ÌJỌ ÀPỌ́SÍTÉLÌ KRISTI Ẹ̀KỌ́ ILÉ Ẹ̀KỌ́ ỌJỌ́ ÌSINMI TI December 9, 2018. ISỌRI KẸTA: ÌDÁHÙN ENIYAN SI IFẸ ỌLỌ́RUN NÍNÚ MAJẸMU TUNTUN.

--> Note :- Are you born again? You are never going to win the battle against the devil if you are not born again. I plead with you to give your life to Jesus today because the longer you stay in sin and remain unsaved, the more hardened your nature becomes against the purpose and the way God wants you to be for His purpose. To give your life to Jesus now, say this prayer: “Father, I come to You in the name of Jesus. I know that I am a sinner and I cannot save myself but Jesus died for me and shed His blood that I might be saved. Today, I accept Jesus as my Lord and Saviour. Jesus, I ask You to come into my heart, be my Lord, wash me with Your blood and make me whole. I believe with my heart and confess with my mouth that Jesus is my Lord. Thank You for saving me. In Jesus' name I pray. Amen.” I congratulate you and welcome you to the family of God if you have sincerely said that prayer. Now you are fit to discover, know and walk in your destiny. Call our helpline on +2348037252124, Join Our Daily Whatsapp Devotionals Group : +2347033046607 for Daily Devotionals, crucial discipleship and counselling.s"
ÌJỌ ÀPỌ́SÍTÉLÌ KRISTI  Ẹ̀KỌ́ ILÉ Ẹ̀KỌ́ ỌJỌ́ ÌSINMI TI  December 9, 2018.  ISỌRI KẸTA: ÌDÁHÙN ENIYAN SI IFẸ ỌLỌ́RUN NÍNÚ MAJẸMU TUNTUN.



Ẹ̀KỌ́ KỌKÀNLÁ
ÀWỌN ÀPẸẸRẸ STEFANU ATI PỌ́Ọ̀LÙ

Nítorí tí Stefanu fẹ́ràn Jesu denunenu, o ṣetán láti fi ẹ̀mí ara rẹ lélẹ̀ fún Un. Èyí naa ni o ru Pọ́ọ̀lù sókè, láàrín wàhálà àti làásìgbò nínú ìṣẹ́ ìránṣẹ́ òkèèrè rẹ. N jẹ ìwọ ṣetán láti fi ẹ̀mí rẹ lélẹ̀ nítorí Kristi bí ọ̀rọ̀ ba wáyé?


AKỌSÓRÍ
Nítòótọ́ láìṣe àní-àní mo sì kà ohun gbogbo sì ofo nítorí itayọ imọ Kristi Jésù Olúwa mi: nítorí Ẹni tí mo ti sofo ohun gbogbo, mo sì kà wọn sì igbẹ, kí èmi kì o lee jere Kristi (Filp. 3:8)

