ÌJỌ ÀPỌ́SÍTÉLÌ KRISTI ISỌRI KÍNNÍ: IFẸ ENIYAN SI ỌLỌ́RUN Ẹ̀KỌ́ KÍNNÍ. ÀWỌN BABA NLÁ WA FẸ́RÀN ỌLỌ́RUN TỌKÀNTỌKÀN.

--> Note :- Are you born again? You are never going to win the battle against the devil if you are not born again. I plead with you to give your life to Jesus today because the longer you stay in sin and remain unsaved, the more hardened your nature becomes against the purpose and the way God wants you to be for His purpose. To give your life to Jesus now, say this prayer: “Father, I come to You in the name of Jesus. I know that I am a sinner and I cannot save myself but Jesus died for me and shed His blood that I might be saved. Today, I accept Jesus as my Lord and Saviour. Jesus, I ask You to come into my heart, be my Lord, wash me with Your blood and make me whole. I believe with my heart and confess with my mouth that Jesus is my Lord. Thank You for saving me. In Jesus' name I pray. Amen.” I congratulate you and welcome you to the family of God if you have sincerely said that prayer. Now you are fit to discover, know and walk in your destiny. Call our helpline on +2348037252124, Join Our Daily Whatsapp Devotionals Group : +2347033046607 for Daily Devotionals, crucial discipleship and counselling.s"
ÌJỌ ÀPỌ́SÍTÉLÌ KRISTI ISỌRI KÍNNÍ: IFẸ ENIYAN SI ỌLỌ́RUN Ẹ̀KỌ́ KÍNNÍ.
ÀWỌN BABA NLÁ WA FẸ́RÀN ỌLỌ́RUN TỌKÀNTỌKÀN.



ÌPÍN KEJÌ.
29 July, 2018 | II. LẸYIN IKUN OMI: ÀPẸẸRẸ ÁBÚRÁHÁMÙ (Gen. 12:1-3; 22:1-19).
Àṣẹhinwa-asẹhinbọ lori ijakulẹ eniyan ni ìbẹ̀rẹ̀ pẹpẹ ẹda eniyan lori ayé, Ọlọ́run pe olúkúlùkù jáde. Opa ìran naa ti sẹgbẹ kan, O si pe ọkùnrin kan, Abraham, ẹni tí yoo di baba orílẹ̀ èdè Hébérù. Bí o tẹle Ọlọ́run pẹlu ìgbọràn àti ifẹ rẹ ti a danwo, ti a si ri i ni òtítọ́, ni a o tu yẹbẹyẹbẹ ninu ẹ̀kọ́ yii.


