (Mat. 5:13-16,43-48).
iii.Ayafi ìgbọràn pátápátá sí Ọlọ́run nínú Kristi Jésù àti Ẹ̀mí Mimọ nìkan ni o le mú wa lọ sínu ayọ̀ ayérayé Kristi (Mt. 7:18-23).
iv. Ìjọba ayérayé Ọlọ́run ni kò yẹ kí ẹnikẹ́ni o pàdánù rẹ, nitori tó kún fún ayọ̀ àti ìgbádùn titi lae (Mat. 18:7-9).
v. O san kí o yàgò fún ohunkóhun tí ó lè mú ọ pàdánù ijọba Ọlọ́run ti o ku si dẹdẹ.
vi. Isaiah safihan kedere lórí bí ojú ọna ti o lọ si ijọba ọrùn tí rí. O wí pé òpópónà yoo wa nibẹ pẹ̀lú ojú ọna, tí a ń pè ní òpópónà iwa mimọ, àwọn àlámọ̀ ki yoo le gba ibẹ... (35:8 lerefee).

ÀWỌN Ẹ̀KỌ́ TÍ A RÍ KỌ
1.  Òtítọ́ ni ọrun àpáàdì wa; bẹẹni ọrùn sì dájú. Mase fi àye rẹ ta tẹtẹ. Mase darapọ mọ àwọn ẹlẹ́gan.
2.  Jesu nìkan ni oògùn aporo sì àti ma balẹ ni ọrùn àpáàdì; Oun ni ọna kan ṣoṣo sì ayọ̀ ayérayé ni ọrun Ọlọ́run.

ÌṢẸ ṢÍṢE
Àwọn ènìyàn kan maa sọ pe, ayé kan ni ènìyàn ni lati gbe tí o ba si ti ku o pari nìyẹn. N jẹ wọn tọ̀nà bí? Kin ni a le ṣe láti rán wọn lọwọ?

KA AWON Ẹ̀KỌ́ ỌJỌ́ ÌSINMI ATI EYINWA NI BI YI

ÌDÁHÙN TÍ A DÁBÀÁ FÚN IṢẸ́ ṢÍṢE
1.  Àwọn tí wọn ń fi ọ̀rọ̀ iye lẹhin ikú ṣe awẹwa/yẹyẹ jẹ ope/àlámọ̀kan pe awọn onigbagbọ yoo wa ni ile pẹlu Ọlọ́run lẹ́yìn ayé yii tàbí, wọn jẹ olùkọ́ aladamọ tí wọn jẹ aṣojú èṣù pọnbele.
ii.  Òtítọ́ naa ni pe ìyẹn bẹ lẹhin ikú. Èyí n fún wa ní ẹri sì ẹ̀kọ́ tí ayérayé tàbí iye ayérayé naa. Ọlọ́run wá titi ayérayé, O si n fẹ́ kí gbogbo onigbagbọ wa pẹlu Rẹ ni ayérayé.
iii.Ohun kan ṣoṣo tí o le ṣe ìdiwọ̀; ìyẹn ni àwọn ìdènà, èyí tí a ti pẹkẹlu (fẹnuba) sẹhin nínú ẹ̀kọ́ yii.
iv. Akaimoye ọna ni Bíbélì tí safihan rẹ fun wá pe a o maa gbe titi láé pẹlu Ọlọ́run (Ifih. 21:1-4). Lati salai gba èyí gbọ ni lati gba/sọ pe Bíbélì tàbí Ọlọ́run jẹ ẹlẹ́tan.
v. Jesu sọ̀rọ̀ ìtùnú fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn Rẹ̀ pẹlu ìdàniloju tí gbígbé ní ayérayé pẹlu ara Rẹ àti Baba Rẹ nígbà tí O sọ fún wọn pe Oun lọ pese aye silẹ ni ile Baba Rẹ (Jhn. 14:1-6).
vi. Lotitọ, gbogbo ènìyàn tí o ba ti wa si aye jẹ ẹ̀dá ayérayé. Gbogbo wa yoo maa gbe titi láéláé. Ẹ̀mí wa ki yoo kú, agọ ara wa nìkan ni yoo pada si erupẹ. Ìyàtọ̀ ibẹ kan ni pé ìwà wa níhìn-ín yii ni yoo sọ irú ayérayé tí a o ni ìrírí rẹ.
vi.Àwọn kan yoo wa ni ìjìyà ayérayé (Ifih. 20:10, 11:-14) nígbà tí àwọn kan yoo wa ni ìgbádùn ayérayé (Ifih. 21:3-7).
viii.O han gedegbe wí pe awọn ti wọn nsọ wí pé ko si aye miran lẹyin ikú ko tọ̀nà. Ọ̀nà kan ṣoṣo láti rán wọn lọwọ ni lati sọ fun wọn pé wọn sina bẹẹni wọn sì gbọdọ ṣetán láti gba òtítọ́ pé wọn kùnà.
ix. Bí bẹẹkọ, wọn n ṣíṣẹ lodisi Ọlọ́run, bẹẹni wọn sì nfa ẹgun inú Bíbélì wá sí orí ara wọn.
ÌJỌ ÀPỌ́SÍTÉLÌ KRISTI Ẹ̀KỌ́ ỌJỌ́ ÌSINMI. Eto Ayeraye Olorun Fun Eniyan Fun February 3, 2019, Ẹ̀KỌ́ KEJÌ: AKORI - ÀWỌN ÌDÈNÀ LÁTI DÉ AYÉRAYÉ ÌJỌ ÀPỌ́SÍTÉLÌ KRISTI  Ẹ̀KỌ́ ỌJỌ́ ÌSINMI.  Eto Ayeraye Olorun Fun Eniyan Fun February 3, 2019, Ẹ̀KỌ́ KEJÌ: AKORI - ÀWỌN ÌDÈNÀ LÁTI DÉ AYÉRAYÉ Reviewed by Muyiwa Abodunrin (Muyilight) on February 03, 2019 Rating: 5

No comments:

Powered by Blogger.