OCTOBER 28, 2018. ÌJỌ ÀPỌ́SÍTÉLÌ KRISTI Ẹ̀KỌ́ ILÉ Ẹ̀KỌ́ ỌJỌ́ ÌSINMI. ISỌRI KEJÌ: IFẸ ENIYAN SI ENIYAN : Ẹ̀KỌ́ KẸJỌ ÀWỌN OBÌNRIN NAA FI IFẸ HAN

--> Note :- Are you born again? You are never going to win the battle against the devil if you are not born again. I plead with you to give your life to Jesus today because the longer you stay in sin and remain unsaved, the more hardened your nature becomes against the purpose and the way God wants you to be for His purpose. To give your life to Jesus now, say this prayer: “Father, I come to You in the name of Jesus. I know that I am a sinner and I cannot save myself but Jesus died for me and shed His blood that I might be saved. Today, I accept Jesus as my Lord and Saviour. Jesus, I ask You to come into my heart, be my Lord, wash me with Your blood and make me whole. I believe with my heart and confess with my mouth that Jesus is my Lord. Thank You for saving me. In Jesus' name I pray. Amen.” I congratulate you and welcome you to the family of God if you have sincerely said that prayer. Now you are fit to discover, know and walk in your destiny. Call our helpline on +2348037252124, Join Our Daily Whatsapp Devotionals Group : +2347033046607 for Daily Devotionals, crucial discipleship and counselling.s"
OCTOBER 28, 2018. ÌJỌ ÀPỌ́SÍTÉLÌ KRISTI  Ẹ̀KỌ́ ILÉ Ẹ̀KỌ́ ỌJỌ́ ÌSINMI.  ISỌRI KEJÌ: IFẸ ENIYAN SI ENIYAN : Ẹ̀KỌ́ KẸJỌ  ÀWỌN OBÌNRIN NAA FI IFẸ HAN



ÌJỌ ÀPỌ́SÍTÉLÌ KRISTI
Ẹ̀KỌ́ ILÉ Ẹ̀KỌ́ ỌJỌ́ ÌSINMI.
ISỌRI KEJÌ: IFẸ ENIYAN SI ENIYAN.
OCTOBER 28, 2018.

Ẹ̀KỌ́ KẸJỌ
ÀWỌN OBÌNRIN NAA FI IFẸ HAN

Rutu gbé ìrora tìrẹ sẹgbẹ kan láti tu iya ọkọ rẹ Naomi, ti ọfọ ṣẹ bi oun naa nínú. Ìfẹ́ tòótọ́ a maa fi àwọn ẹlòmíràn ṣáájú nínú irú àwọn iṣẹlẹ bẹẹ.


AKỌSÓRÍ
Rutu sì wí pé, mase rọ mi láti fi ọ silẹ, tàbí láti padà kúrò lẹyin rẹ nítorí ibi tí ìwọ bá lọ ní èmi o lọ, ibi tí ìwọ bá sì wọ ni èmi o wọ, àwọn ènìyàn rẹ ni yoo maa jẹ ènìyàn mi, Ọlọ́run rẹ ni yoo si maa ṣe Ọlọ́run mi (Rutu 1:16).

ÀLÀYÉ KÚKÚRÚ
Ifẹ oníwà-bí-Ọlọ́run ti o si jẹ òtítọ́ maa n wa ire, ìtura àti igbayegbadun àwọn ẹlòmíràn (Juda 21). Iru ifẹ Kristi yii farahàn, o si di riri nínú ayé Rutu ara Moabu obìnrin tí o pinnu láti fi òtítọ́ àti òdodo fẹ́ràn àti láti dúró tì ìyá ọkọ rẹ, ẹni tí o bá ara rẹ nínú iṣẹlẹ tí o n fa iporuuru ọkàn àti ainireti. Rutu tete gbe akoko ìrora àti àìní idunu rẹ sẹgbẹ láti fún Naomi ni ìdánilójú. Esteri ko dúró lórí aawẹ àti àdúrà nìkan, bikose pé o tún dìde láti gbé igbesẹ nípa títọ ọba lọ. O foju rena òfin tí o n wí pé ẹnikẹ́ni ko gbọ́dọ̀ tọ ọba lọ lai ṣe pé ọba ransẹ pe iru ẹni bẹẹ. Gbogbo rẹ nítorí ìfẹ́.