ÀLÀYÉ KÚKÚRÚ
Pọ́ọ̀lù safihan ìfẹ́ rẹ̀ fún agbo Kristẹni tí o wà ní Fílípì àti gbogbo agbo onigbagbọ, nípasẹ̀ kíkọ episteli rẹ sì àwọn ara Fílípì, nítorí o ti sọ gbogbo ìyà tí o ti jẹ nítorí Kristi àti ihinrere lẹkunrẹrẹ. O ṣàlàyé ni ori kẹta níbi tí a ti yọ akọsórí, ipilẹ (ìbẹ̀rẹ̀) ayé rẹ tí o wunilori àti àwọn amuyẹ tí o fún Un ní ìgboyà pupọ nínú ara, Pọ́ọ̀lù gẹ́gẹ́ bí ipò rẹ jẹ Farisí, ara Hébérù àti Onítara pupọ (o n ṣe inúnibíni sí iye) àti nípa isòtítọ́ sì òfin, o jẹ aláìlẹ́bi, síbẹ̀, nígbà tí o ní òye Kristi, o pinnu láti yẹra fún gbogbo ohun wọnyìí gẹ́gẹ́ bí ènìyàn tii ṣe sí igbẹ. O wí pé "ṣùgbọ́n ohunkohun ti o ti ja si ere fún mi, àwọn ni mo ti kà sí ofo nítorí Kristi". O ka gbogbo anfaani, amuyẹ àti ṣíṣápọnlè ara ẹni wọ̀nyí sì ofo nítorí Kristi àti ihinrere. O tẹsiwaju ni ẹsẹ 9-11 láti safihan ni gbangba àwọn ohun wọnnì tí o ní ìtumọ̀ si i nísinsìn yii. Àwọn ni wọnyìí (a) Láti jere Kristi (b) Láti wa nínú Kristi (c) O n fẹ́ Kristi, kii ṣe tìrẹ mọ, (d) O n fẹ́ láti mọ Kristi kí o sì ni ìrírí agbára àjíǹde Kristi (e) O n pongbẹ láti ṣalábàápín nínú ìjìyà Kristi (f) O n fẹ́ láti jẹ̀gbádùn ajinde bii Kristi. Irufẹ ìpinnu tí o yanilẹ́nu fún Kristi wo ni eyi! Kin ni àwọn ohun wọnyìí túmọ̀si fún awa onigbagbọ? A gbọ́dọ̀ ṣe ìpinnu láti jọ̀wọ́ gbogbo (ere ayé) kí a sì tẹle Kristi. Gbogbo Kristẹni gbọ́dọ̀ ṣe ìpinnu láti jọ̀wọ́ gbogbo (ere ayé) kí á sì tẹle Kristi. Gbogbo Kristẹni gbọ́dọ̀ kẹ́kọ̀ọ́ nípa bí ati n fẹ́ràn Jésù ju ohun gbogbo lọ. Ayafi bí a bá ṣe ìyẹn, a kò le tẹsiwaju nínú ìgbé-ayé Kristẹni wa. A o gba iranlọwọ láti pongbẹ fún Kristi ni ti àtẹ̀yìnwá àti leke ohun gbogbo ni orúkọ Jésù. Àmín.

BÍBÉLÌ KÍKÀ FÚN OJOOJUMỌ
Mon.   3:   Stefanu, A Kun un Fún Àgbàrá Láti Ṣe Ìtànkalẹ Ihinrere (Ìṣe. 6:5-8)
Tue.    4:    Stefanu, Onígboyà Oníwàásù Ihinrere (Ìṣe. 6:9-12)
Wed.   5:    Pọ́ọ̀lù Di Ẹlẹ́wọ̀n Nítorí Kristi (Film. 1-3)
Thur.   6:    Filimoni Fẹ́ràn Ọlọ́run Dénúdénú (Film. 4-7)
Fri.      7:    Pọ́ọ̀lù Fẹ Ìdáríjì Àti Imúlọ́kànlè (Film. 8-16)
Sat.     8:    A Da Ifẹ Filimoni Fún Ìgbọràn Mọ (Film. 17-22).

ÀṢÀRÒ FÚN ÌFỌKÀNSÌN
1.   Gbogbo Kristẹni ni wọn gbọ́dọ̀ ṣetán láti gbé igbesẹ elewu tàbí kódà kí wọn kú nítorí ihinrere, ní idahunsi ìfẹ́ ailafiwe tí Kristi.
2.  Ohun tí o túmọ̀ sí láti fẹ́ràn Jesu àti ihinrere ni lati fi gbogbo aye wá fún Un tọkàntọkàn kí a sì ṣetán láti jìyà àti láti kú fún Un tàbí pẹ̀lú Rẹ.

ẸSẸ BÍBÉLÌ FÚN IPILẸ Ẹ̀KỌ́ : Ìṣe Àwọn Aposteli 6,7

ILEPA ATI ÀWỌN ERONGBA
ILEPA: Láti fihan wí pé kò sí ọna miran láti safihan ìfẹ́ fún Kristi ju fífi ẹ̀mí wá lélẹ̀ fún Un àti èré ije ihinrere.