A.   Ó FI ÌGBỌRÀN TẸLE ỌLỌ́RUN (Gen. 12:1-3).
Bẹẹ ni Abramu lọ, bi Oluwa ti sọ fun un; Lọti si baa lọ. Abraham si jẹ ẹni arundinlọgọrin ọdun nigba ti o jade ni Harani (Gen. 12:4).
i.    O yẹ ki ikun omi ti gba gbogbo ẹsẹ lọ kuro ni laye, ṣùgbọ́n Noa pẹlu siwahu lẹyin ti o ti ni iriri agbayanu pẹlu Ọlọ́run (Gen. 9:20-22).
ii.   Isọ̀tẹ̀ n tẹsiwaju bi a ti ri ninu Genesisi ori kọkànlá, eyi ti o yọrísí kíkọ ile Isọ Babeli. Isọ̀tẹ̀ eniyan ko le mu ifẹ Ọlọ́run ti ko tọ si wa kuro. O yan lati bẹ̀rẹ̀ pẹlu Abramu (Gen. 11:1-4; Ise. 7:1-8).
iii.   Abramu ti o wa lati idile keferi ri oore-ọ̀fẹ́ Ọlọ́run gba, Ọlọ́run si pe fun iriri àgbàyanu àti ibasepọ ọtun lẹyin ìkún omi (Gen. 12:1-3). O gbọ ohun Ọlọ́run, o si ri oore-ọ̀fẹ́ ìjọwọ ara ẹni àti ìgbọràn gba. Ko si ohun ti o satilẹyin fun idahun rẹ ti o tọ naa, ayafi ifẹ rẹ si Ọlọ́run Alààyè ni ọna ara ẹni ti o see fojuri (kiise òrìṣà àwọn baba rẹ, ṣùgbọ́n Ọlọ́run Alààyè nìkanṣoṣo).
iv.  O yan lati tẹle Ọlọ́run (Gen. 12 :4) laika sisọ ipo rẹ nu, aini ìdánilójú ọlá, asitumọ lati ọdọ ẹbi rẹ, aìrọmọbi abbl (Heb. 11:8). O yan lati gbọ́ràn, ki o si fẹ́ràn Ọlọ́run. O safihan eyi ni onírúurú ọna. A n sọ̀rọ̀ pupọ, a si n gbe igbesẹ niwọnba. Se òtítọ́ ni a tilẹ jẹ irú ọmọ Abrahamu (Gal. 3:29)?
v.   Ẹ jẹ ki a safihan ifẹ ati igbagbọ wa nipa àwọn igbesẹ rere ati irẹlẹ (1 Jhn. 3:18). Igbesẹ àkọ́kọ́ ni yiyan lati tẹle E laisi àní-àní.
vi.  Kò tilẹ ṣáko lọ, bẹẹ ni ko gba lati jẹ ki oju ti àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ.

B.   A DAN IFẸ RẸ WO (Gen. 22:1-19).
O si se lẹyin nnkan wọnyi ni Ọlọ́run dan Abrahamu wo, O si wi fun un pe, Abrahamu, oun si dahun pe "Emi niyi" (Gen. 22:1).
i.    Orúkọ rẹ tẹ́lẹ̀ ni Abramu nigba ti a pe e, ṣùgbọ́n, o ti di Abrahamu bayii. Yiyi orúkọ padà túmọ̀ sí pipọ sii, fifẹ sii, sisọ di pupọ, eyi ti Ọlọ́run ọrun ṣe fúnrarẹ, nítorí oore-ọ̀fẹ́ Rẹ pẹlu ifẹ ati ìgbọràn nínu ìṣe ti Abrahamu safihan wọn (Gen. 17:1-8).
ii.   Abrahamu ti safihan ifẹ rẹ si Ọlọ́run ni ọpọlọpọ igba nipasẹ awọn igbesẹ rẹ (kiise ọrọ ẹnu lasan).
iii.   Òtítọ́ ati ododo rẹ si Sara fun ọpọlọpọ ọdun, tii di igba ti Sara dabaa ti o jẹ mọ asa. Tẹtisì Abrahamu bi o ti ba Ọlọ́run sọ̀rọ̀ (Gen. 21:8-14).
iv.   Sisan idamẹwa fun àlùfáà Ọlọ́run laisi mimuni ni dandan tabi ìtànjẹ jẹ sisafihan ifẹ si Ọlọ́run (Gen. 14:18-20), ṣàgbéyẹ̀wò igbagbọ Abrahamu ninu ipese Ọlọ́run.
v.   Gen. 22:1-4. O ti duro fun ọpọlọpọ ọdun ki o to ri Isaaki ti o túmọ̀si Ẹrin gba. O gba ìtọ́ni lati ọdọ Sara (pẹlu ìfọwọsi Ọlọ́run) lati le Ismaeli jade. N jẹ Ọlọ́run tii tẹ́wọ́gba ẹbọ (ìrúbọ) ti a pese pẹlu ẹran ara ènìyàn ri bi? Ṣùgbọ́n o gbọ bi Ọlọ́run ti sọ̀rọ̀, Oun si setan lati gbọ́ràn ----- Ifẹ ninu ise. Abajade rẹ ni a sọ ketekete ni ẹsẹ Kejìlá.
vi.   Ẹ jẹ ki a huwa bi ọmọ Ọlọ́run àti iru ọmọ Abrahamu ifẹ ninu ise (Gal. 3:29).
vii.  Ifẹ ni ohun àkọ́kọ́ fun ìgbọràn; Abrahamu gbọ́ràn si àwọn ìtọ́ni Ọlọ́run Ẹni tí o gbẹkẹle.