BÍBÉLÌ KÍKÀ FÚN OJOOJUMỌ
Mon.   22:    Abigaili Mọ, Síbẹ̀ O Fẹ́ràn Nábálì (I Sam. 25:2-3a)
Tue.    23:    Ọkọ Abigaili Jẹ Onroro (I Sam. 25:3b)
Wed.   24:    Ọkọ̀ Abigaili Jẹ̀gbádùn Inurere Dafidi (I Sam. 25:4-8)
Thur.  25:     Ọlọ́run Dan Ọkọ Abigaili Wo (I Sam. 25:9)
Fri.     26:      Ọkọ Abigaili Aláìnífẹ́ Kùnà (I Sam. 25:9-13)
Sat.    27:       Ifẹ Abigaili Wa Ọna-Àbáyọ Si Iṣẹlẹ Naa (I Sam. 25:14-26).

ÀṢÀRÒ FÚN ÌFỌKÀNSÌN
1.   Ọlọ́run ti fún àwọn obìnrin ni ọkàn rírọ tí wọn le lo láti fi safihan ìfẹ́ Ọlọ́run ní onírúurú ọna.
2.   Ìfẹ́ oníwà-bí-Ọlọ́run maa n fojúsọ́nà fún ìṣẹ́gun òtítọ́ níkẹyìn, o si n safihan ìpamọ́ra tí o dúró tiiri.

ẸSẸ BÍBÉLÌ FÚN IPILẸ Ẹ̀KỌ́: 2 Àwọn Ọba 4:8-17

ILEPA ATI ÀWỌN ERONGBA
ILEPA:   Láti fi hàn àwọn akẹ́kọ̀ọ́ pé Ọlọ́run n beere pé kí gbogbo ènìyàn o ni ifẹ pẹlu òtítọ́ àti tọkàntọkàn, àti àwọn obìnrin pẹ̀lú.

ÀWỌN ERONGBA: Ni ipari ẹ̀kọ́ yii, a n retí kí àwọn akẹ́kọ̀ọ́ o le:
i.  ní ìfẹ́, laiwo tí ìpalára, ìrora tàbí ìnira;
ii. kọ bí a ti ń fi ẹ̀mí wewu fún wíwà láàyè àwọn ẹlòmíràn,
iii.safihan ìfẹ́ Kristi nígbà tí ó wọ àti nígbà tí ko wọ.

IFAARA
ORÍSUN Ẹ̀KỌ́: RUTU 1:6-19; 2:2,3,11; ESTERI 4;5;7;8.
Afi ogo fún Ọlọ́run fún àwọn ọ̀nà tí O ti gba fi ara Rẹ hàn wá nípasẹ̀ àwọn ẹ̀kọ́ tí ó kọjá. Nínú ọwọ yii, Ọlọ́run ti n lo àwọn ẹ̀kọ́ naa lati safihan ìfẹ́, tòótọ́, àìní-tìtorí àti ti ara, èyí tí Ọlọ́run ń reti tí o sì n beere lọwọ gbogbo igbagbọ tí a n pe mọ orúkọ Rẹ, láti ni ati lati safihan.

Nínú ẹ̀kọ́ keje, ÀWỌN IGBESẸ IFẸ TI O NII ṢE PẸLU DAFIDI, a rí bí Jonatani tí fẹ́ràn Dafidi gidigidi, àti bi Dafidi ṣe padà fi ìfẹ́ hàn sí àwọn ọrẹ àti ọ̀tá rẹ tí o n fẹ́ láti gba ẹ̀mí rẹ. Ọlọ́run ti rán wa lọwọ láti kẹ́kọ̀ọ́ pupọ.

Ẹ̀kọ́ kẹjọ tí de gẹ́gẹ́ bí isiju lórí òtítọ́ naa pé àwọn Obìnrin naa safihan ìfẹ́ ni àwọn ọ̀nà pàtàkì kan, tí a ko le e gbàgbé nínú Bíbélì. Laarin awọn miran a o tún maa sọ̀rọ̀ nípa Rutu onifẹ tí a ko le gbàgbé nínú ìtàn, àti Esteri, nínú ibasepọ wọn ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ àti ní àkókò ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀.