ÀWỌN ERONGBA: Ní ìparí ẹ̀kọ́ yii, àwọn akẹ́kọ̀ọ́ gbọdọ:
i.   le ṣàlàyé ni kíkún bí Stefanu tí fi ẹ̀mí rẹ lélẹ̀ lójú ọna naa nítorí ihinrere bí o ti n wàásù (jẹ́rìí) pẹ̀lú gbogbo ìgboyà
ii.  tí bẹ̀rẹ̀ sii mú ìfẹ́ tòótọ́ fún Jésù Kristi dàgbà débi pé kò ní nira fún wọn láti fi ẹ̀mí wọn lélẹ̀ fún Un àti fún ihinrere.
iii. lè ṣàlàyé bí Pọ́ọ̀lù tí safihan ìfẹ́ tòótọ́ fún Ọlọ́run nípa wiwaasu Rẹ, fún àwọn tí o ti gbọ nípa Rẹ ati awọn ti ko ti gbọ́ nípa Rẹ pẹlu igbona ọkàn àti ìtara.
iv. tí lè bẹ̀rẹ̀ sii ni ìtara àti ipongbẹ tí kii kú fún àwọn ènìyàn Ọlọ́run ti ko ti gbọ nípa Rẹ pẹlu ihinrere tí wọn sì ṣetán láti jáde nígbàkúùgbà tí Ẹ̀mí Mímọ́ bá fún wọn ní àmì fún ìṣẹ́ ìránṣẹ́ òkèèrè.

IFAARA
ORÍSUN Ẹ̀KỌ́: ÌṢE. 7:1-60; 2 KOR. 2:4; FILIPI 3:1 SÍWÁJÚ; FILEMONI.
A fi gbogbo ògo fún Ọlọ́run bí O ti n ṣe sí wa ni saa ilé ẹ̀kọ́ ọjọ́ ìsinmi yìí. Ní ọsẹ tí o kọja, a parí ẹ̀kọ́ Kẹ̀wá ni isọri kẹta, pẹ̀lú àkòrí "Bibori Imunilẹrú pẹ̀lú ìfẹ́ Kristi." Ajiroro lórí bí Aposteli Pétérù àti ẹlẹgbẹ rẹ tí gba ariwisi fún gbígbọ́ran òfin Kristi ni wiwaasu ihinrere pẹ̀lú ìgboyà sì àwọn Kèfèrí àti bí o ti dúró gangan lodisi fifi àwọn ènìyàn Ọlọ́run ṣe ẹrú ni ọnakọna. A tún jiroro lórí bí àwọn ìjọ àkọ́kọ́ tí dahunsi lọ́nà títọ sì àdéhùn Kristi pé a gbọ́dọ̀ wàásù ihinrere sì àwọn Kèfèrí lọfẹẹ.

Ni bayii, a wa ni ẹkọ kẹta tí isọri kẹta ni saa yii. O jẹ ẹ̀kọ́ ọlọsẹ kan. O safihan bí Stefanu tí wàásù Kristi sì àwọn Juu, tí ó sọrọ sì wọn lọ́nà agbára (líle). A rii bí kò ti bẹru ohun tí o le sẹlẹ nípa sísọ òtítọ́ líle naa, bí o tilẹ mọ pé oun yoo dojúkọ àwọn onroro Juu àti apànìyàn. Àpẹẹrẹ Aposteli Pọ́ọ̀lù ni a ko lee saisọro nípa rẹ bí o ti han pe o fẹ́ràn Kristi àti àwọn ẹlòmíràn denunenu.

A gbàdúrà kí Ọlọ́run bukun wa bí a ti n kẹ́kọ̀ọ́ lọdọ Ẹ̀mí Mímọ́ ni ọsẹ yii ni orúkọ Jésù.

IFAARA SI ÌPÍN KỌ̀Ọ̀KAN:
Ẹ̀kọ ọ̀sẹ̀ kan ni yii ti a si tún pín sí A àti B

ÌPÍN A: STEFANU AJẸRIKU
Abala yii sọ̀rọ̀ nípa Stefanu, Ajẹriku naa, ẹni tí o koju àwọn Juu láti wàásù Kristi sì wọn laibẹru. Stefanu jẹri ayé, ikú àti àjíǹde Jésù sì àwọn Juu. O fi àye rẹ wewu, kò sì wò ibi tí wọ́n le ṣe sí oun. Níkẹyìn, wọn sọ ọ ní òkúta pa. O fi ẹ̀mí rẹ iyebíye wewu nítorí ihinrere Jésù.