ÀWỌN Ẹ̀KỌ́ TÍ A RÍ KỌ
1.   Ìpínlẹ̀ aini Ọlọ́run àti ti ibọrisa, laifi ti Abrahamu se; o gbọ ohun Ọlọ́run, o si pinnu pátápátá lati tẹle Ọlọ́run ninu ìgbọràn àti ìgbàgbọ́ kikun.
2. Abrahamu jẹ alafojuri. Baba ìgbàgbọ́ ṣàgbéyẹ̀wò ìgbọràn rẹ si Ọlọ́run, ifẹ si Lọti, ẹ̀bùn fun Melikisédékì. Isotitọ si Sara igbona ọkan fun aabo ati ipese fun Isaaki abbl. N jẹ a ní ipenija?

ÀWỌN ÌBÉÈRÈ
1.   Bawo ni o se ro pe a le borí iru iriri Noa ninu Gen. 9:20-22?
2.   Ọlọ́run dan Abrahamu wo, n jẹ O ti n dan awọn ọmọ Rẹ wo lonii?

ÀMÚLÒ FÚN ÌGBÉ AYÉ ẸNI
Lẹ́yìn ìṣubú, Ọlọ́run fún ayé ni ìbẹ̀rẹ̀ ọtun ṣùgbọ́n lai pẹ iwa buburu ènìyàn gbilẹ kan, titi o fi ku àní ọkùnrin olódodo kan, Noa. Lẹ́yìn-ó-rẹyìn, Ọlọ́run pín olódodo àti àwọn ènìyàn ẹni buburu niya.

Ọlọrun tun pe ọkùnrin kan jáde laarin awọn eniyan rẹ láti bẹ̀rẹ̀ igbesẹ lori orílẹ̀ ede kan ti a yan.

Noa àti Abrahamu ni Ifẹ Ọlọ́run, wọn si fi sí ìṣe níwájú Rẹ. Ìbùkún agbọn gbẹ àti àṣeyọrí n dúró de ẹnikẹ́ni ti o ba fẹ Ọlọ́run ní tòótọ́ ti o si n se e ninu ìgbàgbọ́ níwájú Rẹ.

Read Previous CAC Sunday School Manuals The Yoruba Version

IGUNLẸ
A ba lọ lati a ba bọ, Ọlọ́run ti fi oore ọ̀fẹ́ mú wá de òpin ẹ̀kọ́ Kin-ni. Ohun ti a tẹnumọ naa ni ifẹ fun Ọlọ́run àti ìgbàgbọ́ ninu Rẹ. Bi a ba le pa àwọn ìdiwọ̀ gbogbo ti sapa kan ki a si gbagbọ pe lóòótọ́, Jesu ṣe e gbẹkẹle, a o ni anfaani lati ni iwa ọrun méjèèjì wọnyi, a o si le maa se amulo wọn.
ÌJỌ ÀPỌ́SÍTÉLÌ KRISTI ISỌRI KÍNNÍ: IFẸ ENIYAN SI ỌLỌ́RUN Ẹ̀KỌ́ KÍNNÍ. ÀWỌN BABA NLÁ WA FẸ́RÀN ỌLỌ́RUN TỌKÀNTỌKÀN. ÌJỌ ÀPỌ́SÍTÉLÌ KRISTI ISỌRI KÍNNÍ: IFẸ ENIYAN SI ỌLỌ́RUN Ẹ̀KỌ́ KÍNNÍ.  ÀWỌN BABA NLÁ WA FẸ́RÀN ỌLỌ́RUN TỌKÀNTỌKÀN. Reviewed by Muyiwa Abodunrin (Muyilight) on July 29, 2018 Rating: 5

No comments:

Powered by Blogger.