Pẹlu ipò ibanujẹ tí Rutu bá ara rẹ nípa ikú aitọjọ (òjìji) ọkọ, bàbà-ọkọ àti ẹ̀gbọ́n ọkọ rẹ, o kọ láti fi iya ọkọ rẹ silẹ, ẹni tí òun naa ni ibanujẹ àti iporuuru ọkàn bii Rutu. O dúró tì í títí dé òpin.

Bákan naa, Esteri ko fàṣẹyín nínú ìfẹ́ rẹ̀ fún àwọn juu àwọn ẹni tí ó wà nínú ipò ainireti tí ìsìnrú. O pinnu láti jọ̀wọ́ ẹ̀mí rẹ pàápàá, fún wọn, o si yọrí sí fífi ẹ̀mí rẹ wewu kọjá ààlà láti Fọwọsowọ́pọ̀ pẹ̀lú Yaweh láti gba àwọn ènìyàn naa là kúrò nínú ìdè (ìgbèkùn) Hamani àti àwọn ẹlẹgbẹ rẹ.

Bi a ti n ṣàgbéyẹ̀wò ẹ̀kọ́ yii, a o ni òye tí o dara nípa ìfẹ́ tí Ọlọ́run ń retí láti ọ̀dọ̀ wá ní orúkọ Jésù. Àmín.

IFAARA SI ÌPÍN KỌ̀Ọ̀KAN:
A pín ẹ̀kọ́ yii si abala meji, I àti II a sì pín ọ̀kọ̀ọ̀kan sì A àti B.

ÌPÍN KÍNNÍ: RUTU FẸ́RÀN NAOMI TỌKÀNTỌKÀN
Ipin yii ni a ni lọ́kàn láti safihan ìfẹ́ tòótọ́ tí ko ni tìtorí, ìwà-bí-Ọlọ́run àìsí ìnira àti òtítọ́ tí Rutu fihan sì Naomi iya ọkọ rẹ, Naomi fi tọkàn-tọkàn safihan ìfẹ́ kódà nígbà tí ó farahàn gbangba pé ó wà ní ipò kan naa (ipo ọfọ) pẹlu Naomi. O pa ẹdun rẹ tí láti tu Naomi nínú. Ìyẹn ni ifẹ òtítọ́ tí o ga julọ.

ÌPÍN KEJÌ:  ESTERI LA EWU PUPỌ KỌJÁ NÍTORÍ ÀWỌN JUU
Ipin yii safihan bí Esteri tí fẹ́ ẹ̀mí àwọn Juu ju ti ara rẹ lọ. Bi o ti lẹ jẹ pé o mọ ewu naa ati awọn àbájáde rẹ (ikú) tí o n dúró de ẹnikẹ́ni tí o bá farahàn níwájú ọba ní irú àkókò líle bẹẹ, ṣùgbọ́n o tẹsiwaju nítorí àwọn ènìyàn rẹ.

KOKO Ẹ̀KỌ́
I.    RUTU FẸ́RÀN NAOMI TỌKÀNTỌKÀN
     A.  KÒ KỌ (FI) NAOMI SILẸ
     B.  O ṢE GBOGBO RẸ NIT'ORI IFẸ

II.  ESTERI LA EWU PUPỌ KỌJÁ NÍTORÍ ÀWỌN JUU
    A. O FI Ẹ̀MÍ RẸ WEWU FÚN ÀWỌN JUU
    B. O DIDE LATI JA FUN ÀWỌN ENIYAN NAA.

ITUPALẸ Ẹ̀KỌ́
RUTU FẸ́RÀN NAOMI TỌKÀNTỌKÀN (Rutu 1:6-19;2:2,3,11).
Rutu jẹwọ́ ifaraji rẹ fún Naomi nípa yiyi idanimọ àti asa rẹ padà nítorí ìfẹ́ láti dúró tì Naomi níkẹyìn.