ÌPÍN B: PỌ́Ọ̀LÙ AJIHINRERE ÒKÈÈRÈ
Abala kejì sọ bí Pọ́ọ̀lù Ajíjìnréré òkèèrè tí n lọ láti ibi kan sì ibi kan láti wàásù Jésù sì gbogbo ènìyàn, paapaa julọ àwọn Kèfèrí. O gbé ipilẹ (ìbẹ̀rẹ̀) rẹ tí o dúró gbọn-in gbọn-in sẹgbẹ kan, gẹ́gẹ́ bí Hébérù, ọmọ igbimọ Sànhẹ́dírìn àwọn Juu àti ọmọwé nla àti olùkọ́ òfin láti fẹ́ràn Jesu Kristi tọkàntọkàn. O faraji fún mímú ọrọ naa lo sì ọdọ àwọn tí ko tii gbọ nípa rẹ.

KOKO Ẹ̀KỌ́
I.   ÀWỌN ÀPẸẸRẸ STEFANU ATI PỌ́Ọ̀LÙ
     A.   STEFANU AJẸRIKU
     B.   PỌ́Ọ̀LÙ, AJIHINRERE ÒKÈÈRÈ.

ITUPALẸ Ẹ̀KỌ́
I.   ÀWỌN ÀPẸẸRẸ STEFANU ATI PỌ́Ọ̀LÙ (Ìṣe. 7:1-60; 2 Kor. 2:4; Filp. 3:1 síwájú;  Filemoni).
A.   STEFANU AJẸRIKU (Ìṣe 7:1-60.
O sì kunlẹ, o kígbe ni ohun rara pe, Olúwa, ma ka ẹsẹ yii si wọn ní ọ̀run, Nígbà tí o wí èyí, o sun (ẹsẹ 60).
i.   6:8-14: Diakoni Stefanu, "kún fún igbagbọ àti agbára," jáde lọ láti ṣe itankalẹ ìròyìn ayọ̀ tí ìjọba Kristi. Ṣùgbọ́n o n dojúkọ ọwọ àwọn ènìyàn kan tí wọn ko fẹ́ràn Kristi. N jẹ ìwọ ṣetán láti gbé ìhìnrere lọ sí àwọn àgbègbè elewu?
ii.  7:1: Àwọn ẹni ibi wọ̀nyí tí wọnú àwọn ènìyàn kan labẹlẹ láti jẹ ẹlẹ́rì eke, ki wọn fẹsun eke kan oníwàásù ìhìnrere (6:11 siwaju), eyi ni ó fa ìbéèrè  pé "Ṣe òtítọ́ ni àwọn ọ̀rọ̀ wọnyi"?
iii. Ẹsẹ 2-53: Saa wo bí o ti n fi ẹsọ ẹso ṣe ìwàásù rẹ bí ó ti bẹ̀rẹ̀ láti orí ipe Ábúráhámù (2-8) si ìrírí ìjáde kúrò lóko ẹrú (ẹsẹ 9-36) si bí orílẹ̀-ede Israeli ṣe sọtẹ sì Ọlọ́run (37-43), sì òtítọ́ tabanaku tí Ọlọ́run fọwọ́si (ẹsẹ 44-50) àti bí orílẹ̀-ede tí n kọ Ẹ̀mí Mímọ́ (ẹsẹ 51-23). Èyí ni nnkan ti Ẹ̀mí Mímọ́ n ṣe fún àwọn tí wọn fẹ́ràn Ọlọ́run tọkàntọkàn, de ìkòríta kíkú fún Un (Luk. 12:11,12).
iv.  Ẹsẹ 54-60: Ifẹ tí Stefanu ni sì Kristi borí ikú tí o dojúkọ ọ. Ó n rí Kristi nìkan tí o fẹ́ràn dáadáa (55-56), bi àwọn apànìyàn tí ṣe iṣẹ́ wọn, ifẹ tòótọ́ tí o ní si Kristi mu un kígbe lóhùn rara pé "Oluwa má ka ẹsẹ yii si wọn ní ọ̀run" (ẹsẹ 60; tun ka Luk. 23:34).
vi.  Ìfẹ́ tòótọ́ fún Kristi ni o ru Stefanu soke láti di Kristẹni ajẹrikú àti idalare yiyan an gẹ́gẹ́ bí diakoni. Eyi bakan naa ni o mu kí o ma ka ẹsẹ sì àwọn asekupani rẹ lọrun. Dipo bẹẹ, o tọrọ ìdáríjì fun wọn gẹ́gẹ́ bii Jesu, Olúwa àti Olùgbàlà rẹ. Adura ìdáríjì tòótọ́ yẹn ni o fún ìjọ àti Aposteli Pọ́ọ̀lù ni anfaani, o si ṣílẹ̀kùn ìgbàlà fún ọpọlọpọ.

B.  PỌ́Ọ̀LÙ, AJIHINRERE ÒKÈÈRÈ (2 Kor. 2:4; Filp. 3:1 siwaju; Filimoni).
Nítorí pe nínú ọpọlọpọ wàhálà àti arodun ọkàn mi ni mo ti fi ọpọlọpọ omije kọ̀wé sì yin; ki i ṣe nitori ki a le bá yin nínú jẹ, ṣùgbọ́n kí ẹyin kí o le mọ ìfẹ́ tí mo ní sì yin lọpọlọpọ rẹkọjá (2 Kor. 2:4).
i.  Filipi 3:4-6: Pọ́ọ̀lù ni oore-ọ̀fẹ́ láti ni ipilẹ, orílẹ̀-ede, ipo ti ẹmi, ẹsin, isẹ asejẹun, imọ ẹ̀kọ́, ìṣẹ́ ọwọ abbl. Lotitọ, oun jẹ ọmọ Farisí àti ọmọ igbimọ agba (Sànhẹ́dírìn).
ii.  Ẹsẹ 7-11: Bi oun tilẹ̀ wa lati idile ọlọ́lá, Kin ni o le faa tí òun yoo fi ka gbogbo anfaani sì ofo (ẹsẹ 7,8)? Ifẹ gbígbóná rẹ sì Kristi pẹlu imọ àti agbára rẹ kíkún.
iii. 2 Kor. 2:4: Pọ́ọ̀lù ko fẹ́ràn Ọlọ́run nìkan, o tun fẹ́ràn àwọn ènìyàn Ọlọ́run denunenu. Ibasepọ rẹ pẹlu wọn nínú ọrọ ati isọwọkọwe rẹ ni a ri ìfẹ́ kíkún rẹ si Kristi (wo I Kor. 16:24).
iv. Iwe Filimoni jẹ ẹri kíkún nípa bí o ti fẹ́ràn gbogbo ènìyàn. O pe Filimoni ni olufẹ ọ̀wọ́n (ẹsẹ 1), bẹẹ naa ni o pe Onesimu ẹrú tí o salọ ni ọmọ mi (ẹsẹ 10). Àwọn ọrọ wọnyi n safihan Ibasepọ tí o munadoko láàárín wọn, èyí tí o dalori ìfẹ́ Kristi.
v.  Bi o ti dasi ija (aṣọ) ti o wa laarin Filimoni ati Onesimu, láìṣe alaibọwọ fún ìdáríjì àti imubọsipo fún Onesimu ẹrúkùnrin (ẹsẹ 10 siwaju), le waye lati inu ọkàn ẹni tí o fẹ́ràn Kristi àti àwọn ènìyàn rẹ lotitọ.
vi. Igbona ọkàn àti ìtara tí Pọ́ọ̀lù fi kede Kristi safihan ìfẹ́ rẹ̀ fun Jésù Kristi, ẹni tí o gba a la tí o si fi oore-ọ̀fẹ́ sọ ọ di Aposteli fun àwọn keferi, ko fẹ́ láti ja Ẹni tí o pe e kulẹ. Nítorí naa, o gbe ìtara àti ìgbóná ọkàn tí o fi ṣe inúnibíni sí ìjọ wọ láti ṣíṣẹ fún Kristi. Eyi ni ẹmi ajihinrere tòótọ́.