A.   KO KỌ (FI) NAOMI SILẸ (1:6-19).
Bẹẹni àwọn méjèèjì lọ títí wọn fi de Bẹ́tílẹ́hẹ́mù (ẹsẹ 19a).
i.   Ẹsẹ 6-9: Naomi (Adùn; Ayọ, tabi daradara) ti bá ara rẹ nínú iṣẹlẹ tí ko ladun tí o sì n gbéni lọ́kàn-sókè ní Moabu (ẹsẹ 1-5). Nítorí naa, o pinnu láti padà sí Bẹ́tílẹ́hẹ́mù, ṣùgbọ́n o yàn láti má mú àwọn ìyáwo àwọn ọmọ rẹ lọ, kí wọn lé dúró síbẹ̀, láti bẹ̀rẹ̀ ayé wọn lọtun nínú ìdílé miran (ẹsẹ 9) ẹdun ọkàn rẹ fún àwọn ọ̀dọ́bìnrin naa (wo ẹsẹ 13).
ii.   Ẹsẹ 10-13: Àti Rutu àti Orpa ni o safihan ìfẹ́ ọkàn wọn láti tẹle ìyá ọkọ wọn tí ọfọ ṣẹ, bii pé àwọn méjèèjì ní ó fẹ́ràn rẹ (ẹsẹ 10). Ṣùgbọ́n Ọlọ́run jẹ ki a dán òtítọ́ wọn wo (ẹsẹ 11-13). N jẹ o da ọ loju wí pé ìfẹ́ tí o jẹwọ pé ó ní fún aya tàbí ọkọ àwọn ọmọ, isẹ, ìjọ rẹ abbl kò nii forísọpọn nígbà tí àti bí a ba dan an wo? (I Jhn. 3:18,19).
iii. Ẹsẹ 14-18: Orpa alaini afojusun (ìran) naa kuna (ẹsẹ 14) nígbà tí Rutu onifẹ tòótọ́ naa ṣàṣeyọrí nínú idanwo ìfẹ́ naa, bí o ti rọ mọ ìyá ọkọ rẹ. Ìdáhùn Rutu ni ẹsẹ 16,17 kii ṣe ìdáhùn orí ahọn lásán, bíkose pé o wa lati ọkàn tí ó ti pinnu tí ó sì ti setan (wo ẹsẹ 18).
iv. Ẹsẹ 19: Ìpinnu rẹ láti mase kọ Naomi silẹ ni a rí nínú bí o ti fi ìrora tẹle Naomi pada lọ sí Juda, ti yoo gba àwọn méjèèjì ní ọjọ́ méje sì mẹwa láti fẹ́ṣẹ̀ rìn debẹ, pẹ̀lú ọgbọ́n sì ọgọ́ta maili, o dalori ibi tí wọ́n ba gba.
v.  Rutu ṣe ìpinnu tó lé gẹ́gẹ́ bí ọdọbinrin lairo tí wiwa (gbígbé) gẹ́gẹ́ bí ẹni tí ko lọkọ láwùjọ tí o buyi fún ìgbéyàwó ju wíwà lai lọkọ tàbí láyà lọ.

B.   O ṢE GBOGBO RẸ NÍTORÍ IFẸ (2:2,3,11).
Boasi sì dá a lóhùn, ó wí fún un pé, gbogbo ohun tí ìwọ ṣe fún ìyá-ọkọ rẹ láti ìgbà ikú ọkọ rẹ, ní o ti ro fún mi pátápátá, àti ní ìwọ ti fi bàbà àti ìyá rẹ àti ilẹ̀ ibi rẹ silẹ, tí o sì wá sọ́dọ̀ àwọn ènìyàn tí ìwọ mọ ri (ẹsẹ 11).
i.   Ẹsẹ 2-3: Orúkọ ara Moabu naa 'Rutu' fúnrarẹ túmọ̀ sí 'ibanirẹ'. N jẹ orúkọ naa ko maa ṣíṣẹ fún un? Ibanirẹ naa farahàn gbangba nínú bí Rutu tí ronú láti lọ ṣíṣẹ fún wíwà láàyè àwọn méjèèjì.
ii.  Ẹsẹ 11:  Àwọn ọ̀rọ̀ ìyìn Bóásì jẹ ìkẹkun daradara fún ipele tí Rutu tí safihan Ibanirẹ naa de. Kin ni idi ti o fi yẹ kí o ṣe gbogbo èyí?
iii. Rutu kun fún ìfẹ́ òtítọ́ fún Naomi àti Ọlọ́run rẹ, gẹgẹ bí Ábúráhámù tí yàn láti fẹ́ àti tẹle Yaweh kan naa ti o fẹrẹ ẹ jẹ pé kò mọ ohunkóhun nípa Rẹ nítorí ó fẹ́ràn Rẹ (Gen. 12:1 siwaju).
iv.  Ronu nípa ìrírí rẹ nígbà tí ó sọ àwọn ọrọ ti o sọ ní 1:16-17. Kin ni ìdí tí o fi yẹ kí o yàn láti tẹle Naomi alainireti, pẹ̀lú àìsí ọmọkùnrin láti ọ̀dọ̀ rẹ tí ó lè fẹ́ Rutu ni ọjọ́ iwájú? Bi o bá ti lẹ jẹ pé o wa, báwo ni yoo ti dúró pẹ̀ tó láti fẹ ẹ?
v.  Kosi ohun kan tí ó ń mú iná ìpinnu rẹ jo gidigidi bíkose ìfẹ́ tí ó ní sì Náómì àti Ọlọ́run rẹ. Bí o bá fẹ́ràn Ọlọ́run nitòótọ́, o ko le sai ríran àwọn tí o wà nínú ìyọnu, pẹ̀lú ipò tìrẹ paapaa (I Jhn. 3:1 siwaju).
iv. O ko le gba omi tí ó ti dànù jọ. Ní ti Rutu; ohun àtijọ́ tí kọjá lọ, ó sì pinnu láti ṣàwárí ọjọ iwájú tí ó dara fún ara rẹ àti ìyá-ọkọ rẹ.