ÀWỌN Ẹ̀KỌ́ TI A RÍ KỌ
1.  Ipele ìfẹ́ rẹ̀ fún Kristi ni yoo sọ bí o ti ṣe lè fi ẹ̀mí rẹ wewu, kí o si mu ìhìnrere lọ sí ìpẹ̀kun ayé.
2. Ìfẹ́ fún ìjọ àti ọmọ ìjọ kọọkan yẹ kí ó jẹ ohun àkọ́kọ́ fún Kristẹni kọ̀ọ̀kan.

ÀWỌN ÌBÉÈRÈ
1.  Bawo ni ikú Stefanu ṣe safihan ìfẹ́ rẹ̀ fún Kristi?
2.  Bi ó ba fẹ́ràn Kristi lotitọ, ko si ipo tàbí ohun ini (ara aye) tí o le e jọ ọ loju láti fi silẹ nítorí Kristi àti ìhìnrere Rẹ. Ẹ jọ jiroro.

ÀWỌN ÌDÁHÙN TI A DÁBÀÁ FÚN ÀWỌN ÌBÉÈRÈ :
ÌDÁHÙN SI ÌBÉÈRÈ KÍNNÍ
--   Stefanu jẹ ọkùnrin tí o kún fún ìgbàgbọ́ nínú Ọlọ́run.
--   Nigba ti wọn fi ẹ̀sùn sisọ ọrọ odi sì Ọlọ́run kan an, ko gbìyànjú láti gbéjà ara rẹ bikose ìhìnrere naa.
--   Ifẹ Kristi mu u ṣàlàyé ọrọ Ọlọ́run fún àwọn tí o fẹ ṣekú pa a láti de ọdọ Kristi.
--   Ni oju igbogunti àti inúnibíni o si tun wàásù Kristi nítorí ìfẹ́.
--   Didi ajẹrikú Stefanu sì ilẹkun ìgbàlà fún àwọn ẹlòmíràn láti de ọdọ Kristi.
--   Ko dabi Abẹli àti àwọn miran ti a pá ni ọna aitọ nínú Bíbélì tí ẹ̀jẹ̀ wọn sì n ke fun ẹsan.
--   Stefanu bèèrè fún àánú bii Jésù. Ìyẹn ni ifẹ tòótọ́ fún Kristi.
--   O ku gẹ́gẹ́ bii ajẹrikú nitori ìgbàgbọ́ rẹ nínú Jésù Kristi.

ÌDÁHÙN SI ÌBÉÈRÈ KEJÌ
Bẹẹni, òtítọ́ ni
Ifẹ tòótọ́ fún Jésù yoo mú wa gba A tọkàntọkàn àti leke ohun miran gbogbo. Ko si ohun ti yoo tóbi, ṣe iyebíye, lẹ́wà, wuni, fanimọ́ra julọ láti ka sí asan fun fifẹ́ràn Kristi nìkan. Gbogbo Kristẹni tòótọ́ gbọdọ ṣetán láti fi silẹ àti láti jọ̀wọ́ ohunkóhun nítorí ere ije ìhìnrere.

Eyi ni idanwo ọmọlẹ́yìn tòótọ́.
A gbọ́dọ̀ tẹle àpẹẹrẹ Jésù. Ọga wa ẹni tí o fi ohun gbogbo silẹ ni ọrùn nítorí ìràpadà ènìyàn. Ẹ jẹ ki awa naa ó ma a safarawe Aposteli Pọ́ọ̀lù tí o ka ohun gbogbo sì ofo láti jere Kristi nìkan (I Kor. 11:1) Ìparun jíjẹ Kristẹni lonii ni àwọn onigbagbọ tí wọn ko tii jawọ nínú ilepa wọn fún Ohun tí ayé nítorí àti ní ìmọ̀ Kristi. Ìṣòro wọn jẹ ohun kerere, wọn kò tii mú ìfẹ́ tòótọ́ fún Jésù Olùgbàlà àti Olúwa wọn dagba.