ÀWỌN Ẹ̀KỌ́ TI A RÍ KỌ
1.   Kíkọ àwọn tí o yẹ ki a fẹ́ràn silẹ ni akoko ìṣòro jẹ́ isafihan àìní ìfẹ́ Kristi nínú wa.
2.  Ìgbà tí a ṣe àwọn ohun tí a fẹ ṣe nínú ìfẹ́ Kristi nìkan ni wọn ṣe ìtẹ́wọ́gbà sì Ọlọ́run Onifẹ́.

ÌṢẸ ṢÍṢE
Rutu pinnu láti tẹle Naomi pẹ̀lú òtítọ́ ọkàn àti òdodo. Báwo ni ó ṣe lè sakawe isafihan ìfẹ́ Rutu pẹ̀lú bí àwọn Kristẹni ṣe n ní ibasepọ pẹ̀lú Ọlọ́run àti ọjọ́ kọọkan?

ÌDÁHÙN TI A DÁBÀÁ FÚN IṢẸ́ ṢÍṢE
Àwọn Kristẹni kò ní ibasepọ pẹ̀lú Ọlọ́run àti àwọn ẹlòmíràn lonii bí Rutu tí ni ibasepọ pẹ̀lú Naomi nítorí:Ìfẹ́ tí àwọn Kristẹni n safihan lonii ni:
i.   Ìfẹ́ tí ó ní tìtorí nínú (fún mi kí n fún ọ)
ii.  Ìfẹ́ tí kò ní òtítọ́ nínú
iii. Ìfẹ́ tí kò ní ìtara nínú
iv. Ìfẹ́kufẹ
    *     Àwọn ènìyàn maa n ní ibasepọ pẹ̀lú Ọlọ́run lonii lojunna àti gba ìbùkún, ìwòsàn ààbò, ìpèsè àtọ̀runwá abbl.
    *    Si àwọn ará wọn, wọn fẹ láti gba owo, oúnjẹ, iranlọwọ tàbí àtilẹhin fún imọtara-ẹni-nikan àti ère, í tẹ-ara-ẹni-lọrun àti Ìfẹ́kufẹ abbl.
OCTOBER 28, 2018. ÌJỌ ÀPỌ́SÍTÉLÌ KRISTI Ẹ̀KỌ́ ILÉ Ẹ̀KỌ́ ỌJỌ́ ÌSINMI. ISỌRI KEJÌ: IFẸ ENIYAN SI ENIYAN : Ẹ̀KỌ́ KẸJỌ ÀWỌN OBÌNRIN NAA FI IFẸ HAN OCTOBER 28, 2018. ÌJỌ ÀPỌ́SÍTÉLÌ KRISTI  Ẹ̀KỌ́ ILÉ Ẹ̀KỌ́ ỌJỌ́ ÌSINMI.  ISỌRI KEJÌ: IFẸ ENIYAN SI ENIYAN : Ẹ̀KỌ́ KẸJỌ  ÀWỌN OBÌNRIN NAA FI IFẸ HAN Reviewed by Muyiwa Abodunrin (Muyilight) on October 28, 2018 Rating: 5

No comments:

Powered by Blogger.