ÀMÚLÒ FÚN IGBE AYÉ ẸNI :
Ẹbi kan ni orílẹ̀-ede America bii ọmọbìnrin kanṣoṣo. Ọmọbìnrin yii fi ara rẹ silẹ láti lọ sí ilé aláwọ̀ dúdú nígbà tí ipe fún wiwaasu ìhìnrere jáde. Àwọn obi rẹ kò faramọ ìpinnu rẹ, nítorí o ti jẹ ọmọbìnrin kanṣoṣo tí wọn bí. Pẹlu pé o ti pinnu láti jáde lọ fún Ọlọ́run ti àwọn òbí rẹ sì kọ, o dubulẹ àìsàn, lẹ́yìn ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọjọ lori pipohunrere ẹkùn àti ìrònú. Idasi Olùsọ-aguntan sì ọrọ naa mú ki awọn òbí rẹ o sọ ìrètí nu lori rẹ wọn si gba a láàyè láti lọ. Ọkàn lára àwọn ọrọ Olùsọ-aguntan naa ni wi pé wọn le pàdánù rẹ bí wọ́n ko ba jẹ ki o lọ. Bi o ti de ilẹ̀ Afrika bayii, oun ni o kọ́kọ́ kú láàrin àwọn ajihinrere òkèèrè naa. Lotitọ o ku, ṣùgbọ́n o dáhùn sì ipe Kristi, o ti fun irúgbìn naa. O san gbèsè naa, èyí tí gbogbo Kristẹni gbọ́dọ̀ ṣetán láti san. Láti maa gbe ni ibi ìtura wá títí láé tàbí láti máa gbé pẹ̀lú Kristi titi láé, ewo ni o lọlá ju nibẹ? A ko le fẹnusọ iye irawọ àti adé tí yoo ni ni ìjọba ọ̀run.

IGUNLẸ
Jésù n wo gbogbo Kristẹni ni gbogbo ibi ìṣẹ́ wọn. O n rí bí a ti faraji tó sì fun Oun ati ìhìnrere. Stefanu àti Pọ́ọ̀lù tí fi àpẹẹrẹ lélẹ̀ fún àwa Kristẹni láti safarawe. A gbọdọ ṣetán láti fi ẹ̀mí wa lélẹ̀ fún Kristi ki a si ṣe gbogbo ohun tí o wa ni ikawọ wa lati wàásù ìhìnrere Kristi. Laiwo ohunkóhun tí yoo na wa, a gbọdọ ṣetán láti fi ẹ̀mí wa rúbọ kí a sì kọ àwọn ibi ìtura àti anfani wa silẹ láti fẹ́ràn Jesu titi de opin ni gbogbo ọna ni adé ayérayé wa fun. Eyi ni ipari ẹ̀kọ́ kọkànlaa.
ÌJỌ ÀPỌ́SÍTÉLÌ KRISTI Ẹ̀KỌ́ ILÉ Ẹ̀KỌ́ ỌJỌ́ ÌSINMI TI December 9, 2018. ISỌRI KẸTA: ÌDÁHÙN ENIYAN SI IFẸ ỌLỌ́RUN NÍNÚ MAJẸMU TUNTUN. ÌJỌ ÀPỌ́SÍTÉLÌ KRISTI  Ẹ̀KỌ́ ILÉ Ẹ̀KỌ́ ỌJỌ́ ÌSINMI TI  December 9, 2018.  ISỌRI KẸTA: ÌDÁHÙN ENIYAN SI IFẸ ỌLỌ́RUN NÍNÚ MAJẸMU TUNTUN. Reviewed by Muyiwa Abodunrin (Muyilight) on December 09, 2018 Rating: 5

No comments:

Powered by Blogger.